Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa ikọ̀ ọlọ́pàá kògbérèégbè 'Operation Kosaye' tó gbérasọ ní ìpínlẹ̀ Eko àti Ogun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ati ti ipinlẹ Ogun ti ṣe ifilọlẹ ikọ ọlọpaa koregbereegbe ti wọn pe orukọ rẹ ni ''Operation Kosaye.''

Ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria ṣe ifilọlẹ ikọ naa lati koju awọn ajinigbe, awọn agbebọn atawọn ọdaran to n ṣọṣẹ ninu igbo to wa ni ipinlẹ mejeeji.

Ifilọlẹ ikọ Operation Kosaye eyi ti Ọga ọlọpaa Naijiria, Tunji Disu, pilẹ rẹ waye nile ẹkọ awọn ọlọpaa to wa ni Iperu nipinlẹ Ogun.

Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Ogun, CP Lanre Ogunlowo Ojajuni ati akẹgbẹ rẹ lati ipinlẹ Eko, CP Fatai Tijani bawọn akọroyin sọrọ nibi ifilọlẹ ikọ naa.

CP Ojajuni ṣalaye nibi eto naa wi pe iṣẹ ti ikọ ọlọpaa naa ti ṣe ṣaaju ifilọlẹ rẹ ti n so eso rere.

Ọga ọlọpaa Ogun sọ pe awọn ọlọpaa ikọ Operation Kosaye ti bẹ sinu igbo lopopona ilu Eko si Sagamu lọ si Ijebu-Ode to fi de Ajebandele ti i ṣe ibode laarin ipinlẹ Eko ati ipinlẹ Ogun.

Ọgbẹni Ojajuni fikun ọrọ rẹ pe ikọ Operation Kosaye ṣekupa afurasi ajinigbe mẹrin, nigba ti wọn fọwọ ofin mu mẹrin mii.

Ọga ọlọpaa naa tun sọ pe ọwọ ikọ naa tun doola eeyan marun un lọwọ ajinigbe ninu igbo Ogere lopopona Sagamu si Ijebu-Ode.

Gẹgẹ bi ọlọpaa ṣe ṣalaye, mẹta ninu awọn eeyan naa n rinrin ajo lọ si ilu Eko nigba ti awọn yooku n lọ si Ibadan ki wọn to bọ ṣọwọ awọn ajinigbe.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ajinigbe naa ṣina ibọn bolẹ sawọn ọkọ ero tawọn eeyan naa wa ninu rẹ ki wọn to gbe wọn wọ inu igbo lọ.

''Yatọ si awọn ajinigbe mẹrin ti ikọ Kosaye fọwọ ofin mu, wọn tun mu afurasi ọdaran mẹrinlelọgọrin mii''

CP Ojajuni ṣalaye siwaju si i pe ikọ Operation Kosaye yoo tun na ọwọja rẹ de ọna marosẹ Eko si Ibadan, opopona Epe si ilu Eko lọ si Ijebu-Ode ati opopona ilu Eko si Ikorodu.

Ọga ọlọpaa naa tun sọ pe yatọ si awọn ajinigbe mẹrin ti ikọ na fọwọ ofin mu, awọn ọlọpaa Kosaye tun ti fọwọ ofin mu afurasi ọdaran mẹrinlelọgọrin mii ti obinrin mẹsan an wa ninu wọn.

Oniruuru ẹsun bii idigunjale, ẹgbẹ okunkun to fi mọ ijinigbe lawọn ọlọpaa fi kawọn afurasi naa.

Ileeṣẹ ọlọpaa ni oriṣiiriṣii ohun ija oloro ni ikọ Operation Kosaye ri gba lọwọ awọn afurasi ọdaran naa.

Ẹwẹ, Gomina Babajide Sanwo-Olu ipinlẹ Eko ati Dapo Abiodun ipinlẹ Ogun ti gboṣuba rabandẹ fun ileeṣẹ ọlọpaa fun idasilẹ ikọ Operation Kosaye.

Sanwo-Olu ni lu awọn ọlọpaa lọgọ ẹnu fun bi wọn ṣe n gbogun tawọn ọdaran ni ipinlẹ Ogun ati ipinlẹ Eko.

Gomina ipinlẹ Eko sọ pe bi ifilọlẹ ikọ Kosaye ti bẹrẹ sii so eso rere fi han pe ifọwọsowọpọ awọn ipinlẹ to wa lẹgbẹẹ ara wọn ṣe pataki fun aṣeyọri ileeṣẹ ọlọpaa.

Sanwo-Olu ko ṣai dupẹ lọwọ Ọga ọlọpaa, Disu, lori bawọn ọlọpaa ti fọwọ ofin mu awọn afurasi ọdaranto n da ilu laamu.

O ṣeleri wi pe ijọba ipinlẹ mejeeji yoo tẹsiwaju lati maa ṣeranwọ fun ileeṣẹ ọlọpaa lati le ri pe aabo to fẹsẹ mulẹ wa.