Makinde ti gbalẹ̀ Òrìṣà, mo máa ṣiṣẹ́ tako Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo nínú ètò ìdìbò tó ń bọ̀ - Fayose

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ, Ayo Fayose, ti fariga wi pe oun yoo ṣiṣẹ tako Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde, ninu eto idibo to n bọ.

Fayose sọrọ yii ninu ifọrọwnilẹnuwo ti o ṣe pẹlu Seun Okinbaloye nileeṣẹ tẹlifisan Channels nibi to ti ṣapejuwe ibaṣepọ rẹ pẹlu Makinde gẹgẹ bii obinrin to n binu lẹyin ti wọn ja ọmọ rẹ gba lọ.

O ni oun yoo gbẹsan lara Makinde lori bo ti da ẹgbẹ oṣelu PDP ru lawọn ipinlẹ Yoruba.

"Makinde ba ilẹ jẹ gan an ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba, o ṣe ọpọ nnkan to tako ofin ati ilana ẹgbẹ"

O ni oun yoo gbẹsan lara Makinde lori bo ti da ẹgbẹ oṣelu PDP ru lawọn ipinlẹ Yoruba.

''Oloṣelu pọnbele ni mi, n ko le wa ọkọ baalu ṣugbọn mo lagbara lati gba ẹnikẹni ni imọran lori ọrọ oṣelu.

Mo maa ṣatilẹyin fun ẹnikẹni to ba fun mi ni ọwọ mi, bakan naa ẹnikẹni ti ko ba fi ọwọ mi wọ mi yoo ri idakeji Fayose.

Emi kii ṣe oloṣelu ti ẹnikan le fi ọwọ yẹpẹrẹ mu un, kete ti o ba ti ja ọmọ gba lọwọ abiamọ ni o ti di ọta iya ọmọ naa.

Lẹsẹkẹsẹ ni obinrin naa yoo di kiniun, koda, to ba jẹ aja; yoo di kiniun.

Mo di kiniun mọ Makinde lọwọ lẹyin to tasẹ agẹrẹ,'' Fayose ṣalaye.

Fayose wa ṣeleri wi pe oun atawọn alatilẹyin oun yoo ṣiṣẹ tako Makinde ninu eto idibo gbogbogbo to n bọ.

Makinde ba ilẹ jẹ gan an ninu ẹgbẹ oṣelu PDP nilẹ Yoruba, o ṣe ọpọ nnkan to tako ofin ati ilana ẹgbẹ.

''Ọmọde ni Makinde nigba ti mo fi n ṣiṣẹ rowo niluu Ibadan, o maa to ọdun mẹwaa ti mo fi ju u lọ lọjọ ori''

Fayose ni ojuṣe gbogbo oloṣelu ni lati bọwọ fun ara wọn.

''Gomina tẹlẹri ni mi, Makinde si jẹ gomina to wa lori oye, niṣe lo yẹ ko fi ọwọ mi wọ mi.

Fayose ni ina ti n jo ile Makinde bayii lagbo oṣelu.

Ọmọde ni Makinde nigba ti mo fi n ṣiṣẹ rowo niluu Ibadan, o maa to ọdun mẹwaa si mọkanla ti mo fi ju u lọ lọjọ ori.

Ibadan ni wọn bi mi si ni ile iwosan Oluyoro, agbegbe Isale Osi ni baba mi n gbe nigba naa.

Emi ati Olubadan to wa lori oye bayii ti jọ ṣiṣẹ pọ ri,'' Foyose lo sọ bẹẹ.

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ sọ pe Makinde ti wa ọta mọ ọta.

O ni Makinde ti gba ilẹ Oriṣa, awọn oriṣa si n binu; wọn fẹ gba ilẹ wọn pada lọwọ rẹ.

Gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ sọ pe erongba Makinde lati dupo aarẹ orilẹede Naijiria ni ibẹrẹ iṣoro rẹ lagbo oṣelu.

''Makinde lẹtọọ lati dupo aarẹ, amọ, ko yẹ ko dalẹ.

Gbogbo wa ni a jọ wa ninu ẹgbẹ gomina G5, amọ, Makinde ti gbalẹ Oriṣa.

Bi awọn ero ba n tẹlẹ eeyan ninu osẹlu ko tumọ si pe ẹni naa wọle ibo o.

Awọn eeyan mi fẹran mi, ṣugbọn oludije ti mo fa kalẹ ko wọle.

Tawọn eeyan ba n pa atẹwọ fun ọ, ko tumọ si pe wa a bori ninu eto idibo.

Fayose wa kasẹ ọrọ rẹ nlẹ pẹlu ọrọ to ti sọ tẹlẹ wi pe Makinde ti gbalẹ Oriṣa, awọn oriṣa yoo si gba ilẹ wọn pada.