Ṣé ẹ l’éèyàn ní àwọn agbègbè yìí l’Ámẹ́ríkà? Ìkìlọ ti jade fún èèyàn 170 miliọ̀nù nipa èéfín, oru

Oríṣun àwòrán, others
O le ni eeyan miliọnu aadọsan ara Amẹrika to ti n jiyaa yala oru gbigbona tabi afẹfẹ buruku to n fẹ ti ikilọ si ti jade pe eefin buruku kan ati oru gbigbona ti di ajalu to re lu ilẹ Amẹrika. Irufẹ afẹfẹ to n fẹ lawọn apa ibi kan ti wọn n pe ni Midwest ati Mid-Atlantic ni awọn onimọ nipa ilera ti ni ko dara fun ilera awọn eniyan.
Ẹwẹ awọn ilu bii Las Vegas ati Phoenix ti n gbaradi fun oju ọjọ gbigbona to le ni 43C (110F) ni opin ọsẹ yii.
O kere tan eeyan bii dọsiini kan lo ti ku latari nnkan to sun mọ oru gbigbona lẹnu ọjọ diẹ bayii.
Afẹfẹ ti ko dara to n fẹ ni wọn ti tọka okunfa rẹ si awọn nnkan to n wa latinu aginju to le ni ẹẹdẹgbẹta ni Canada bi wọn ṣe fi ọpọlọpọ eefin ranṣẹ sita bo tilẹ jẹ pe nnkan ti n dara lawọn apa ibi kọọkan ni aarin gbungbun Ila Oorun.
Ni Ọjọ Ẹti ni wọn reti afẹfẹ ti ko dara ju ni orilẹede naa kaakiri ọpọlọpọ ilu to tan kan lati Michigan ati Ohio titi de East Coast. Afẹfẹ ti ko dara ju ni US waye ni Ọjọ Ẹti ni nnkan bii ago mẹsan wọn (14:00 BST) ni ilu New York, lẹyin naa, o tun waye ni Washington DC, ni Detroit ati Chicago gẹgẹ bi oju opo IQAir.com ṣe fi sita.
Ajọ to n boju to aabo ayika sọ pe afẹfẹ ni awọn agbegbe yii jẹ eyi ti “ko dara fun ilera awọn eeyan kan pato” – bii awọn arugbo, ọmọ kekere atawọn to jẹ ita ni wọn ti n ṣiṣẹ tabi ka kan ṣaa ni ko dara fun ilera rara. Awọn alaṣẹ ti wa fi imọran sita jakejado ilẹ Amẹrika nipa iru afẹfẹ to n fẹ ti wọn si ni ki awọn ara New York ṣọ ilera wọn.
Ni agbegbe Washington DC, erongba ti n waye lori iru afẹfẹ to n fẹ eyi to jẹ ki wọn wọgile ọpọlọpọ nnkan to maa n waye nita gbangba to fi mọ ikilọ kan latọdọ awọn onimọ ilera labẹle wipe ki awọn eeyan yago fun iṣẹ ti wọn n ṣe nita to ba lagbara ju ati pe ki wọn lo ibomu ti wọn ba ti wa nita.
Ẹwẹ, ni apa Iwọ Oorun Us, ọpọlọpọ miliọnu awọn eniyan ni Nevada, Arizona ati California ni ki wọn maa reti oru gbigbona bẹrẹ lati ọjọ Abamẹta pẹlu oju ọjọ oru ti yoo goke sii si bii 43C.
Ni Texas, ti awọn ti baba ri oju ọjọ oru to gbona to 37C fun bii ọsẹ meji bayi, o ti bẹrẹ si ni wa silẹ. Iroyin ni eeyan mọkanla lo ti ku latari ohun to sunmọ oru gbigbona ni bii agbegbe ilu Laredo lọna ibode Mexico.
Ikilọ ti waye bakan naa fun awọn ara agbegbe East Texas bakan naa ni wọn ni iji lile ṣeeṣe ko waye ni iha Guusu eyi to yẹ ko mu oju ọjọ oru yii walẹ ni ọjọ Abamẹta ati ọjọ Aiku.
O le ni eeyan ẹẹdẹgbẹrin to n ku latari ohun to sunmọ oru gbigbona lọdọọdun gẹgẹ bi iṣiro CDC pẹlu nnkan bii eyan ẹgbẹrun lọna mejidinlaadọrin ti wọn maa n gbe lọ si ile iwosan fun itọju pajawiri. Iji oru ti wa di lemọ lemọ bayii, o lagbara o si n pẹ gan to ba ti ja nitori awọn nnkan to jẹ afọwọfa ọmọ eniyan, awọn onimọ sayẹnsi lo sọ eyi.
Awọ́n kan naa ti kilọ pe ayipada oju ọjọ ṣeeṣe ko mu ki ọpọ eefin pọ sii. Atẹjade kan lati Ile ẹkọ giga fasiti kan ni California – “Irvine study” eyi to jade ni ọjọ kejila oṣu kẹfa fun apẹrẹ fi iwadi han pe “oju ọjọ gbigbona yoo lọ soke sii ati ọgbẹlẹ si ti jẹ ọkan lara ohun to maa n ṣokunfa bi igbo aginju ṣe maa n jó.











