Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ìròyìn òfegè ni pé BVN yín yóò ''expire'' lẹyìn ọdún mẹwàá -CBN

    Ile ifowopamọ apapọ Naijiria CBN ti ke si araalu pe ki wọn yago fun iroyin to n gbode pe nọmba to n so akoto ikowopamọsi onibara banki pọ,BVN, yoo jọba lẹyin ọdun mẹwaa.

    Oludari eto ibaraẹnisọrọ banki apapọ naa Isa Abdulmumin lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan.

    O ni irọ to jina si ootọ ni ọrọ yi ati pe nọmba yi kii jọba lẹyin igba ti wọn ba ti fun onibara banki kọọkan ni tiẹ.

    Amọ o fi kun alaye rẹ pe awọn ilana kan to so mọ iṣakoso awọn iroyin alabara sọ pe o ṣeeṣe ki alabara banki ṣe atunse ninu awọn iroyin ti wọn fi kalẹ.

    O ni eleyi yoo waye lẹyin tawọn alaṣẹ ba fi ọwọ si.

    Isa sọ pe fun idi eyi ''a rọ awọn alabara banki lati maa ṣamulo nọmba BVN wọn lai si idiwọ kankan titi ayeraye paapa awọn ti banki ti gba iroyin nipa wọn silẹ''

    Inu oṣu keji ọdun 2015 ni ijọba Naijria gbe aṣẹ kalẹ eleyi to sọ di dandan pe ki gbogbo onibara banki ni nọmba idanimọ mọkanla yi fun gbogbo idunadura lori akoto owo wọn.

    CBN ni awọn gbe eto yi kalẹ lati ri pe aabo to peye wa fun owo ọlọdani ati ileeṣẹ to ba wa ni apamọ ile ifowopamọ wọn.

    Pẹlu nọmba yi, awọn ile ifowopamọ yoo le so gbogbo akoto ikowopamọ si ti eeyan ba ni papọ.

    Koda ko jẹ mẹ́waa ni akanti to o ni, BVN kan ṣoṣo ni yoo so gbogbo wọn papọ mọ ọ.

    Aworan afihan owo Naijiria

    Oríṣun àwòrán, getty

  2. Ààrẹ Buhari fi ọ̀ṣẹ̀ kan kún ìrìnàjò rẹ̀ sí ìlú London láti ṣe àyẹ̀wò eyín

  3. Ilé ẹjọ́ sún ẹjọ́ tí Peter Obi pè tako èsì ìbò tó gbé Tinubu wọlé síwájú

  4. Lóòtọ́ ni Trump ṣe asemáse pẹ̀lú E Jean Carroll nínú ilé ìtajà ní New York – Iléẹ̀jọ́

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Adajọ to n gbọ ẹsun ibipabanilopọ ti wọn fi kan aarẹ tẹlẹri lorilẹede Amerika, Donald Trump ti kede pe o jẹbi ẹsun ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu arabinrin E Jean Carroll.

    Amọ adajọ naa ni oun ko lee fidi rẹ mulẹ pe Trump fi ipa ba obinrin naa lopọ ninu yara ti wọn ti n yi aṣọ pada ni Bergdorf Goodman, ni ilu New York.

    Bakan naa ni adajọ naa ni Trump ṣeeṣe ki o foju wina ofin lori sisọ ọrọ kubakugbe nipa obinrin naa to fi ẹsun kan an, nitori o pe ni opurọ.

    Igba akọkọ ni yii ti ileẹjọ yoo fidi rẹ mulẹ pe o jẹbi ẹsun to niise pẹlu ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu obinrin.

    Ileẹjọ naa ni Manhattan wa paṣẹ ki Trump san miliọnu marun un dọla fun obinrin naa fun ipalara to ṣe obinrin naa.

    Aworan

    Ninu ọrọ rẹ, arabinrin Carroll to tun jẹ onkọwe ni inu oun dun fun yiyege ni ileẹjọ nitori iṣẹgun naa jẹ ti gbogbo obinrin to ti koju iru iṣẹlẹ bẹẹ.

    Amọ agbẹjọro Trump ni aarẹ tẹlẹri naa ṣetan lati gbe ẹjọ naa lọ si ileẹjọ kọtẹmilọrun nitori ko faramọ igbẹjọ naa.

    Ninu ọrọ rẹ lori ẹrọ ibanidọrẹ rẹ, Truth Social kọ pe oun ko mọ ẹni ti obinrin naa n ṣe

    O ṣapejuwe idajọ naa gẹgẹ bi ibanilorukọ jẹ, to si ni ọna lati fitinati ohun ni idajọ naa.

    Bio tilẹ jẹpe ileẹjọ naa ni Trupm jẹbi ẹsun ṣiṣe aṣemaṣe pẹlu obinrin, amọ ko si aridaju pe o fi ipa ba obinrin naa lopọ.

  5. Ikú bàbá mi lo sọ mí di fẹ́ndọ̀ láti ọdún 1974; mo ṣì ń ta "paper" d'òní àmọ́ ohun tójú mi ń rí ... - Nureni Adesegun

  6. Onílè yìnbon lú ọmọ ọdún mẹ́rìnlá tó n ṣeré bójú-bójú níwájú ilé rẹ̀

    Wọn ti fẹsun iyinbọmọniyan kan baba onile kan to yinbọn lu ọmọdebinrin kan to n ṣere bojuboju niwaju ile rẹ.

    Ileeṣẹ ọlọpaa ilu Louisiana ni Amẹrika sọ pe wọn gbe ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹrinla yi lọ si ile iwosan lẹyin ti onile yi yinbọn mọ lẹyin ori rẹ.

    David Doyle ẹni ọdun mejidinlọgọta n koju ẹsun ikọlu eeyan lọna aitọ.

    O sọ fawọn ọlọpaa pe niṣe loun ṣina ibọn nigba toun ri awọn ''ojiji niwaju ile oun''

    Iṣẹlẹ iyinbọn mọ eeyan lori ọrọ ti ko fa ariwo yi ni o tun ṣẹṣẹ waye nilẹ Amẹrika

    Lowurọ ọjọ Aiku lawọn agbofinro dahun si ipe lori ago pe eeyan kan yinbọn mọ ọmọdebinrin kan ni ilu Starks ti o wa ni kilomita irinwo si iwọ oorun New Orleans.

    Atẹjade lati ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa Calcasieu sọ pe awọn gbọ pe ọpọ awọn ọmọde kan lo n ṣe ere bojuboju ladugbo naa tawọn kan si n sa pamọ lẹgbẹ ile baba onile yi.

    O tẹsiwaju pe onile naa arakunrin Doyle sọ pe oun gburo ojiji lẹgbẹ ile oun tori naa loun fi lọ gbe ibọn ninu ile.

    'O wa sọ fun awọn agbiofinro pe oun jade sita pada toun si ri tawọn eeyan n sa niwaju ile oun.O ni igba naa loun bẹrẹ si ni yinbọn ti ọta si ṣeṣi ba ọmọdebinrin yi.''

    Arakunrin Doyle wa ni ahamọ ọlọpaa lọjọ Iṣẹgun lẹyin tawọn ọlọpaa fẹsun kan an.

    Aworan afihan awọn ọmọ to n ṣere bojuboju
  7. Adeleke ṣe ìdàrò alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP Adagunodo tó jáde láyé

    Aworan Gomina Adeleke ati Soji Adagunodo

    Oríṣun àwòrán, Adeleke Ademola Facebook

    Gomina Ademola Adeleke ti ile ẹjọ giga ṣẹṣẹ kede gẹgẹ bi ẹni to jaweolubori ninu idibo Gomina nipinlẹ Osun ti kẹdun ọkan lara awọn eekan ẹgbẹ rẹ, Peoples Democratic Party, PDP.

    Soji Adagunodo to jẹ alaga ẹgbẹ nigba kan ri ni ipinlẹ Osun jade laye lọjọ Aje.

    Adeleke juwe iku rẹ gẹgẹ bi eleyi to ''fọwọ kan ẹmi ẹgbẹ ni Osun ati awọn araalu lapapọ''

    Ninu atẹjade ti Adeleke buwọlu lati ọwọ Mallam Olawale Rasheed,o ni ọrẹ timọ ni Adagunodo jẹ si oun ti oun si ṣatilẹyin fun nigba to fẹ di alaga ẹgbẹ PDP.

    O ni bẹẹ naa ni ''oun naa ṣatilẹyin fun mi lati fi di Sẹnẹtọ''

    Orileeede Amẹrika ni Adagunodo dakẹ si lẹyin aisan ranpẹ.

    Pupọ ọmọ ẹgbẹ PDP lo ti n kẹdun iku rẹ yi ti wọn ni ko jẹ ki awọn yọ ayọ pe Adeleke jaweolubori ni ile ẹjọ to gaju lọ ni Naijiria lori esi idibo rẹ.

    Yatọ si pe o jẹ alaga ẹgbẹ PDP nigba kan ri, Adagunodo ni alaga ẹgbẹ PDP ni agbegbe iwọ oorun Guusu Naijiria ko to jade laye.

    Ẹni ọdun mejilelọgọta nii ṣe.

  8. Ọkọ̀ agbépo ṣe'ku pa ọlọ́kadà ní Ibadan,l'awakọ bá fẹsẹ̀ fẹ

    Aworan awọn agbofinro ati tanka to kọlu ọlọkada

    Arakunrin ọlọkada kan ti kagbako iku lọwọ awakọ agbepo ''tanker'' kan to kọlu u ni adugbo Olodo, ilu Ibadan.

    Arakunrin naa taa gbọ pe orukọ rẹ n jẹ Idowu Familurin ku loju ẹsẹ ninu ijamba ọkọ to waye yi.

    Ni ọjọ Aje ni nkan bi ago mẹrin ọjọ Aje ni akọroyin wa jabọ pe ọkọ agbepo naa n bọ lati agbegbe iyana sọọsi to si n lọ si ọna ilu Iwo ni ipinlẹ Osun.

    O ni ṣadede lawọn araadugbo lawọn gbọ ariwo ti awọn akẹgbẹ ọlọkada yi si sare jade lati le awakọ naa to fẹsẹ fẹ.

    Wọn ribi ba lori afara Olodo ti wọn si fẹ fi ibinu dana sun ọkọ rẹ.

    Ọpẹlọpẹ awọn oṣiṣẹ ajọ to n mojuto lilọ bibọ ọkọ,OYRTMA,ati awọn ọlọpaa agbegbe Iyana Offa,wọn ki ba dana sun ọkọ rẹ ni.

    Ni bi owo ago merin irole ana ni ijanba oko tanker se ku pa okunrin olokada kan ti oruko re nje Ogbeni Idowu familurin ni nilu Ibadan.

    Akọroyin wa jabọ pe awọn agbofinro ti gbe oku ọlọkada ati awakọ to kọlu u lọ si agọ wọn to wa ni Iyana Offa.

  9. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè máa gbé irun dàda lọ sílé ẹ̀kọ́ báyìí ní Malawi – Ilé ẹjọ́

    Dreads

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Ile ẹjọ giga kan ni Malawi ti paṣẹ fun ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ ko maa gba awọn akẹkọọ to ṣe irun dada laaye nile ẹkọ ijọba kaakiri orilẹ-ede naa.

    Ile ẹjọ ọhun to joko niluu Zomba lo paṣẹ bẹẹ lẹyin to gbọ ẹjọ awọn ọmọ ‘Rastafarian’ meji kan ti ile ẹkọ ko gba laaye lati wọle sile ẹkọ ijọba lọdun 2010 ati ọdun 2016.

    Amọ awọn akẹkọọ meji naa ti wa nile ẹkọ bayii lẹyin ti ile ẹjọ fun wọn laṣẹ bẹẹ.

    Ṣaaju ni ẹgbẹ awọn ‘Rastafarian’ ni Malawi ti kọkọ n jiroro pẹlu aṣofin agba orilẹ-ede ọhun lati yanju ọrọ naa, amọ wọn ti lo ọpọlọpọ akoko nile ẹjọ ti ọrọ naa ko si niyanju, ki idajọ yii to waye.

    Adajọ Zione Ntaba dajọ pe wọn ti tẹ ẹtọ awọn ọmọ naa lati kẹkọọ loju bi wọn ṣe kọ lati fun wọn laaye lati wọ ile ẹkọ nitori irun dada ori wọn.

    O ni “Ileeṣẹ eto ẹkọ gbọdọ fi atẹjade lede, eyii ti yoo gba awọn ọmọ Rastafarian laaye lati maa lọ sile ẹkọ pẹlu irun dada lori wọn, wọn si gbọdọ ṣe eyii titi ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa, ọdun 2023.”

    Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan mẹta lo pe ẹjọ naa lorukọ awọn eeyan ọhun.

  10. Àwọn èèyàn má n pè mí ní Ẹbọra, Amotekun àti Ọ̀wàwà nítorí bí àwọ̀ ara mi ṣe rí - Oluwatosin Ojetola

  11. Ọmọdé mẹ́ta wà lára àwọn tí agbébọn ṣe ikọlu sí ní Texas

    Awọn mọlẹbi n kawọ lori tori iṣẹlẹ buruku yi

    Ọmọ ọdun mẹta kan ati awọn obi rẹ,awọn akẹkọọ ile ẹkọ alakọbẹrẹ meji ati onimọ ẹrọ kan lati India wa lara awọn to farakasa ninu ikọ lu agbebọn si ile itaja kan ni Texas.

    Ọmọde yi James Cho ati awọn obi rẹ Cho Kyu Song, ati Kang Shin Young,pẹlu awọn to kagbako agbebọn yi.

    Ẹgbọn rẹ naa to jẹ ọmọ ọdun mẹfa farapa ṣugbọn o ye ikọlu naa.

    Idanimọ awọn eeyan wọnyi n waye bi awọn alaṣẹ ṣe n tẹsiwaju iwadii lati mọ boya agbebọn naa ni ibaṣepọ pẹlu awọn alakatakiti kan.

    Eeyan mẹjọ lo ku ninu ikọlu naa.Aimọye lo farapa ti wọn si wa ni ile iwosan.

    Oju opo GofundMe ti wọn fi n gba owo jọ ṣalaye pe awọn mọlẹbi Cho lọ si ile itaja lati paarọ aṣọ ayẹyẹ ọjọ ibi ọmọ wọn to waye lọjọ meloo kan sẹyin.

    Loju opo naa,awọn mọlẹbi kọ ọrọ sibẹ pe:

    ''Ọjọ to yẹ ko jẹ ọjọ idunnu pada wa di ọjọ ibanujẹ nitori bi agbebọn yi ṣe ge ẹmi awọn eeyan ni kukuru''

    Awọn alaṣẹ ileeṣẹ Korea to wa ni ilẹ Amẹrika sọ fun ileeṣẹ iroyin Dallas Morning News pe orileede Korea lawọn idile Cho ti sẹ wa ati pe awọn ti n gbe igbesẹ lati kan si mọlẹbi wọn.

    Awọn akẹkọọ́ meji kan Daniela ati Sofia Mendoza to jẹ ọmọ iya kanna wa lara awọn ti agbebọn yi pa.

    Bẹẹ la gbọ pe iya wọn Ida naa n gba itọju ni ileewosan gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin CBS ti ṣe sọ.

    Aishwarya Thatikonda,onimọ ẹrọ ọmọ orileede India kan naa wa lara awọn ti agbebọn yi ṣeku pa.

    Eeyan mẹfa ni awọn alaṣẹ kede pe wọn ku loju ẹsẹ nibi iṣẹlẹ yi to waye ni agbegbe Dallas.

    Awọn meji mii pada ku ni ileewosan.

    Afurasi to ṣeku pa awọn eeyan yi ni ọlọpaa kan ti yinbọn pa loju ẹsẹ ti iwadii ṣi n tẹsiwaju lati mọ adisọkan rẹ.

    Awọn ọlọpaa n ṣe iwadii yi nipa ayẹwo oju opo ayelujara rẹ.

    Mauricio Garcia lorukọ rẹ.

  12. Afurasí 'ọmọ yahoo' fi ọkọ̀ pa akẹ́kọ̀ọ́ tó n ṣe WAEC lọ́wọ́ nílùú Akure

  13. ‘A fún Tinubu di May 29 láti kéde àwọn dúkìá rẹ̀’

  14. Iná ẹlẹ́tíríìkì ṣekúpa akẹ́kọ̀ọ́ onímọ̀ ẹ̀rọ ní Sudan bó ṣe ń bá ilé ìwòsàn tún iná ṣe

  15. ''Ọtí wáìnì ní mo mú ye fún ọjọ́ márùn ún lẹ́yìn tí mo há sí igbó aginjù''

    Àkọlé fídíò, Woman found after five days stranded in bushland in Australia

    Arabinrin ẹni ọdun mejidinlaadọta ti sọ iriri pẹlu bi o sẹ jajabọ lẹyin to ṣọnu si inu igbo fun ọjọ marun un lorilẹede Australia.

    Arabinrin naa ti orukọ rẹ n kẹ Lilian lp ni ọti ẹlẹrindodo ati sweet lo n jẹ lasiko ti oun ha sinu igbo ni ipinlẹ Victoria.

    O ni oun sọnu sinu igbo lẹyin ti oun gba ọna ti ko yẹ ki oun gba, ti ọkọ oun si ha sinu ilẹ.

    Arabinrin lp to ni ohun kii mu ọti ni igo kan pere lo wa ninu ọkọ ohun ti oun si fẹ lọ fun ọrẹ oun kan ni lati ta ni ọrẹ.

    Lẹyin ọjọ marun un ni awọn oṣiṣẹ pajawiri ṣawari rẹ lasiko ti wọn n wa kiri ninu igbo naa.

    ‘’Ohun akọkọ to wa si ọkan mi ni omi ati siga nigba ti awọn to doola ẹmi mi de’’

    ‘’Mo ro pe mo maa ku ni, ti gbogbo ẹya ara mi ti da iṣẹ silẹ lẹyin ọjọ marun un, ti mo si ti sọ gbogbo ireti nu pe wọn yoo ri oun laaye.

    Asiko ti o sọ ireti nu naa ni o kọ lẹta si awọn mọlẹbi rẹ pe oun fẹran wọn.

    Ileeṣẹ ọlọpaa ni ọlọpọlọ pipe ni arabinrin naa nitori waini to o fẹ lọ fun iya rẹ lo doola ẹmi rẹ, to si jẹ gẹgẹ bi omi fun un nitori ko si omi lati mu.

    Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa naa ni arabinrin oun ṣe daradara to duro si idi ọkọ rẹ, ti ko si tun rin wọnu igbo lọ, nitori naa ni awọn ṣe tete ri.

    Lẹyin naa ni wọn tun gbe arabinrin naa lọ si ileewosan fun iwosan pipe, to si ti pada si ile.

  16. Àwọn aṣòfin tuntun dá ẹgbẹ míràn sílẹ̀ nínú Ilé Ìgbímọ̀ Aṣòfin Naijiria láti yan ẹ̀ni tí wọ́n fẹ́ gẹ́gẹ́ bíi adarí

  17. Ó tí tó 400 èèyàn tí ẹ̀kún omi ti pa ní DR Congo

    Ẹkun omi

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Awọn alaṣẹ ni orilẹ-ede Dr Congo sọ pe diẹ lo ku, ki oku eeyan ti wọn ko jade ninu omi pe irinwo, lẹyin ti ẹkun omi ati ilẹ riri waye ni abule meji ni Ọjọbọ.

    Yatọ si awọn to ku, ọpọ lo fi ara pa, ti eeyan bi 176 si di awati.

    Awọn abule mejeeji, Bushushu ati Nyamukubi, to wa ni ẹgbẹ adagun odo Kivu, lo rì sinu omi patapata lẹyin ti awọn odò to wa ni ila oorun DR Congo kún kọja bèbè wọn.

    Ileeṣẹ irotin AFP jabọ pe apapọ 394 eeyan ni wọn ti ri oku wọn, gẹgẹ bi alakoso agbegbe Kalehe, nibi ti awọn abule naa wa, Thomas Bakenga, ṣe sọ.

    Eeyan 203 lo kede ni ọjọ Aiku nikan.

    Ilẹ riri tun waye ni ọpọ igba, eyi to ba awọn ile to wa ni agbegbe naa jẹ.

    Iroyin sọ pe o le ni ida mẹta ninu mẹrin to wa ni awọn abule naa, ti omi gbe lọ patapata.

    Iṣẹlẹ omiyale yii waye lẹyin ọjọ diẹ ti iru rẹ ti kọkọ ṣẹlẹ ni awọn abule kan to wa ni odikeji adagun odo Kivu, ni orilẹ-ede Rwanda to mule ti DR Congo.

    Eeyan 130 lo ku nibẹ.

  18. Àhesọ ọ̀rọ̀ lásán ní pé mo n wà ipò SGF labẹ̀ ìjọba Tinubu-El Rufai

    Aworan Gomina Kaduna El-Rufai

    Oríṣun àwòrán, Facebook/Nasir El Rufai

    Gomina ipinlẹ Kaduna Mallam Nasir El-Rufai ni ko si ootọ ninu iroyin pe oun n wa ipo olori awọn oṣiṣẹ labẹ ijọba Bola Ahmed Tinubu.

    Ipari oṣu kaarun yi ni wọn yoo bura wọle sipo fun aarẹ ti araalu dibo yan yi.

    El-Rufai fidi ọrọ yi mulẹ lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ọjọ Abameta ni ipinlẹ Gombe.

    O ni ofutu fẹẹtẹ ọrọ ti ko fẹsẹ rinlẹ ni wọn n gbe kaakiri yi.

    Gomina yi ti o n palẹmọ lati kuro nipo nipari oṣu kaarun yi ni ohun to jẹ oun logun ni idagbasoke Naijiria ati pe bi oun ba ṣetan isinmi loun yoo kọkọ sinmi lẹyin igbejọba kalẹ.

    Ọrọ wi pe El-Rufai yoo gba ipo labẹ ijọba tuntun yi ko ṣẹṣẹ maa jade.

    Ni paapa, aarẹ ti araalu dibo yan Ahmed Tinubu lawọn aaye kan ti tẹnumọ pe oun nifẹ si ki El-Rufai ko ipa to lamilaaka labẹ ijọba rẹ.

    Inu ẹgbẹ kanna ni El Rufai ati Tinubu wa tii ṣe All Progressives Congress, APC to wa lori alefa ni Naijiria.

    Ninu awọn eekan ẹgbẹ to gbaruku ti Tinubu lasiko ipolongo idibo si ni El-Rufai wa.

    Ọmọ bibi ipinlẹ Kaduna yi kii ṣe aimọ lagbo oṣelu Naijiria.

    Lati igba to ti kọkọ di ilumọọka pẹlu iṣẹ to ṣe labẹ ijọba Olusegun Obasanjo gẹgẹ bi Minisita fun olu ilu Naijiria,FCT, lọpọ ti ri ipa to ko ni idagbasoke ilẹ naa.

    Ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu Kaarun yi ni wọn yoo bura wọle sipo fun Tinubu.

    Ireti awọn araalu si ni pe ko ni jẹ ko pe ki o to kede awọn ti yoo baa ṣiṣẹ pọ labẹ ijọba rẹ.

    Titi di asiko yi, Tinubu ko ti mẹnuba eeyan kankan ni pato ti yoo ba ṣiṣẹ pọ to ba dori ipo aarẹ Naijiria.

  19. O kéré tàn,760 ọmọ Nàìjíríà ní yóò tún darí láti Sudan l'Ọjọ́ Àìkú

    Aworan awọn ti wọn seto lati ko pada wa si Naijiria

    Oríṣun àwòrán, NIDCOM

    Àjọ to n risi ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okere,NIDCOM, sọ pé eto ti n lọ láti ri pe awọn ọmọ ilẹ naa to din diẹ ni ẹgbẹrun meji ko ni pẹ padà sile lati Egypt.

    Awọn yii ni ogun le kuro ni Sudan tí ìjọba si n ṣètò lati gbe wọn padà sile lati awọn papakọ ofurufu ni Egypt.

    Atẹjade yi lati ọwọ agbẹnusọ ajọ naa, Abdulrahaman Balogun, fi kun pe o kere tan 760 ninu awọn wọnyi yoo dari pada lọjọ Aiku ni ikọ meji ọtọọtọ

    O ni l'owurọ ọjọ Aiku, awọn ọkọ akero mẹrindinlogun kan de si papakọ ofurufu Aswan lati ibodè Wadi Halfa tawon meji mii sí kó ẹrọ dé lati Arqeen.

    Abdulrahaman salaye pe wọn ti bẹrẹ eto ayẹwo àwọn ti yoo wọ baalu ti ireti sí wa pe wọn yoo dari pada si Naijiria.

    Eleyi ni ikọ kaarun awọn ọmọ Naijiria ti ijọba n fi baalu ko pada wa sile lati igba ti ogun ti le wọn kuro ni Sudan.

    Akẹkọọ ni pupọ awọn to n dari pada wa sile yi jẹ.

  20. Tinubu fí ọ̀rọ̀ ìkíni ránṣẹ sí ọba Charles lórí ìwúyè rẹ̀

    Aworan Bola Ahmed Tinubu

    Oríṣun àwòrán, officialasiwajubat

    Ààrẹ ti araalu ṣẹṣẹ dibo yan ni Naijiria,Bola Ahmed Tinubu,ti ranṣẹ ikini sí Ọba Charles III.

    Ninu iwe ikini naa to kọ, o ni oun ṣetan lati pawọpọ pẹlu oriade ilẹ Gẹẹsi .

    Tinubu sọ pe oun n'igbagbọ pe Ọba naa yoo tọ ipasẹ iya rẹ Obabirin Elizabeth nipa mimu idagbasoke ba ilẹ Gẹẹsi ati awọn orilẹ-ède Commonwealth.

    Ààrẹ ti wọn dibo yan ti oun naa n gbaradi de iburasipo, se lalaye pe oun lero pe itẹsiwaju yoo ba ibaṣepọ Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi lasiko ti Charles III wa lori oye.

    Lakotan,Tinubu gba adura àṣeyọrí fún Ọba tuntun titi ti yoo fi pari saa rẹ.

    Lọjọ Kokandinlogbon oṣù kaarun ni wọn yoo bura wọlé sipo fún Tinubu lẹyìn àṣeyọrí rẹ ninu idibo ààrẹ to waye losu Keji ọdún 2023