Wo ohun tí òfin nọ́mbà ìdánimọ̀ tí Aarẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ buwọ́lù túmọ̀ sí fún ọ

Kaadi idanimọ NIN

Oríṣun àwòrán, NIMC

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu ti buwọlu aba to n ri si nọmba idanimọ, National Identity Management Commission, NIMC di ofin.

Tinubu lasiko to n buwọlu aba naa lọjọ Ẹti ni ilu Abuja sọ pe ofin tuntun naa yoo mu aabo to peye ba orilẹ ede tuntun ti wọn n gbero fun Naijiria, ti yoo si tun mu eto ọrọ aje Naijiria.

O fi kun pe labẹ ofin tuntun yii, ẹnikẹni ko ni le ni anfaani lati lo ohunkohun nipa eeyan lai gba aṣẹ lọwọ ẹni naa ati pe wọn ko ni le lo kọja ohun ti eeyan ba fun wọn laṣẹ lati lo lọ.

O ni ẹni to ba fẹ lo data eeyan yoo gba ilana ofin to yẹ kọja nitori ẹtọ ọmọ Naijiria ni to si yẹ ki wọn da aabo bo o.

O tun ṣekilọ fawọn to maa n ṣayederu idanimọ ẹlomiran lati jawọ nitori ofin tuntun naa yoo tun aṣiri wọn, ti itanran wọn si ti le kun eyi to fi mọ lilọ si ẹwọn.

Ki ni ofin tuntun naa tumọ si?

Aarẹ ni nọmba idanimọ NIN ni eeyan yoo maa nilo lati forukọ silẹ fun iwe irinna ilẹ okeere, ṣiṣi akanti nile ifowopamọ, ti eeyan ba fẹ ra ilẹ, lati forukọsilẹ fun nọmba ipe, eto ifẹyinti lẹnu iṣẹ, gbogbo eto ati iṣẹ ijọba ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Labẹ ofin tuntun yii, wọn maa fun eeyan ni kaadi kan ti yoo le maa ṣe ọpọ iṣẹ, ti eeyan si le lo ni gbogbo ẹka.

Fun awọn ọmọ Naijiria to wa nilẹ okeere, Tinubu ni ofin naa maa jẹ ko rọrun fun wọn lati le ni anfaani si ọpọ nnkan ni gbogbo ibi ti wọn ba wa.

Ṣaaju asiko yii, oniruuru nọmba idanimọ ni awọn eeyan maa n lo fun eto ọtọọtọ, ọtọ fun iwe irinna, ọtọ ni eyi to wa fun ile ifowopamọ ṣugbọn to ti di ọkan bayii pẹlu ofin tuntun yii.

Àlàyé lórí bí àkọsílẹ̀ káàdì NIN ti ṣèrànwọ́ láti mú ọmọ ẹgbẹ́ Boko Haram méje àtàwọn adarí ISWAP tó ń darí bọ̀ láti Mecca

Agbesunmomi gbe ibọn lọwọ, o si tun daṣọ boju

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Minisita to wa fun ọrọ abẹnu lorilẹede Naijiria, Ọmọwe Olubunmi Tunji-Ojo, ti ṣalaye pe akọsilẹ ajọ to n ri si ọrọ kaadi idanimọ NIN ni Naijiria, NIMC, ti ṣe iranlọwọ nipa mimu ọmọ ẹgbẹ Boko Haram meje pẹlu awọn adari ikọ agbesunmọmi ISWAP kan to n dari bọ lati ibi isin Hajj ti wọn lọ ṣe ni Saudi Arabia.

Tunji-Ojo sọrọ yii lọjọ Ẹti, nile ijọba Naijiria to wa l'Abuja, kete ti Aarẹ Tinubu buwọlu ofin ajọ to n ri si idanimọ lorilẹede yii, (National Identity Management Commission Act 2026).

Bawo lọwọ ṣe ba Boko Haram meje atawọn ọga ISWAP naa?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bi Tunji-Ojo ṣe ṣalaye, o ni Ọjọbọ to kọja ni ọwọ ba awọn afurasi naa ni papakọ ofurufu ipinlẹ Katsina, lẹyin ti wọn de lati Mecca.

Minisita naa ṣalaye pe bi ọwọ ofin ṣe ba wọn naa ni wọn ṣe fa wọn le ẹka ọtẹlẹmuyẹ DSS lọwọ.

‎Nigba to n ṣalaye ipa ti ẹka to n ri si akọsilẹ idanimọ awọn eeyan ko ninu ọrọ yii, Minisita fun ọrọ abẹnu sọ pe ọwọ ba awọn eeyan naa pẹlu ajọṣepọ ileeṣẹ to n ri si iwọle-jade ni Naijiria ti a mọ si Immigration, ati ajọṣe awọn ọlọpaa abẹnu ti a mọ si Interpol.

‎Tunji-Ojo ṣalaye pe "mo mọ pe nigba kan, ominu kọ Aarẹ ile igbimọ aṣofin Naijiria nipa bawọn agbesunmọmi ṣe lọ fun irinajo ẹsin, o n ya a lẹnu pe bawo ni wọn ṣe kọja lawọn ẹnu ibode wa.

"Amọ mo layọ lati sọ fun yin pe l'Ọjọbọ to kọja yii, meje ninu awọn adari Boko Haram ati ISWAP ti wọn lorukọ ni ọwọ ba nigba ti wọn n dari bọ lati Mecca, wọn mu wọn ni papakọ ofurufu ni Katsina, wọn si fa wọn le awọn DSS lọwọ.

‎"Eyi ṣee ṣe nitori idanimọ NIMC ti a ti so pọ mọ akọsilẹ awọn ẹka to n ri si iwọlejade, bẹẹ lo si n ṣiṣẹ pẹlu awọn ọlọpaa abẹnu lojoojumọ ati ni gbogbo wakati, a si ti n lo ẹrọ fun eyi."

O fi kun alaye rẹ pe ofin NIMC ti Aarẹ ṣẹṣẹ buwọlu yii yoo tubọ ro eto aabo Naijiria lagbara, nipa siso awọn akọsilẹ kaluku pọ lawọn ẹka to n ri si i.

‎Gẹgẹ bi Tunji-Ojo ṣe ṣalaye, ofin tuntun yii yoo ṣe iranlọwọ fun Naijiria lati ṣẹgun ole jija, igbesunmọmi, ajẹbanu, aisi aabo ati bẹẹ bẹẹ lọ.

‎Niṣoju Aarẹ ile igbimọ aṣofin agba Naijiria, Godswill Akpabio, Igbakeji Abẹnugan ile igbimọ aṣoju; Benjamin Kalu atawọn lọgaa-lọgaa mi-in lẹnu iṣẹ ọba ni Aarẹ Tinubu ti buwọlu ofin NIMC ti ọdun 2026 naa lọjọ Ẹti, ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu Kẹfa ọdun yii.