Àwọn ọmọdé méjì kan móríbọ́ lọ́wọ́ ikú nígbà tí wọ́n ṣàwárí
létí òkun Lake Kivu lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí àgbàrá ṣekúpa ènìyàn tó lé ní irinwó lẹ́kùn
ìlà oòrùn Democratic Republic of Congo.
“Ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún gbogbo wa” adarí ìlú, Delphin
Birimbi sọ fún BBC.
Birimbi ní àwọn òbí àwọn ọmọ náà ti kú àmọ́ àwọn ti ń bá àwọn
tó lè ṣe ìtọ́jú àwọn ọmọ ọ̀hún sọ̀rọ̀.
Bí àwọn ọmọ náà ṣe yé lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n lò lórí omi
àmọ́ àwọn tó ṣàwárí ní àwọn rí wọn tí wọ́n léfòó lórí àwọn ìdọ̀tí tó wà létí
omi náà.
Birimbi ní ọjọ́ Ajé ni wọ́n rí àwọn ọmọ náà yọ, ọ̀kan ní
Bushushu, tí wọ́n sì rí ìkejì ní Nyamukubi, àwọn ìlú méjèèjì tí àgbàrá òjò ńlá
ti ṣọṣẹ́ ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Àjọ Red Cross orílẹ̀ èdè Congo ní ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé yìí ti fa
kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí sùn tí ominú sì ń kọ àwọn lórí bí òórùn àwọn òkú tó ti ń jẹrà
ṣe gbòde.
Ọ̀pọ̀ òkú ni wọ́n tún ṣe àwárí rẹ̀ nínú irà lọ́jọ́rú èyí sì
ti jẹ́ kí ènìyàn tó ti kú ti wọ 411 báyìí.
Nínú àwọn wọ̀nyí, 317 òkú ni wọ́n ti sìn.
Àwọn olórí ìlú agbègbè náà ní ó ṣòro láti dá òkú àwọn ènìyàn
tó pàdánù ẹ̀mí wọn mọ̀ tán nítorí púpọ̀ nínú àwọn tó kú náà ló kàn wá ná ọjà kí
òjò ńlá tó ká wọn mọ́ ibẹ̀.
Agbenusọ àjọ Red Cross ní DR Congo, John Kashinzwet sọ fún BBC pé
látàrí bí kò ṣe sí ilé ìgbókùúpamọ́sí ńlá ní agbègbè náà, sínsin àwọn òkú náà láìpẹ́
ló yẹ ní kété tí àwọn ènìyàn wọn bá ti rí wọn.
Nínú fídíò kan tí akọ̀ròyìn kan fi sórí Twitter, obìnrin kan
ń sọ níbẹ̀ pé ọ̀kan nínú àwọn ọmọdé náà ti fi ẹsẹ̀ ṣèṣe.
Birimbi ní ènìyàn tí àwọn ṣì ń wá lé ní ẹgbẹ̀rún márùn-ún
báyìí àti pé iṣẹ́ ṣì ń lọ láti ṣàwárí wọn.
Kò dín ní ènìyàn igba tó farapa ni ìròyìn ní wọ́n wà ní ilé
ìwòsàn níbi tí wọ́n ti ń gba ìtọ́jú látàrí omíyalé ọ̀hún.
Ilé ìgbé 1,300, ọ̀pọ̀ ilé ẹ̀kọ́, ilé ìwòsàn, ilé ìjọsìn àti
omi ló ti bàjẹ́.
Gentile Ndagijimana sọ fún BBC gbogbo nǹkan òun ni àgbàrá
náà ti gbé lọ.
“Mi ò ní nǹkankan mọ́, kò sí ẹbí, ọkọ, gbogbo ẹ ni àgbàrá ti
gbà lọ.”
Birimbi wá ní láti ìgbà tí àjálù náà ti wáyé, ìjọba pàápàá
Ààrẹ àti Mínísítà kankan kò yọjú sí ibẹ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n kéde ọjọ́ Ajé
láti fi ṣe ìdárò àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn.
Àgbàrá òjò yìí ló ń wáyé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ìṣẹ̀lẹ̀ omíyalé
àgbàrá ya ṣọ́ọ̀bù ṣekúpa ènìyàn tó lé ní 130 ní Rwanda.
Ọ̀gá àgbà àjọ ìṣọ̀kan àgbáyé Antonio Guterres ní àwọn omíyalé
yìí ń wáyé látàrí àyípadà ojú ọjọ́.