Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Òkú tó jí dìde lásìkò tí wọ́n fẹ́ sin-ín padà kú pátápátá lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan

  2. Iléeṣẹ́ ìbáraẹnisọ̀rọ̀ Airtel ní Naijiria ti bẹ̀rẹ̀ lílo ìmọ̀ èrọ ayárabíàsá 5G

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Airtel

    Ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ Airtel lorilẹede Naijiria ti bẹrẹ lilo imọ ẹrọ 5G

    Igbesẹ tuntun yii mu ki awọn ileeṣẹ to n lo imọ ero ayarabiasa di mẹta lorilẹede Naijiria.

    Imọ ẹrọ ayarabiasa 5G naa yoo mu ki ẹrọ ayelujara ja geere fun awọn ti wọn ba n lo, to fi mọ fun imọ eto ilera ati eto ọgbin.

    Ileesẹ iroyin The Nation gbe pe MTN lo kọkọ bẹrẹ lilo 5G, ti Mafab to tẹle.

    Ninu ọrọ rẹ, adari ẹka karakata ni ileeṣẹ ibaraẹnisọrọ Airtel, Femi Oshinlaja ni 5G naa yoo bẹrẹ si ni ṣisẹ niAbuja, Lagos, Ogun ati ipinlẹ Rivers.

    Airtel fikun un pe laipẹ ni ẹrọ ayarabiasa yii yoo de awọn ipinlẹ to ku.

  3. Aliko Dangote àti Bill Gates ṣe àbẹ̀wò sí Niger àti Naijiria

    Aworan

    Aarẹ orilẹede Niger Republic, Mohamed Bazoum ti gbalejo aarẹ ileeṣẹ Bill and Melinda Gates Foundation, Bill Gates at Aliko Dangote to jẹ aarẹ ileeṣ̣ Dangote Group of companies.

    Ipade naa waye ni Naimey ni Niger Republic ni ọjọ Aje.

    Melinda Gates to sabẹwo si ilẹ Afrika naa ni ẹni to ni owo julọ ni agbaye.

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Facebook

    Aworan
    Aworan
    Aworan
    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Facebook

    Gates ati Dangote se abẹ si Niger ati Naijiria lati jiroro pẹlu awọn adari orilẹede naa ati lati jiroro nipa eto ilera lorilẹede naa ati idagbasoke awọn ilẹ yii.

    Bakan naa ni iroyin gbe pe Bill Gates sepade pẹlu aarẹ orilẹede Niajiria, Bola Ahmed Tinubu ni ilu Abuja ki wọn to gbera kuro ni Ọjọ Aje lọ si Naimey.

    Iroyin ni Bill Gates rin irinajo yii gẹgẹ bi ọkan lara igbesẹ rẹ lati sisẹ pọ pẹlu awọn adari ni ilẹ Afrika fun idagbasoke awọn orilẹede naa ni kiakia.

  4. Ààrẹ Tinubu yọ àwọn adarí àjọ tó wà ní àwọn iléeṣẹ́ ìjọba kúro ní ipò

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti rọ gbogbo awọn adari ajọ to wa ni awọn ileeṣẹ ijoba kuro ni ipo.

    Aṣẹ tuntun naa jade ninu atẹjade ti ijọba fi lede gba ọwọ adari ẹka eto iroyin, Willie Bassey ni ileeṣẹ akọwe ijọba orilẹede Naijiria, to si tun wa ni oju opo ikansiraẹni Twitter wọn.

    Atẹjade naa ni Aarẹ Tinubu buwọlu yiyọ awọn adari ileeṣẹ ijọba naa nipo gẹgẹ bi aṣẹ to ni labẹ ofin orilẹede Naijiria.

    Aarẹ ni igbesẹ ati yọ awọn adari naa waye lati fi aye silẹ fun ofin orilẹede Naijiria lati bori ati fun ifẹ awọn araalu.

    Bakan naa ni aarẹ fikun un pe titi wọn yoo fi yan awọn adari ileeṣẹ ijọba miran si ipo, wọn kede fun awọn adari ẹka ileeṣẹ naa lati fi gbogbo igbesẹ wọn ko akọwe ijọba leti, eleyii ti yoo fi to aarẹ orilẹede Naijiria leti.

    Igbesẹ tuntun yii yoo ti bẹrẹ lati Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Kẹfa, ọdun 2023.

    Amọ iyọnipo naa ko kan awọn ileeṣẹ ijọba wọnyii to wa ni abẹ ofin orilẹede Naijiria, ti wọn la kalẹ ni ẹka ‘’Third Schedule, Part 1, Section 153 (i)’’ ti iwe ofin orilẹede Naijiria ti ọdun 1999.

    Awọn ileeṣẹ ijọba wọnyii ni iyọnipo naa ko kan...

    1. Code of conduct Bureau

    2. Council of State

    3. Federal Character Commission

    4. Federal Judicial Service Commission

    5. Independent National Electoral Commission

    6. National Defense Council

    7. National Economic Council

    8. National Judicial Commission

    9. National Population Commission

    10. National Security Council

    11. National Police Council

    12. Police Service Commission

    13. Revenue Mobilization Allocation and Fiscal Commission

  5. Ààrẹ Tinubu rọ gbogbo olórí iléeṣẹ́ ọmọogun àti ọ̀gá ọlọ́pàá Nàìjíríà lóyè

  6. Ààrẹ Tinubu yóò rìnrìnàjò lọ Paris fún ìpàdé àdéhùn ìṣúná àgbáyé

    Aarẹ Bola Tinubu

    Aarẹ Bọla Tinubu yoo darapọ m awọn adari orilẹede lagbaye lati kopa nibi ipade adehun iṣuna agbaye, Global Financial Pact ti yoo waye ni ilu Paris lorilẹede France.

    Atẹjade kan lati ileeṣẹ aarẹ Naijiria ṣalaye pe Tinubu pẹlu awọn aarẹ yooku lagbaye yoo peju lọjọbọ ọjọ kejilelogun oṣu kẹfa lati jiroro lori adehun iranwọ iṣuna fun awọn orilẹede to ku diẹ kaato fun.

    Awọn orilẹede ti yoo janfani iṣuna to ba jade labẹ adehun naa lawọn orilẹede ti wahala ọrọ ayika, wahala nnkan amuṣagbara ati atubọtan ajakalẹ arun COVID-19 ba finra.

    Igba akọkọ niyi ti aarẹ Tinubu yoo maa rirnrinajo lọ silẹ okeere lati igba ti o ti gun ori aga aarẹ orilẹede Naijiria loṣu karun un.

  7. Ẹ sọ owó yíyá fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ di ẹ̀bùn owó fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó tálákà - ASUU

    Ẹnu ọ̀nà Fáṣítì Ibadan

    Ẹgbẹ awọn olukọ ni Fasiti, ASUU, ni ki Aarẹ Bola Tinubu yi eto owo yiya fun awọn akekọọ pada si ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́.

    Ààrẹ ẹgbẹ́ ASUU, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke, to sọ ọ̀rọ̀ naa ní ìdá aadọrun ninu àwọn akekọọ ni ko ni le ri gbogbo nnkan ti ijọba n beere fun kó sílẹ̀, saaju ki wọn to ri owo yá tabi sàn-án pada.

    Ọjọgbọn Osodeke sọ̀rọ̀ naa lasiko to kopa ninu Ifọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Channels lọjọ Àìkú.

    "Eto naa ko ba dara púpọ̀ ka ni àwọn akekọọ to tálákà gan-an la n fún. Owo ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ lo yẹ ko jẹ, kii ṣe owó yiya."

    O ni ko bojumu bi awọn akekọọ yoo ṣe san gbese laarin ọdun meji ti wọn ba kẹ́kọ̀ọ́ jáde, eyi to le yọrí si ẹ̀wọ̀n ti wọn ko ba ri owo naa san pada si apo ijọba.

    Osodeke sọ pe igba àkọ́kọ́ kọ́ rèé ti ìjọba da eto owo yiya silẹ fun awọn akekọọ.

    " Eto owo yiya fun awọn akekọọ ti waye ri lọdun 1972, awọn banki ti wọn dá silẹ nitori rẹ si lo mojuto o.

    " Àwọn to ya owo naa ko sàn-án padà."

    O ni ijọba ologun tun da àjọ miran silẹ fun eto naa lọdun 1994, ṣùgbọ́n o tun foriṣanpọn, ti owo ti ìjọba ko silẹ si pòórá.

    Ọjọgbọn Osodeke sọ pe owo naa ko le to o pín laarin bi miliọnu kan akekọọ to wa ni awọn fasiti ijọba ni Naijiria.

    Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹtàlá, osu Karùn-ún, ni Ààrẹ Bola Tinubu buwọlu eto owo yiya fun awọn akekọọ.

    Ìjọba ni eto yii labẹ akoso ileeṣẹ eto ẹkọ yoo seto ẹyawo fawọn akẹkọọ fasiti ti nkan ko gunrege fawọn ati obi wọn.

    Olori ile aṣojusofin tẹlẹ Femi Gbajabiamila lo ṣagbatẹru aba ofin naa nigba to jẹ olori ile.

  8. Aṣojú àti agbẹjọ́rò fún NLC kọ̀ láti yọjú sílé ẹjọ́ lòdì sí ìjọba

    Ile ẹjọ

    Bí ètò ìgbẹ́jọ́ se bẹ̀rẹ̀ ní ilé ẹjọ́ Industrial court nílùú Àbújá tó ń gbọ́ ẹ̀sùn tó wà láàrin ìjọba àpapọ̀ ati ẹ̀gbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà NLC ati TUC, akọ̀wé ilé ẹjọ́ tí ní ìgbẹ́jọ́ náà yóò tún wáyé lọ́jọ́ míìràn.

    Agbẹjọ́rò tó ń sójú fún ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ ní àwọn sẹ̀sẹ̀ gba ìwé ìpẹ̀jọ́ ní òwúrọ̀ yìí ni, nítorí náà, ó wa rọ adájọ́ pé kí wọ́n sún ètò ìgbẹ́jọ́ náà síwájú, bi èyí tí àgbẹjọ́rò ìjọba kò faramọ́ ohun tó wáyé.

    Ìdí ni wípé kò sí aṣojú ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ ìyẹn TUC àti NLC kankan tó fara hàn nílé ẹjọ́.

    Marshal Abubakar ni àgbẹjọ́rò fún ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ TUC àti NLC nígbà tí Ochum Emmanuel jẹ́ agbẹjọ́rò fún ìjọba.

    Kódà gbogbo àwọn ènìyàn tó wà nílé ẹjọ́ kò ju ènìyàn méjìdínlógún(18) lọ, tí a bá ka adájọ àtí àwọn òṣìṣẹ́ ilé ẹjọ́ mọ́ wọn.

    Bí ẹ kò bá gbàgbé, ní ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù kàrún ún ọdún yìí lásìkò ètò ìbúrawọlé ààrẹ Ahmed Bola Tinubu tí ó kéde yíyọ owó ìrànwọ́ orí epo bẹntiro kúrò ìyẹn PMS, ní èyí tí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ kò faramọ́ ni fà-kí-n-fà ayìí ti bẹ̀rẹ̀.

    Èyí ló fàá tí ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ se kéde ètò ìyansẹ́lódì, tí ìjọba àpapọ̀ kò bàá yí ìpinnu rẹ padà.

    Ìdí sì tún nìyí tí ìjọba àpapọ̀ se gbé ẹjọ́ náà wá sí ilé ẹjọ́ tó ń gbọ awuye-awuye ètò tó rọ̀ mọ́ àwọn òṣìṣẹ́ (Industrial court) láti má jẹ́ kí àwọn òṣìṣẹ́ gúnlè ètò ìyansẹ́lódì ọ̀hún.

    Adájọ́ àgbà Olufunke Anuwe ló ń gbọ́ ẹ̀sùn ìjọba àti ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ yìí, ó sì sún ìgbèjọ́ náà síwájú sí ogunjọ́ oṣù keje ọdún tí a wà yìí.

    Bákan náà, adájọ́ àgbà Olufunke Anuwe tún pàṣẹ fún ẹgbẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ láti má ṣe gùnlé ètò ìyansẹ́lódì lásìkò tí ẹjọ́ náà ṣì wà nílé ẹjọ́.

    Ile ẹjọ
  9. Torí ìfẹ́ àwọn ìbejì ni mo ṣe kọ̀ láti sọ ohunkóhun láti ọjọ́ yìí - Damola Olatunji

  10. A ń gbọ́ pé nítorí àwọn olùdókòwò kan láti China nìjọba fi ń wó ṣọ́ọ̀bù wa ní Alaba – Adarí ọjà Alaba

  11. 'Lásìkò tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ń kọrin ìyìn kí wọ́n tó sùn ni àwọn agbéṣùmọ̀mí dáná sun wọ́n'

  12. 'Ifá ló mú èmi o! Ẹnu iṣẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n Fásitì ni mo wà tí wọ́n ní kí n wá jẹ Olota ti ìlú Ota'

  13. Wọ́n fún mi ní májèlé jẹ ní ‘PDP secretariat’, Ọlọ́run ló kó mi yọ – Wike

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Gomina ipinlẹ Rivers tẹlẹ, Nyesom Wike ti ni wọn fun oun ni majele jẹ ni PDP secretariat in ọdun 2018 lasiko ipolongo idibo.

    O ni asiko yii ni wọn dunkoko mọ oun ninu ẹgbẹ naa amọ oun bori.

    Wike lo sọ bẹẹ lasiko idupẹ to se ni ọjọ Aiku, ni ijọ St. Peter’s Anglican church ni agbegbe Rumuepirikom Deanery, ni ipinlẹ Rivers.

    Wike ni Osu Kejila ọdun 2018 ni iṣẹlẹ naa waye to si yẹ ki oun lọ si ibi ayẹyẹ ni ọjọ keji amọ oun ko lee lọ nitori irora ti oun jẹ ni abẹ aṣọ.

    O ni lato ọjọ naa ni oun ko lee jade kuro ninu yara oun, ti wọn sare gbe oun lọ si ileewosan ni oke okun ti oun si ro pe aye ti pari fun oun.

    Nigba ti mo de ileewosan awọn dokita ni edo ati kidinrin oun ko ṣiṣẹ moọ, amọ pe awọn yoo gbiyanju lati sa ipa wọn.

    Awọn dokita ni kindinrin ati ẹdọ ti da iṣẹ silẹ, ti wọn si ti dudu.

    Amọ Ọlọrun gbakoso nitori awọn dokita pada wa pe ẹya ara oun naa ti bẹrẹ si ni dahun si itọju ti wọn si ti n ṣiṣẹ pada.

    Ọlọrun gbakoso, ẹdo mi ni ṣisẹ daradara, kidinrin mi n ṣiṣẹ daradara, ti awọn dokita si ni mo le pada si Naijiria lẹyin ọsẹ kan.’’

  14. Irọ́ ni pé à ń wá gómìnà ìpínlẹ̀ Zamfara tẹ́lẹ̀, Bello Matawalle – EFCC

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Matawalle

    Ajọ to n gbogun iwa ibajẹ lorilẹede Naijiria, EFCC ti ni ko si otitọ ninu iroyin to ni pe awọn n wa gomina ipinlẹ Zamfara to ṣẹṣẹ kuro ni ipo, Bello Matawalle.

    Ninu iroyin ti wọn fi si oju opo Twitter wọn, EFCC ni iroyin ti ileeṣẹ iroyin kan fi sit ani Ọjọ Isinmi, Ọjọ Kejidinlogun, Osu Kẹfa pe ko si otitọ ninu iroyin naa.

    Iroyin ọhun ni EFCC ti kede pe awọn n wa gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ naa, ti wọn si ti paṣẹ fun ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ki wọn fi panpẹ ọba mu ti wọn ba ti ri nibikibi.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

    Amọ ajọ EFCC ni awọn ki n ṣisẹ ti awọn bẹẹ ti awọn si ma n tẹlẹ ilana ati alakalẹ to ba ofin mu lati se iṣẹ wọn.

    Wọn ko si otitọ ninu iroyin naa ati pe awọn ko kede pe wọn n wa gomina naa.

    Bakan naa ni wọn ni awọn ko bẹ DSS nisẹ kankan lati mu Matawalle.

    Ajọ naa kesi awọn oniroyin lati jawọ gbigbe iroyin ẹlẹjẹ nipa ileeṣẹ awọn.

    Amọ saaju ni aawọ ti w ani aarin gomina ipinlẹ Zamfara tẹlẹ naa ati ajọ EFCC lori ẹsun ti Mtawalle fi kan olori ajọ naa tẹlẹ, Abdulrasheed Bawa wi pe iwa ajẹbanu lorisirisi lo kun ọwọ rẹ.

    Ni ọsẹ to kọja ni aarẹ orilẹede Naijiria, Bola Ahmed Tinubu paṣẹ ki adari ajọ EFCC naa, Absulrasheed Bawa lọ rọkun nile.

  15. ‘’A ti dóòlà ẹ̀mí àwọn ènìyàn 120 tí ọkọ̀ ojú omi wọn gbiná’’

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Awọn ẹsọ alaabo lorilẹede Philipine ti awọn ti doola ẹmi awọn eniyan to le ni ọgọfa ti ọkọ oju omi wọn gbana.

    Iṣẹlẹ yii waye lasiko ti ọkọ oju omi nla naa wa lori agbaami nla ti o sunmo awọn ilu to w ani eti omi.

    Iroyin ni ọkọ oju omi naa gbe awọn ero ọkọ marunlelọgọta, awọn ikọ ọmọogun marunlelaadọta to fi mọ awọn oṣiṣẹ ọkọ oju omi naa.

    Agbẹnusọ ileeṣẹ ẹsọ alaabo oju omi orilẹede naa ni iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa amọ awọn ko mọ ohun to fa ina naa lori omi.

    Iroyin ni kii se igba akọkọ ree ti iru iṣẹlẹ naa yoo ma waye.

  16. Àwọn olóṣèlú alátẹnujẹ kan fẹ́ lo àìlera Akeredolu fi ja ìpínlẹ̀ Ondo lólè – Amúgbálẹ́gbẹ́ fún gómìnà Akeredolu

  17. ‘Omijé gba ojú mi kan’, Davido ń dárò ní àyájọ́ ‘Father’s Day’

  18. Àwọn olórí orílẹ̀ èdè Adúláwọ̀ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Russia àti Ukraine láti dáwọ́ ogun dúró

  19. Iṣẹ́ olùkọ́ kò lówó lórí àmọ́ ó ní ipa púpọ̀ ju iṣẹ́ tíátà lọ fún mi - Saka

  20. Àsírí àwọn tó fé se ìfẹ̀họ́núhàn láti dìtẹ̀ mọ́ ìjọba ti tú sí wa lọ́wọ́ -DSS

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ lorilẹede Naijiria, DSS ti kede pe awọn ti ri awọn eniyan kan ati igbimọ kan ti wọn gbimọ pọ lati se ifẹhọnuhan tako ijọba.

    Wọn ni awọn to fẹ se ifẹhọnu han naa n se atilẹyin fun gomina banki apapọ Naijiria tẹlẹ, Godwin Emefiele ti wọn yọ ni ipo.

    Ileesẹ Ọtẹlẹmuyẹ naa ni awọn eniyan yii fẹ kora wọn jọ pọ ni ilu Abuja ati ni ilu Eko ni awọn agbegbe ni ọsẹ to n bọ lati gbe paali ifẹhọnu han kaakiri agbegbe naa.

    DSS ni oun ti awọn wọnyii fẹ se ni lati ba orukọ ijọba jẹ ati lati tabuku ajọ DSS to n sisẹ ilu.

    Wọn awọn yii fẹ beere fun ki wọn fi Emefiele silẹ ni kiakia, lati fi ti ẹnikẹni se

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

    DSS wa fi asiko yii kilọ fun awọn araalu wi pe awọn ko ni fi aye gba awọn to fẹ da oju ijọba kalẹ, tabi dena awọn lati se isẹ awọn ni ọna to ba ofin mu.

    Bakan naa ni DSS ni awọn ri awọn fidio ati awọn ọrọ kubakugbe ti awọn kan n pin kaakiri lori ẹrọ ayelujara lọna ati tako awọn.

    Wọn wa fi n to awọn araalu leti pe awọn ti wọ aarin awọn wọnyii ti wọn ko mọ, ti adari wọn si ti w ani arọwọto wọn.

    Bakan naa ni DSS fi n da awọn araalu loju pe awọn ẹbi, ati awọn dokita Emefiele to fi mọ awọn to letọ lati ri ni wọn fun ni anfaani, ki ileẹjọ to pasẹ bẹẹ ni awọn ti tẹle ofin ọhun.