Àwọn adarí ní Naijiria kò nílò láti lọ sí òkè òkun fún ìwòsàn- Aisha Buhari

Oríṣun àwòrán, Aisha Buhari/Twitter
Iyawo aarẹ orilẹede Naijiria, Aisha Buhari ni ko yẹ ki awọn adari ni Naijria maa lọ si oke okun fun ayẹwo ati itọju ara wọn.
Aisha Buhari sọ eyi lasiko ti wọn n se ifilọlẹ ile iwosan ninu ileeṣẹ aarẹ ni ilu Abuja, ni Naijiria.
Iyawo aarẹ Buhari naa ni ọdun mẹfa sẹyin ni oun ti gbero lati da ilewosan naa silẹ lati bii ọdun mẹfa sẹyin.
O ni asiko naa ni ọkọ rẹ lo ọpọlọpọ igba ni oke okun fun ilera ara rẹ ti o ku diẹ kaato fun.
Aisha ni nibayii ni wọn ti kọ ileewosan naa tan, awọn adari ni Naijiria ati mọlẹbi wọn ko nilo lati lọ si oke okun fun iwosan.
Amọ o ni wọn nilo dokita to kunjuwọn ni awọn ileewosan naa ni Naijiria.
Eyi n waye lasiko ti awọn dokita lorilẹede Naijiria gunle iyanṣẹlodi lati lori owo osu wọn ti ko gbe ppẹẹli rara si oke.








