You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Ẹ̀ẹ̀mejì péré lọ́sẹ̀ ni kí ẹ máa lọ síbi iṣẹ́ - ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ COEASU
Awọn ọmọ Nàìjíríà fẹ́ràn láti gba adigunjalè mọ́ra ju àwa "transgender" táa ń múra bí obìnrin lọ - Jay Boogie
Bí ọwọ́ ṣe tẹ ẹni ọdún 32 tó fún ìyá rẹ̀ lọ́run pa nípinlẹ̀ Ogun níyì
Ọ̀pọ̀ iléepò wà ní títìpa, àwọn ọlọ́kọ̀ ń tò féto bí lítà epo ṣe di N617 ní Abuja, Fuel Price Increase: Owó líta epo kan di N617 ní Abuja, N500 ló sì wà ní Ogun
Iroyin kan ti n ja rainrain nilẹ pe ajọ elepo rọbi nilẹ wa, NNPC ti fi ele le owo lita epo pẹtiroolu kan.
Awọn ọlọkọ ero lẹkun ariwa ati guusu Naijiria si lo n figbe bọnu pe lootọ ni ele ti ba owo lita epo petrolu ni Naijiria.
Awọn ila gbọọrọ si ti bẹrẹ si ni foju han lawọn epo kaakiri.
Ni Abuja, tiise olu ilu ilẹ wa, ileepo to jẹ ti ajọ NNPC kan ti yi owo lita epo tiẹ si N617.
N539 si ni ile epo yii n ta lita epo kan tẹlẹ ki ele yii to de
Bakan naa, olugbe kan nilu Jos nipinlẹ Plateau salaye pe oun ra lita epo pẹtirooluu ni N617 laarọ oni ọjọ isẹgun.
N500 ni owo lita epo kan nipinlẹ Ogun, ọpọ ileepo wa ni titipa
Ikọ BBC Yoruba to wa lagbegbe Sango Ota bọ sigboro lati mọ iye ti wọn n ta lita epo kan lagbegbe naa.
Gbogbo ọpọ ileepo to wa ni agbegbe yii lo wa ni titipa, to si jẹ pe ileepo NNPC nikan lo ni epo lati ta fun araalu.
Amọ fun iyalẹnu, ileepo NNPC to n ta epo lagbegbe Ijoko n ta lita epo ni N500 tii se iye to wa jẹ tẹlẹ.
Se ni awọn ọlọkọ ati ọlọkada ya bo ileepo NNPC naa lati ra epo, paapaa nigba to jẹ pe oun nikan nile epo to n ta epo ni agbegbe naa.
Amọ a ko tii le fidi rẹ mulẹ boya ajọ NNPC ti kede ele owo ori epo petrolu.
Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Anthrax to ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ Nàìjíríà
Ẹ̀sùn wo ni wọ́n fi kan Iyiola Omisore tí ipò akọ̀wé APC fi bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀?
Ilé aṣòfin Osun buwọ́lu àbá láti mú àyípadà bá orúkọ ìpínlẹ̀ náà
Ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Osun ti buwọ́lu àbá láti mú àyípadà bá orúkọ ìpínlẹ̀ náà sí "Osun State" dípò "State of Osun" tó ń jẹ́ báyìí.
Ẹ ó rántí ní ọdún 2012 lábẹ́ ìṣèjọba Rauf Aregbesola gẹ́gẹ́ bí gómìnà ni wọ́n pa orúkọ ìpínlẹ̀ náà dà sí "State of Osun."
Ilé aṣòfin nínú àbá kan tí wọ́n pè ní ṣíṣe àyípadà sí orin àti àsíá ìpínlẹ̀ Osun ní àwọn ti dá orúkọ náà padà sí "Osun State" tó wà tẹ́lẹ̀ ṣáájú kí wọ́n tó mú àyípadà bá a.
Abẹnugan ilé aṣòfin náà, Adewale Egbedun nígbà tó ń buwọ́lu àbá náà lẹ́yìn tí ìjókòó ilé tí kà á fún ìgbà ìkẹta ní àwọn máa fi ṣọwọ́ sí gómìnà fún ìbuwọ́lù tirẹ̀.
Àmọ́ wọn ò ṣe àyípadà sí orin ìpínlẹ̀ náà, tí wọ́n sì fi kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ṣe wà nínú ìwé òfin ti àtijọ́.
Ẹ̀wẹ̀, ilé aṣòfin ti ṣe àyẹ̀wò fún àwọn mẹ́tàlá nínú mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí gómìnà Ademola Adeleke fi orúkọ wọn ṣọwọ́ sílé láti yàn gẹ́gẹ́ bí kọmíṣọ́nà.
Akinyode Oyewusi, alága ìgbìmọ̀ tó ń ṣe ìwádìí àwọn ènìyàn náà ní gbogbo àwọn mẹ́tàlá tí àwọn ti ṣe àyẹ̀wò fún ló pegedé tí wọ́n sì yẹ ní kọmíṣọ́nà.
Oyewusi ní gbogbo wọn ló pegedé lábẹ́ ìwé òfin Nàìjíríà.
Abẹnugan ilé, Egbedun ní àwọn máa buwọ́lu ìyànsípò àwọn ènìyàn náà ní kété tí ìgbìmọ̀ bá ti parí ìwádìí wọn.
Wòlíì tó lẹ̀dí àpòpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin kan láti pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ gba ìdájọ́ ikú
Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Osun tó fi ìlú Ikire ṣe ibùjókòó ti dájọ́ pé kí wọ́n lọ yẹgi fún wòlíì kan, Segun Philip àti Owolabi Adeeko fẹ́sùn wí pé wọ́n pa arábìnrin kan, Favour Daley-Oladele.
Daley-Oladele ló jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ti ìpele tó kẹ́yìn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì ti ìpínlẹ̀ Eko kí wọ́n tó dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò láti fi ṣe ètùtù ọlà.
Nígbà tó ń gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ lọ́jọ́ Ajé, Adájọ́ Christiana Obadina tún ju Bola Adeeko tó jẹ́ ìyá Owolabi sí ẹ̀wọ̀n ọdún méjì fẹ́sùn wí pé ó jẹ ẹ̀yà ara ènìyàn.
Báwo ni ọ̀rọ̀ ṣe wáyé?
Ìròyìn ní ilé ẹ̀kọ́ gíga Fásitì LASU ni Favour àti Owolabi ti pàdé tí àwọn méjéèjì sì jọ ń ṣe wọléwọ̀de.
Nínú oṣù Kejìlá ọdún 2019 ni Owolabi ní kí Favour tẹ̀lé òun lọ sí Ikoyi ní ìpínlẹ̀ Osun.
Nígbà tí wọ́n dé Ikoyi ni Owolabi tún fi ọgbọ́n tan Favour lọ sí ilé ìjọsìn Philip níbi tí wọ́n ti fún ní nǹkan jẹ kí wọ́n tó fi ọmọ odó pa á.
Lẹ́yìn tí wọ́n pa Favour tán ni wọ́n yọ àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ kan, tí wọ́n sì tún sin òkú rẹ̀ sínú ọgbà ilé ìjọsìn náà.
Àwọn ẹ̀yà ara Favour tí wọ́n yọ yìí ni ìròyìn ní wọn fi pèsè àwọn àsèjẹ fún ìyá Owolabi kí ọjà rẹ̀ lè máa yá ju ti àtẹ̀yìnwá lọ.
Lẹ́yìn tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ àwọn afurasí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ni wọ́n wọ́ wọn lọ sílé ẹjọ́ Májísírèètì ní Apomu lọ́dún 2020 kí wọ́n tó tún gbé wọn lọ sí ilé ẹjọ́ gíga Ikire lọ́dún 2021 fẹ́sùn ìpànìyàn àti lílẹ̀dí àpòpọ̀ èyí tó lòdì sí òfin ìpínlẹ̀ Osun.
Lásìkò tí ìgbẹ́jọ́ náà fi ń wáyé, olùpẹjọ́, tó tún jẹ́ Akọ̀wé àgbà ilé iṣẹ́ tó ń rí sí ètò ìdájọ́ ní ìpínlẹ̀ Osun, Adekemi Bello sọ fún ilé ẹjọ́ pé Owolabi jẹ́wọ́ fún àwọn ọlọ́pàá pé òun lo Favour láti fi pèsè àsèjẹ ètùtù ọlà fún ìyá òun.
Adájọ́ Obadina nígbà tó ń gbé ìdájọ́ kalẹ̀ ní olùpẹjọ́ fi ẹ̀rí múlẹ̀ dáadáa pé Philip àti Owolabi lẹ̀dí àpòpọ̀ láti pa Favour.
Adájọ́ ní kí wọ́n lọ yẹgi fún àwọn méjéèjì títí tí ẹ̀mí ma fi bọ́ lọ́rùn wọn fẹ́sùn ìpànìyàn.
Bákan náà ló tún jù wọ́n sí ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́rìnlá fún lílẹ̀dí àpòpọ̀.
Bẹ́ẹ̀ náà ló ní ìyá Owolabi jẹ̀bi jíjẹ ẹran ènìyàn, tó sì ní kí òun náà lọ lo ọdún méjì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n.
Dá àwọn iléeṣẹ́ tó ń pín iná lẹ́kun láti má fi owó kún owó iná - OPC rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Tinubu
Ẹgbẹ́ Oodua Peoples Congress (OPC) ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti sọ fún àwọn ilé iṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná láti ṣe ìdádúró àlékún tí wọ́n fẹ́ fi kún owó iná.
Ààrẹ OPC, Wasiu Afolabi nínú àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé ẹgbẹ́ náà, Bunmi Fasehun fi léde lọ́jọ́ Àìkú, ló ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ náà.
Ní ọjọ́ Ẹtì tó kọjá ni ìròyìn ní àwọn ilé iṣẹ́ tó ń pín iná mọ̀nàmọ́ná mọ́kànlá ti ń bèèrè fún àtúngbéyẹ̀wò iye owó wọn.
Afolabi rọ Tinubu láti paná èròńgbà náà nítorí ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC àti ẹgbẹ́ àwọn olùpèsè ọjà ìyẹn Manufacturers Association of Nigeria (MAN) ti ṣáájú bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ̀ náà.
Ó ṣàlàyé pé ìnira tí àwọn ènìyàn ń kojú lásìkò yìí pọ̀ ju kí ọ̀wọ́n gógó iná tún kun.
Ó ní ó yẹ kí Ààrẹ sọ fún àwọn ilé iṣẹ́ tó ń pín iná náà pé tí wọn kò bá lè máa ta iná ni iye tí wọ́n ń tà á lọ́wọ́ kí wọ́n gbé ìwé àṣẹ wọn kalẹ̀.
Bákan náà ló wòye pé àsìkò ti tó fún ìjọba láti yé gba ilé iṣẹ́ ẹyọ̀kan péré láti máa mójútó agbègbè kan, pé ó yẹ kí àwọn ilé iṣẹ́ tí yóò máa pín iná mọ̀nàmọ́ná pọ̀ kí ààyè lè wá fún àwọn ènìyàn láti rà lọ́wọ́ èyí tó bá wù wọ́n.
Bí ọ̀rọ̀ ₦70bn tí a fẹ́ ná ṣe jẹ́ nìyí - Ilé aṣòfin àgbà fohùn léde
Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ti ní àwọn kò ṣe àfikún sí àbá ìsúná tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gbé síwájú àwọn èyí tí wọ́n buwọ́lu ní ọ̀sẹ̀ tó kọjá.
Ṣáájú ni ìròyìn gba orí ayélujára pé ìjọba ṣe àfikún àádọ́rin bílíọ̀nù náírà sínú àbá ìsúná náà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún àwọn aṣòfin.
Àtẹ̀jáde kan tí alága ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ìròyìn àtàwọn ọ̀rọ̀ tó ń lọ nílé aṣòfin àgbà, Sẹ́nétọ̀ Yemi Adaramodu fi síta lọ́jọ́ Àìkú ní ṣíṣe òfin ni iṣẹ́ àwọn tí àwọn ènìyàn yan àwọn láti lọ ṣe.
Adaramodu ní àwọn kò nílò ẹ̀bùn kí àwọn tó ṣe ojúṣe àwọn.
Ó ṣàlàyé pé bí buwọ́lu àbá ìsúná tí Tinubu gbé síwájú àwọn wáyé láti lè jẹ́ kí ìrànwọ́ tí ìjọba fẹ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà lẹ́yìn tí wọ́n yọ ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù yá ní kíákíá.
Adaramodu tẹ̀síwájú pé tí àwọn ènìyàn bá ṣe àbẹ̀wò sí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ni wọ́n máa mọ àwọn nǹkan tó nílò àtúnṣe níbẹ̀ èyí tí wọ́n fẹ́ fi àádọ́rin bílíọ̀nù náírà náà ṣe.
"Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Sẹ́nétọ̀ ló ní láti gbé àga, tábìlì wá láti ilé wọn, ṣe àwọn àtúnṣe kéékèèké ní ọ́fíìsì wọn fúnra wọn."
Ó fi kun pé owó tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kìí ṣe wí pé wọ́n máa sán fún Sẹ́nétọ̀ kankan, ó ní ilé aṣòfin ló máa ṣe àmójútó owó náà fúnra rẹ̀ láti ri pé wọ́n fi ṣe àwọn nǹkan tó yẹ.
"Ó yẹ kí a tẹmpẹlẹmọ pé kìí àwọn aṣòfin nìkan ló wà ní ilé aṣòfin, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ló wà níbẹ̀ tí wọ́n sì nílò irinṣẹ́ àti ààyè tó dára láti ṣiṣẹ́."
Ó ní ẹ̀sùn pé àwọn ṣe àfikún owó náà lọ́nà àìtọ́ jẹ́ ojúnà láti tàbùkù ilé aṣòfin ẹlẹ́kẹ̀wàá.
Ó wá rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti rí ilé aṣòfin bí èyí tó ń ṣiṣẹ́ láti mú ìlọsíwájú bá Nàìjíríà lápapọ̀.
Ènìyàn kan kú, ọ̀pọ̀ èèyàn ń dákú ṣeré bí ooru àpọ̀jù ṣe bẹ̀rẹ̀ ní gúúsù Yúróòpù
Ńṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè ní ẹkùn gúúsù Yúróòpù ń gbóná janjan lásìkò yìí bí àyípadà ojú ọjọ́ ṣe ń peléke si.
Orílẹ̀ èdè Greece ti gbóná wọ 40C tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ báyìí.
Àwọn aláṣẹ orílẹ̀ èdè Greece ti ti Acropolis - tó jẹ́ ibi tó gbajúmọ̀ jùlọ tí àwọn ènìyàn ti máa ń lọ fún ìnàjú níbẹ̀ - tó pa báyìí láti dá ààbò bo àwọn àlejò nígbà tí gbogbo ìlú gbóná janjan ní ọ̀sán.
Àjọ tó ń ṣe àmójútó ojú ọjọ́ ilẹ̀ Yúróòpù ní Italy, Spain, France, Germany àti Poland ni ìrètí wà pé wọn yóò gbóná jùlọ.
Wọ́n ní ó ṣeéṣe kí àwọn ibìkan ní Italy gbóná wọ 48C, èyí tó ma jẹ́ gbígbóná tó pọ̀ jùlọ tí wọ́n máa ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ ní Yúróòpù.
Nínú oṣù Kẹjọ ọdún 2021 ni wọ́n ṣe àkọ́ọ́lẹ̀ ìlú tó gbóná jù ní Yúróòpù nígbà tí Sicily gbóná wọ 48.8C.
Ìròyìn ní ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó fi mọ́ àwọn tí wọ́n lọ fún ìnàjú ni wọ́n kàn ń dákú ní Italy nítorí bí orílẹ̀ èdè náà ṣe gbóná tó.
Bákan náà ni ìròyìn fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ènìyàn kan ti pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lórí ooru àpọ̀jù náà.
Àjọ tó ń mójútó ojú ọjọ́ ní orílẹ̀ èdè náà ní ìlú mẹ́wàá ni ó ṣeéṣe kó gbóná to bẹ́ẹ̀.
A ṣetán láti pe àwọn aṣòfin lẹ́jọ́ lórí ₦40b tí wọ́n fẹ́ fi ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ fún ara wọn – SERAP
Ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, SERAP ti rọ Aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria, Godswill Akpabio ati Tajudeen Abbas, to jẹ Aarẹ ile igbimọ aṣojuṣofin lati maṣe na owo ti iye rẹ to aadọrin biliọnu naira lori ọkọ ayọkẹle to ni ayẹta.
SERAP rọ awọn aṣofin naa ki wọn din iye owo ti wọn ya sọtọ lati fun awọn aṣofin ku latari bi nnkan ṣe wọn wọn gogo laarin ilu, ti ọpọ araalu ko si rọwọ họri.
Ajọ ọhun tun ke si awọn aṣofin lati bẹ Aarẹ Bola Tinubu ko pese afikun eto iṣuna ti yoo gbọ bukata nnkan bii ogun miliọnu ọmọ wẹwẹ ti ko lanfaani ati lọ sile ẹkọ ni Naijiria.
Iroyin ni ko din ni aadọrin biliọnu naira ti ijọba ti ya sọtọ fun awọn aṣofin ọhun ti apapọ wọn ko to irinwo, nigba to ya ẹẹdẹgbẹta biliọnu naira fun miliọnu mejila ọmọ Naijiria ti iṣẹ n ba finra.
SERAP sọ pe ko bojumu bi awọn aṣofin naa ṣe dede n ya owo gọbọi sọtọ fun ara wọn nigba ti ọpọ araalu n jiya lati ọwọngogo epo.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, nnkan bii ogoji biliọnu naira lawọn aṣofin naa ti ya sọtọ fun ọkọ ayọkẹlẹ to ni ayẹta fun ara wọn.
Lẹyin naa ni SERAP fun awọn aṣofin naa lọjọ meje pere lati ṣe atunṣe, bi bẹẹ kọ, oun yoo gbe awọn aṣofin naa lọ sile ẹjọ.
Ṣé lóòótọ́ ni pé àrá sán pa àwọn ajínigbé ní Kwara? Àbọ̀ ìwádìí rèé
Tinubu pàrọwà sáwọn olórí ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti bọ̀wọ̀ fófin ìjọba àwaarawa
Ààrẹ Nàìjíríà, Bola Ahmed Tinubu ti rọ àwọn olórí orílẹ̀ èdè ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti máa bọ̀wọ̀ fún òfin ìjọba àwaarawa.
Tinubu pàrọwà yìí níbi ìpàdé àwọn àjọ ìṣọ̀kan ilẹ̀ Adúláwọ̀ èyí tó ń wáyé ní ìlú Nairobi, olú ìlú orílẹ̀ èdè Kenya.
Ààrẹ Tinubu ní ó pọn dandan fún àwọn adarí ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti máa ri dájú òfin tó de ìjọba àwaarawa fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.
Ó ní gbogbo ìgbésẹ̀ ìdìtẹ̀gbàjọba káàkiri tó ń wáyé lẹ́kùn ilẹ̀ Adúláwọ̀ gbọ́dọ̀ wá sópin pàápàá lásìkò yìí tí àìsí ètò ààbò, àyípadà ojú ọjọ́ àtàwọn àìsàn kan ń bá ẹkùn Adúláwọ̀ fínra.
Ó fi kun pé ó jẹ́ ohun ìbànújẹ́ pé ẹkùn ìwọ̀ oorun ilẹ̀ Adúláwọ̀ tí ìṣèjọba rere àti ìjọba àwaarawa ti tún ń rẹ́sẹ̀ walẹ̀ náà ni àwọn kan ti ń ti ìwé òfin sí ẹ̀gbẹ́ kan láti fi dá ètò ìṣèjọba rú.
Bákan náà ló ṣe ìkìlọ̀ lórí gbígba ìjọba mọ́ àwọn alágbádá lọ́wọ́ látọwọ́ àwọn ológun, ìgbésẹ̀ tó ní ó ń fa ìfàsẹ́yìn lórí ètò ààbò, fa iṣẹ́ àti òṣì fáwọn èèyàn ilẹ̀ Adúláwọ̀.
"Láàárín ọdún 2020 sí àsìkò yìí, ìdìtẹ̀gbàjọba kan ti wáyé, tí àwọn mẹ́ta mìíràn sì gbìyànjú láti gbàjọba ní orílẹ̀ èdè mẹ́ta mìíràn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àmọ́ tí kò bọ́ sì."
"Àwọn nǹkan yìí ń kó ìpalára bá ètò ìjọba àwaarawa lẹ́kùn Adúláwọ̀."
"Nítorí náà, mò ń fi àsìkò yìí bẹ àwọn olórí ilẹ̀ Adúláwọ̀ láti ṣe ohun gbogbo tó wà ní ìkáwọ́ wọn láti bọ̀wọ̀ fún ètò ìṣèjọba àwaarawa, kí wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún òfin lójúnà àti lè ri pé ètò òṣèlú tó rẹ́sẹ̀ walẹ̀ wà ní ẹkùn Adúláwọ̀," Tinubu sọ.
Ìjàm̀bá ọkọ̀ gbẹ̀mí obìnrin tó ń tajà lójú pópó ní Eko
Ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹẹ̀dógún oṣù Keje ni obìnrin kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé lórí afárá bírìjì Otedola ìpínlẹ̀ Eko.
Akọ̀wé àgbà àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, Dókítà Olufemi Oke-Osanyintoluló fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ nínú àtẹ̀jáde kan.
Oke-Osanyintolu ṣàlàyé pé ìjàm̀bá ọkọ̀ náà wáyé nígbà tí ọkọ̀ ńlá pàdánù ìjánu ọkọ̀ rẹ̀ tó sì lọ kọlu àwọn ọkọ̀ mẹ́ta mìíràn.
Ó ní nígbà tí àwọn fi máa débi ìṣẹ̀lẹ̀ náà, àwọn ri pé ọkọ̀ ńlá náà nígbà tó pàdánù ìjánu rẹ̀ tán kọlu obìnrin kan, lára àwọn tó máa ń ta ọjà ní ẹsẹ̀ títì, tí obìnrin náà sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀.
"Ìwádìí wa fi hàn pé ọkọ̀ ńlá tó gbé epo dísù lítà ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́ta pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì lọ kọlu àwọn ọkọ̀ mẹ́ta."
"Àwọn ọkọ̀ tí ọkọ̀ ńlá náà kọlu ni Suzuki pẹ̀lú nọ́mbà ìdánimọ̀ EPE_303HR, Toyota Camry pẹ̀lú nọ́mbà ìdánimọ̀ MUS242HM àti Avalon pẹ̀lú nọ́mbà ìdánimọ̀ AYE 453SF."
Oke-Osanyintolu fi kun pé àjọ àwọn pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá, àjọ FRSC, LASTMA, RRS àti LASAMBUS ni àwọn jọ ṣiṣẹ́ níbi tí ìjàm̀bá náà tí wáyé.
Ọ̀gá LASEMA náà ní iṣẹ́ ń lọ láti ri pé wọ́n kó àwọn ọkọ̀ tó ní ìjàm̀bá ọ̀hún kúrò lójú pópó.
Nígbà wò ni ààrẹ Tinubu yóò kéde àwọn dúkìá rẹ̀? Aráàlú ń bèèrè
Bàalẹ̀ abúlé méjì dèrò ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn títa ilẹ̀ ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun
Ile ẹjọ́ Majisireti kan niluu Abeokuta ti ju baalẹ meji ati eeyan mẹrin mii si ẹ̀wọ̀n fun ẹ̀sùn pe wọn gba ilẹ̀ to jẹ ti Iléèṣẹ́ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ ijọba ipinlẹ Ogun.
Ilẹ naa ni ìwé ìròyìn Punch jábọ̀ pé o le ni eékà mẹrinlelogun, ni abule Olorunsogo, ìjọba ibilẹ Obafemi Owode, niluu Abeokuta.
Adajọ Majisireti naa, Morenikeji Osibajo lo ju Baalẹ abule Agejo ati Ake, Olalekan Odemuyiwa ati Segun Konigbagbe, si ẹ̀wọ̀n.
Ọlọpaa to ko wọn lọ sile ẹjọ́, Adekanmi Adeusi, sọ pe awọn Baalẹ naa ta diẹ ilẹ̀ ọ̀hún, wọn si tun kọ́ ile sori eyi to kù.
Igbesẹ naa lo mú ki àwọn alákòóso ileeṣẹ agbóhùnsáfẹ́fẹ́ OGBC gbe wọn lọ sílé ẹjọ́.
Onidajọ Osibajo ti sun ẹjọ́ si ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Kẹjọ.
Àwọn ọmọ Nàìjíría ń kọminú lórí 70 bilìọ̀nù táwọn aṣòfin àpapọ̀ yà sọ́tọ̀ fún ara wọn
Bàlúù ọmọogun Nàìjíríà tó já ní Benue, ohun tí a mọ̀ rèé