Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ọmọdé mẹ́ta wà nínú àwọn èèyàn mẹ́fà tí afurasí gún lọ́bẹ pa ní China

    Eeyan mẹfa to fi mọ awọn ọmọde mẹta kan wa ninu awọn ti afurasi kan gun lọbẹ pa ni ile ẹkọ jẹleosinmi kan ni agbegbe Guangdong ni China.

    Ọlọpaa sọ pe awọn ti mu afurasi arakunrin ẹni ọdun marundinlọgbọn kan ni ilu Lianjiang.

    Ninu awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ yi la ti ri awọn obimeji ati olukọ kan gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin AFP ti ṣe jabọ.

    Eeyan kan naa farapa ninu iṣẹlẹ ọhun.

    Ni ọjọ Aje ni a gbọ pe iṣẹlẹ yi waye ni nkan bi ago mẹjọ ku ogun iṣẹju eleyi to ṣe deede ago mejila oru ku ogun iṣẹju ni onka GMT.

    O ṣẹlẹ nigba ti awọn obi n ja awọn ọmọ wn sile ẹkọ.

    Awọn ọlọpaa mu arakunrin ni nkan bi ago mẹjọ ti wọn si sọ pe iṣẹlẹ ikọlu ni ohun to ṣẹlẹ yi.

    Oniṣowo kan to ni ṣọọbu lagbegbe naa sọ pe awọn ọlọpaa ti gbegi dina agbegbe naa.

    Niṣe lawọn araalu gbarata bi fọnran fidio iṣẹlẹ naa ṣe bẹrẹ si ni ran kaakiri loju opo ayelujara.

    Wọn ko faaye gba gbigbe ibọn kaakiri ni China.

    Eleyi mu ki ọpọ iṣẹlẹ ikọlu si araẹni ma waye nipa gigun awọn eeyan lọbẹ lẹnu ọdun meloo kan sẹyin ni China.

    Koda a gbọ pe eeyan kan da kẹmika lati fi da ọgbẹ sara awọn akẹkọọ aadọta to wa ninu kilaasi wọn.

    BBC ti ṣe iwadii to ṣafihan iṣẹlẹ igunilọbẹ mẹtadinlogun ni awọn ile ẹkọ to fi mọ fasiti lati ọdun 2010.

    Mẹwaa ninu awọn iṣẹlẹ yi waye laarin ọdun 2018 ati 2023.

    Aworan afihan eeyan to fẹ fi ọbẹ gun eeyan.

    Oríṣun àwòrán, Gordon Johnson

  2. Kìí ṣe nítorí Yari kọ̀ láti gbé ìpè Tinubu là ṣe ránṣẹ́ pè é - DSS

    Aworan Yari, DSS ati Tinubu

    Oríṣun àwòrán, COLLAGE

    Iléeṣẹ́ ẹ̀ṣọ́ ààbò ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, DSS ti jiyàn ìròyìn pé àwọn ránṣẹ́ pé aṣòfin tó ń ṣojú ẹkùn iwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Zamfara nílé aṣòfin àgbà, Abdulaziz Yari nítorí pé ó kọ̀ láti gbé ìpè Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.

    Àtẹ̀jáde kan tí Agbẹnusọ DSS, Peter Afunanya fi síta lọ́jọ́ Àìkú ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.

    Bí ó tilẹ̀ jẹ́ Afunanya kò sọ ìdí tí àjọ náà fi fọ̀rọ̀ wá Yari lẹ́nu wò, irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ látọwọ́ Iléeṣẹ́ ìròyìn ṣàfihàn bí àwọn kan ṣe ń tàbùkù iṣẹ́ ìròyìn.

    Ó ní ohun tó dájú ni pé Yari, tó ti fìgbà kan jẹ́ gómìnà ní ìpínlẹ̀ Zamfara fúnra rẹ̀ mọ ìdí tí àwọn fi ránṣẹ́ pé òun.

    Ó ṣàlàyé pé tí àjọ àwọn bá nílò láti ránṣẹ́ pé ẹnìkan tàbí fi èèyàn kan sí àhámọ́ àwọn kò ní kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ níwọ̀nba ìgbà tí àwọn bá ti tẹ̀lé ìlànà tí òfin là kalẹ̀.

    Bákan náà ni Afunanya tún jiyàn àwọn ìròyìn pé àwọn lọ yawọ ọ́fíìsì àjọ ICPC àti CCB tí àwọn sì kó àwọn fáìlì níbẹ̀.

    Afunanya fi kun pé láti fi ìdí òótọ́ múlẹ̀, àwọn kò lọ sí ICPC tàbí CCB láti lọ kó fáìlì kankan.

    Ó ní ìròyìn elẹ́jẹ̀ ni gbogbo rẹ̀ tó sì rọ àwọn akọ̀ròyìn láti máa ṣe ìwádìí wọn dáadáa kí wọ́n tó máa gbé ìròyìn.

    Ó fi kun pé Iléeṣẹ́ àwọn kò ní jẹ́ kí ìròyìn elẹ́jẹ̀ kó ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá àwọn láti ṣe ojúṣe àwọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

  3. Mà á wọ́ PDP lọ sílé ẹjọ́ tí wọ́n bá gbèrò láti fìyà jẹ mí nítorí àtìlẹyìn tí mo ṣe fún Tinubu lásìkò ìbò

    Tinubu, Fayose ati Atiku

    Oríṣun àwòrán, ChannelsTV

    Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Ayodele Fayose ti ṣàlàyé pé òun ṣiṣẹ́ tako olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú òun, Alhaji Atiku Abubakar.

    Fayose, ẹni tó jẹ́ èèkàn nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP ní òun ṣiṣẹ́ tako Atiku nítorí ẹgbẹ́ náà kò ṣe dada sí òun.

    Gómìnà tẹ́lẹ̀ rí náà ní Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni òun ṣiṣẹ́ fún ní ìpínlẹ̀ Ekiti níbi ètò ìdìbò sípò Ààrẹ Nàìjíríà tó kọjá.

    Níbi ètò iléeṣẹ́ ìròyìn ChannelsTV tó wáyé lọ́jọ́ Àìkú ni Fayose ti sọ wí pé nítorí pé Asiwaju jẹ́ ènìyàn pàtàkì láti ẹkùn gúúsù ìwọ oòrùn Nàìjíríà ni òun ṣe ṣàtìlẹyìn fún un.

    Ó ní ẹkùn gúúsù Nàìjíríà ló kàn láti pèsè Ààrẹ Nàìjíríà àmọ́ PDP kọ̀ láti fa olùdíje kalẹ̀ láti ẹkùn yìí.

    Ó fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, tí òun ti jìyà fún, fòfin de òun àti ọmọ òun, Oluwajomiloju nítorí òun sọ wí pé ẹkùn gúúsù ló kàn láti jẹ Ààrẹ.

    Fayose fi kun pé PDP fi àwọn ọmọ Nàìjíríà ta tẹ́tẹ́ ni bí wọ́n ṣe gbé tíkẹ́ẹ̀tì ẹgbẹ́ fún Atiku Abubakar tó wà láti árèwà lẹ́yìn tí Ààrẹ Muhammadu Buhari lo ọdún mẹ́jọ.

    Bákan náà ló jẹ́jẹ̀ẹ́, tó sì tún dún okò pé òun máa wọ́ PDP lọ sí ilé ẹjọ́ bí wọ́n bá fi lè gbé ìgbésẹ̀ láti fìyà jẹ òun nítorí àtìlẹyìn tí òun ṣe fún Tinubu lásìkò ìbò.

    "Ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ló wà lẹ́nu mi tí mi ò tíì sọ, tí ẹnikẹ́ni bá gbèrò láti pamí lẹ́nu mọ́, mà á tún sọ̀rọ̀ jù báyìí lọ."

    Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àbẹ̀wò tó ṣe sí Tinubu láìpẹ́ yìí, Fayose ní kò ní nǹkankan ṣe pẹ̀lú ẹjọ́ òun àti àjò EFCC.

    Ó tẹ̀síwájú pé ó dá òun lójú pé Tinubu kò ní agbára láti dá ẹjọ́ òun àti EFCC dúró àti pé ọdún karùn-ún rèé tí àwọn tí wà lórí ẹjọ́ náà.

    Ó tún fi kun pé kìí ṣe nítorí ipò Mínísítà ni òun fi ṣe àbẹ̀wò náà àti pé bí Tinubu bá fi Mínísítà lọ òun gan, òun kò ní gbà á.

    Fayose rọ Tinubu láti láti ri dájú pé awon ọ̀dọ́ àtàwọn obìnrin ló pọ̀ jù nínú àwọn tó máa fún ní ipò nítorí àwọn ọ̀dọ́ nílò àwọn aṣojú nínú ìjọba.

  4. Ọlọ́kadà tàbí oníkẹ̀kẹ́ tí a bá gbámú láàárín aago mẹ́sàn-án alẹ́ sí mẹ́fà ìdajì máa...- Ọlọ́pàá Kwara

    Àwọn ọlọ́kadà àti Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara

    Oríṣun àwòrán, KWARA POLICE

    Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ti ṣèkìlọ̀ fún àwọn ọlọ́kadà àti oníkẹ̀kẹ́ akérò láti yé ṣiṣẹ́ kọjá aago mẹ́sàn-án alẹ́ mọ́ gẹ́gẹ́ bí òfin tó ti wà nílẹ̀.

    Wọ́n tún ní òfin kò fàyè gba àwọn ọlọ́kadà àti oníkẹ̀kẹ́ akérò láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ṣáájú aago mẹ́fà òwúrọ̀.

    Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kwara, Ebunoluwarotimi Adelesi tó ṣèkìlọ̀ náà lásìkò ìpàdé rẹ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú ẹgbẹ́ ọlọ́kadà àti oníkẹ̀kẹ́ ní àwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní tẹ̀lé òfin náà báyìí.

    Adelesi fún àwọn adarí ẹgbẹ́ náà láti fa àwọn ọmọlẹ́yìn létí láti má tẹ òfin lójú mọ́lẹ̀.

    Ó ní ẹni tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá bá tẹ̀ wí pé ó tẹ òfin lójúmọ́lẹ̀ tàbí lòdì sí òfin máa fojú winá òfin.

    Bákan náà ló rọ àwọn ọ̀daràn láti fi ìpínlẹ̀ Kwara sílẹ̀ pátápátá nítorí bí wọn kò bá ṣe bẹ́ẹ̀ òfin ti ṣetán láti fì wọ́n làkàlàkà.

    Adelesi tún kan sáárá sí àwọn ènìyàn tó máa ń tẹ̀lé òfin, tó sì ní kí ẹnikẹ́ni má ṣe bẹ̀rù tàbí fòyà, kí wọ́n máa bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn lọ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ.

    Ó jẹ́jẹ̀ẹ́ pé gbogbo ipá òun ni òun máa sà láti ri dájú pé kò ní sí ààyè fún ìwà ọ̀daràn ní ìpínlẹ̀ Kwara rárá.

  5. Sanwo-Olu padà ṣí afárá Apogbon lẹ́yìn ọdún kan àti oṣù mẹ́ta tí iná sọ níbẹ̀

    Apogbon Bridge

    Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

    Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu ti ṣi afara Apongbon lẹyin ọdun kan ati oṣu mẹta ti wọn ti afara ọhun latari ina to ṣẹyọ ni sakani rẹ.

    Inu ibẹrubnojo lawọn oniṣowo ati onimọto to wa lagbegbe afara naa wa lasiko ti ina ọhun dede ṣẹyọ laarọ ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta.

    Lara awọn nnkan ti ina ọhun jo ni awọn ọkọ akero ati ọkọ ayọkẹlẹ to wa labẹ afara ọhun.’

    Apogbon Bridge

    Oríṣun àwòrán, @jidesanwoolu

    Lẹyin iṣẹlẹ naa ni ijọba ti afara ọhun pa, to si pese ọna miran ti awọn araalu yoo maa gba kọja amọ ko rọrun.

    Gomina Babajide Sanwo-Olu funra rẹ lo lọ pada ṣi afara ọhun.

    Lara awọn to kọwọ rin pẹlu Sanwo-Olu lọ sibẹ ni akọwe ileeṣẹ to n ri si akanṣe iṣẹ, Olufemi Daramola.

    Awọn mii to tun wa nibẹ ni Olukorede Keisha to jẹ ọga agba ileeṣẹ to n ri si ọrọ iṣẹ nipinlẹ Eko.

  6. Tinubu balẹ̀ sí Guinea-Bissau fún àpérò àjọ ECOWAS

    Tinubu ni orile ede Guinea-Bissau

    Oríṣun àwòrán, TWITTER

    Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti balẹ̀ sí orílẹ̀ èdè Guinea-Bissau láti kópa níbi àpérò àwọn olórí orílẹ̀ èdè àjọ ECOWAS.

    Agbẹnusọ Ààrẹ, Dele Alake nínú àtẹ̀jáde kan tó fi síta lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní Tinubu máa lò àkókò yìí láti fi sáwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tó wà ní Guinea-Bissau.

    Ó ní àpérò yìí tó jẹ́ ẹlẹ́kẹtàlélọ́gọ́ta irú rẹ̀ ni àpérò ilẹ̀ Adúláwò àkọ́kọ́ tí Tinubu yóò kópa níbẹ̀ láti ìgbà tó ti dé ipò Ààrẹ.

    Ó ṣàlàyé pé àwọn olórí orílẹ̀ èdè mẹ́rìndínlógún ni ìrètí wà pé wọ́n máa sọ̀rọ̀ lórí àwọn nǹkan tó ń bá ilẹ̀ Adúláwọ̀ fínra pàápàá lórí ètò ààbò.

    Bákan náà ló ní wọ́n tún máa jíròrò lórí bí àwọn alágbádá ṣe máa gba ìjọba padà ní orílẹ̀ èdè Mali, Burkina Faso àti Guinea, ìṣàmúlò owó ẹyọ kan ṣoṣo láàárín àwọn orílẹ̀ èdè àjọ ECOWAS àti ìdènà tó ń bá ọjà rírà àti títà láàárín Eko àti Abidjan.

    Nígbà tó ń bá àwọn ọmọ ogun Nàìjíríà tó wà ní Guinea-Bissau sọ̀rọ̀, Ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ ọ̀gá wọn iṣẹ́ ìsìn wọn sí Nàìjíríà àti orílẹ̀ èdè tí wọ́n wà.

    Tinubu ní ìrètí wà pé yóò tún ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn orílẹ̀ èdè kan kí ìbáṣepọ̀ Nàìjíríà àtàwọn orílẹ̀ èdè le máa tẹ̀síwájú.

  7. Àwọn agbébọn jí alága ẹgbẹ́ APC Ekiti gbé lọ

    Paul Omotosho

    Oríṣun àwòrán, TRIBUNE

    Alága ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressive Congress, APC ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Paul Omotosho ti kó sọ́wọ́ àwọn ajínigbé.

    Ìròyìn ní òpópónà Agbado-Imesi- Ekiti ní ìjọba ìbílẹ̀ Gbonyin ni àwọn ajínigbé náà ti jí alága náà gbé lọ.

    Agbenusọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC ní ìpínlẹ̀ Ekiti, Segun Dioe tó fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé.

    Dipe ṣàlàyé pé alága náà ló dá wà nínú ọkọ̀ Venza rẹ̀ kí àwọn ajínigbé ọ̀hún tó ṣe ìkọlù sí i.

    Ó ní àwọn ti fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó àwọn ọlọ́pàá àti Amotekun létí lójúnà àti lè tètè ṣàwárí Omotosho.

  8. Ṣé ó yẹ kí ìjọba fi òfin de 'Prank' ṣíṣe?

  9. 'Ganduje lẹ́jọ́ láti jẹ́ lórí fídíò gbígba dọ́là'

  10. Ṣé lóòótọ́ ni Adeleke kó mọ̀lẹ́bí rẹ̀ méjì sínú àwọn tó fẹ́ yàn ní kọmíṣọ́nà?

  11. Ẹni tó bá lọ sílé ẹjọ́ lórí ìlànà ọba jíjẹ nílùú Ibadan ń tan ara rẹ̀ - Makinde

  12. Bí ẹgbẹ́ òkùnkùn "One Million Boys" àti Ekugbemi ṣe bẹ̀rẹ̀ rèé

  13. Ẹ̀yin ènìyàn ẹ ṣọ́ra, àìsàn Diphteria tí pa ènìyàn 80 ní Naijiria

  14. Makinde ṣe ìlérí láti parí aáwọ̀ láàrin Fasoranti àti Adebanjo

  15. Ilé ẹjọ́ gba béèlì Abba Kyari pẹ̀lú ₦‎50m

    Abba Kyari

    Oríṣun àwòrán, @nifemioguntoye

    Ile ẹjọ giga kan niluu Abuja ti gba beeli ọga ọlọpaa ti NDLEA n ba ṣe ẹjọ, Abba Kyari.

    Adajọ James Omotosho gba beeli afurasi naa ni owo ti iye rẹ ko din ni aadọta miliọnu naira.

    Kyari ati ibatan rẹ meji ni ajọ to n gbogun ti egboogi oloro, NDLEA n ba ṣe ẹjọ lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn pe wọn kuna lati kede iye dukia ti wọn ni fun NDLEA.

    Ṣaaju jni NDLEA ti kọkọ fẹsun kan Kyari ninu oṣu Kẹfa, ọdun yii, toun ti awọn ibatan rẹ naa, Mohammed Kyari ati Ali Kyari.

    Adajọ Omotosho gba beeli Kyari pẹlu oniduro meji ti wọn gbọdọ ni dukia niluu Abuja ti iye rẹ to miliọnu marundinlọgbọn naira.

    Omotosho tẹsiwaju pe, bo tilẹ jẹ pe oun ti gba beeli Kyari, kikuro rẹ ni ahamọ da lori ẹjọ rẹ mii to n lọ lọwọ niwaju adajọ Emeka Nwite nile ẹjọ giga mii niluuu Abuja.

    O ni bo tilẹ jẹ awọn agbesumọmi ja ọgba ẹwọn Kuje lọjọ karun un, oṣu Keje, ọdun 2022, nibi ti ọpọ awọn ọdaran ati afurasi ti salọ, Kyari kọ lati salọ.

    Ẹwẹ, Kyari n koju ẹjọ lilọwọ si gbigbe oogun oloro pẹlu awọn afurasi mẹrin mii.

    Ọdun kan ati oṣu mẹfa lo ti lo ninu ahamọ ṣaaju akoko yii.

  16. Ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó bá ṣe ayẹyẹ ‘7/7’ yóò jẹ iyán rẹ̀ níṣu – Iléeṣẹ ọlọ́pàá Osun

    Cultism in Nigeria

    Oríṣun àwòrán, Others

    Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti kilọ fun awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun to wa nipinlẹ naa pe ko si aye fun ayẹyẹ ‘7/7‘ ti wọn maa n ṣe ni gbogbo ọjọ keje, oṣu Keje ọdun.

    Alukoro ileeṣẹ naa, Yemisi Opalola lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan to fi sọwọ si awọn akọroyin niluu Osogbo.

    O ni “a ti ṣawari ninu ọfintoto wa pe awọn ọmọ ẹgbẹ kan fẹ ṣe ayẹyẹ lati gbe ẹgbẹ naa larugẹ lọjọ keje, oṣu Keje.”

    “O tun to wa leti pe awọn kọlọrọsi kan ti wọ ipinlẹ Osun latawọn ipinlẹ mii fun ayẹyẹ ọhun.”

    “Fun idi eyii, ileeṣẹ ọlọpaa fẹ ṣe ikilọ fun awọn ọmọ ẹlẹgbẹ okunkun atawọn kọlọrọsi mii nipinlẹ Osun lati jawọ kuro ninu irufẹ erongba bẹẹ, ati pe ọlọpaa n ṣọ wọn loju-lẹsẹ.”

    “Nitori naa, ileeṣẹ ọlọpaa atawọn ileeṣẹ eto abo miran ko ni faye gba ikorajọ Kankan lati sami si ayẹyẹ 7/7, eyii to le yọri si itajẹsilẹ ati biba dukia jẹ.”

    Opalola wa rọ awọn obi lati kilọ fun awọn ọmọ wọn ki wọn ki wọn kilọ fun wọn.

    Lẹyin naa lo rọ awọn araalu lati pe aago ileeṣẹ ọlọpaa ti wọn ba kofiri awọn ọmọ ẹgbẹ kankan ni ayika wọn.

  17. Mà á ri dájú pé ààbò tó péye wà fún ẹ̀mí àti dúkìá àwọn ọmọ Nàìjíríà – Tinubu

  18. 'Russia ni Prigozhin wà kìí ṣe Belarus'

    Yevgeny Prigozhin

    Oríṣun àwòrán, Reuters

    Adarí orílẹ̀ èdè Belarus, Alexander Lukashenko ti ní kò sí ọ̀gá àgbà ikọ̀ ogun Wagner, Yevgeny Prigozhin ní orílẹ̀ èdè àwọn.

    Níbi ìpàdé kan tí Lukashenko ṣe lọ́jọ́bọ̀ pẹ̀lú àwọn akọ̀ròyìn ló ti sọ wí pé òun kò lè sọ ní pàtó pé ibi báyìí ni Prigozhin wà àmọ́ òun ní ìgbàgbọ́ pé Russia náà lọ ṣì wà.

    Ní oṣù tó kọjá ni Prigozhin gbèrò ìdìtẹ̀gbàjọba láti gba ìjọba lọ́wọ́ ààrẹ Vladmir Putin tí orílẹ̀ èdè Russia kí òkété tó bórù mọ lọ́wọ́.

    Láti parí làásìgbò tó fẹ́ súyọ lórí ìgbésẹ̀ Prigozhin yìí, Russia kọ̀ láti ṣe fìyà ìwà tó wù jẹ ẹ́, tí wọ́n sì tún gbà á láàyè láti máa lọ gbé ní Belarus.

    Àmọ́ àti ìgbà náà ni ibi tí Progozhin wà kò ti fojú hàn dáadáa fún àwọn ènìyàn.

    Lukashenko wà lára àwọn tó parí aáwọ̀ lórí ìdìtẹ̀gbàjọba náà, tó sì ní Prigozhin ti balẹ̀ sí orílẹ̀ èdè òun ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.

    Ìwádìí BBC fi hàn pé ọkọ̀ bàálù Prigozhin tó lọ sí Belarus ní ìparí oṣù Kẹfà padà sí orílẹ̀ èdè Russia ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà àmọ́ BBC kò lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé bóyà òótọ́ ni ohun tí Lukashenko sọ pé Russia ní Prigozhin wà.

    Ikọ̀ ọmọ ogun Wagner ló jẹ́ ti aládàni tó ń bá Russia ja ogun tí wọ́n ń gbé ti Ukraine láti oṣù Kejì ọdún 2022.

    Ilé tí àdó olóró bà

    Ẹ̀wẹ̀, ènìyàn márùn-ún ti pàdánù ẹ̀mí wọn nígbà tí àdó olóró tí Russia jù sí ìlú Lviv balẹ̀ sí ilé ìgbé kan.

    Bákan náà ni ènìyàn mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n mìíràn tún farapa nínú ìkọlù ọ̀hún tí Mayor ìlú Lviv sì jùwe ìkọlù náà bíi èyí tó fẹ́ẹ̀ lágbára jùlọ sí ilé ìgbé àwọn ará ìlú.

    Olórí ẹkùn Lviv, Maksym Kozytskyi ní ilé tí ìkọlù náà ṣe àkóbá fún lé ní ọgbọ̀n àmọ́ ilé iṣẹ́ ìr]oyìn Russia ní ilé ẹ̀kọ́ ọmọ ogun Ukraine ni àdó olóró náà bà.

    Wọ́n ní irọ́ ni pé ìròyìn pé ilé ìgbé ni ibi tí àdó olóró náà bà, pé Ukraine fẹ́ fi ọwọ́ bó òótọ́ mọ́lẹ̀ ni.

    Kozytskyi nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde lórí Telegram ní àwọn ti rí òkú àwọn márùn-ún tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ yọ àti pé iṣẹ́ ti ń lọ láti yọ àwọn mìíràn tó há sínú ilẹ̀.

    Ó ní àwọn òṣìṣẹ́ àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì wà ní ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tí wọ́n ń gbèrò láti yọ àwọn tó há sínú ilẹ̀.

    Àwọn tó pàdánù ènìyàn wọn

    Oríṣun àwòrán, EPA

  19. Tinubu mú àyípadà bá àfikún owó orí tí Buhari ṣe kó tó kúrò nípò

  20. 'Ohun ìbànújẹ́ ló jẹ́ fún mi pé wọ́n dáná sun ìyá mi lójú mi láì rí nǹkankan ṣe si'