Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Àwọn àǹfààní tí Naijiria yóò jẹ nínú ìrìnàjò àkọ́kọ́ Tinubu sí France

  2. Kókó, ‘Afẹ́fẹ́ "oxygen" tí àwọn arìnrìnàjò ọkọ̀ ojú omi Titan tó dàwátì ń mí sínú lè ti fẹ́ẹ̀ tán báyìí’

    Irinṣẹ to n wa inu omi

    Oríṣun àwòrán, PA Media

    Ìrètí wà bí a ṣe ń wá àwọn arìnrìnàjò tó ń lọ wo àfọ́kù ọkọ̀ oju omi inú ìtàn Titanic

    Bí ẹ ba ṣẹ n gbọ nipa iroyin to ṣẹlẹ pe awọn arinrinajo igbafẹ kan dede dawati ninu agbami nla Atlantic nigba ti wọn fẹ lọ foju lounjẹ nibi afọku ọkọ oju omi inu iwe nni, Titanic, ibi ti ọrọ de duro ree:

    • Adari ikọ ẹṣọ oju omi ti ilẹ Amẹrika ti woye pe afẹfẹ ti wọye pe afẹfẹ inu ẹrọ ti awọn to wa ninu ọkọ oju omi to n rinrinajo naa n mi sinu labẹ omi ṣeeṣe ko ti fẹẹ tan ti a ba fi wo wakati melo kan sii. Eyi jẹ iwoye pẹlu iṣiro ti wọn ṣe.
    • Awọn oṣiṣẹ adoola ni wọn gbudọ wa ninu ireti toripe ọkọ oju omi mẹwaa atawọn mii to n ṣiṣ lati ibomiran yoo darapọ mọ wiwa awọn arinrinajo naa lonii eyi to jẹ bii ilọpo meji akitiyan ti wọ́n ti n ṣe bọ latẹyinwa.
    • Amọṣa ọgagun to n dari ikọ awọn adoola ọhun naa ti sọ pe: “Ẹ jẹ ka sọoju abẹ niko fun yin, a ko mọ ibi ti wọn wa”.
    • Ojukoo ibi ti wọn n wa wọn si ti fẹ sii bayii nitori ohun ti wọn gbọ ni ọjọ Iṣẹgun ati Ọjọru. O ti wa di agbegbe to fẹ to ilọpo meji ibi ti wọn n wo tẹlẹ to si tun jin sii.
    • Ko tii daju boya lati inu ọkọ oju omi to dawati ni ohun ti wọn n gbọ ti wa.
    • Ibi ti Polar Prince, ọkọ oju omi to wa nibi ti wọn ti bẹrẹ akititan yii naa ni yoo ṣi jẹ adari awọn ikọ ọkọ tokuo si joko ni ẹgbẹ ibudo afọku ọkọ oju omi Titanic.
    • Awọn ọkọ to ni ẹrọ ayaworan lara ti wọn yoo si fi remootu dari wọn yoo maa wo jinjin inu omi naa lataarọ dalẹ.

    Yoo to ọpọlọpọ wakati lati kan ọkọ oju omi naa lara ni kete ti a ba ti ri i – Ọmọwe nipa inu omi

    Ọmọwe kan to jẹ akọṣẹmọṣẹ ninu wiwa inu omi, Ọmọwe David Gallo gbagbọ pe ayafi iṣẹ iyanu lo lee ṣẹlẹ lati le doola awọn to ha sinu ọkọ oju omi Titan ṣugbọn o ni oun ṣi ni ireti.

    O sọ fun ileeṣẹ iroyin ITV ti ilẹ Britain pe awọn ariwo to n wa lati abẹ omi n wa ni lemọ lemọ eyi to tumọ si pe awọn ikọ nilo lati mura si iṣẹ nipa wiwoo bii pe awọn eeyan naa ti n jade bọ ki wọn si sunmọ wọn kiakia.

    “Wọn ni lati wa ni igbaradi bii pe ibi iṣẹlẹ yẹn gangan ni wọn wa lati le wa a ri ki wọn si sare bọ sibẹ”.

  3. Kìí ṣe torí àwọn ọmọ Nàìjíríà la ṣe dáwọ́ kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ máa mú ẹbí dání wá kàwé dúró! – ìjọba UK

  4. 'Mo n bẹ ọlọ ata, òpó iná, tọ̀ sínú ẹ̀yìn iná lálẹ́, kí ń má baà tọ̀ sílé lóru'

  5. 'Kìí ṣe ìdí iṣẹ́ tíátà làwọn òṣèré ti ń rí owó ra ọkọ̀ ńlá àti ilé àwòdamiẹnu'

  6. Ó kéré tán ènìyàn 29 ló farapa nínú ìbúgbàmù tó wáyé ní Paris

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, AFP

    O kere tan eniyan mọkandinlọgbọn ti farapa yanayana ninu ibugbamu to waye ni ilu Paris , ni orilẹede Faranse.

    Mẹ́rin nínú àwọn tó farapa náà ló wà ní ẹsẹ̀ kan ayé, ẹsẹ̀ kan ọ̀run.

    Ibugbamu naa waye ni ileẹkọ awọn onimo nipa imọ ‘Art’ ati awọn ọfiisi to w ani ileẹkọ Catholic education on Rue Saint-Jacques ni olu ilu ile Faranse naa.

    Awọn oṣiṣẹ pajawiri ni awọn n sewadii iṣẹlẹ naa nipa ayẹwo ibi ti isẹlẹ naa ti waye, to si seese ki wọn maa wa awọn eniyan meji.

    Gẹgẹ bi awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn se sọ, awọn eniyan kọkọ n gbo ooru afẹfẹ gaasi ki ibugbamu naa to waye.

    Adari ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ ni Paris, Baure Baccaau lẹyin to de ibi ti iṣẹlẹ naa ti waye ni ẹrọ amohunmaworan fihan pe ile to sunmọ ile ijọsin Val de Grace Church ni ibugbamu naa ti sẹlẹ.

    Amọ ijọba orilẹede naa ni awọn ko tii le sọ tabi fi idi ohun to fa ibugbamu naa mulẹ bayii.

    Adari ileeṣẹ ọlọpaa ni Paris, Laurent Nunez ni saaju ni ina sọ yika gbogbo ile naa, ti awọn panapan to seese pa ina naa

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Reuters

  7. Sé lóòtọ́ ni ìjọba buwọ́lu àfikún owó osù ààrẹ Tinubu, Shettima, àwọn gómìna?

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Tinubu/Facebook

    Ajọ to n risi ọrọ abẹnu, The Revenue Mobilisation, Allocation and Fiscal Commission (RMAFC), ti ni ko si otitọ ninu iroyin to n ja ranyin nilẹ pe ajọ naa ti se afikun owo osu awọn oloselu ti wọn yan si ipo bii aarẹ Tinubu, igbakeji rẹ, awọn gomina, minisita ati bẹẹ lọ.

    Ninu atẹjade ti agbẹnusọ fun aarẹ tẹlẹ, Bashir Ahmad fi si oju opo Twitter rẹ lo ti ni iroyin ẹlẹjẹ ni iroyin naa.

    O ni ko si ohun to jọ pewọn fẹ se afikun ida mẹrindinlọgọfa owo osu awọn wọnyii.

    Bashir Ahmad fikun un pe alukoro ajọ naa, Christian Nwachukwu ni aarẹ Bola Ahmed Tinubu koi tii buwọlu afikun owo osu awọn oloselu naa.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

    Amọ saaju ni iroyin ti gbe pe ileeṣẹ ijọba labẹnu, Nigerian Revenue Service ti buwọlu afikun owo osu awọn oloselu ti wọn ba dibo yan to fi mo ti aarẹ ati igbakeji aarẹ.

    Afikun owo osu yii yoo kan awọn gomina ati igbakeji wọn, to fi mo awọn aṣofin ati adajọ ati awọn to di ipo ijọba mu.

    O ni ida 114 ni owo osu wọn yoo fi pọsi, eleyii to tunmọ si pe aarẹ le gba owo osu to le ni miliọnu meji naira ni osu.

    Adari ajọ RMAFC, Muhammadu Shedu ni awọn ti se agbeyẹwo awọn eto to wa nilẹ, ki wọn to gbe igbesẹ naa.

    Amọ, o fikun un pe ko ti le di ofin afi igba ti awọn igbimọ amusẹya ijọba apapo ba buwọlu ki o to le di ofin.

    Bakan naa ni afikun owo osu oṣiṣẹ naa yoo kan awọn minisita, kọmisọnna to fi mọ awọn oluranlọwọ gẹgẹ bi alakalẹ iwe ofin section 84 ati section 124, iwe ofin orilẹede Naijiria.

    Gẹgẹ bi ọrọ ajọ naa, ọdun 2007 ni awọn oloselu ti gba afikun owo osu gbẹyin.

  8. Akọ̀ròyìn wọ gàù fún sísọ̀rọ̀ àlùfàǹsá sí ààrẹ

  9. Asamoah Gyan, òdú agbábọ́ọ̀lù Ghana fẹ̀yìntì

  10. Ohun táa mọ̀ nípa ìròyìn ọkọ̀ ojú omí tó ń gbé àwọn èèyàn lọ ṣàbẹ̀wò sí Titanic inú ìtàn tó dàwátì rèé

    Ọkọ oju omi Titan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Akitiyan ti n lọ lọwọ lati gbiyanju wiwa ọkọ oju omi igbafẹ kan (submarine) atawọn ero inu rẹ to dawati lori omi nla Atlantic lati opin ọsẹ to kogba wọle lọ.

    Iroyin ni se ni awọn wọn eeyan to wọ ọkọ naa n lọ fun irinajo igbafẹ lati lọ wo afọku gbajugbaja ọkọ oju omi nla Titanic ti wọn ti gbọ itan nipa rẹ.

    Lati igba ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni oriṣiriṣi iroyin ti n jade to si jẹ pe ko tii si eeyan kankan ti wọn ri lara awọn to wọ ọkọ oju omi ọhun.

    Ki lo ṣẹlẹ gangan?

    Ọkọ oju omi naa ti orukọ rẹ n jẹ Titan to jẹ ti ileeṣẹ igbafẹ kan, OceanGate Expeditions, lo dede ri lasiko to n lọ si ibi ti afọku ọkọ oju omi igbaani, Titanic wa ni owurọ ọjọ Aiku, ọjọ kẹtadindinlogun oṣu kẹfa.

    Atukọ ati oṣiṣẹ to wa ninu rẹ jẹ marun to si di wipe gbogbo wọn ṣina lori omi ti ipa wọn ko ran an mọ ni nnkan bii wakati kan ati iṣẹju marunlelogoji ti wọn bẹrẹ irinajo ọhun.

    Lara awọn iwadii ti BBC kojọ ni pe:

    • Bi wọn ṣe n wa awọn to wọ ọkọ oju omi naa jẹ eyi to gba agbara gan bẹẹ si ni awọn alabaṣiṣẹpọ lati awọn orilẹede mii naa ti darapọ lati fọwọ kun wiwa ọkọ naa atawọn to wa ninu rẹ.
    • Ọkọ baalu kan to ni irinṣẹ kan to lee ri nnkan to ba ri wọ inu omi lara ti wọn n pe ni “sonar buoys” ko firi ariwo labẹ omi ṣugbọn “awa o mọ orisun awọn ariwo naa”.
    • Ọpọlọpọ nnkan bii irin wa ni ibi ọkọ oju omi Titanic ti wọn n rinrinajo lọ - eyi to lee jẹ orisun ariwo ti wọn gbọ.
    • Awọm alaṣẹ ni ariwo naa jẹ atọka, o si jẹ ohun ti awọn gbudọ foju sun pẹlu lilo awọn irinṣẹ to ba wa nitosi.
    • Ikọ to n wa awọn arinrinajo yoo tẹsiwaju ninu iṣẹ wọn “niwọn igba ti anfani ba ti wa fun awọn to sọnu lati wa laaye”. Wọn yoo maa ṣiṣẹ pẹlu awọn irinṣẹ to ba wa nitosi.
    Ọkọ oju omi Titan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

  11. Ẹ ràn mí lọ́wọ́! Ìyá ń jẹ èmi àti àwọn ọmọ láti ìgbà tí Rolling Dollar ti kú - Iyawo

  12. BBC tú àṣírí àwọn tó ń fìyà jẹ ọ̀bọ láti fi pa owó

  13. Ọmọ ààrẹ ilẹ̀ Amẹrika,Joe Biden yó̀ò fi ojú ba iléẹjọ́ lórí ẹ̀sùn lílo ìbọn lọ́nà àìtọ́

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Arakunrin Hunter Biden to jẹ ọmọ aarẹ orilẹede Amerika, Joe Biden ni yoo fi oju ba ileẹjọ lori ẹsun aisan owo ori ati lilo ibọn ilerọ lọna ti ko ba ofin mu.

    Wọn ni Hunter se asemase yii lasiko to n gba itọju fun asilo oogun oloro.

    Igbesẹ yii lo n waye lẹyin iwadii lori iṣẹlẹ naa fun ọdun marun un.

    Olori ẹka eto idajọ ni ipinlẹ Delaware ni yoo fi ẹri naa le le ni iwaju adajọ.

    Hunter Biden ni ireti wa wipe yoo jẹwọ pe lootọ ni oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan oun lasiko ti oun gba itọju fun lilo oogun oloro.

    O seese ko fi ẹwọn ọdun kan jura fun aisan owo ori ati ẹwọn ọdun mẹwaa fun ibọn ti wọn ba lọwọ rẹ lọna to lodi si ofin.

    Agbẹnusọ rẹ ni Hunter setan lati jẹwọ awọn ohun to se nigba aimọ, ti o si ti jọwọ rẹ silẹ patapata.

    Bakan naa ni wọn fikun un pe Hunter setan lati gbe igbeaye tuntun fun idasoke ati itẹsiwaju ọjọ ọla rẹ.

    Hunter Biden to jẹ ẹni ọdun metalelaadọta ni o ti ṣiṣẹ gẹgẹ bi agbẹjọro ati ọlọpaa ni ilẹ okeere bii China ati Ukraine.

    Ọdun 2014 ni wọn ni ko lọ rọkun nile kuro ni ieeṣẹ ọmọogun ilẹ Amẹrika ti oju omi fun ẹsun pe o mu ọti para.

    Bakan naa ni wọn lo paro nipa sisan owo ori rẹ, to si tun paro ibọn ẹrọ ilewo ati ọna ti o gba ni lọwọ.

  14. Ẹ wo bí aláboyún kan se rọbí nínú ọkọ̀ òfúrufú tó ń lọ láti Eko sí Amsterdam, to sí bí ọmọ obìnrin Jòjòló!

    Aworan

    Arabinrin kan lo bẹrẹ si ni rọbi lasiko to wa ninu ọkọ ofurufu KLM to n lọ lati ipinlẹ Eko lọ si Amsterdam.

    Iṣẹlẹ naa lo mu ki ọkọ ofurufu naa duro ni Spain fun itọju pajawiri fun obinrin naa.

    Gẹgẹ bi iroyin se sọ, ni alẹ Ọjọ Aje ni ọkan lara awọn ero inu ọkọ ofurufu KLM 588, bẹrẹ si ni rọbi ninu ọkọ baalu naa.

    Ileeṣẹ iroyin Vanguard ni obinrin alaboyun naa ti wọn ko darukọ rẹ ni wọn gbe lọ si iwaju ọkọ ofurufu naa to si bi ọmọ obinrin.

    Lẹyin eyi ni ọkọ naa balẹ si ilu Barcelona, nibi ti awọn oṣiṣẹ eto ilera pajawiri ti wa ni pese lati fun obinrin naa ni itọju to peye.

    Iroyin ni iya ati ọmọ naa wa ni alaafia ara.

    Agbẹnusọ ileesẹ ọkọ ofurufu naa ni lootọ ni oun le fi idi rẹ mulẹ pe wọn bi ọmọ tuntun jojolo ni ọkọ ofurufu to n lọ lati ipinlẹ Eko lọ si Amsterdam ni Netherlands.

    Amọ o ni oun ko ni le sọ ju bẹẹ lọ lori ọmọ jojolo naa nitori aabo ati ẹtọ iya ati ọmọ si igbesi aye idakọnkọ.

  15. ‘’Àwọn ìpínlẹ̀ tó bá gbà kí àwọn aláboyún lọ fún Hajj ní ọdún yìí yóò fojú winá òfin’’

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, NAHCOM

    Ẹgbẹ awọn dokita to n seranwọ fun awọn eniyan lasiko Hajj ti gba ijọba orilẹede Naijiria lati mase gba awọn ipinlẹ ti wọn b ani alaboyun to pọ laaye lati lọ fun Hajj ni Saudi Arabia ni ọdun yii.

    Dokita Usman Galadima to jẹ adari ẹgbẹ naa lo parọwa naa lasiko to n ba ileeṣẹ iroyin News Agency of Nigeria sọrọ ni Makkah.

    NAN fi lede gbe ajọ to n risi irina lọ si ilẹ mimọ Hajj gbe igbimọ awọn dokita naa kalẹ lati ri pe awọn eniyan to ba lọ si Hajj gba eto ilera to peye lasiko ti wọn ba lọ fun Hajj ọun.

    Wọn ni eyi ko ṣẹyin bi alaboyun kan se ku ni orilẹede Saudi Arabia lasiko Hajj bio tilẹ sepe wọn gbiyanju lọpọlọpọ lati doola ẹmi rẹ.

    Bakan naa ni wọn fikun un pe ọmọ Naijiria bi ọmọ osu meje ni Hajj, ni ilu Medina lẹyin ti wọn ṣiṣẹ abẹ fun.

    Ni ero tirẹ, o ni ẹnikẹni to ba fẹ lọ fun Hajj gbọdọ w ani ilera pipe, ti ko gbọdọ ni oyun sinu nitori ilera ara rẹ.

    O fikun un pe ijiya gbọdọ wa fun awọn ipinlẹ ti wọn ba ran oloyun lọ fun Hajj, ki awọn eniyan ba le mu ilera wọn lọkunkundun.

  16. Ó ń ṣe mí bíi kìnìún tó ń bú ramúramù láti pa àwọn ọ̀daràn tó ń dàmú Nàìjíríà jẹ - Kayode Egbetokun

  17. Wo adarí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin tuntun ìpínlẹ̀ Ogun, Oluomo àti ìgbákejì rẹ̀, Latifat

  18. Obìnrin ẹni ọdún 57 kó sí kàǹga ní Ilorin, pàdánù ẹ̀mí rẹ̀

  19. Trinity Guy: Kí ni gbajúmọ̀ apanilẹ́rìín oní "prank" yìí ṣe tí Ọlọ́pàá ní ó yẹ kí wọ́n fòfin gbé e?

  20. Ẹ yé fi ọ̀rọ̀ ara yín pamọ́ tí ẹ bá ń jápa nítorí... - Woli Arole