Àlàyé lórí agbègbè 200 tó léwu láti rìn sí ṣáájú ìbò gómìná ìpínlẹ̀ Osun tó ń bọ̀, INEC kéde

Oríṣun àwòrán, Ademola adeleke/x/AFP via Getty Images
Bi eto idibo si ipo gomina ipinlẹ Osun ti yoo waye lọjọ kẹẹẹdogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ṣe n sunmọle, ajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ẹka tipinlẹ Osun, ti kede pe awọn agbegbe kan wa to lewu lati de fun ibo didi.
Aaye idibo ọrin le lóòdúnrún ó le márùn-ún (385) ati igba (200) ibo mi-in lo ṣoro lati de fun idibo bi INEC ṣe sọ.
Kọmiṣanna fun eto idibo Osun, Oluwatoyin Babalola, lo fi ọrọ naa lede nileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun lọjọ Ẹti.
"A ti fi awọn agbegbe naa to awon olori agbofinro leti, a si ti ṣe idanilẹkọọ fun awon oṣiṣẹ ti yoo bojuto ibẹ"
Ni itẹsiwaju alaye rẹ lori awon agbegbe to lewu wọnyi, Babalola sọ pe INEC ti gbaradi to bẹẹ ti awọn ti sọ gbogbo awọn aaye naa fun awọn olori agbofinro kaakiri ijọba ibilẹ ọgbọn to wa nipinlẹ Osun .
O ni, "Bakan naa ni a ti ṣe idanilẹkọọ lori ọna ti awọn oṣiṣẹ wa le gba koju ewu lawọn agbegbe yii.
"Aaye 385 to fẹ abojuto ni a ri nipinlẹ Osun, eyi ti a ti fi to awon agbofinro leti.
"A tun ri awọn ibi to maa ṣoro lati de, nitori awọn ibi kan ṣi wa nipinlẹ yii ti mọto ko le de, ti ko si dẹrun lati debẹ."
Bakan naa ni alabojuto idibo naa sọ pe oun ṣabẹwo si ijọba ibilẹ Ila ati Ifedayo, nibi ti awọn ẹsun ijinigbe ti waye ri.
O fi kun un pe amọ awọn agbofinro fi da oun loju pe alaafia yoo wa ṣaaju, nigba ti idibo ba n lọ lọwọ ati lẹyin rẹ.
"Nitori ti a ba ṣeto idibo ti ọkan awọn eeyan ko si balẹ, koda ka ṣeto to dara ju, to wa di pe ẹnikẹni ko jade dibo, bii ẹni to pọnmi sinu apẹrẹ ni."
Bẹẹ ni Babalola wi.
O rọ gbogbo awon ẹṣọ alaabo l'Osun lati fi kun ipa wọn. Alabojuto idibo naa sọ pe oun gbagbọ pe wọn le ṣe ju bẹẹ lọ bi idibo ṣe n bọ yii, ki ohun gbogbo si ri bo ṣe yẹ ko ri.
"Awa ti ṣetan lati ṣeto idibo to ni alaafia pẹlu akoyawọ, bẹẹ ni awọn nnkan elo ti a nilo ti wa"
Nigba to n sọrọ lori igbaradi INEC fun idibo gomina Osun, Babalola sọ pe ajọ INEC ti ṣetan lati ṣeto idibo to kun fun alaafia ati otitọ.
"Ni tiwa, a duro ṣinṣin lori ṣiṣe eto idibo to fi otitọ ato akoyawọ han.
"Ida marundinlọgọrun-un (75%) awon nnkan eelo idibo ni a si ti ri gba fun idibo naa.
"Fun apẹerẹ, a ti ko awon nnkan ti a nilo funra wa lọ sawọn agbegbe to yẹ. Bẹẹ si ni Kọmiṣanna ọlọpaa pẹlu awon ajọ alaabo fi n da wa loju pe idibo naa yoo lọ ni irọwọrọsẹ."
Alabojuto idibo gomina Osun lo sọ bẹẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe mọ, Gomina Ademola Adeleke to n ṣejọba Osun lọwọ n dije fun saa keji ninu ẹgbẹ Accord, bo tilẹ jẹ pe PDP lo gbe e wọle fun saa akọkọ.
Lara awọn ti wọn jọ n dupo naa ni Bola Oyebamiji (AMBO) ti ẹgbẹ oṣelu APC, ati Najeem Salaam to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, (ADC).


























