Òṣìṣẹ́bìnrin ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú òfurufú pokùnso, ìwádìí bẹ̀rẹ̀

Oríṣun àwòrán, TWITTER
Arábìnrin kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò ojú òfurufú kan ìyẹn Nigeria Air Force (NAF) ni wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú ilé níbi tó pokùnso sí.
Arábìnrin náà tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní George gba ẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀ sínú ilé ìgbé àjọ ọ̀hún ní block T5, Sam Ethnam Base tó wà ní agbègbè Ikeja ìpínlẹ̀ Eko.
Ìròyìn ní àwọn òṣìṣẹ́ ilé ìwòsàn NAF ló lọ gbé òkú náà.
Ní nǹkan bíi aago méjì ọ̀sán ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìṣẹ̀lẹ̀ búburú náà wáyé.
Agbenusọ ẹ̀ṣọ́ ààbò òfurufú, Commodore Ayodele Famuyiwa tó fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ ní àwọn tí gbé ìgbìmọ̀ dìde láti ṣèwádìí ikú rẹ̀.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ, ohun tó fà á tí obìnrin náà fi gba ẹ̀mí lọ́rùn ara rẹ̀ nípa pípokùnso kò ì tíì yé ẹnikẹ́ni báyìí.










