Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ 5,344.1Kg igbó nípìnlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, NDLEA
Awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti lilo oogun oloro ni Naijiria, NDLEA, ti gbẹsẹ le igbó ti odinwọn rẹ le ni ẹgbẹrun marun-un kilogiraamu, 5, 344.1Kg nipinlẹ Eko.
Ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ ajọ naa, Femi Babafemi fi sita, o ni ọwọ tẹ oogun oloro naa lẹyin ti iroyin tẹ ajọ NDLEA lọwọ pe ọkọ̀ akẹru kan yoo gba agbegbe Alpha Beach, loju ọna Epe si Lekki kọja.
“Awọn oṣiṣẹ NDLEA dena de ọkọ to ko oogun oloro ti ìwọ̀n rẹ jẹ́ 2434.1kg, ti wọn dì sinu aadọta àpo, ni owurọ kutu ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa."
Ṣugbọn awakọ rẹ fo jade ninu ọkọ to si sare ko sinu ọkọ awọn oṣiṣẹ alaabo to n ba a rinrinajo.
Yatọ si eyi, Ọgbẹni Babafẹmi sọ pe ọwọ tun tẹ awọn ọkunrin meji kan to jẹ ọmọ orilẹ-ede Ghana ni ogunjọ oṣu Kẹfa bakan naa, nibi ti wọn ti wa pẹlu iwọn 2,910kg igbo ni Alpha Beach bakan naa.












