You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Emefiele tún fi ẹ̀yìn DSS janlẹ̀, iléẹjọ́ míràn ní kí wọ́n tú u sílẹ̀

  2. Wọ́n rán wa láti ṣekúpa Apostle Suleman - Afurasí

  3. Wo oríṣiríṣi nǹkan tí àwọn ọmọ Nàìjíríà ń ṣe tí wọ́n ló fẹ́ fa ìwé GWR ya

  4. Pásítọ̀ fọ́ ṣọ́ọ̀bù kẹ́míkà torí N150,000 tí yóò fí sìnkú ìyá rẹ

    Ile ẹjọ majistereeti ni Akure ti dajọ ẹwọn ọdun meji fun Pasitọ kan Friday Okeneji lori ẹsun pe o fọ ṣọọbu onikẹmika kan to si ji kẹmika ti iye owo rẹ to ẹgbẹrun lọna aadoje Naira.

    Adajọ Damilọla Sekoni sọ pe ẹsun onigun meji lawọn fi gbe idajọ kalẹ lori Okeneji tori naa yoo ṣe ẹwọn naa lasiko kanna ni pẹlu anfaani sisan owo itanran ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira.

    Sekoni to rọ ọdaran naa lati yi iwa rẹ pada parọwa si lati maa hu iwa ni ibamu pẹlu ilana ẹsin Kristẹni gẹgẹ bi iwe mimọ ti ṣe sọ.

    Saaju ni ọdaran naa ti sọ pe oun jẹbi ẹsun naa ṣugbọn ọna ijẹ ati mu lo sun oun de ibi ole jija.

    O ṣalaye pe atijẹ ṣoro ati pe oun ni lati wa ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira ti oun yoo fi sinku iya rẹ loṣu Kẹjọ ọdun yi.

    Okeneji jẹ pasitọ ijọ Christ Apostolic Church( CAC),Ona Iwa-Mimo, Iwaro Oka Akoko nipinlẹ Ondo.

    Ọjọ Keji oṣu Keje ni o lọ huwa ọdaran yi ni Iwaro Oka Akoko.

  5. Aráàlú tẹ́wọ́ gba òfin tó fi àyè gba ọ̀gbìn igbó ní Ghana

    Òfin tuntun ti ile igbimọ aṣòfin orile-ede Ghana ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe, lati faaye gba ọ̀gbìn igbó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fun ìṣègùn òyìnbó, ti di ìtẹ́wọ́gbà.

    Sugbọn o, o ṣi lodi si ofin lati ma a lo igbó fun faaji.

    Ṣaaju ni ile ẹjọ́ to ga jùlọ kọ àtúnṣe si ofin ti àjọ to n mojuto lilo egbògi, 'nitori pe àwọn aṣòfin ko jiroro daada lori rẹ'.

    Idajọ naa bi agbẹjọ́rò agba ati olori ile aṣòfin ninu - sugbọn erongba wọn pada di òfin lẹ́yìn ijiroro àwọn aṣòfin ní Ọjọ́rú.

    Àwọn èèyàn ti BBC ba sọrọ niluu Accra sọ pe, igbesẹ to dùn mọ wọn nínú ní, níwọ̀n ìgbà tí ìjọba ba n mojuto awọn to n gbìn ín bí ó ṣe yẹ

    Àwọn kan ni ọ̀gbìn igbó nilo amojuto pupọ, paapaa nitori àwọn ọ̀dọ́ to n mu ú - ati igbagbọ pe o wa lara awọn nnkan to mu ki iwa ọ̀daràn pọ̀.

  6. Ààrẹ Tinubu kéde ìlú ò fararọ ní ẹ̀ka ìpèsè oúnjẹ

    Aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu ti kede nnkan o fararọ lori ipese oúnjẹ ni orile-ede naa.

    Agbẹnusọ rẹ̀, Dele Alake, lo kede eyi fun awọn akọroyin nile ijoba nílùú Abuja.

    Ọgbẹni Alake sọ pe ààrẹ ti pàṣẹ pe ki gbogbo ọ̀rọ̀ ati ìgbésẹ̀ to ni ṣe pẹlu ipese oúnjẹ ati omi, gẹgẹ bi nnkan ti ko ṣe é má nìí, wa ni abẹ ìṣàkóso igbimọ eto aabo gbogbogboo.

    Alake sọ pe igbesẹ naa jẹ ara ìpinnu ijọba Tinubu lati pese iranlọwọ fun awọn alailagbara niluu.

    O ni bi owo oúnjẹ ṣe n wọ́n si, ati ipa to n ní lara awọn tálákà ni orile-ede Naijiria, jẹ́ nǹkan to n ba ààrẹ lọkan jẹ.

    Dele Alake tun sọ pe aarẹ ti pàṣẹ pé kí wọ́n fun awọn àgbẹ̀ ni ajílẹ̀ ati èso irugbin, lati din ìrora subsidy eporọ̀bì ti wọn yọ kù.

    O fi kún un pé àwọn alákòóso eto ọ̀gbìn ati omi mímu gbọdọ ṣiṣẹ́ papọ lati ri pe ipese oúnjẹ tó tó n wa ni gbogbo ìgbà tó wà nínú ọdún.

  7. Gbajúmọ̀ akọrin, Portable ko ìjàmbá ọkọ́, wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí G-Wagon rẹ̀

  8. Ta ló lẹ́tọ̀ọ́ gan láti di Mínísítà tí Tinubu fẹ́ yàn?

  9. Bí àwọn ọmọ 50 ṣe di èrò iléèwòsàn ní Kenya lẹ́yìn tí ìfèhónúhàn bẹ́ sílẹ̀

    O kere tan wọn ti gbe awọn ọmọde to le ni aadọta digba digba lọ si lẹyin ti ọlọpaa yin tajutaju si kilaasi wọn lasiko ifẹhọnuhan

    Dokita Aron Shikuku lati ilewosan Eagle Nursing Hospita ni wọn ti fi awọn naa silẹ lati lọ si le wọn lẹyin ti wọn gba itọju tan.

    Dokita naa ni awọn ọmọ naa ni ijaya, ti wọn ko lee mi daradara lasiko ti iṣẹlẹ naa waye, amọ ti wọn si ti gba iṭju.

    Awọn afẹhọnu naa ti ẹgbẹ alatako pe ni wọn fi ẹhọnu han tako bi ọwọngogo se gbode lorilẹede naa.

    Amọ ifẹhọnuhan naa lo da nkan mii, ti o kere tan eniyan mẹfa si gbẹmi mi.

    Amọ awọn ajo ajafẹtọ ni o kere tan eniyan mejila lo gbẹmimi, ti ọpọlọpọ si farapa.

    Awọn meji ku lẹyin ti wọn dana sun agọ ọlọpaa, ti wọn si tun pa ẹlomiran lasiko ti wọn seọlu si ọkọ awọn ọlọpaa ni opopona Nairobi.

    Ni idahun wọn, ileesẹ ọlọpaa ni awọn yoo sa ipa wọn lati ri pe opin de ba rogbodiyan ati ipaniyan ti ifẹhọnuhan naa da silẹ.

    Ifẹhọnuhan to waye laipẹ yii ko sẹyin bi awọn ololufẹ ijoba to wa lode ati awọn alatako wọn se ifẹhonuhan tako ara wọn, ti ọpọ ẹmi si lọ si iṣẹlẹ naa.

    Amọ ajọ ajafẹtọ ọmọniyan ni ileesẹ ọlọpaa lo ipa lọpọlọpọ lasiko ifẹhọnuhan naa.

    Eleyii ti mu ki awọn ara ilẹ Kenya pin laarin ara wọn ti awọn kan si faramọ igbesẹ ijọba, nigba ti awọn miran ni ọwọngogo ti poju, ki ijọba wa nkan se si.

  10. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọdé di èrò iléèwòsàn lẹ́yìn tí ọlọ́pàá yín 'teargas' lú àwọn olùwọ́de ní Nairobi

    Ko din ni ọmọdé mẹtalelaadọta ti wọn sáré gbe lọ si ileewosan ni olu ilu Kenya, Nairobi, lẹyin ti wọn dákú rangbandan nigba ti awọn ọlọpaa ju afẹ́fẹ́ tajú-tajú sinu yàrá ikẹkọọ wọn lasiko ìwọ́de.

    Dokita Aron Shikuku to ni ileewosan Eagle Nursing Home, sọ fun BBC pe àwọn jí àwọn ọmọ naa pada saye nigba ti yoo fi to wakati mẹrin ti wọn ti wa ni iléèwòsàn.

    Lati bi ọjọ díẹ̀ ni iwọde ti n waye jakejado Kenya, eyi ti ẹgbẹ alatako pè nitori ọ̀wọ́n gógó nnkan.

    Eeyan meji ni iroyin sọ pe ó kú lasiko ti awọn olùwọ́de yabo àgọ̀ ọlọpaa kan, ti wọn si dáná sun-ún.

    Ọkùnrin kan tun kú nigba ti awọn olùwọ́de kọlu ọkọ̀ ọlọpaa ni òpópónà Mlolongo niluu Nairobi.

    Eto kátàkárà ati irinna ti dẹnu kọlẹ ni orile-ede naa nitori ìwọ́de.

    Ojoojumọ si ni awọn olùwọ́de n dáná si ojupopo, ti awọn awakọ̀ paapaa si sọ awọn ibùdókọ̀ di pápá bọ́ọ̀lù gbígba ati awọn ère idaraya mii.

  11. Naijiria san 500m Dola lára gbèsè Eurobond

    Orilẹ-ede Naijiria ti san ẹẹdẹgbẹta miliọnu Dola gbese Eurobond to jẹ.

    Ọjọ́rú, ọjọ kejila, oṣu Keje, ni wọ́n san gbese naa.

    Ninu oṣu Keje, ọdún 2013 ni Naijiria yá owo naa gẹgẹ bi ara biliọnu kan Dola to ya fun ọdun mẹwaa pẹlu èlé 6.375% lọdọọdun.

    Ṣaaju ni Naijiria ti kọkọ san ẹwà ẹẹdẹgbẹta miliọnu Dola gbese Eurobond ninu ọdun 2018, to si tun san iye kan naa ninu oṣu Kinni ọdun 2021, ati gbese ọọdunrun miliọnu Dola mii ninu oṣu Kẹfa, ọdun 2022.

    Igbimọ to n ṣe akoso awọn gbese ti Naijiria jẹ sọ ninu a hutẹjade kan pe gbese ti Naijiria ṣẹ̀ṣẹ̀ san yii ti mu ki àpapọ̀ iye to san jẹ 1.8b Dola, ni ọjà ayanilowo ni agbaye.

    Igbimọ naa sọ pe bi Naijiria ṣe san awọn gbese rẹ lati bi ọdun mẹfa fi han pe ni eto to dara nilẹ fun sísan awọn owo to n yá.

    Oṣù Kọkànlá, ọdun 2025 ni Naijiria yoo tun san gbese Eurobond mii, gẹgẹ bi akọsilẹ lori ileeṣẹ iroyin Nairametrics

  12. Èdè Yorùbá ni Àbọrú Àbọyè, kò ní nǹkan ṣe pẹ̀lú Ifá, Òrìṣà - Tope Alabi fọhùn lórí àwọn tó ń ta kò ó

  13. Adarí oŕilẹ̀èdè Iran bẹ̀rẹ̀ àbẹ̀wò sí ilẹ̀ Afrika

    Aarẹ orilẹede Iran, Ebrahim Raisi ti wa ni orilẹede Kenya lati bẹrẹ abẹwo ọlọjọ mẹta si ilẹ Afrika.

    Igba akọkọ ni yii ti aarẹ orilẹede Iran yoo sabẹwo si ilẹ Afrika lati bii ọdun mẹwaa.

    Bakan naa ni aarẹ Raisi yoo maa sabẹwo si orilẹede Uganda ati Zimbabwe.

    Awọn ti yoo maa tẹle aarẹ naa ni awọn olori ni ẹka idokowo, to fi mọ awọn onimọ nipa ibaṣepọ laarin orilẹede.

    Ohun pataki ti yoo waye lasiko ibẹwo naa ni pe, Iran yoo maa wa ọna lati sisẹpọ pẹlu ilẹ Afrika nipa eto idokowo, ati ajọsepọ to dan mọran laarin ilẹ Iran ati ilẹ Afrika.

    Laipẹ yii naa ni adari Iran, Raisi sabẹwo si ilẹ Latin Amerika ati Indonesia, nibi ti Iran ti pada lati darapọ mọ ajọ Shanghai Cooperation Organisation ti wọn wa tẹlẹ.

  14. Olè jí àwọn iná ibi tí bàálù n balẹ̀ sí ní pápákọ̀ òfurufú Eko

    Awọn olè ti ji awọn iná ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà to wa ni papakọ ọkọ̀ ofurufu Murtala Mihammed nílùú Eko.

    Eyi waye lẹyin oṣu díẹ̀ ti wọn ṣe awọn iná naa síbẹ̀.

    Àwọn aláṣẹ ni papakọ naa fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yii múlẹ̀ fun BBC.

    Àwọn ina ti wọn ji lo ma n ran awọn awakọ̀ ọkọ ofurufu lọwọ lati gbe bàálù fò tabi balẹ̀ ni alẹ́, òru tabi ti kurukuru ba wà.

    Ko si ẹni to mọ pàtó igba ti wọn ji awọn ina naa.

    Sugbọn awọn alaṣẹ sọ pe iwadii ti bẹ̀rẹ̀ lati mu awọn to ji wọn.

    Oṣù Kọkanla, ọdún to kọja ni wọn fi awọn iná ọ̀hún síbẹ̀ nitori pe àìsì wọn n ṣe ipalara fun igbokegbodo ọkọ ofurufu.

  15. Ààrẹ Tinubu ba ọkàn jẹ́ lórí ìkọlu tó pa ọmọ oṣù mẹ́jọ ní Plateau

    Aarẹ Bola Tinubu ti fi ẹdun ọkan rẹ han si rògbòdìyàn to waye láìpẹ́ yii nipinlẹ Plateau.

    Ninu atẹjade kan ti oluranlọwọ rẹ, Dele Alake, fi sita ni aarẹ ti bu ẹnu ẹ̀tẹ́ lu rògbòdìyàn naa, eyi to yọri si iku àwọn eeyan kan ni ìjọba ibilẹ Mangu.

    O ni "sùúrù ati ìdáríjì ṣe kókó ti a ba fẹ ni awujọ to dara."

    O ni o jẹ nnkan buruku pe, ọmọ kekere, ọmọ oṣu mẹjọ padanu ẹ̀mí rẹ nitori ede aiyede ti ko mọ nípa rẹ ni abule Farin Lamba, nípìnlẹ̀ Plateau.

    O ti wa kesi awọn olori agbegbe naa ati awọn olori ẹgbẹ́ Jama'atu Nasril Islam àti ẹgbẹ́ Kristẹni, CAN, lati fọwọsowọpọ wa ọna àbáyọ si ọrọ naa.

    Bakan naa ni Aarẹ Tinubu tun pàṣẹ fun awọn ileeṣẹ alaabo, lati ṣe awari gbogbo awọn to lọwọ ninu ipaniyan naa, ki wọn le jiya labẹ ofin.

    O tun rọ ijọba ipinlẹ Plateau lati pèsè iranlọwọ ni kiakia fun awọn ti ìṣẹ̀lẹ̀ naa kàn.

    Ọjọ Aiku ni ìkọlu waye ni awọn abule kan nijọba ibilẹ Mangu, eyi to mú ki ìjọba ipinlẹ Plateau kede isede ni agbègbè naa.

  16. Àjọ NATO kùnà láti sọ pàtó àkókò tí Ukraine yóò darapọ̀

  17. Àarẹ Tinubu fi orúkọ àwọn adarí ológun ṣọwọ́ sí àwọn aṣòfin àpapọ̀

    Aarẹ Tinubu ti fi orukọ awọn adari ẹka ologun ati ileeṣẹ alaabo gbogbo to yan laipẹ yii ṣọwọ si ile igbimọ aṣofin apapọ Naijiria fun ibuwọlu.

    Aarẹ ile aṣofin agba, Godswill Akpabio to ka lẹta naa si eti awọn senetọ to wa nijoko ile lọjọ Iṣẹgun ni gbogbo awọn aṣofin ni yoo joko ṣe ayẹwo fun awọn oga ileeṣẹ ologun ati alaabo gbogbo naa.

    Amọṣa, Sẹnetọ Akpabio ko sọ ọjọ ti ayẹwo naa yoo waye. Aarẹ Timubu ti fi irufẹ lẹta yii kan naa ṣọwọ si ile igbimọ aṣojuṣofin lọṣẹ to kọja.

    Olori ile aṣofin naa, Họnọrebu Abass Tajudeen pẹlu ko sọ ọjọ ti ayẹwo ọhun yoo waye.

    Ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹfa ni wọn kede orukọ awọn olori ileeṣẹ ọmọogun ati alaabo naa.

  18. Wo orúkọ àwọn olùrànlọ́wọ́ 20 tí Tinubu yan láti bá a ṣiṣẹ́ pọ̀

  19. Ìjọ̀ba ipinlẹ Plateau ní òun kò tíì le sọ iye èèyàn tó kú nínú ìkọlu ọ̀tun tó wáyé

    Inu ibẹru ni awọn olugbe ijọba ibilẹ Mangu, nípìnlẹ̀ Plateau ṣi wa, lẹyin ipaniyan to waye.

    Òrumọ́jú ọjọ Aiku, ọjọ kẹsàn-án, oṣu Keje, ni ìkọlu tuntun naa waye.

    Awọn olugbe agbegbe naa sọ pe abule meji ni awọn agbébọn kọlu, nibi ti wọn ti pa àwọn eeyan, wọn si tun dáná sun ọpọlọpọ ile.

    Iṣẹlẹ naa mu ki ijọba kede isede, fun igba keji laarin oṣù mẹta.

    Ọjọ ti pẹ́ ti ija ẹsin ati ẹlẹyamẹya ti n waye nipinlẹ Plateau.

    Ninu oṣu Karun-un, iroyin sọ pe wahala waye nijọba ibilẹ Mangu, eyi to yọri si iku ọpọ eeyan.

    Ninu ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹlu BBC, agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Plateau, GÒrumọ́jú ọjọ Aiku, ọjọ kẹsàn-án, oṣu Keje, ni ìkọlu tuntun naa waye.

    Bere, sọ pe ijọba ko tii ri akọsilẹ iye eeyan to ku ninu wahala to tun ṣẹ̀ṣẹ̀ waye.

    O ni nnkan ti oun mọ ni pe inu rogbodiyan nla ni awọn eeyan ijọba ibilẹ Mangu wà.

    Saaju ni awọn olori ẹ̀yà Fulani sọ pe oku eeyan mẹẹdogun ti wọn pa ni awọn kà, ati ile mejidinlọgọrin.

    Sugbọn Ọgbẹni Bere sọ pe ijọba ko tii ni aridaju pe iye ti awọn olori naa kede niye eeyan to kú.

    O ni oun ko le sọ boya òtítọ́ tabi irọ́ ni nkan ti awọn olori Fulani sọ, nitori pe awọn ko ri idi iroyin naa fi múlẹ̀, ṣùgbọ́n 'a mọ pe lootọ ni ipaniyan waye ni Mangu.

    Bakan naa lo sọ pe ijọba ti ko awọn oṣiṣẹ alaabo lọ si agbegbe naa lati mu ki alaafia jọba.

    O fikun ọrọ rẹ pe "a n bẹ awọn eniyan agbegbe naa lati gba alaafia laaye."

    Bakan naa ni awọn alakoso eto NYSC ti kede pe awọn ti gbe eto ifiniwọ àwọn àgùnbánirọ̀ kuro ni ijọba ibilẹ Mangu, lọ si Jos South, nitori wahala naa.

    Àjọ NYSC kede igbesẹ naa ninu atẹjade kan loju opo Facebook rẹ.

  20. Ààrẹ Amerika Joe Biden ti sèpàdé pẹ̀lú Olóòtú Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti Ọba Charles III

    Aarẹ orilẹede Amerika, Joe Biden ti sepade pẹlu Olootu Ilẹ Gẹẹsi, Rishi Sunak lasiko to se abẹwo ranpẹ si Ilẹ Gẹẹsi.

    Aarẹ Biden ti wọn ti pari ipade naa to waye ni Downing Street ni wọn fi wa papọ fun ogoji iṣẹju.

    Lara awọn ohun ti iroyin gbe pe wọn yoo jiroro le lori niogun to n lọ lọwọ ni Ukraine, ti ilẹ Amerika si kede pe awọn yoo fi ado oloro, cluster bombs fi ranṣẹ si Ukraine lọna ati seranwọ fun wọn ninu ogun naa pẹlu Russia.

    Biden ọun lo ti pada sinu ọkọ aarẹ to wọ wa pẹlu awọn ẹṣọ alaabo to tẹlẹ.

    Lẹyin naa ni yoo lọ si aafin ọba ni Windsor lati sepade pẹlu Ọba Ilẹ Gẹẹsi, Charles III.

    Biden ni yoo tẹ ọkọ leti lati ibẹ lọ si Lithuania fun ipade Ajọ eleto aabo NATO, ti yoo bẹrẹ nibẹ ni ọla.

    Osu to kọja ni Sunak se abẹwọ si Ilẹ Amẹika nibi ti orilẹede mejeeji ti kede lati sisẹ pọ lori ọrọ aje ti wọn pe ni Atlantic Declaration.

    Bakan naa ni aarẹ Biden wani ibi isinku Ọbabinrin Elizabeth ni Ilu London ni ọdun to kọja, to si tun sabẹwo si Northern Ireland atiRepublic of Ireland in Osu Kẹrin, ọdun 2023.

    Amọ Biden ko yoju sibi ayẹyẹ ti wọn ti fi Ọba Charles jẹ, amọ iyawo rẹ, Lady Jill Biden ati ọmọ-ọmọ rẹ wa nibi aseyẹ naa.