Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Àwọn àwòrán tó làmìlaaka níbi ìwúyè Ọba Charles III
Oríṣun àwòrán, PA MEDIA
Oríṣun àwòrán, PA
Oríṣun àwòrán, JONATHAN BRADY / PA MEDIA
Oríṣun àwòrán, JONATHAN BRADY / PA MEDIA
Oríṣun àwòrán, YUI MOK / POOL
Oríṣun àwòrán, YUI MOK / POOL
Àkọlé àwòrán, Aṣòfin Penny Mordaunt gbe idà ti wọn ṣe ni ọ̀ṣọ́ lé Ọba Charles lọwọ
Oríṣun àwòrán, JONATHAN BRADY / PA MEDIA
Àkọlé àwòrán, Asiko yii ni wọn gbe ade le ayaba Camilla lori
Oríṣun àwòrán, ANDREW MATTHEWS / POOL
Àwọn èèyàn kan ṣe ìwọ́de tako fífi Ọba jẹ
Ko din ni eeyan
bi ọọdunrun, to ṣe iwọde niluu Cardiff, tako iyansipo Ọba Charles.
Nibi iwọde naa ni
awọn kan lara wọn ti gbe akọle dani pẹlu akori “Not Our King” (Kii ṣe ọba wa).
Ẹnikan lara awọn
oluwọde naa, Bethan Sayed, to ti fi igba kan jẹ oloṣelu, sọ pe “owo ti wọn naa
si ori ayẹyẹ iwuye naa ti pọ ju, paapaa niru asiko ti ọpọ eeyan ko ri owo naa
ni UK”.
Arabinrin Sayed
ni iyalẹnu ni ayẹyẹ to n ṣẹlẹ niluu London jẹ́.
Bakan naa lo sọ
pe awọn ṣe iwọde ni ọjọ ti Ọba Charles gba ade, lati fi ṣe ilanilọyẹ fun awọn ọdọ
nipa ijọba awaarawa.
“Ọba jijẹ kii ṣi
ijọba awaarawa.”
Wọ́n ti gbé adé lé Ọba Charles lórí ní Westminster Abbey
Oríṣun àwòrán, Reuters
Ọba Charles ati aya rẹ ti pada si aafin Buckingham Palace.
Lati ọdun 1903, lasiko ti Edward VII fi jẹ ọba, lo ti di aṣa pe ki ori ade tuntun, ki awọn eero lati gbagede Buckingham Palace.
Kẹkẹ ti wọn fi goolu ṣe lo gbe wọn pada si aafin, lẹyin ti Ọba Charles gba ade.
Oríṣun àwòrán, Reuters
Oríṣun àwòrán, Reuters
Oríṣun àwòrán, Reuters
Ìràn Yorùbá tó n tun ayé ṣe náà ba Oba Charles kẹta yọ ayọ ìgbadé pé à[sikò rẹ yóò tu agbáyé lára
Ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀ kìí bá
wọn re òde ìbànújẹ́....
Gbogbo ọmọ Yoruba
káàkiri àgbáyé kò ni fojú sunkún lásìkò Oba Charles kẹta tó n jẹ lónìí
Àkọlé àwòrán, Ìràn Yorùbá tó n tun ayé ṣe náà ba Oba Charles kẹta yọ ayọ ìgbadé pé à[sikò rẹ yóò tu agbáyé lára
Àkọlé àwòrán, Ìràn Yorùbá tó n tun ayé ṣe náà ba Oba Charles kẹta yọ ayọ ìgbadé pé à[sikò rẹ yóò tu agbáyé lára
Àkọlé àwòrán, Kò sí ibi kí àwọn ọmọ Oodua má bá aláyọ̀ yọ̀ níbí tí wọ́n ba wa, àwọn ọmọ Yorùbá tó n tún ayé ṣe kan rèé ni Westminster Abbey ti wọ́nba Oba Charles kẹta yọ ayọ̀ ìgbadé rẹ̀ lónìí
Àkọlé àwòrán, Kò sí ibi kí àwọn ọmọ Oodua má bá aláyọ̀ yọ̀ níbí tí wọ́n ba wa, àwọn ọmọ Yorùbá tó n tún ayé ṣe kan rèé ni Westminster Abbey ti wọ́nba Oba Charles kẹta yọ ayọ̀ ìgbadé rẹ̀ lónìí
Àkọlé àwòrán, Kò sí ibi kí àwọn ọmọ Oodua má bá aláyọ̀ yọ̀ níbí tí wọ́n ba wa, àwọn ọmọ Yorùbá tó n tún ayé ṣe kan rèé ni Westminster Abbey ti wọ́nba Oba Charles kẹta yọ ayọ̀ ìgbadé rẹ̀ lónìí
Àkọlé àwòrán, Kò sí ibi kí àwọn ọmọ Oodua má bá aláyọ̀ yọ̀ níbí tí wọ́n ba wa, àwọn ọmọ Yorùbá tó n tún ayé ṣe kan rèé ni Westminster Abbey ti wọ́nba Oba Charles kẹta yọ ayọ̀ ìgbadé rẹ̀ lónìí
Àkọlé àwòrán, Ojoojúmọ̀ ló máa ń wù mí pé mo jẹ́ ògidì ọmọ Oduduwa níbíkíbi tí orí bá gbé mi lọ...
Àkọlé àwòrán, Ojoojúmọ̀ ló máa ń wù mí pé mo jẹ́ ògidì ọmọ Oduduwa níbíkíbi tí orí bá gbé mi lọ...
Àkọlé àwòrán, Ojoojúmọ̀ ló máa ń wù mí pé mo jẹ́ ògidì ọmọ Oduduwa níbíkíbi tí orí bá gbé mi lọ...
Kí ni Ọba Charles sọ nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tó bá ìlú sọ?
Wo ǹkan mẹ́fà tí o kò mọ́ nípa ìtẹ́ Oba Charles keta
Àkọlé àwòrán, Itẹ Oba Charles keta
Wo àwòrán inú Westminster Abbey níbití Oba Charles keta yóò ti gbàdúrà àṣeyọrí láti tukọ̀ gbogbo eèyàn abẹ́ rẹ̀ lónìí ọjọ́ kéfa, oṣukarun un, ọdun 2023
Àkọlé àwòrán, Ade ti a fi okuta olowo iyebiye diamọọndi ṣe eyi ti Oba Charles yoo máa de lọ sibi pataki lẹyin iwuye oni ọjọ kẹfa, oṣu kẹfa, ọdun 2023
Àkọlé àwòrán, Ọkọ Ayokele olomi goolu ti Oba Charles wo lọ si aafin re lasiko iwuye rẹ ni ọdun 2023
Àkọlé àwòrán, Sibi goolu ti Oba Charles lo to sami ipa pataki ninu itan iran rẹ̀ lasiko iwuye rẹ ni ọdun 2023
Ati agogo goolu ti wọn yoo ti bu ororo si Oba Charles keta lori
Àkọlé àwòrán, Agbelebu ti Oba Charles máa mu dani lasiko iwuye rẹ ni ọdun 2023
‘Mo ti dáríjin ìbátan mi tó da ásíìdì sí mi lára’
Ìjàmbá iná lọ́jà Alaba l'Eko, ará ọjà àti iléeṣẹ́ panápaná tako ara wọn lórí aìráye pa iná náà
Iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria dóòlà akẹ́kọ̀ọ́ Chibok méjì lẹ́yìn ọdún mẹ́sàn án lákàtà Boko Haram
Oríṣun àwòrán, @ZagazOlaMakama
Ileeṣẹ ọmọ ogun Naijiria ti tun ti doola meji ninu awọn akẹkọ ile
ẹkọ girama Chibok ti Bokom Haram ji gbe lọdun mẹsan sẹyin.
Inu oṣu to kọja ni awọn ọmọ ogun doola awọn akẹkọọ ọhun,Esther Marcus ati Hauwa Malta
lagbegbe Lagara, nibi ti awọn ọmọ ogun Boko Haram ti n ṣọṣẹ.
Apapọ iye awọn akẹkọọ ti awọn ọmọ ogun ti doola bayii ti jẹ márùndínláàdóje,
125.
Ọdun 2018 ni Boko Haram funra rẹ kọkọ jọwọ mẹ́tàdínláàdọ́fà,
107, ninu awọn akẹkọọbirin naa, nigba ti awọn ọmọ ogun Naijiria doola
mẹta lọdun 2019, meji lọdun 2021 ati mọkanla lọdun 2022.
Inu oṣu Kẹrin, ọdun 2014 ni Boko Haram ji awọn akẹkọọ ọhun gbe
nile ẹkọ wọn.
Ọpọ eeyna kaakiri agbaye lo si bu ẹnu atẹ lu ijọba Naijiria fun
iṣẹlẹ naa, paapaa bo ṣe kuna lati doola awọn akẹkọọ ọhun.
Naijiria làwọn èèyàn ti ń san owó iná tó kéré jùlọ ní gbogbo àgbáyé – Ìjọba àpapọ̀
Oríṣun àwòrán, ikejaelectric
Ijọba apapọ ti sọ pe Naijiria lawọn eeyan ti n san owo ina mọnamọna
to kere julọ ni gbogbo agbaye.
Minisita abẹle fun ohun amuṣagbara, Abubakar Aliyu, lo sọ bẹẹ nibi
apero kan pẹlu igbimọ ile aṣofin lori ina manọmanọ niluu Abuja.
O ni ogunlọgọ owo ni ijọba n na gẹgẹ bii iranwọ ori ina
mọnamọna, eyii to mu ki awọn araalu maa san iwọmba owo perete fun ina ọhun.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, iye owo ti awọn eeyan n ra ina ijọba ni
Naijiria ko ti iye ti wọn n ra idiyele ina kan naa lawọn orilẹ-ede mii bii Niger
Republic, Benin Republic, Mali, Senegal ati Burkina Faso.
O fi kun pe bo tilẹ jẹ pe ijọba n tiraka ki awọn ọmọ Naijiria le
maa ri ina lo ni gbogbo igba, ọpọ araalu atawọn ileeṣẹ nla-nla ni kii san
owo ina ọhun.
Obìnrin tó gún orogún rẹ̀ tó jẹ́ aláboyún lọ́bẹ pa nílùú Eko dèrò ẹ̀wọ̀n
Oríṣun àwòrán, Pixabay/Succo
Ile ẹjọ giga kan niluu Eko ti paṣẹ ki obinrin ẹni ọdun
mejilelogoji kan lọ logba diẹ ninu ọgba ẹwọn lori ẹsun ipaniyan.
Iroyin ni afurasi ọhun, Fatima Rahman, to jẹ ọmọ orilẹ-ede Chad
Republic, gun iyawo keji ọkọ rẹ pa lagbegbe Ikorodu.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ṣe ni Fatima dibọn bii nọọsi, to si lọ
sile iyawo keji ọkọ rẹ naa ti oyun wa ninu rẹ, ko to gun lọbẹ pa.
Alabagbe oloogbe naa kan lo ri ninu agbara ẹjẹ, ti wọn ti gun ni ori
ati ọrun rẹ.
Bo tilẹ jẹ afurasi naa sọ pe oun ko jẹbi ẹsun ọhun, ile ẹjọ ni
ko lọ simi ninu ọgba ẹwọn Ikoyibi
igbẹjọ naa yoo ṣe maa tẹsiwaju.
Adajọ ile ẹjọ naa, P.E. Nwaka, ti wa sun igbẹjọ ọhun si ọjọ
karundinlọgbọn, oṣu Karun un, ọdun 2023 yii.
Ọwọ́ òfin tẹ ọmọ ọdún mẹ́tàlá tó ṣekúpa èèyàn mẹ́jọ ní Serbia
Ọwọ ọlọpaa ti tẹ ọmọ ọdun
mẹtala kan to ṣekupa akẹkọọ mẹjọ ni Serbia.
Wọn mu ọmọde naa lẹyin iro ibọn
to dun lakọlakọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ Vladislav Ribnikar, to wa ni Belgrade,
nibi ti akẹkọọ mẹfa ati olukọ kan ti farapa.
Ọlọpaa in awọn ṣi n ṣe iwadii
eredi ikọlu ọhun.
Iroyin ni ibọn baba rẹ ni ọmọ naa lo fun ikọlu ọhun, baba rẹ naa
si ti ṣe akọsilẹ awọn ibọn naa lọdọ ijọba ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
A gbọ pe afurasi naa maa n tẹle baba rẹ lọ ibi ti wọn ti n kọ bi wọn
ṣe n yinbọn ṣaaju iṣẹlẹ naa, ọlọpaa si ti fi panpẹ ofin mu baba ati
iyarẹ bayii.
Aarẹ Aleksandar Vucic ti juwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bii eyii to ba oun
ninu jẹ, ati eyii to buru ju ninu itan orilẹ-ede ọhun.
O ni awọn yoo tare ọmọ naa sile iwosan awọn alaarun ọpọlọ fun
ayẹwo nitori wọn ko tii le gbe lọ sile ẹjọ nitori ọjọ ori rẹ.
Iroyin ni afurasi naa ni iwe kan lọwọ, ninu eyii to kọ orukọ awọn
to fẹ ṣekupa si ki ọwọ to tẹ ẹ.
Àwọn olùfẹ̀hónúhàn ya bo ọọ́físì CBN nitóri ọ̀wọ́ngógó owó naira tuntun
Oríṣun àwòrán, Naijra PR
Awọn ọmọ Naijiria kan ti ṣe ifẹhonuhan niwaju ọọfisi banki apapọ
Najiria, CBN, lori ọwọngogo owo naira tuntun.
Awọn eeyan naa ni gomina banki naa, Godwin Emefiele gbọdọ kọwe fi
ipo silẹ, ati pe ijọba gbọdọ fi panpẹ ofin mu alatari inira ti awọn ọmọ
Naijiria la kọja lasiko ọwọngogo owo naira.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, ọpalanba iya lo jẹ awọn ọmọ Naijiria
lasiko ọwọngogo naira naa, ti awọn kan si padanu ẹmi wọn pẹlu.
Wọn ni awọn yoo tẹsiwaju lati maa ṣe ifẹhonuhan naa titi ti gomina
banki ọhun yoo fi ṣe ohun ti awọn n fẹ.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ, ẹni to ko awọn eeyan naa jọ, George
Uboh sọ pe Emefiele gbọdọ ko owo naira tuntun sita ki awọn eeyan le ri owo
ọhun.
Uboh sọ pe eredi ifẹhonuhan awọn ko ṣẹyin idajọ ile ẹjọ to
paṣẹ fun CBN pe o gbọdọ ko owo naira tuntun naa si igboro.
Ẹwẹ, ọpọ araalu ni ko ri owo naira tuntun naa laarin ilu mọ lati igba
ti ile ẹjọ ti sọ pe awọn eeyan ṣi le maa na owo naira atijọ ati owo naira
tuntun naa papọ.
Ẹ̀kún omi ni Rwanda,èèyàn tó le ni ọgọ́rùn ún kú
Iye awọn to ba iṣẹlẹ omiyale lọ ni Rwanda ti le ni ọgọrun gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ti ṣe sọ.
Ileeṣẹ iroyin orileede naa RBA jabọ pe eeyan ọgọrun le mẹsan an lo ti ku bayi.
Ninu wọn la ti ri eeyan marundinlọgọrun lati agbegbe iwọ oorun ti awọn mẹrinla siwa lati agbegbe ariwa.
Ṣaaju,gomina agbegbe iwọ oorun sọ fun BBC pe eeyan aadọta padanu ẹmi wọn lẹyin arọrọda ojo mọjumọ.
''Ọpọ ile lo wo lu awọn eeyan,iye awọn taa ṣi ri bayi jẹ marunlelaadọta ti ọpọ si farapa''
Bẹẹ ni Gomina François Habitegeko ṣe ṣalaye.
O ni awọn oju ọna pataki lagbegbe naa to fi mọ ọna tuntun ti wọn ṣẹ́ṣẹ ṣe to gba ti Lake Kivu ni ko ṣe gba bayii.
O fi kun pe awọn igbiyanju lati doola awọn eeyan ṣi n tẹsiwaju ni awọn igberiko to si ṣeeṣe ki iye awọn to farapa pọ si.
Ajọ to n risi ọrọ bi oju ọjọ ti ṣe ri ti ṣaaju kilọ pe ojo inu oṣu yi yoo peleke.
Oríṣun àwòrán, Rwanda Broadcasting Agency
Àkọlé àwòrán, Ọpọ ile ni omi dawo ti awọn eeyan si padanu ẹmi wọn
Arákùnrin tó lọ pa ẹja dàwátì, inú ọ̀ni ní wọn ti rí òkú rẹ̀
Àkọlé àwòrán, Aworan ọ̀ni
Wọn ti ri oku arakunrin kan to dawati lẹyin toun ati awọn ọrẹ rẹ lọ pẹja ni Australia,
Inu ọ̀ni kan ni wọn ti pada ri oku rẹ.
Lọjọ Abamẹta ni wọn ri arakunrin Kevin Darmody kẹyin lagbegbe Kennedy's Bend.
Aaye yi jẹ ibi kan tawọn ọni pọ si ni ariwa Queensland.
Lẹyin ọjọ meji tawọn agbofinro fimu finlẹ lagbegbe naa, wọn pa awọn ọni nla meji kan ti wọn si ba ajẹku oku eeyan ninu wọn.
Wọn ko ti ribi sọ pato ẹni ti oku yi jẹ ṣugbọn awọn ọlọpaa sọ pe o ṣeni laanu pe iru ikẹyin bayi lo tọ si ẹni ọdun marundinlaadọrin yi.
Apẹja to dantọ ni arakunrin Darmody jẹ ti ọpọ eeyan si mọ ladugbo Cape York.
Lọjọ Aje ni wọn yinbọn pa awọn ọni mejeeiji ọhun lẹba ibi ti wọn ti ri arakunrin Darmody kẹyin.
Wọn ba ageku ẹran ara eeyan ninu awọn ọọni mejeeji ti awọn oṣiṣẹ to n mojuto ẹranko inu igbẹ si ni o ṣeeṣe ki awọn mejeeji mọ nipa iku arakunrin naa.
Ìrírí ìrẹ̀wẹ̀sí ọkàn lẹ́yìn ìbímọ ló jẹ́ kí n pinnu láti ran àwọn obìnrin míì lọ́wọ́
Kìí ṣe ojúṣe ìjọba ni láti pèsè iṣẹ́ fún àwọn aráàlú, ojúṣe àwọn aládàni ni – Femi Adesina
Oríṣun àwòrán, @yabaleftonline
Agbẹnusọ
Aarẹ Muhammadu Buhari, Femi Adesina ti sọ pe kii ṣe ojuṣe ijọba ni lati
pese iṣẹ fun awọn araalu, amọ ijoba le pese awọn ohun to yẹ fun awọn
ileeṣẹ aladani lati pese iṣẹ ọhun.
Adesina
lo sọ ọrọ naa ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Arise lasiko to n
yanana awọn aṣeyọri ijọba Buhari.
Gẹgẹ
bii ohun to sọ, pupọ ninu awọn ileri ti awọn eeyan n sọ pe Buhari ṣe fun
awọn ọmọ Naijiria ni ko ti ẹnu Buhari Buhari funra rẹ jade.
O
ni “Pupọ ninu awọn ileri ti awọn n sọ pe Buhari ṣe lasiko to n dije du ipo
ni ko ti ẹnu oun funra rẹ jade, ohun ti mo ranti ni pe Buhari ni ọpọ araalu
ni ko niṣẹ lọwọ, ko si darukọ iye awọn alainiṣẹ naa ni pato.”
“Amọ
sibẹsibẹ naa, ojuṣe ijọba ni lati pese ayika to rọrun lati ṣiṣẹ ni
Naijiria, kii ṣe ijọba ni yoo pese iṣẹ ọhun.”
“Ohun
ti ijọba yoo ṣe ni lati pese anfaani to rọrun lati ṣiṣe, ọdọ awọn
aladani ni pupọ ninu awọn iṣẹ naa yoo ti wa.”
“Niwọn
igba ti anfaani to rọrun naa ba ti wa, awọn aladani ni yoo pese iṣẹ ọhun.”
Àǹfàní ńlá ni Naijiria kùnà bí Osinbajo ṣe kùnà láti di Ààrẹ – Sanusi
Oríṣun àwòrán, @abati1990
Emir ilu Kano tẹlẹri, Muhammad Sanusi II, ti sọ pe anfani nla ni
Naijiria sọnu bi Ọjọgbọn Yemi Osinbajo ṣe kuna lati di Aarẹ.
Sanusi lo sọ ọrọ naa nibi ifilọlẹ iwe kan ti wọn fi sọri igbakeji
Aarẹ ọhun.
O ni Osinbajo jẹ ọkan lara awọn eeyan to n fẹ ilọsiwaju ati
idagbasoke Naijiria.
Ti ẹ ko ba gbagbe, Osinbajo wa lara awọn to dije ninu idibo abẹnu
ẹgbẹlu oṣelu APC lati du ipo Aarẹ lọdun to kọja amọ o lulẹ ninu idibo
abẹnu naa.
Ọpọ eeyan lo si bu ẹnu atẹ lu igbakeji Aarẹ ọhun pe o dije tako
ẹni to jẹ ọga ati oloore rẹ ninu oṣelu, iyẹn Bola Ahmed Tinubu.
Gomina banki apapọ Naijiria nigba kan ri naa ni “Mo le fọwọ rẹ sọya
pe ifa nla ni Naijiria sọnu bi irufẹ eeyan bii tirẹ ko ṣe si nipo Aarẹ.”
“Amọ mo gbagbọ pe yoo fi ara rẹ jin
lati maa gba ijọba to ba wa lori oye lamọran fun itẹsiwaju Naijiria.”
Ọkọ̀ òfúrufú Air Peace balẹ̀ sí Egypt láti kó àwọn tí ogun lé kùró ní Sudan padà wálé
Oríṣun àwòrán, @flyairpeace
Ọkọ ofurufu akero ti ileẹṣẹ Air Peace ti gbera kuro ni Naijiria
lati lọ ko awọn ọmọ Naijiria to ha si Egypt kuro nibẹ pada wale.
Awọn ọmọ Naijiria naa, ti ọpọ ninu wọn jẹ akẹkọọ ni ogun le kuro ni Sudan ti wọn si lọ si Egypt lati
gba ibẹ wale.
Ninu atẹjade kan ti Air Peace fi lede, o ni nnkan bi aago mẹta ọsan ni
baalu naa gbera kuro niluu Eko lọ si Egypt.
Atẹjada naa ni “Ọkọ ofurufu Boeing 777 wa to ni nọmba idanimọ 5N-BE
gbera kuro ni papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa niluu Eko ni aago mẹta
kọja iṣẹju mẹwaa ọsan oni lọ si Egypt lati lọ ko awọn ọmọ Naijiria ti
ogun le kuro ni Sudan wale.”
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.
End of X post
Ileeṣẹ naa ni yatọ si pe awọn n ṣowo, awọn ko le la oju awọn silẹ ki iya maa jẹ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere lawọn ṣe gbe igbesẹ naa.
Lẹyin naa ni wọn dupẹ lọwọ ijọba apapọ fun akitiyan rẹ lati ko awọn eeyan ọhun kuro ni Egypt.
Ti ẹ ko ba gbagbe, kii ṣe igba akọkọ ree ti ileẹṣẹ Air Peace yoo fi baalu ọfẹ ko awọn ọmọ Naijiri ti iya n jẹ kuro nilẹ okeere pada wale.
Ọpọ awọn araalu lo ti bẹrẹ si n kan sara si ileeṣẹ naa fun akitiyan rẹ.