Ìròyìn òfegè ni pé BVN yín yóò ''expire'' lẹyìn ọdún mẹwàá -CBN
Ile ifowopamọ apapọ Naijiria CBN ti ke si araalu pe ki wọn yago fun iroyin to n gbode pe nọmba to n so akoto ikowopamọsi onibara banki pọ,BVN, yoo jọba lẹyin ọdun mẹwaa.
Oludari eto ibaraẹnisọrọ banki apapọ naa Isa Abdulmumin lo fidi ọrọ yi mulẹ ninu atẹjade kan.
O ni irọ to jina si ootọ ni ọrọ yi ati pe nọmba yi kii jọba lẹyin igba ti wọn ba ti fun onibara banki kọọkan ni tiẹ.
Amọ o fi kun alaye rẹ pe awọn ilana kan to so mọ iṣakoso awọn iroyin alabara sọ pe o ṣeeṣe ki alabara banki ṣe atunse ninu awọn iroyin ti wọn fi kalẹ.
O ni eleyi yoo waye lẹyin tawọn alaṣẹ ba fi ọwọ si.
Isa sọ pe fun idi eyi ''a rọ awọn alabara banki lati maa ṣamulo nọmba BVN wọn lai si idiwọ kankan titi ayeraye paapa awọn ti banki ti gba iroyin nipa wọn silẹ''
Inu oṣu keji ọdun 2015 ni ijọba Naijria gbe aṣẹ kalẹ eleyi to sọ di dandan pe ki gbogbo onibara banki ni nọmba idanimọ mọkanla yi fun gbogbo idunadura lori akoto owo wọn.
CBN ni awọn gbe eto yi kalẹ lati ri pe aabo to peye wa fun owo ọlọdani ati ileeṣẹ to ba wa ni apamọ ile ifowopamọ wọn.
Pẹlu nọmba yi, awọn ile ifowopamọ yoo le so gbogbo akoto ikowopamọ si ti eeyan ba ni papọ.
Koda ko jẹ mẹ́waa ni akanti to o ni, BVN kan ṣoṣo ni yoo so gbogbo wọn papọ mọ ọ.