Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Messi dara pọ̀ mọ́ Inter Miami
Oríṣun àwòrán, other
Gbajumọ ẹlẹsẹ ayo, Lionel Messi ti sọ pe ẹgbẹ agbabọọlu Inter
Miami loun yoo ti maa gba bọọlu jẹun ni saa to n bọ.
Messi n ko ẹru rẹ kuro ni ikọ PSG lorilede France nibi ti o ti
n gba bọọ jẹun lati nnkan bii ọdun meji sẹyin.
Ṣaaju ikede rẹ, ọpọ eeyan, paapaa awọn ololufẹ rẹ ati ti ẹgbẹ
agbabọọlu Barcelona lo ti n wo pe Barca ni Messi yoo lọ.
Oríṣun àwòrán, other
Bakan naa lawọn miran n wo o pe boya liigi ilẹ Saudi Arabia ni
yoo lọ pẹlu bi awọn eekan agbabọọlu bii Cristiano Ronaldo, Kareem Benzema ati beebeelọ
ṣe n dari kọ ilẹ Saudi lẹnu akoko yii.
Lionel Messi ni kii ṣe rori owo loun se gbe igbesẹ naa ari pe
to ba jẹ bẹẹ ni, orilẹede Saudi loun iba gba lọ
“Mo ri pinnu lati dara pọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu Inter Miami” ni ọrọ
ti Messi ba awọn akọroyin kan sọ
‘A ò tíì gbúròó Tinubu, ohun táa fẹ́ lọ́dọ́ rẹ̀ rèé bí àwa aráàlú ṣe ń jẹ pálí ìyà toríi subsidy’
Pope Francis tó jẹ́ ẹni ọdún 86 yóò nílò iṣẹ́ abẹ inú
Poopu Agba, Francis ni wọn ti ṣetan lati se iṣẹ abẹ fun
ni ọsan Ọjọru ni ileewosan Rome Gemelli Hospital.
Pope naa ni wọn lero pe yoo wa ni ileewosan fun ọjọ diẹ
lati le sinmi, ko si gba iwosan to peye lẹyin iṣẹ abẹ inu ti wọn pe orukọ
rẹ ni, hernia operation.
Aisan isalẹ inu naa ni wọn ni ohun fa inira lọpọlọpọ
fun Pope naa, ti ko si see fi mọ ara mọ.
Agbẹnusọ fun Vatican, Matteo Bruni ni ọpọlọpọ ipenija
ilera ni Pope naa n la kọja lati bii ọdun diẹ.
Bruni fikun un pe nigba miran lori aga tabi ọpa ni Poopu
naa fi n rin nitori erunkun ẹsẹ to n
dun un.
Bakan naa lo fikun un pe Pope Francis yoo lo ọjọ diẹ ni
ileewosan naa lati wo bi ara rẹ yoo se ri lẹyin iṣẹ abẹ naa.
Ni Ọjọ Iṣẹgun ni Poopu Francis lọ si ileewosan fun
ayẹwo ni Rome Hospital naa, lẹyin to ti lo ọpọlọpọ osu ni ileewosan fun
aisan ‘’Bronchitis’’.
Bakan naa lo lo ọjọ mẹta ni ileewosan ni Osu Kẹta fun
aisan ọna ọfun, ni osu naa lo se ayajọ ọ̀un kẹwaa to gori oye Pope.
Osu to kọja ni Pope oun kuro nibi ẹsin Ọjọ Ẹti nitori
ara rẹ to gbona kọja bi o se yẹ.
Bio tilẹ jẹpe Pope Benedict XVI to kuro nibẹ ki oun to de
ibẹ kọ iwe fi ipo silẹ ni, amọ Pope ti ni ko si ohun to jọ bẹẹ ni ọrọ
ti oun.
Pope Gbagbo wi pe kii se orunkun ni eniyan fi n dari ẹsin
bi ko se imọ, ọgbọn ati oye, eleyii to wa lati inu ọpọlọ.
Ariwo gbòde pé Sweden tí sọ ìbálòpọ̀ dì eré ìdárayá; Èsì ìjọba rèé lórí European Championship in Sex
Àjọ INEC kéde orúkọ̀ àwọn olùdíje fún ipò gómìnà ní ìpínlẹ̀ Kogi, Bayelsa àti Imo
Oríṣun àwòrán, other
Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC ti gbe orukọ awọn
oludije fun ipo gomina ni ipinlẹ Kogi, Bayelsa ati Imo jade.
Alamojuto agba fun eto ilanilọyẹ fun awọn iludibo,
Festus Okoye sọ pe nibi ipade igbimọ iṣakoso ajọ INEC to waye lọjọ Iṣẹgun ni wọn
ti buwọlu orukọ awọn oludije naa.
“Eyi wa ni ibamu pẹlu a ala ikejilelọgbọiwe ofin eto idibo ti ọdun 2022 eyi to laa kalẹ
pe ki wọn kede orukọ awọn oludibo, o pẹ ju aadọjọ ọjọ si ọjọ idibo, eleyi to jẹ
ọjọ Ẹti, ọjọ kẹsan an oṣu kẹjọ ọdun 2023.”
O ni oruko awọn oludije naa ti wa loju opo ayelujara
ajọ naa bayii.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.
End of X post
Gẹgẹ bi atẹjade naa ṣe sọ, ẹgbẹ oṣelu mejidinlogun
lo n kopa ni eto idibo gomina ni Kogi, ẹgbẹ oṣelu metadinlogun lo n kopa ni ti Bayelsa
ti mẹrindinlogun yoo si kopa ni ti ipinlẹ Imo.
Bakan naa lo tun fi han pe ẹgbẹ oṣelu meji lo n
fa obinrin kalẹ gẹgẹ bi oludije ni Bayelsa ati Kogi, nigba ti ko si oludije obinrin
kankan fun ti Imo.
Ajọ wa ran awọn oloṣelu lawọn ipinlẹ yii leti pe
ọjọ kẹrinla oṣu kẹfa ni ilẹkun ipolongo ibo fun awọn oludije yoo to ṣi silẹ.
Olórí méjì ń jà fún àkóso ilé aṣòfin Nasarawa
Oríṣun àwòrán, others
Olori meji lo ti dide ni ile igbimọ aṣofin ipinlẹ
Nasarawa.
Awọn aṣofin fun saa ile igbimọ aṣofin keje ni ipinlẹ
Nasarawa yan awọn aṣiwaju lẹtin ti wọn bẹrẹ iṣẹ lọjọ Iṣẹgun.
Ibrahim Balarabe ati Daniel Ogazi lati ẹkun iwọ
oorun ipinlẹ naa lawọn meji to n pe ara wọn
ni olori ile naa bayii.
Ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹfa lo yẹ ki wọn ṣe ifilọlẹ ile
igbimọ aṣofin keje ni ipinlẹ naa, ṣugbọn akọwe agba ile aṣofin ni ipinlẹ Nasarawa
kede isunsiwaju eto ifilọlẹ naa nitori ohun to pe ni ikayasoke lori abo.
Awọn agbofinro di ile aṣofin naa pa eyi ro mu ki
Ogazi at’awọn to gbe lẹyin rẹ o duro pa si inu gbagede ile igbimọ aṣofin naa titi
di agogo mẹfa irọlẹ.
Arúmọjẹ lásán ni ìfilọ́lẹ̀ Nigeria Air tí ìjọba Buhari ṣe kó tó kúrò nípò
Oríṣun àwòrán, other
ile igbimọ aṣofinṣoju lorilẹede Naijiria ti tọka
si eto ifilọlẹ ileeṣẹ baluu Nigeria Air lasiko ti ijọba ana labẹ Muhammadu Buhari
n ko igba wọle gẹgẹ bi arumọjẹ lasan
alaga igbimọ ti ile aṣofinṣoju gbe kalẹ lori irinna
ofurufu, Nnolim Nnaji sọ laifọtape 0e bi ijọba ana ṣe ṣe kurukẹrẹ sare ṣe ifilọlẹ
ileeṣẹ baluu Nigeria Air naa ni jibiti lasan ni eyi nitori pe awọn eekan to lọwọ
ninu idasilẹ ileeṣẹ naa lati ibẹrẹ pẹpẹ, bii ijọba apapọ ati ileeṣẹ irinna ofurufu,
Ethiopian Airlines ni wọn n sẹ.pe awọn ko mọ si ọrọ naa.
Ileeṣẹ irinna ofurufu nijọba apapọ ti kọkọ sọ wi pe, wọn kan
ṣi aṣọ kuro loju rẹ ni, wọn ko tii ṣe ifilọlẹ rẹ.
Iyalẹnu lo jẹ fun igbimọ naa nigba ti ajọ ro n ri si igbokegbodo ọkọ ofurufu NAMA, pẹlu bọ
sita ṣalaye eyi.
Kókó, Ìgbìyànjú ń lọ lọ́wọ́ láti dóòlà ẹ̀mí àwon ènìyàn níbi adágún odò Ukraine tó ya lulè
Àkọlé fídíò, Watch: Water gushes through damaged Ukraine dam
Awọn oṣiṣẹ
pajawiri n gbiyanju lati doola ẹmi awọn eniyan nipa kiko wọn kuro ni agbegbe
Kherson ni orilẹede Ukraine.
Eyi waye lẹyin ti
adagun odo ti wọn n pe ni Dam fay naa ya ni agbegbe Kherson, ti orilẹede Russia ti
gba lọwọ Ukraine lasiko ogun to n lọ lọwọ nibẹ.
Awọn ikọ ọmọgun
Ukraine ti fi ẹsun kan Russia wi pe awọn lo sekọlu si adagun odo naa ni ilu
Nova Kakhovka.
Amọ ni idahun si
ẹsun yii, orilẹede Russia ni awọn ko mọ nkankan nipa iṣẹlẹ naa.
Aarẹ orilẹede
Ukraine, Volodymr ni awọn ilu kereje bii ọgọrin ni omiyale naa ti ṣọṣẹ
si.
Nibayii, Ileeṣ̣ẹ iroyin ilẹ Russia ni ijọba orilẹede Russia ti kede ilu ko fararọ ni agbegbe
naa.
Aarẹ ajọ iṣọkan
ilẹ Yuroopu, Charles Michel da ẹbi iṣẹlẹ naa ru Russia, to si ni ikọlu
ohun ini awọn araalu jasi iwa ọdaran ni agbegbe.
Bakan ni adari ikọ
Iṣọkan Agbaye, UN to n risi lilo ohun ija oloro ọlọgọọrọ ni aisi omi
tutu le fa ifasẹyin fun igbiyanju wọn lati doola ẹmi awọn eniyan, amọ o ni
igbiyanju n lọ lọwọ lati da omi naa duro.
Amọ oṣiṣẹ
orilẹede Russia to wa nibẹ ni ẹrọ amunawa to wa nibẹ ni ado oloro ti wọn
ju bajẹ, amọ kii se adagun odo naa, nitori naa kii se awọn.
Bakan naa ni Russia da ẹbi iṣẹlẹ naa ru
Ukraine, pe Ukraine lo jẹbi iṣẹlẹ naa.
Nínú ibojì òkú yìí làwa ti ń jẹun, sùn, ṣiṣẹ́, ẹ ṣàánú wa torí ...
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC, TUC ṣẹ́wé lé ìyanṣẹ́lódí tí wọ́n ń gbèrò
Oríṣun àwòrán, others
Ni alẹ ọjọ Aje ni wọn ṣe ipinnu yii lẹyin ijiroro
pẹl’awọn aṣoju ijọba apapọ nibi ipade kan ni ile Aarẹ, Aso Rock Villa lori owo iranwọ
‘subsidy’ori epo bentiroolu ti ijọba yọ.
Olori ile aṣojuṣofin apapọ NaijiriaHọnọrebu Fẹmi Gbajabiamila ṣalaye abajade ipade
naa fun awọn akọroyin pe adehun ati ifẹnuko ti waye pẹlu NLC ati TUC lori awọn ọrọ
to jẹyọ lori yiyọ owo iranwọ naa.
Oríṣun àwòrán, others
Bakan naa lo ni peijọba apapọ, ẹgbẹ oṣiṣẹ TUC ati
NLC ti gba lati gbe igbimọ kan kalẹ lati ṣe agbeyẹwo awọn aba to wa nilẹ lori owo
oṣu to kere julọ fun oṣiṣẹ, ki wọn su tun ṣe agbekalẹ akoko ti yoo gba won lati
bẹrẹ si nii san an.
Bakan naa lo ni igun mejeeji yoo jọ mojuto pinpin owo ti ijọba apapọ
fẹ ya lọwọ banki agbaye lati fi san owo iranwọ fun araalu ati atunṣe awọn ibudo
ipọnpo gbogbo to di apati lorilẹede Naijiria at’awọnipinnu mii.
Ọjọru lẹgbẹ oṣiṣẹ NLC n gbero lati gunle iyanṣẹlodi tẹlẹ
Nǹkan tó yẹ kí o mọ̀ nípa Tomiwa Omolewa, alága PMS tuntun nípìnlẹ̀ Oyo tó rọ́pò Auxilliary
NLC kò kópa,TUC ìjọba ṣèpàdé lórí owó oṣù tó kéré jùlọ
Oríṣun àwòrán, COLLAGE
Ìjọba àpapọ̀ ti ní àwọn yóò ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn nǹkan tí ẹgbẹ́
òṣìṣẹ́ TUC gbé síwájú àwọn tó fi mọ́ owó oṣù tó kéré jùlọ.
Nígbà tó ń bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lẹ́yìn ìpàdé tó wáyé
láàárín ìjọba àpapọ̀ àti TUC èyí tó wáyé fún bíi wákàtí mẹ́ta, Agbẹnusọ ìjọba àpapọ̀,
Dele Alake ní àwọn máa wò ó tó bá jẹ́ wí pé àwọn ìbéèrè jẹ́ ohun tí ìjọba le ṣe
àmúṣẹ rẹ̀.
Ó ní lára nǹkan tí ìjọba ń rò láti ṣe tẹ́lẹ̀ láti mú ìdẹ̀kùn
báwọn lórí ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù tí wọ́n yọ ni láti fi ojú fo owó orí fún
wọn fún ìgbà kan ná.
Ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ Nàìjíríà, NLC kọ̀ láti yọjú síbi ìpàdé náà.
Alake ní ohun tó dájú ni pé Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yóò gbé
ìgbìmọ̀ kan dìde èyí tí àwọn ìpínlẹ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ yóò ní aṣojú níbẹ̀, tí wọn
yóò sì jíròrò lórí owó òṣìṣẹ́ tó kéré jùlọ.
Ó ṣàlàyé pé kò sí aáwọ̀ láàárín ìjọba àpapọ̀ àti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́
Nigeria Labour Congress, NLC lórí ìbéèrè wọn pé kí ìjọba fowo kún owó òṣìṣẹ́.
Bákan náà ló fi kun pé bí NLC kò ṣe sí níbi ìpàdé tí wọ́n ṣe
lọ́jọ́ Àìkú kò túmọ̀ sí pé wọ́n fojú kéré wọn.
Agbẹnusọ Tinubu ní ìjọba àpapọ̀ tún ti ń gbìyànjú láti kàn
sí wọn fún ìpàdé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Ẹ̀wẹ̀, TUC nínú ìbéèrè tí wọ́n gbé síwájú ìjọba àpapọ̀ ní kí
ìjọba dá owó epo padà sí iye tó wà tẹ́lẹ̀ kí ìjíròrò fi wáyé láàárín wọn.
Ààrẹ TUC, Festus Osifo ní àwọn ní ìrètí pé ìjọba àpapọ̀ yóò
gbọ́ tàwọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣe ṣe ìlérí pàápàá lórí ọ̀rọ̀ owó oṣù tó kéré jùlọ tí
òṣìṣẹ́ yóò máa gbà.
Ọba ò lè pé méjì láàfin ni mo fi yọ Auxiliary nípò - Makinde
Oríṣun àwòrán, COLLAGE
Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde ti ṣàlàyé ìdí tó fi ní kí
alága tẹ́lẹ̀ rí fún gááràjì ní ìpínlẹ̀ náà, Alhaji Mukaila Lamidi tí ọ̀pọ̀ mọ̀
sí Auxiliary lọ rọ́kún nílé.
Makinde ní ọba kò lè pé méjì láàfin ni òun fi fọwọ́ òsì júwe
ilé fún Auxiliary.
Níbi ètò ìsìn ìdúpẹ́ fún ìbúrawọlé sáà kejì rẹ̀ ní ilé ìjọsìn
Cathedral of St. Peter, Aremo, Ibadan lọ́jọ́ Àìkú ni Seyi Makinde ti sọ̀rọ̀
náà.
Makinde sọ àrídájú rẹ̀ wí pé ìjọba yóò ṣe àfọ̀mọ́ àwọn
gáréèjì àti pé gbogbo àwọn tó ń da ìlú láàmú ni àwọn máa fi òfin gbé.
Ó ṣàlàyé pé kí ètò ìdìbò tó wáyé ni àwọn ti pe àwọn alókòóso
gáréèjì sí ìpàdé láti ṣe ìkìlọ̀ fún wọn pé àwọn kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni máa fa
wàhálà.
"A ṣàlàyé fún wọn pé tí a bá wọlé fún sáà kejì, a ma ri
dájú pé àláfíà jọba, tí a máa ri pé ìrẹ́pọ̀ wà láàárín wọn."
"Ẹnìkan ló fárígá pé òun kò lè bá àwọn yòókù ṣe, èmi
náà sì sọ wí pé ìjọba méjì kò lè máa ṣàkóso ìlú kan."
Ìdí rèé tàwọn òṣìṣẹ́ iná mọ̀nàmọ́ná láwọn náà yóò da iṣẹ́ sílẹ̀ jákèjádò Nàìjíríà
Ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ mọnamọna ni Naijiria naa ti kede pe awọn yoo darapọ mọ ẹgbẹ oṣiṣẹ NLC ninu iyanṣẹlodi tori afikun ow epo bẹntiroo ni Naijiria.
Wọn lawọn gbe igbesẹ naa nitori pe ẹgbẹ oṣiṣẹ lawọn n ṣe iyanṣẹlodi naa nitori bi ijọba ṣe yọ ẹkuwo epo taa mọ si subsidy eleyi to mu ki nkan wọn lọja ni Naijiria.
Olori ẹka alamojuto ẹgbẹ naa Godfrey Aba to n ṣe akoso ilu Abuja ati Kogi fidi ọrọ yi mulẹ fun BBC pe iyanṣẹlodi yi yoo bẹrẹ lọjọ Keje oṣu Kẹfaa titi di igba ti ijọba yoo fi yi ipinnu pada lori afikun owo epo bẹntiroo.
Ninu atẹjade ti adele akọwe agba ẹgbẹ naa wọnDominic Agwebike fi sita o ni o kesi awọn ọmọ ẹgbẹ lati maa fọkan tẹle ikede ẹgbẹ lati gunle iyanṣẹlodi yi lọsẹ yi.
Oríṣun àwòrán, TCN
Ẹgbẹ oṣiṣẹ Naijiria NLC ati TUC ti ṣaaju kede pe awọn yoo ṣe iyanṣẹlodi l'Ọjọru tako bi ijọba ṣe yọ subsidy lori epo bẹntiroo.
Aarẹ tuntun Bola Ahmed Tinubu lo kede pe ko ni si ẹkunwo lori epo bẹntiroo mọ lasiko ayẹyẹ iburawọle sipo rẹ.
Awọn ẹgbẹ akọroyin naa pẹlu awọn to ni awọn yoo darapọ mọ iyanṣẹlodi yi.
Bi aarẹ tuntun ba ṣe yanju ọrọ yi si yoo jẹ atọna bi ijọba rẹ yoo ṣe ba awọn oṣiṣẹ ati araalu ṣepọ lori awọn igbesẹ to nipa ni igbesi aye wọn.
Oríṣun àwòrán, NUEE
Wo ìpéjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Èṣù àti bí wọ́n ṣe ń ṣe ìjọ́sìn, ìgbéyàwó, àtàwọn ayẹyẹ wọn
Dúkìá Ààrẹ Buhari kò lè síi nígbà tó wà lórí oyè - Garba Shehu
Àwọn jàǹdùkú ṣe ìkọlù sí Yahaya Bello, àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò farapa
Oríṣun àwòrán, Facebook
Àwọn afurasí gẹ́gẹ́ bí jàǹdùkú òṣèlú ní ọjọ́ Àbámẹ́ta ṣe ìkọlù
sí gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello.
Ìkọlù yìí ṣokùnfà bí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó ń mójútó Yahaya ṣe
farapa.
Ní nǹkan bíi aago méjìlá ọ̀sán ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrin oṣù
Kẹfà ni ìkọlù náà wáyé ní agbègbè Naval Base, kìlómítà díẹ̀ sí ìlú Lokoja tó jẹ́
olú ìlú ìpínlẹ̀ ọ̀hún.
Kọmíṣọ́nà fétò ìròyìn Kogi, Kingsley Fanwo nígbà tó ń fi
ìròyìn náà léde ní bí àwọn jàǹdùkú náà ṣe rí ọkọ̀ gómìnà tó ń bọ̀ ni wọ́n sí á
ìbọn bolẹ̀ fún un.
Fanwo fẹ́sùn kàn pé àwọn alátakò ẹgbẹ́ àwọn ló wà nídìí ìkọlù
yìí àmọ́ BBC Yoruba kò lè fìdí èyí múlẹ̀.
O fi kun pé gómìnà Bello kò fi ara pa nínú ìkọlù ọ̀hún
nítorí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò rẹ̀ tètè gbé e kúrò níbẹ̀ ṣùgbọ́n tí díẹ̀ lára àwọn ẹ̀ṣọ́
ààbò náà farapa.
Kọmíṣọ́nà náà wá ké sí àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò láti ṣàwárí àwọn tó
wà nídìí ìkọlù ọ̀hún kí wọ́n sì fojú wọn winá òfin.
Bákan náà ló tún ní gómìnà Bello tí ṣèkìlọ̀ pé ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú
kankan kò gbọdọ̀ dìde láti sọ wí pé òun fẹ́ gbẹ̀san ìkọlù ọ̀hún.
Ìkọlù yìí ló ń wáyé bí ètò ìdìbò sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tí
yóò wáyé nínú oṣù Kọkànlá ṣe ń súnmọ́ etílé.
Wo àwọn gbajúmọ̀ ọmọ Yorùbá tí ilé ẹjọ́ sọ sẹ́wọ̀n gbére tàbí dájọ́ ikú fún
N kò ní èròńgbà láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC - Wike
Oríṣun àwòrán, Others
Gomina tẹlẹ nipinlẹ Rivers, Nyesom Wike ti ni oun ko ni
erongba lati darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lẹyin to kopa ninu ipade alatilẹkunmọri pẹlu
Aarẹ Bola Tinubu.
Wike, pẹlu Gomina Seyi Makinde ti ipinlẹ Oyo ati James Ibori
lo se abẹwo si Aarẹ lati kede atilẹyin wọn fun un lẹyin ọjọ mẹrin ti wọn se
ibura fun Aarẹ orilẹede Naijiria.
Wike, lasiko to n ba awọn akọroyin ile ijọba sọrọ lẹyin
ipade naa ni ko si nnkan to jọ pe oun fẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu kan si kan.
“Ko si nnkan to jọ bẹẹ. Asiko ti a wa yii ni pe ki a gbe ẹgbẹ
oṣelu si ẹgbẹ kan, ki a si jiroro bi ilọsiwaju yoo se deba orilẹede Naijiria .
“Ọmọ orilẹede Niajiria ni wa, a si wa lati kede atilẹyin fun
Aarẹ wa.
“Ko si nnkan to jọ pe mo fẹ kuro ninu ẹgbẹ oṣelu PDP.”
Ohun tó ṣẹlẹ̀ níbi ìgbẹ́jọ́ láàárín Sanwoolu àti Rhodes-Vivour rèé
Oríṣun àwòrán, Twitter
Ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò ìpínlẹ̀ Eko ti ní ọjọ́ kan náà
ni òhun yóò gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹjọ́ tí gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Babajide Sanwoolu
àti igbákejì rẹ̀, Obafemi Hamzat pè.
Bákan náà ni wọ́n ní ọjọ́ tí àwọn máa gbé ìdájọ́ kalẹ̀ yìí
náà ni àwọn máa dájọ́ lórí ẹjọ́ tí àjọ elétò ìdìbò ilẹ̀ wa INEC pè.
Níbi ìjókòó ìgbẹ́jọ́ náà tó wáyé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹta
oṣù Kẹfà ọdún 2023, ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́ta ọ̀hún tí Adájọ́ Arum Ashom ṣáájú rẹ̀
ní ọjọ́ kan ni àwọn máa gbé gbogbo ìdájọ́ kalẹ̀.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Babajide Sanwoolu àti igbákejì rẹ̀,
Obafemi Hamzat ló pẹjọ́ pé kí ìgbìmọ̀ náà da ẹjọ́ tí olùdíje sípò gómìnà Eko lẹ́gbẹ́
òṣèlú Labour Party, Gbadebo Rhodes-Vivour ti kọ́kọ́ gbé síwájú wọn nù.
Agbejọ́rò gómìnà Eko àti igbákejì rẹ̀, Wole Olanipekun níbi
ìgbẹ́jọ́ níẹjọ́ tí Rhodes-Vivour pè
láti tako ìjáwé olúborí Sanwoolu níbi ètò ìdìbò tó wáyé lọ́jọ́ kejìdínlógún oṣù
Kẹta kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti pé kò ṣàlàyé ìdí tó fi lẹ́tọ̀ọ́ láti pe àwọn lẹ́jọ́.
Olanipekun fi kun pé Rhodes-Vivour nìkan ló dá pe ẹjọ́ tí ẹgbẹ́
òṣèlú tó díje lábẹ́ rẹ̀ kò sí nínú àwọn tó ń pè ẹjọ́ láti tako bí Sanwoolu ṣe
gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.
Ó ní ìgbésẹ̀ yìí tako òfin ètò ìdìbò ọdún 2022 tó sì rọ ilé ẹjọ́
láti da ẹjọ́ náà nù pátápátá.
Nígbà tó ń fèsì, Rhodes-Vivour gba tẹnu agbejọ́rò rẹ̀,
Olumide Ayeni ní òfin ètò ìdìbò ọdún 2022 náà ti fi ààyè gba olùdíje láti pé ẹjọ́
fúnra rẹ̀ láìsí àtìlẹyìn ẹgbẹ́ to bá gbe dìde.
Rhodes-Vivour fi kun pé ẹjọ́ tí òun pè kò ní ẹja n bákàn
nínú àti pé kí ilé ẹjọ́ má gba ẹjọ́ tí gómìnà àti igbákejì rẹ̀ pè láàyè.
Lẹ́yìn gbogbo atótónu àwọn agbejọ́rò méjéèjì ni ìgbìmọ̀ ọ̀hún
rọ̀ wọ́n láti ri pé wọ́n gbé àwọn ẹ̀rí wọn síwájú ìgbìmọ̀ kó tó di ọjọ́ Kẹrìndínlógún
oṣù Kẹfà.
Adájọ́ Ashom tún sún ìgbẹ́jọ́ síwájú di ọjọ́ Ajé, ọjọ́
Karùn-ún tí ìgbẹ́jọ́ yóò tún tẹ̀síwájú.