Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Kò sí àyè láti fẹnukonu fún wákàtí 72 ní ìpínlẹ̀ wa fun ami ẹyẹ GWR – Ijọba Ekiti

    Oyebamiji/GWR

    Oríṣun àwòrán, Oyebamiji/GWR

    Ijọba ipinlẹ Ekiti ti tako igbesẹ awọn eeyan kan ti wọn n mura lati ṣe ifẹnukonu fun ọjọ mẹta gbako lọna ati gba ami ẹyẹ Guinness World Record nipinlẹ naa.

    Ẹgbẹ kan, ti wọn pe ara wọn ni ‘Sugartee’ ni wọn ṣe ipolongo lati ṣagbatẹru idije ti awọn eeyan kan yoo ti fẹnu ko ara wọn lẹnu fun wakati méjíléláàdọ́rin ni gbagede kan niluu Ado Ekiti.

    Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ekiti, ninu lẹta kan to kọ si ẹgbẹ awọn onile itura sọ pe oun ko fọwọ si eto naa rara.

    Ijọba ni ẹnikẹni tabi ileeṣẹ to ba yọnda gbagede rẹ fun eto naa yoo jẹ iyan rẹ niṣu.

    Ninu lẹta kan lati ọọfisi ileeṣẹ to n ri si irinajo afẹ nipinlẹ naa kọ, ijọba ni o ṣeeṣe ki eto ọhun ba orukọ ipinlẹ naa jẹ.

    O ni “eto Kiss-a-thon ti wọn fẹ ṣe yii jẹ arameeriri, eyii ti ko bojumu, to le ba orukọ ipinlẹ wa jẹ ati eyii to le mu ki awọn ọdọ wa ṣi iwa wu.”

    “Nitori naa, ileeṣẹ to n ri so ọrọ aṣa fofin de ṣiṣe irufẹ eto bẹẹ ni gbagede eyikeyi to ba fẹ gba oreofẹ ijọba lati maa ṣiṣẹ nipinlẹ Ekiti.”

    Ti ẹ ko ba gbagbe, laipẹ yii ni akẹkọọbinrin kan, Damilola Adeparusi, ti ọpọ mọ si Chef Dammy se ounjẹ fun ọgọfa wakati nilu Ilupeju-Ekiti, eyii to mu ki okiki rẹ kan kaakiri Naijiria.

  2. Ẹgbẹ́ àwọn dókítà fún ìjọba àpapọ̀ ní ọ̀sẹ̀ méjì láti fi ìdá 200% kún owó oṣù wọn

    Nigerian doctors's strike

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Ẹgbẹ awọn dokita ni Naijiria, NARD, ti fun ijọba apapọ ni ọsẹ meji pere lati ṣe afikun owo oṣu wọn ni ida 200%, eyii ti wọn ti n bere fun tẹlẹ.

    Ọrọ yii lo jade lẹyin ipade wọn kan to waye lọjọru, nibi ti wọn ti ṣe agbeyẹwo ibi ti ijọba ba iṣẹ de lori awọn ibere wọn.

    Gbedeke tuntun yii ni Aarẹ ẹgbẹ awọn dokita naa, Orji Innocent atawọn akọwe ẹgbẹ ọhun, Chikezie Kelechi ati Umar Musa buwọlu.

    NARD ke si ijọba apapọ lati san awọn owo to ti jẹ wọn sẹyin ni kankan, to fi mọ awọn to yẹ ko san fun wọn laarin ọdun 2014 si 2016.

    Awọn dokita naa ni ko si awijare kankan fun ijọba lati maa jẹ awọn lowo, paapaa awọn ajẹmọnu to yẹ ko ti san sẹyin.

    Wọn ni ti ijọba ba kọ lati dahun ibeere awọn titi ọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2023, o ṣeeṣe ki awọn da iṣẹ silẹ.

  3. Ọwọ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo tẹ bàbá àti ọmọ tó jí Ìmáàmù gbé

    @OndoPoliceNg

    Oríṣun àwòrán, @OndoPoliceNg

    Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi ṣikun ofin mu eeyan mẹta lori ẹsun pe wọn ji imaamu kan, Alhaji Ibrahim Bodunde gbe lọ nipinlẹ Ondo.

    Imaamu naa to jẹ ẹni ọdun mẹ́tàdínláàdọ́rin ni wọn ji gbe ninu oko rẹ loṣu to kọja lasiko to n ṣiṣẹ nibẹ.

    Iroyin ni ọjọ keji ọjọ ti wọn ji gbe lawọn ajinigbe naa tu silẹ lẹyin ti wọn gba miliọnu meji owo itusilẹ rẹ tan.

    Wayi o, ọwọ ọlọpaa ti tẹ awọn to ji imamu naa gbe bayii, o si ti fi oju wọn lede.

    Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Funmilayo Odunlami sọ fun awọn akọroyin pe ọwọ tẹ awọn afurasi naa lẹyin akitiyan awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa.

    Gẹgẹ bii ohun to sọ, lara awọn ti ọwọ tẹ ni Muinah Mohammed, Aisha Bello, ati Isah Bello.

    Iwadii ọlọpaa fi han pe baba ati ọmọ ni Aisha Bello, ati Isah Bello, amọ Aishat sọ pe akoba lasan ni ọrọ naa jẹ fun oun.

    Ẹwẹ, Odunlami ti sọ pe awọn afurasi ọhun yo foju bale ẹjọ laipẹ.

  4. Ìpínlẹ̀ Oyo, Ogun, Kwara àtàwọn míì gba kọmísọ́nà ọlọ́pàá tuntun

    Adejobi Olumuyiwa

    Oríṣun àwòrán, Adejobi Olumuyiwa

    Ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria, Olukayode Egbetokun, ti pin kọmiṣọna ọlọpaa marundinlogoji kaakiri awọn ipinlẹ ni Naijiria.

    Alukoro ileẹṣẹ naa, Olumuyiwa Adejobi lo fi iroyin ọhun sọwọ si awọn akọroyin niluu Abuja.

    Igbesẹ yii lo n waye lẹyin ti ajọa to n ri si ọrọ wọn ọlọpaa, Police Service Commission, buwọlu igbesẹ naa.

    Egbetokun ni igbesẹ ọhun wa lara afojusun ileeṣẹ naa lati pese abo to daju fun gbogbo ọmọ Naijiria.

    Lara awọn kọmiṣọna ọlọpaa tuntun naa ni CP Adelesi E. Oluwarotimi si Kwara, CP Adebola Ayinde Hamzat, lọ si Oyo ati CP Alamatu Abiodun Mustapha lọ si ipinlẹ Ogun.

    Yatọ si awọn wọnyii, ipinlẹ Kebbi, Bauchi ati Ebonyi naa yoo tun ni kọmiṣọna ọlọpaa tuntun.

    Egbetokun rọ awọn eeyan naa ki wọn mu iṣẹ wọn ni pataki, ki wọn si jẹ apẹrẹ rere fun awọn to wa lẹyin wọn atawọn araalu.

  5. Bamidele, Ashiru, Olalere àtàwọn míì di adarí ilé aṣòfin àgbà

  6. 'Ẹ yé lo àwọn ọlọ́pàá bí ọmọ ọ̀dọ̀ mọ́'

  7. Tinubu ṣe ìpàdé àkọ́kọ́ pẹ̀lú àwọn olórí iléeṣẹ́ ọmọ ogun Naijiria, àbọ̀ ìpàdé náà rèé

    Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

    Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

    Aarẹ Bola Tinubu ti sọ fun awọn olori ileeṣẹ ọmọ ogun atawọn ẹṣọ alaabi ki wọn fọwọsowọpọ lati ṣiṣẹ fun abo to daju ni Naijiria.

    Tinubu lo sọ ọrọ naa nibi ipade akọkọ to ṣe pẹlu awọn eeyan naa niluu Abuja.

    Olubadamọran si ijọba Naijiria lori eto abo, Nuhu Ribadu, sọ fun awọn akọroyin lẹyin ipade naa pe Aarẹ Tinubu ṣeleri lati ṣatilẹyin fun awọn olori eleto abo naa lẹnu iṣẹ wọn.

    Ribadu ni awọn olori ileeṣẹ ọmọ ogun ọhun tun ti ṣeleri fun Aarẹ lati tii lẹyin ki awọn ọmọ Naijiria le ri abo to daju.

    Nigba to n sọrọ lori ipade naa, Ribadu ni “o fi da wa loju pe digbi loun wa lẹyin wa.”

    “O ni gbogbo wa ni lati ṣe ara wa ni oṣuṣu ọwọ nitori iṣẹ pọ niwaju ti a ni lati ṣe, yoo maa reti ki a ṣe iṣẹ naa bii iṣẹ, awa naa ko ni ja kulẹ.”

    Ọjọ kọkandinlogun, oṣu to kọja ni Aarẹ Tinubu yan Ribadu atawọn olori ileeṣẹ ọmọ ogun to ku lati di opo eto abo Naijiria mu.

  8. NAFDAC sọ̀rọ̀ sókè lórí fídíò tó sọ pé èròjà ‘plastic’ ló wà nínú Semovita àti Semolina

    NAFDAC

    Oríṣun àwòrán, @sikiru_4me

    Ajọ to n ri si ọrọ ounjẹ ati oogun lilo ni Naijiria, NAFDAC, ti kede pe ko si eroja ‘plastic’ ninu ounjẹ Semovita ati Semolina, eyii ti ileeṣẹ Golden Penny ṣe.

    NAFDAC lo sọ ọrọ yii lasiko to n fesi si fidio kan to n milẹ titi lori ayelujara, nibi ti obinrin kan to fi omi tutu fọ Semovita naa ti sọ pe ike lo wa ninu rẹ ti awọn araalu n jẹ.

    Gẹgẹ bii ohun ti NAFDAC sọ, kii ṣe igba akọkọ ree ti irufẹ fidio bayii yoo jade, iru rẹ ti kọkọ waye lọdun 2020, eyii ti awọn da si.

    O fi kun pe Semovita ni awọn eroja to yẹ ko ni, paapaa eroja Vitamine A to le ṣe ara loore.

    NAFDAC sọ siwaju si pe ko si ootọ ninu fidio naa to sọ pe ‘plastic’ lo wa ninu Semovita.

    O fi kun pe “NAFDAC fẹ ki gbogbo araalu mọ pe Golden Penny Semovita atawọn ounjẹ mii to jẹ ti Semolina ko ni ewu ninu, wọn si gba ontẹ ajọ wa ki wọn to gbe jade.”

    “A fẹ ki awọn araalu sọra bi wọn ṣe n lo ikanni ori ayelujara lati sọrọ nipa awọn ounjẹ atawọn ọja mii to wa nigboro.

  9. Ibi tí rògbòdìyàn tó ń lọ ní France lórí ọmọ ọdún 17 tí ọlọ́pàá kan pa nìyí

  10. Tinubu ní láti ṣàlàyé bó ṣe ná ₦‎400b owó ìrànwọ́ orí epo tàbí kí a pèé lẹ́jọ́ – SERAP

    Bola Tinubu

    Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

    Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, SERAP, ti ke si Aarẹ Bola Tinubu pe ko ṣalaye bi ijọba rẹ ṣe na ₦‎400b owo iranwo epo bentiro ti ko na lati oṣu kan sẹyin tabi ko foju bale ẹjọ.

    Ninu lẹta kan ti igbakeji adari ajọ naa, Kolawole Oluwadare, buwọlu ni SERAP ti fi ọrọ naa lede.

    Iroyin ni owo ti kodin ni ₦‎400b ni ijọba ti fi pamọ laarin ọsẹ mẹrin sẹyin lẹyin ti Tinubu gba ọpa aṣẹ, eyii to yẹ ko na lori iranwọ owo epo bẹntiro.

    Ninu lẹta kan ti SERAP kọ lọjọ kini, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, o ni gbogbo ọmọ Naijiria ni lati mọ bi ijọba ṣe na owo naa niwọn igba ti ko na gẹgẹ owo iranwọ epo bẹntiro.

    Skip X post
    Allow X content?

    This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

    Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

    End of X post

    SERAP ni “ẹtọ ijọba rẹ ni lati ri daju pe awọn ọmọ Naijiria to n jiya iranwo epo bẹntiro ti o yọ janfaani rẹ.”

    “Anfani araalu ni pe ijọba yọ owo iranwọ ori epo ti awọn eeyan kan fi n ṣe jibiti… ṣugbọn ẹtọ awọn eeyan naa ni lati mọ bi ijọba ṣe na owo ọhun.”

    “Kikede bi ijọba ṣe na owo naa yoo tumọ si pe ijọba ko fi ohunkohun pamọ, yoo si mu adinku ba iwa ajẹbanu.”

    “Inu wa yoo dun ti ijọba ba le gbe igbesẹ yii laarin ọjọ meje… bi bẹẹ kọ, a o gba ile ẹjọ lọ.”

  11. Yèyé Osun ṣàlàyé èrèdí tó fi wọ́gilé ọdún Ìṣèṣe tó yẹ kó wáyé nílùú Ilorin

    Yeye Olokun Omolara

    Oríṣun àwòrán, Yeye Olokun Omolara

    Obinrin oniṣẹṣe kan, Yeye Ajesikemi Olokun Omolara, ti ṣalaye eredi to fi wọgile ọdun Isese kan to yẹ ko waye ni nipinlẹ Kwara.

    Ọjọ Aje to kọja ni wahala naa kọkọ bẹrẹ fun Yeye Osun naa lẹyin to kede pe oun fẹ ṣe ọdun Iṣẹṣe ọlọjọ mẹta.

    Amọ ẹgbẹ awọn Musulumi kan, Majlisu Shabab li Ulamahu Society, yabo ile rẹ, wọn si kilọ fun pe ko gbọdọ ṣe ọdun naa nitori o lodi si ẹsin Musulumi ti ọpọ eeyan tẹwọgba niluu Ilorin.

    Gẹgẹ bii ohun ti awọn eeyan naa sọ, wọn ni Emir Sulu Gambari lo ran awọn niṣẹ ọhun.

    Yeye Olokun Omolara sọ pe lati igba ti awọn Musulumi naa ti kilọ fun oun pe ki oun ma ṣe ọdun naa ni awọn eeyan kan ti n dunkoko mọ oun.

    O ni o pẹ ti oun ti n gbe niluu Ilorin, irufẹ nnkan bẹẹ ko si ṣẹlẹ si oun ri.

    Bo tilẹ pe ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n bu ẹnu atẹ lu igbesẹ awọn Musulumi naa, abala awọn eeyan kan ni ohun ti wọn n ṣe ko buru nitori ẹsin Islam nikan lawọn faye gba niluu Ilorin.

    Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti sọ pe oun ko gbọ nipa idunkokomọni kankan nitori ko si ẹni to tii fi ọrọ naa lọ lagọ awọn.

  12. Ìsọkúsọ ni ọ̀rọ̀ EU tó ní ìbo Ààrẹ ọdún 2023 ní màgòmágó nínú – Ìjọba àpapọ̀

    Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

    Oríṣun àwòrán, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu

    Ijọba apapọ Naijiria ti kọ abajade iroyin ajọ EU to sọ pe eto idibo Aarẹ ọdun 2023 ni magomago ninu.

    Olubadamọran pataki si Aarẹ Bola Tinubu, Dele Alake lo sọ ọrọ naa ninu atẹjade kan.

    Alake ni o han gbangba pe Aarẹ Bola Tinubu ti ẹgbẹ oṣelu APC lo jawe olubori ninu eto idibo naa to waye ninu oṣu Keji ọdun yii.

    O ni “a rọ ajọ EU atawọn ajọ mii lati ilẹ okeere ki wọn dẹkun ati maa ṣe ojuṣaju lori ohun ti wọn ba n sọ nipa ohun to n ṣẹlẹ Naijiria, ki wọn jẹ ki Naijiria rimu mi.”

    “O jẹ ohun ti ko ṣe e gbọ seti pe awọn ajọ kan lati ilẹ okere yoo maa sọrọ odi nipa eto idibo to waye ni Naijiria.”

    Alake sọ siwaju si pe ko tọ awọn aṣoju ajọ EU, ti wọn ko ju aadọta eeyan lọ ṣe idajọ lori esi ibo Aarẹ naa to waye kaakiri Naijiria.

    Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu to kọja ni EU gbe abajade iriri re ninu eto idibo naa le ajọ eleto idibo, INEC, lọwọ.

    Ti ẹ ko ba gbagbe, awọn oludije ninu ẹgbẹ alatako, Peter Obi ati Atiku Abubakar ṣi wa nile ẹjọ lori esi ibo Aarẹ naa to waye lọdun yii.

    Awọn oludije mejeji, ti wọn wa ni ipo keji ati ipo kẹta lẹyin esi ibo sọ pe awọn lo bori ninu ibo naa.

  13. Àwọn afurasí ajínigbé yawọ ṣọ́ọ̀ṣì, pa pásítọ̀, jí èèyàn méje gbé lọ ní Ogun

  14. Ẹ ri pé ẹ gba ife ẹ̀yẹ wálé níbi ìdíje àgbáyé - Tinubu sí Super Falcons

  15. Ìgboro ti dàrú ní France lẹ́yìn ìwọ́de lórí ikú ọmọ tí ọlọ́pàá yìnbọn pa

    France shooting

    Oríṣun àwòrán, EPA

    Awọn ọlọpaa atawọn olufẹhonuhan ti kọlu ara wọn nilu Marseille lorilẹ-ede France bayii lẹyin iwọde to n lọ lọwọ nibẹ.

    Iwọde ọhun bẹrẹ lẹyin ti ọlọpaa yinbọn pa ọmọ ọdun mẹtadinlogun kan nibẹ.

    Awọn fidio ti a ri ṣafihan bi ọlọpaa ṣe n yin gaasi tajutaju si awọn olufẹhonuhan, a si gbọ pe wọn ti fi ṣikun ofin mu eeyan bii mẹrindinlọgọta niluu naa.

    Ilu ti awọn agbofinro korajọ si ju ni Paris lọna ati dena iwọde siwaju si nibẹ.

    Ọpọ araalu lo korajọ lati ṣe idaro oloogbe naa, Nahel M, ti ọlọpaa yinbọn pa.

    Lẹyin iṣẹlẹ naa ni oniruru iwọde bẹ silẹ kaakiri orilẹ-ede ọhun.

    Minisita fun ọrọ abele, Gérald Darmanin, ti kan sara si awọn ọlọpaa, fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe, eyii ti ko jẹ ki iwọde naa ti kọja bo ṣe yẹ lọ.

  16. NSCDC dóòlà obìnrin tí bàbá rẹ̀ tì mọ́ inú yàrá fún ọdún márùn ún ní Jigawa

    NSCDC

    Oríṣun àwòrán, @official_NSCDC

    Ileeṣẹ eto abo Nigeria Security and Civil Defence Corps, NSCDC, ti doola obinrin kan ti baba rẹ ti mọ inu yara fun ọdun marun un gbako

    Ipinlẹ Jigawa ni iṣẹlẹ naa ti waye.

    Alukoro ileeṣẹ ọhun ni Dutse, Adamu Shehu, lo fidi iroyin naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin Channels.

    Iroyin ni inu yara ti baba rẹ ti mọ naa ni ẹni ọdun marundinlọgbọn ọhun n sun si, ibẹ lo ti n jẹun to tun ti n ṣe igbọnsẹ.

    Aladugbo kan, Safiya Mustapha, lo ke gbajare ọrọ naa sita, eyii to mu ki NSCDC doola obinrin naa ni igbekun baba rẹ.

    Ajafẹtọ ọmọniyan kan, Musbahu Basirka, lo kọkọ de ile ti wọn ti obinrin ọhun mọ.

    Afurasi naa, Garba Musa ati iyawo to fẹ lẹyin iya obinrin naa ti wa ni atimọle NSCDC bayii fun iwadii.

  17. Tó bá jẹ́ pé mo kùnà láti wọlé ipò Sẹ́nétọ̀ ni, màá ti ní ẹ̀jẹ̀ ríru – Oshiomole

    Oshiomole

    Oríṣun àwòrán, @Mario9jaa

    Gomina ipinlẹ Edo nigba kan ri, Adams Oshiomole ti sọ pe oun ko ba ti ni ẹjẹ riru to ba jẹ pe oun lulẹ ninu idibo sipo Sẹnetọ to waye ipinlẹ naa.

    Oshiomole lo sọ ọrọ naa nibi wẹjẹ-wẹmu kan ti awọn ọrẹ ati ololufẹ rẹ kan ṣe fun ni ilu Iyamho, Etsako, nipinlẹ Edo.

    Gomina to ṣejọba lẹyin Oshiomole, Godwin Obaseki ni wọn jọjọ du ipo Sẹnetọ naa amọ o jamọ Oshiomole lọwọ.

    O ni “to ba jẹ ẹ ko dibo fun mu ni, ẹjẹ mi yoo ti ru si 240/ 360, iyẹn ti mo ba ṣi wa laaye.”

    Gẹgẹ bii ohun to sọ, ọpọ awọn eeyan lo ti ṣe gomina ti wọn si kuna lati di Sẹnetọ lẹyin saa wọn amọ ko ri bẹẹ fun oun, yoo si jẹ ohun itiju ti oun ba lulẹ.

    Lẹyin naa lo dupe lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Edo ti wọn fi ibo wọn gbe oun wọle gẹgẹ bii Sẹnetọ lẹyin to ṣe gomina tan.

    O tun dupe lọwọ awọn eeyan ọhun fun atilẹyin wọn fun Aarẹ Naijiria tuntun,Asiwaju Bola Tinub lasiko eto idibo to kọja.

  18. Ìjọba France tí fi páńpẹ́ mú ènìyàn tó lé ní 1300 nítorí ìwọ́de lórí bí ọlọ́pàa se pa omọ ọdún 17

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    O kere tan eniyan to le ni ẹgbẹrun kan ati ọdunrun lo ti wa ni panpẹ ọlọpaa bayii ni orilẹede Faranse.

    Minisita fun ọrọ abẹnu ni orilẹede Faranse lo kede awọn eniyan to wa ni ahamọ ọlọpaa naa.

    Eyi ko ṣẹyin ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ to bẹ silẹ lẹyin ti ọlọpaa kan ṣekupa ọdọkunrin ọmọ ọdun mẹtadinlogun.

    Awọn ti wọn fi panpẹ ọba mu naa ni wọn n kopa ninu ifẹhọnuhan lo ti pe ọjọ kẹrin bayii.

    Ifẹhọnuhan naa lo n waye ni awọn ilu bii Marseille, Lyon, Grenoble ati awọn agbegbe miran ni Paris.

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Reuters

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Getty

    Bakan naa ni wọn yoo ma sin oku ọdọkunrin naa ni agbegbe Nanterre ni Ọjọ Satide.

    Aarẹ Emmanuel Macron ti ni awọn afẹhọnuhan n lo iṣẹlẹ yii lati hu iwa aitọ to si kesi awọn obi lati kilọ fun awọn ọmọ ki wọn jawọ ifẹhọnuhan, ki wọn si joko si ile wọn.

    Ninu ọrọ rẹ Balogun ikọ agbabọọlu orilẹede Faranse, Kyllian Mbappe ti kesi awọn to n hu iwa ipa lati jawọ, ki wọn si fi aye silẹ fun awọn eniyan lati ṣedaro ọmọkunrin to doloogbe naa, ki ijiroro ati aṣoyẹpọ lee waye.

  19. Àwọn àwòrán míràn láti ibi ìfẹ̀họ́núhàn tó ń wáyé ní France rèé...

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Reuters

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Reuters

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Reuters

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Reuters

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, EPA

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, EPA

    Aworan
  20. 'Kasnaty Sugar' tí sọ́ bí òun ṣe bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ''Conductor'' kí òun tó da ìlúmọ̀ọ́ká lórí rédíò