Ohun tí a mọ̀ nípa ìròyìn tó ní ọlọ́pàá mú pásítọ̀ tó kó ìbọn fún àwọn ajínigbé tó ṣọṣẹ́ ní Ogbomoso

Obinrin to wa lakata ajinigbe, Seyi Makinde ati mọlẹbi awọn to wa lakata ajinigbe

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti kede pe ko si ootọ ninu iroyin to n lọ ni igboro pe awọn ti fi ṣikun ofin mu pasitọ kan lori ẹsun pe oun lo pese ohun ija oloro fun awọn agbesunmọmi to ji olukọ ati akẹkọọ gbe lọ ni ijọba ibilẹ Oriire.

Ọlọpaa ni irọ nla gbaa ni iroyin naa ati pe ko si ohun to jọ bẹẹ rara.

Ṣaaju ni atẹjade kan ti milẹ titi loju opo Facebook pe pasitọ kan lo n ko ohun ija oloro fun awọn agbesunmọmi naa bo tilẹ jẹ pe atẹjade naa ko kede orukọ pasitọ ọhun tabi ibi to n gbe.

Ninu atẹjade ti agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa, CSP Ayanlade Olayinka, fi lede, o ni ọlọpaa ko mu pasitọ kankan lori ẹsin naa bẹẹ ni awọn agbofinro mii ko mu pasitọ kankan lori rẹ.

O fi kun pe iwadii ijinigbe awọn akẹkọọ ati olukọ naa ṣi n lọ lọwọ, nitori naa ki awọn araalu maṣe naani iroyin ọhun tabi awọn iroyin ẹlẹjẹ miran to le da ipaya silẹ laarin ilu.

O ni "Ileeṣẹ ọlọpaa ri atẹjade naa gẹgẹ bii ọna lati mu oju awọn agbofinro kuro lara akitiyan wọn lati doola awọn eeyan naa ti wọn wa ni akata agbesunmọmi.

"A rọ awọn araalu ki wọn ma ṣe ka iroyin naa si ki wọn si gbẹkẹle iroyin to ba jade lati ọọfisi ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo nikan ṣoṣo.

"Lafikun, a kilọ fun gbogbo awọn eeyan ati oju opo ti wọn n mọọmọ gbe iroyin ẹlẹjẹ kiri ki wọn jawọ ninu rẹ…."

Ayanlade sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko ni kọ lati ṣawari awọn oniroyin ẹlẹjẹ naa ki wọn le jẹ iyan wọn niṣu.

Lẹyin naa lo sọ pe afojusun ọlọpaa ipinlẹ Oyo ni ọna bi wọn yoo ṣe doola awọn ọmọde atawọn olukọ wọn ti wọn wa ni ahamọ ajinigbe.

Ti ẹ ko ba gbagbe, nnkan bii ogoji ọjọ sẹyin ni awọn agbesunmọmi ya bo ile ẹkọ awọn eeyan naa ni Ahoro Esinele ati Yawota ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo ti wọn si ji ọpọ akẹkọọ ati olukọ gbe lọ.

Wọn ṣekupa olukọ kan lẹsẹkẹsẹ lasiko ikọlu ọhun ki wọn to tun ge ori olukọ mii ninu igbo lakata wọn.