You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kò sí ohun tó burú kí èèyàn máa ta àkàrà, àgbado sísun tàbí kúlíkúlí – Agbẹnusọ Ààrẹ
Minisita fun ọrọ awọn ọdọ nigba kan ri ni Naijiria to tun jẹ agbẹnusọ Aarẹ Bola Tinubu, Sunday Dare ti ṣegbe lẹyin ọrọ iyawo Aarẹ lori ṣiṣẹ awọn owo kekeke.
Ṣaaju ni iyawo Aarẹ, Oluremi Tinubu ti kọkọ sọ pe awọn owo kekeke bii akara tita, kulikuli ati agbado sisun tita ko buru lati ṣe latari pe iye owo ti wọn yoo fi bẹrẹ irufẹ owo bẹẹ ko ni pọ ju.
Remi Tinubu ni "A n gbiyanju lati fun awọn eeyan ni ireti ọtun ati lati bẹrẹ owo bii kara tita ti ko ni nilo owo gọbọi lati bẹrẹ.
"Lati bẹrẹ si n ta agbado sisun, tabi, ẹnikan tilẹ sọ pe eeyan ko nilo owo gọbọi lati bẹrẹ si n ta kulikuli. A ko ya wọn lowo, niṣe ni a n fun wọn lati bẹrẹ owo."
Lẹyin ti aya Aarẹ sọrọ yii, ọpọ araalu lo koro si lori ayelujara ti wọn si n sọ pe oun ati ọkọ rẹ ko ni eto rere fun ọmọ Naijiria.
Mo ti kiri ọgẹdẹ ri nigba ti no wa ni kekere – Sunday Dare
Wayi o, lasiko to n sọrọ lori eto 'Mic On Podcast' pẹlu Seun Okinbaloye, Sunday Dare sọ pe awọn oniṣowo kekeke lo gbe opo ọrọ aje Naijiria ro.
Dare ni "Gbogbo ibi ni wọn wa, koda, wọn wa ni iha ariwa pẹlu."
Olubadamọran Aarẹ lori ọrọ to n lọ naa ṣalaye pe niṣe lo yẹ ki awọn ọmọ Naijria mu koko ọrọ iyawo Aarẹ lo kaka ki wọn maa bu nitori oun funra oun gan ti kiri ọja lasiko toun n dagba.
O ni "Ko yẹ ki ẹ padanu koko inu ọrọ to sọ, eyii ni pe; ohunkohun ti ọwọ yin ba ri lati ṣe, ki ẹ ṣe."
"Wo mi daadaa, ko ni nnkan lati ṣe ibi ti mo de lonii, iya mi ti ta akara ri… iya mi ti ta ọgẹdẹ ri.
"Mo gbe ọgẹdẹ lori ti mo si n kiri ninu ọja niluu Jos, ipinlẹ Plateau.
"Iya mi ta ọsan, ninu rẹ ni wọn si ti ran mi nile ẹkọ.
"Ti awọn eeyan ba le ṣe irufẹ owo bẹẹ lọgọta ọdun sẹyin, ki lo buru ti wọn ba ṣe iru owo kan naa lode oni?"
Sunday Dare ni Dangote to jẹ olowo lonii ko ṣadede di olowo amọ oun naa ṣowo, bẹẹ lo ta ọja ko to di ẹni nla.