You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àlàyé lórí báwọn ọ̀dọ́ kan ṣe fi ipá mú abílékọ jáde ní àhámọ́ ọlọ́pàá tí wọ́n sì dáná sun ún
Awọn ọdọ kan ti fi ibinu wọ abilekọ kan jade ni ahamọ ọlọpaa ti wọn si dana sun un.
Iṣẹlẹ ọhun ṣẹlẹ lẹyin ti iroyin kan gbalẹ kan wi pe abilekọ naa ji awọn ọmọde gbe ni agbegbe Maraban Jos ni ijọba ibilẹ Igabi nipinlẹ Kaduna.
Ibẹru-bojo gbalẹ lagbegbe naa tori awọn ara adugbo n kọminu lori iroyin ijinigbe awọn ọmọde ti wọn gbọ.
Iroyin sọ pe nibi ipejọpọ kan ti wọn ti n waasu ni obinrin ọhun wa tawọn ọdọ kan fi fẹsun kan an wi pe o fẹ ji ọmọ gbe.
Bayii lawọn kan sare gbe e lọ si agọ ọlọpaa to wa lagbegbe naa fun aabo ati ki wọn le ṣewadii rẹ.
Amọ, ọrọ bẹyin yọ nigba ti ọgọọrọ awọn ọdọ yabo agọ ọlọpaa naa ti wọn si sọ pe kawọn ọlọpaa jọwọ arabinrin ọhun fawọn.
Bayii ni wọn bẹrẹ sii lu obinrin naa ti wọn si tun dana sun un.
Ẹwẹ, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kaduna ti bẹnu ẹtẹ lu bi wọn ti ṣeku pa obinrin naa lọjọ kọkanlelogun oṣu Kẹfa yii lori ẹsun pe o ji ọmọ gbe.
A ti fọwọ ofin mawọn afurasi kan ti wọn lọwọ ninu isẹkupani naa - Ọlọpaa
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, DSP Mansir Hassan, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe awọn ọlọpaa gbiyanju lati daabo bo obinrin naa lo jẹ ki wọn fi si atimọle.
Ṣugbọn DSP Hassan ni ọrọ bẹyin yọ nigba ti ọgọọrọ awọn ọdọ fipa wọ atimọle ọlọpaa ti wọn si ṣeku abilekọ naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọmọbibi agbegbe Maraban Jos ni arabinrin naa.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣapejuwe iṣẹlẹ naa gẹgẹ bi iwa ọdaran eyi ti to buru jai ti o si lodi si ofin.
DSP Hassan ni ko si ẹni to ni ẹtọ lati gbẹmi ẹnikẹni tabi lati fọwọ pa ida ofin loju.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti fọwọ ofin mawọn afurasi kan ti wọn lọwọ ninu isẹkupani naa.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa tun ni awọn si n wa awọn eeyan mii ti wọn kopa ninu iṣẹlẹ naa.
DSP Hassan sọ pe gbogbo awọn to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa ni yoo foju wina ofin.
Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Kaduna, CP Rabiu Muhammad, ti wa kilọ wi pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni foju 're wo awọn to n ṣe idajọ ọwọ ara ẹni fawọn afurasi ọdaran tabi awọn to n ṣe ikọlu si agọ ọlọpaa.