Ọkùnrin kan rèé tó ti wà lórí ìdúró fún ọdún márùn-ún láì jòkòó tàbí dùbúlẹ̀

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Yoruba bọ, wọn ni ẹni to ba ni igbagbọ kii bẹru ọla.

Bẹẹ gan lọrọ ri fun olori ijọsin kan ti ko fẹ iyawo orilẹ ede India yii, Daulat Giri Ji Maharaj, ẹni to ti wa lori iduro fun ọdun marun-un bayii.

Daulat Giri Ji Maharaj jẹjẹẹ lati wa lori iduro fun ọdun mejila ni ibura lati fọ ọkan ati ara rẹ mọ fun igbagbọ rẹ lati sunmọ oriṣa Shiva.

Daulat Giri Ji Maharaj jẹ ọkan lara ọmọ ẹgbẹ Khareshwari, ẹgbẹ ti awọn eeyan maa n jẹjẹẹ lati wa lori iduro fun igba tabi akoko kan lojuna ati fọ ọkan wọn mọ lati ni ibaṣepọ ẹmi pẹlu Oriṣa Shiva.

Lati le mu ki ẹjẹ wọn wa si imuṣẹ, ọpọ wọn lo maa n gbe ara le okun atawọn nnkan mii lati le ri pe wọn wa lori iduro fun igba tabi akoko ti wọn ba da funra wọn lati wa bẹẹ.

Pẹlu bi ẹsẹ rẹ ṣe wu to, Daulat Giri Ji Maharaj ṣi n rin lati ibikan si omiran amọ bo ṣe n wa lori iduro soju kan fun igba pipẹ n ṣakoba fun ilera rẹ

Fun Daulat Giri Ji Maharaj, ọdun mejila lo jẹjẹẹ lati wa lori iduro da, to ti lo ọdun marun-un ninu ọdun mejila naa bayii.

Ori iduro lo ti n jẹun, sun, ṣe gbogbo nnkan to ba fẹ ṣe.

Ni ọsẹ to kọja ni awọn aworan ati fidio to ṣafihan Daulat Giri Ji Maharaj nibi to ti gbarale ori pako ti wọn fi okun so soke gba ori ayelujara.

Awọn aworan naa ṣafihan bi ẹsẹ rẹ mejeeji ṣe wu, to si tun dudu yatọ si awọn ẹya ara rẹ yooku.

Fidio naa tun ṣafihan bi eeyan kan ṣe n ba fi ororo pa ẹsẹ naa, to si jẹ pe awọn eeyan lo saba maa n ba ṣe awọn nnkan to ba nilo lati ṣe.

Pẹlu bi ẹsẹ rẹ ṣe wu to, Daulat Giri Ji Maharaj ṣi n rin lati ibikan si omiran amọ bo ṣe n wa lori iduro soju kan fun igba pipẹ n ṣakoba fun ilera rẹ ti awọn eeyan si n woye pe ṣe o ṣeeṣe fun-un lati si le mu ejẹ rẹ ṣẹ ki ọdun mejila to da to pe.

Awọn eeyan n woye pe o ṣeeṣe ki wọn ge ẹsẹ rẹ ko to di pe ọdun mejila rẹ to pe rara.

Awọn dokita ni wiwa lori iduro fun igba pipẹ le mu ki awọn iṣan to wa ni ẹsẹ ma gbe ẹjẹ lọ sinu ọkan bo ṣe yẹ to si le fa ki ẹsẹ maa wu, ko si maa dun eeyan.

Bakan naa ni wọn ni o le di aisan to le la ẹmi lọ bii "vein thrombosis".

Daulat Giri Ji Maharaj kọ ni ẹni akọkọ to n jẹjẹẹ iru nnkan bayii si oriṣa Shiva, ọkunrin kan Amar Bharati ti ka ọwọ ọtun rẹ soke lati ọdun 1973 latari ẹjẹ to ṣe fun Shiva pe ko n ka ọwọ naa kalẹ.

Amar Bharati ni oun ṣe bẹẹ lati fi maa beere fun ki alaafia jọba kaakiri agbaye lọwọ oriṣa Shiva.