Ọkọ̀ òfúrufú tó já lulẹ̀ ní France gbẹ̀mí èèyàn mọ́kànlá

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Eeyan mọkanla ti jada laye lẹyin ti ọkọ ofurufu ti wọn wa ninu rẹ ja lulẹ niluu Tomblaine, to wa ni ila oorun orilẹede France.

Awakọ ofurufu naa ati eeyan mẹwaa mii ni wọn padanu mii wọn ninu ijamba ọkọ ofurufu ọhun.

A gbọ pe awọn to maa n fo lati inu ọkọ ofurufu lati gbafẹ lawọn ero inu ọkọ naa.

Marun ninu wọn lo jẹ ogbontarigi ẹni to maa n fo lati inu baalu nigba ti awọn marun un to ku jẹ ẹni to ṣẹṣẹ n kọ bi wọn ṣe n se bẹẹ.

Papakọ ofurufu Nancy-Essey ni baalu naa ti gbera ko to danu.

Ọlọpaa ti rọ araalu ki wọn yago fun agbegbe ti ijamba ọkọ ofurufu naa ti waye.

Minisita eto Irina ni France, Philippe Tabarot ti juwe iṣẹlẹ naa gẹ bii iṣẹlẹ ibanujẹ fun orilẹede ọhun, o fi kun pe oun ati olootu ijọba, Laurent Nunez yoo ṣabẹwo si ojukọ ijamba naa laipẹ.

Ileeṣẹ iroyin AFP jabọ pe ko si araalu kankan to farapa lasiko ti baalu naa jabọ lulẹ.

Gẹgẹ bii AFP ṣe sọ, agbegbe ti ile gbigbe wa ni baalu naa ti jabọ, koda ile itaja igbalode kan wa lagbegbe ọhun pẹlu.

Nọọsi ni idaji awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ gẹgẹ bii aarẹ ẹgbẹ awọn nọọsi agbegbe naa ṣe sọ.

Awọn alaṣe ni awọn mọlẹbi awọn oloogbe ọhun wa layika lasiko ti baalu ọhun ja lulẹ.