Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ilé aṣòfin àgbà ṣe ìpàdé pàjáwìrì lọ́jọ́ Àbámẹ́ta

    Sẹ́nétọ̀ Ahmad Lawan

    Oríṣun àwòrán, Nigeria Senate

    Ààrẹ ile aṣòfin àgbà Naijiria , ti salaye idi ti wọn fi ṣe ipade pajawiri lọjọ Abamẹta.

    Ninu atẹjade to fi si ori ayelujara Twitter, Sẹnetọ Ahmad Lawan sọ pe awọn gbé igbesẹ naa lati le fi ontẹ lu afikun owo isuna ti ìjọba gbe wa siwaju wọn.

    Gẹgẹ bo se sọ, o ni "bayii kọ ni a ṣe ma n ṣe ipade wa, sugbọn o jẹ dandan fun wa lati buwọlu eto owo isuna tuntun nitori pe yoo ti pẹ ju ti yoo ba fi di oṣù Kẹfà.

    Àwọn Sẹnetọ tuntun ni yoo wa nile aṣòfin lasiko naa.

    Sẹnetọ Lawan salaye pe awọn owo ti wọn o fi ṣe àtúnṣe awọn afárá ati oju ọna ti àgbàrá òjò ba jẹ lọdun to kọja, lo wa ninu iwe isuna naa.

    "Tí a ba kọ ta o fi ontẹ luu bayii, yoo ti pẹ ju ninu osu kẹfà nigba ti òjò yoo ti ma a rọ̀ púpọ̀.

    Igba keji rèé ti ile aṣòfin ṣe agbeyẹwo isuna naa, wọn si ti fà á le igbimọ ti yoo mojuto o lọwọ.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  2. Seyi Makinde buwọ́lu òfin tuntun tí yóò yí ètò oyèjíjẹ padà nílú Ibadan

  3. Ọ̀rọ̀ àti ìṣesí ààrẹ Buhari márùn ún tó dá awuyewuye sílẹ̀ lásìkò ìjọba rẹ̀

  4. Àwọn agbébọn dáná sun Ọmọọba nípínlẹ̀ Imo

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Awọn afurasi agbebọn kan yabo abule Orsu Obodo nijọba ibilẹ Oguta nipinlẹ Imo ti wọn si ṣekupa àwọn oloye ilu naa.

    Gẹgẹ bii iroyin to tẹ wa lọwọ ṣe sọ, lati Ọjọbọ ọsẹ yii ni Ikọlu naa ti bẹrẹ, to si waye lọọtọ.

    Wọn ṣekupa Ese Victor Ijioma to jẹ Ọmọọba ninu ọkọ ayọkẹlẹ rẹ niluu Izombo.

    Osojumikoro salaye pe awọn agbébọn ọhun da Ọmọọba duro ni agbegbe Umuamaka niluu Izombo, ti wọn ṣekupa.

    Lati ri aridaju pe o ti ku, ní ṣe ni awọn agbébọn naa tun dana sun mọ ọkọ ayọkẹlẹ rẹ.

    Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa, Henry Okoye fìdí iṣẹlẹ naa nilẹ.

    O ni Kọmisọna ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ naa, Muhammad Barde ti palasẹ pe ki iwadi bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa

  5. Atiku fọnmú lẹ́yìn tí ilé ẹjọ́ da ẹjọ́ tó pè tako Tinubu nù

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Oludije ẹgbẹ oselu PDP ati Igbakeji Aarẹ tẹlẹ lorilẹede Naijiria, Atiku Abubakar ti ní mimi kan ko mi awọn rara lori bi ileęjọ ṣe wọgile ẹjọ to fi tako Aarẹ tí ilu sẹsẹ dibo yan, Bola Tinubu.

    Ileęjọ to ga ju lorilẹede Naijiria wọgile ẹjọ tí ẹgbẹ oselu PDP pe lati tako bi Bola Tinubu ati Igbakeji rẹ ṣe kopa ninu eto idibo to waye ninu oṣu kẹta.

    Ninu idajọ rẹ, ileęjọ ni ẹgbẹ oselu PDP ko lẹtọ lati pe ẹjọ pe ko yẹ kí ẹnikan dibo nítorí wọn ko n ṣe ẹgbẹ oselu kankan.

    Atiku ninu ọrọ to gbe sori opo ayelujara rẹ salaye pe ko si mimi kankan ti yoo mi oun, ti idajọ ododo yoo si waye.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  6. Ìjọba kéde ìsinmi lẹ́nú iṣẹ́ nítorí ètò ìbúrawọlé Tinubu

    Aworan Minisita Aregbesola

    Oríṣun àwòrán, Facebook/Rauf Aregbesola

    Ijọba orileede Naijiria ti kede ọjọ Aje,ọjọ Kọkandinlọgbọn gẹgẹ bi ọjọ isinmi fun gbogbo oṣiṣẹ lorileede Naijiria.

    Ọjọ isinmi yi ni ijọba sọ pe awọn ya sọtọ nitori ayẹyẹ iburawọle aarẹ ikẹrindinlogun tii ṣe Bola Ahmed Tinubu.

    Minisista feto abẹle Rauf Aregbesola lo fi ikede yi sita to si rọ awọn ọmọ Naijiria lati pawọpọ mu agbega ba ijọba awarawa.

    Pupọ awọn ọmọ Naijriia lo ti n foju sọna fun isinmi yi debi pe awọn kan bọ si oju opo Twitter ti wọn si ni ki Minisita kede isinmi tawọn n reti yi.

    Ni bayii, awọn ọmọ Naijiria yoo jẹ anfaani isinmi lọjọ iburawọle ti wnh yoo si tyun gba isinmi miran lọjọ ayajọ ijọba awarawa tii ṣe ọjọ kejila oṣu Kẹfa.

    Bi a ko ba gbagbe ijọba aarẹ Buhari mu iyipada ba ọjọ isinmi ayajọ ominira kuro ni ọjọ Kẹakndinlọgbọn oṣu Kaarun si ọjọ Kejila oṣu Kẹfa.

    Wọn gbe igbesẹ iyipada yi lati bọwọ fun Moshood Abiola ti ọpọ gba pe o jaweolubori ninu idibo June 12 lọdun 1993.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

  7. Buhari ṣì ní ẹ̀tọ́ di òru May 28 láti yáwó, gbé iṣẹ́ fún kọngílá síta- Fashola

  8. Ọkùnrin kan rí ẹ̀wọ̀n he fún ẹ̀sùn pé ó jí Bíbélì mẹ́rin ní ilé ìjọsìn

    aworan

    Oríṣun àwòrán, others

    Ileęjọ kan to n joko niluu Abuja tí ni kí ọkùnrin, ẹni Ọgbọn ọdun, Zakaraya Usman lọ ma gba atẹgun fun oṣu meji fun ẹsun pe o jí Bíbeli mẹrin ati ọpọlọpọ iwa idarapo sí ile jọsin.

    Ileeṣẹ Ọlọpaa lo fẹsun ole jiga kan afurasi naa.

    Adajọ Malam Abubakar ran afurasi naa lọ si ọgba ẹwọn lẹyin to jẹ wọ pe oun ni oun gbe awọn Bíbélì naa Bakan lo fun afurasi naa ni anfani lati san owo itanran, ẹgbẹrun mẹwa.

    Saaju ni Agbẹjọro awọn olùpẹjọ, O.S Osho sọ fun ileęjọ pe afurasi ọhun lo yọ kẹlẹ wọle sinnu ile jọsin lati ja wọn lole.

    Osho ni afurasi naa ji Bíbélì mẹrin, Caprisoon męrinla, ati nnkan mìíran

  9. San owó ₦40m fún gbígbèrò láti dáwọ́ ìbúrawọlé Tinubu dúró - ilé ẹjọ́ sọ fún olùdíje sípò Ààrẹ tẹ́lẹ̀ rí

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, others

    Ileęjọ kotẹmilọrun to n joko niluu Abuja ti ni ki Oludije fun ipo aarẹ tẹlẹ, Ambrose Owuru lọ san ogoji milọnu naira owo itanran fun bí o ṣe pe ẹjọ lati fi tako bibura aarẹ tuntun ti ilu sẹsẹ dibo yan, Bola Tinubu lọjọ kọkandinlọgbọn.

    Ileęjọ ni kí Owuru san milọnu mẹwaa fun Aarẹ Muhammadu Buhari, milọnu mẹwaa fun agbẹjọro agba fun orilẹede Naijiria, Abubakar Malami, milọnu mẹwaa fun ajọ INEC ati milọnu mẹwaa fun Aarẹ tuntun, Bola Tinubu.

    Adajọ Jamil Tukur, ẹni to lewaju igbimọ awọn adajọ ni ẹjọ tí Owuru pe ni ko lẹsẹ ni ilẹ rara, ti ko si ni itẹwọgba.

    Adajọ Tukur ni igbesẹ Owuru lati lọ gbe ìpẹjọ to ti ku làti ọdun 2019 ni ileęjọ to ga ju ni o fẹ ki awọn ile ẹjọ maa wọ iyaja pẹlu ile àṣẹ ile ẹjọ.

    Saaju ni Owuru, ẹni to jẹ Oludije ẹgbẹ oselu Hope Democratic Party lọdun 2019 kesi ileęjọ ko tẹmilọrun lati fi ofin de Aarẹ, Malami ati Àjọ INEC lati ma le ni anfani lati bura fun Aarẹ tuntun lọsẹ to n bọ

  10. Buhari foyè GCFR tó ga jùlọ dá Tinubu lọla,Shettima náà gba oyè GCON

    Aworan Buhari lasiko to n fi ami oye si ọrun Tinubu

    Oríṣun àwòrán, Tunde Rahman

    Aarẹ Naijiria Muhammadu Buhari ti fi oye Grand Commander of the Federal Republic GCFR, da Bola Ahmed Tinubu,aarẹ ti araalu dibo yan lọla.

    Ayẹyẹ ifoye dani lọla yi wa lara awọn eto ti yoo waye ṣaaju iburawọle sipo fun Tinubu gẹgẹ bi aarẹ Kọkanla orileede Naijiria.

    Tinubu ati Igbakeji rẹ ti araalu dibo yan Kashim Shettima ni wọn fi oye da lọla.

    Orukọ oye ti Shettima ni Grand Commander of the Order of the Niger (GCON),

    Ninu ọrọ rẹ si aarẹ Buhari lasiko idanilọla yi Tinubu kan saara si aarẹ Buhari to si ni oun dupẹ pe o ranti fi oye GCFR da oloogbe MKO Abiola lọla lẹyin iku rẹ.

    Tinubu sọ pe oun ko ni ja ireti awọn ọmọ Naijiria to fi igbagbọ dibo yan oun wọle gẹgẹ bi aarẹ.

    O ni ''awọn araalu ti fi ẹmi tan wa,Ẹ ti ṣe ipa ti yin gẹgẹ bi aarẹ.''

    O ni bayi ti o ti wa kan oun lati sa are yi,''oun yoo sa are naa daada.''

    Lọjọ Kọkandinlọgbọn oṣu karun un yi ni Tinubu yoo gba iburawọle sipo gẹgẹ bi aarẹ Naijiria.

  11. Igi àtọjọ́mọjọ́ wó lulẹ̀ ní Freetown- gbọ ohun tí aráàlú sọ

    Atẹgun ojo lile kan ti wo igi atayebaye kan lolu ilu Sierra Leone tii ṣe Freetown.

    Aarẹ Julius Maada Bio ṣalaye pe igi naa wo lẹyin arọrọda ojokan lalẹ Ọjọru.

    O ṣapejuwe iṣẹlẹ yi gẹgẹ bi ''adanu nla forileede wa''

    O ni ọpọ lo ri igi yi gẹgẹ bi ami idanimọ ominira fawọn to kọkọ tẹdo silẹ naa.

    Bi a ko ba gbagbe wọn da ilu Freetown silẹ gẹgẹ bi ilu fawọn adulawọ ti wọn tu silẹ loko ẹru lọdun 1787.

    Aworan igi ilumọọka yi wa lara owo orileede Sierra Leone ti ọpọ si ri gẹgẹ bi ọkan lara awọn iru igi yi to dagba julọ.

    Aarẹ sọ pe awọn yoo ṣe ami idanimọ si ojubọ igi yi lati ṣafihan pataki igi yi ninu itan orileede ọhun.

    Aworan igi ti ojo wo ni Freetown.

    Oríṣun àwòrán, BBC/Umaru Fofana

    Aworan igi naa ree lọdun 2013 ki o to wo lulẹ.

    Aworan igi atayebaye

    Oríṣun àwòrán, Gett

  12. Wo àwọn gómìnà tí wọ́n tú ìgbìmọ̀ ìṣàkóso wọn ká l'oṣù yìí

  13. Óṣe! Ọkọ̀ tó kó àwọn èrò tó ń lọ Mecca ní ìjàmbá

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, others

    Bọọsi akero to n gbe awọn eeyan to n mura irinajo lọ si ilẹ mimọ Mecca ni ijamba nipinlẹ Nasarawa.

    Iṣẹlẹ naa lo waye lọjọbọ ọsẹ yii lasiko ti wọn rìn irinajo lọ si olu ilu Abuja.

    Agbegbe Kara ni ijọba ibilẹ Kaffi ni iṣẹlẹ naa ti waye, ti ọpọ si farapa. Oni ọjọru lo yẹ kí awọn eeyan naa gbéra lọ si ilu Mecca.

    Iwadii ni ẹnikẹni ko ba iṣẹlẹ ijamba naa lọ.

  14. Ìjọba Tinubu ni yóò ṣe ìfilọ́lẹ̀ òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan- Fashola

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, others

    Minisita fun isẹ ode, Babatunde Fashola ti ní isejọba tuntun tí Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni yoo se ifilọlẹ opopona marose Eko sí Ibadan.

    Fashola sọ eleyi nibi ipade igbimọ lori ọrọ Naijiria eyi ti Aarẹ Muhammadu Buhari lewaju rẹ ni ile ijọba niluu Abuja. Gẹgẹ bii minisita ṣe sọ, Ọgbọnjọ osu kẹfa ni ifilọlẹ naa yoo waye.

    "A ko fẹ pe nitori a fẹ kanju ṣe ifilọlẹ oju ọna naa ka ṣe isekuse nitori rẹ ni a fi n se awọn atunse ní oju ọna naa. "

    Bakan naa ni Fashola sọ fun Aarẹ Buhari pe yoo se ifilọlẹ awọn isẹ akanse kakiri orilẹede Naijiria.

  15. Akẹ́kọ̀ọ́ pàdánù owó ilé ẹ̀kọ́ sóko tẹ́tẹ́, ló bá gba ẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, others

    Akẹkọọ ile ẹkọ gbogbo nise Poly ti ilu Ilaro, Samuel Adekoya ni wọn ni o po kẹmika pọ, to si gbe mu lẹyin to padanu owo ile ẹkọ oun ati ti ọrẹ rẹ si idi tẹtẹ tita.

    Samuel ni bọ sidi tẹtẹ lori ayelujara, to si lo owo ile ẹkọ rẹ sugbọn ko rí bí o ṣe fẹ.

    Akẹkọọ ọhun to wa ni ipele kejì ni ile ẹkọ Poly ni ṣekupa ara rẹ lowurọ ojo Aje lasiko ti awọn akẹgbẹ n mura fun idanwo wọn.

    Saaju ni ile ẹkọ ti ṣe ní ikilọ pe wọn ko ni fun akẹkọọ to ba jẹ owo ẹkọ ni anfani lati se idanwo.

    Igbakeji alukoro ile ẹkọ naa, Sola Abiala ni ile ẹkọ naa gbinyanju lati dola ẹmi akẹkọọ, ti wọn si sure gbe lọ si ile wosan sugbọn o jade laye ni isẹju diẹ to de ile wosan.

    Abiala ni ayẹwo ile wosan lo safihan pe akẹkọọ naa gbe kẹmika jẹ ní.

  16. Bíbúra Tinubu kò ní dá ìdájọ́ òdodo dúró - Iléẹjọ́

    aworan

    Oríṣun àwòrán, others

    Ileęjọ to n gbọ awuyewuye lori eto idibo aarẹ ti ni bi wọn ṣe fẹ bura fun Aarẹ tuntun ti ilu sẹsẹ dibo yan ko ni ṣe akoba fun ẹjọ ti Peter Obi ti Labour Party ati Atiku Abubakar gbe wa si ileęjọ

    Peter Obi ati Atiku Abubakar lo gbe ẹjọ eyi to tako esi idibo to gbe Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ oselu APC wọle gẹgẹ bii Aare.

    Ileęjọ ni awọn ti gba gbogbo àwọn ẹjọ naa ti yoo si ni iyanju laipẹ yìí.

    "Gbigbọ ẹjọ yoo bẹrẹ Ọgbọnjọ osu karun si ọjọ karun osu kẹjọ, ti wọn yoo si gbe idajọ kalẹ laipẹ

  17. Ọwọ́ tẹ èèyàn méjì fún bí wọ́n ṣe fipá bá ìyá arúgbó àti ìyàwó ilé lòpọ̀ tí wọ́n fi jáde láyé

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, others

    Ọwọ ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti tẹ awọn afurasi meji fun bi wọn ṣe fipa iya arugbo ati iyawo ile kan tí tí wọn fi jade laye ni adugbo ọtọọtọ nipinlẹ naa.

    Mima Chinecherem, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn ni ọwọ tẹ ni Ore ni ijọba ibilẹ Odigbo fun o se fipa ba ẹni ọgọrin ọdún, Felicia Aderibigbe lori oko rẹ.

    Bakan naa ni ọwọ tẹ ọmọ orilẹede Togo, Gbegele Mustapha lẹyin to gbinyanju lati fipa ba iya ile rẹ sun, to si tun ṣekupa iya naa.

    Chinecherem to wa lati ipinlẹ Ebonyi ni ọwọ tẹ lori ọkọ ti wọn ti sawari ọkọ iya naa ati ẹrọ ibaraẹnisọrọ oloogbe.

    Agbẹnusọ ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Fummi Odunlami lasiko to n safihan awọn afurasi naa o se koko tí awọn araalu gba ruku tí ileeṣẹ Ọlọpaa nipinlẹ Ondo lati fi opin iwa ọdaran to wọpọ

  18. Tinubu yóò sèbúra tàn kí ìgbẹ̀jọ awuyewuye ìdìbò ààrẹ Nàìjíríà tó tẹ̀síwájú

    Igbimọ to n gbẹjọ awuyewuye esi idi aarẹ Naijiria ti sọ pe kawọn to tẹsiwaju pada lori igbẹjọ di lẹyin iburawọle sipo Bola Ahmed Tinubu.

    Iroyin yi jẹyọ lẹyin ti awọn alatako Tinubu ti ṣaaju beere pe ki ile ẹjọ ṣe afihan igbẹjọ naa lori amohunmaworan ti ile ẹjọ si wọgile aba ti wọn mu wa yi.

    Ohun ti eleyi tunmọ si bayii ni pe Tinubu yoo ti wa lori ipo aarẹ lasiko ti igbẹjọ yi ba n waye.

    Igbẹjọ naa ti to bi ọsẹ meji kọja diẹ tyo bẹrẹ to si le to oṣu mẹta ki wọn to kasẹ ẹjọ naa nilẹ.

    Awọn alatako Atiku Abubakar ati Peter Obi lo lewaju ninu awọn to lawọn fẹ ki ile ẹjọ wọgile esi ibo to gbe Tinubu wọlẹ.

    Laaye arawọn lọtọọtọ si ni wọn lawọn fẹ ki adajọ kede awọn gẹgẹ bi oludije to jaweolubori.

    Ni ọjọ Aje tii ṣe jọ kọkandinlọgbọn oṣu Kaarun ni iburawọle sipo Tinubu yoo waye ni olu ilu Naijiria tii ṣe Abuja.

    Aworan awọn oludije mẹta to lewaju ninu idibo aarẹ Naijiria

    Oríṣun àwòrán, Facebook/Peter Obi, Bola Ahmed Tinubu/Atiku Abubakar

  19. Nọ́ọ̀sì méjì kò sí gbaga fún ẹ̀sùn yíyọ ẹ̀yà àra ibèjì ọmọ tuntun

    Inu yaara ayẹwo nileewosan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Ijọba orilẹ-ede Tanzania ti pari eto lati gbe nọọsi meji lọ sile ẹjọ fun ẹsun pe wọn yọ ẹya ara ọmọ tuntun jojolo meji to jẹ ibeji.

    Iwadii ti igbimọ ti awọn alaṣẹ gbe kalẹ lati ṣe iwadii ẹsun naa fihan pe, niṣe ni wọn ge ara awọn ọmọ tuntun naa lẹyin ti wọn kú.

    Iya awọn ọmọ naa deede ba oku wọn, ti wọn ti yọ oju wọn, ti apa kan ara wọn si bó fẹlẹfẹlẹ lati iwaju ori.

    Alamojuto agbegbe Tabora, Batilda Buriani sọ pe wọn ti da awọn nọọsi naa duro lẹnu iṣẹ, ti wọn si wa ni ahamọ awọn agbofinro.

    O ni yiyọ ẹya ara eniyan niiṣe pẹlu iwa àjẹ́.

    Arabinrin Buriani sọ pe awọn nọọsi naa kọkọ parọ fun igbimọ oluwadii pe, yaara awọn obinrin to ṣẹṣẹ bimọ ni awọn gbe oku awọn ọmọ naa si, amọ iwadii fihan pe inu yaara ti awọn nọọsi n jokoo si ni wọn ti ba wọn.

    Iroyin sọ pe aisi itọju to peye nileewosan naa, lo pa awọn ibeji ọhun nigba ti wọn bi wọn.

  20. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo tún kíláàsì kà kí n tó di ọ̀jọ̀gbọ́n lọnìí- Ojogbon Ayodele Desalu