Gbogbo akẹ́kọ̀ọ́ Nàìjíríà tí ogun lé ní Sudan láti dá padà sílé-NIDCOM
Isi ikẹẹdogun awọn akẹkọọ ọmọ Naijiria ti ogun le kuro ni Sudan ti pada sile.
Pẹlu igbesẹ yi,gbogbo awọn akẹkọọ Naijiria ti wọn gbe lati papakọ ofurufu Egypt pada sile ni wọn ti ko tan bayii.
Bẹẹ ni Abike Dabiri Erewa to jẹ ọga agba ajọ Naijiria to n risi ọrọ ọmọ ilẹ Naijiria nilẹ okere ti ṣe kede loju opo Twitter rẹ.
Dabiri sọ pe awọn akẹkọọ 147 to gbera lati papakọ ofurufu Port Sudan balẹ si papakọ ofurufu Nnamdi Azikwe,Abuja, ni nkan bi ago mẹjọ abọ alẹ ọjọ Abamẹta.
''Ni paapa gbogbo awọn akẹkọọ wa lo ti dari pada sile bayii''
Lapapọ ajọ naa sọ pe awọn ti ribi gbe awọn ọmọ Naijiria 2,518 pada sile.
Bẹẹ ni wọn fi kun pe ko si ẹmi eeyan kankan to padanu lasiko ti wọn n gbe wọn pada sile.
A ko le fidi rẹ mulẹ wi pe gbogbo ọmọ Naijiria ti ogun le ni Sudan lo pada sile bayii nitori ọpọ ni ko gba ọna ti Egypt sa asala tori ogun Sudan.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post












