Kí ló fa ìbúgbàmù tó wáyé ní Eko tó dá ìbẹ̀rù àti ìdààmú sílẹ̀?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Niṣe ni iberu gbọkan awon agbegbe Mushin, ipinlẹ Eko bi ado oloro ṣe bu gbamu labẹ ọkọ kan ni agbegbe naa lọjọ Aje.
Gẹgẹ bi iroyin to tẹ wa lọwọ, nnkan bii aago mefa idaji ni iṣẹlẹ naa waye ni ojule kejilelogun, opopona Wey Street, Oke Mushin, nibi ti wọn ti maa n ta awọn ohun elo ti wọn fi n ṣe bata.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ salaye pe ọkunrin kan to ni ọkọ Toyota Sienna to paaki sita mọjumọ lo fẹ gbe ọkọ rẹ jade ki ado oloro naa to bu gbamu labẹ ọkọ rẹ lẹyin to ṣina si ọkọ naa.
Wọn ni bo ṣe ṣina si ọkọ ni ado oloro naa bu gbamu labẹ ọkọ rẹ lati ibi ẹgbẹ bi ti ero maa n jokoo si, eyi to mu ki ọkọ naa bajẹ, ti ọkunrin naa si farapa.
Iṣẹlẹ yii sokunfa ki awọn ẹṣọ aabo ṣe abẹwo sibi ibugbamu naa to fi mọ Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Tijani Fatai lati fidi ohun to waye gangan mulẹ.
Nigba to n sọrọ nibi ibugbamu naa, Fatai ṣalaye pe ni kete ti awọn gbọ nipa iṣẹlẹ naa ni wọn fi awọn oṣiṣẹ to n mojuto ibugbamu ranṣẹ si agbegbe naa lati mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an ni pato.
Kọmiṣanna ọlọpaa ni iwadii tawọn kọkọ ṣe bayii fi han pe ado oloro "Improvised Explosive Device" ni wọn fi sabẹ ọkọ to bu gbamu ọhun to si bu gbamu lẹyin ti wọn ṣina ọkọ naa.

Oríṣun àwòrán, Lagos Police
O ṣalaye pe awọn tig be ọkunrin to farapa nibi ibugbamu naa lọ sile iwosan fun itọju to peye ti iwadii si n tesiwaju lati mọ bi ado oloro naa ṣe de abẹ ọkọ naa.
O fi kun pe awọn onimọ nipa ado oloro ti ṣayẹwo gbogbo agbegbe naa daadaa lati mọ boya irufẹ ado oloro bẹẹ ṣi tun w ani agbegbe naa amọ ti wọn ko ṣawari ohunkohun.
O wa rọ awọn olugbe atawọn to n ta ọja ni agbegbe naa lati fi ọkan balẹ pe iwadii fi han pe ko si ewu kankan fun wọn ati pe aabo to peye wa ni agbegbe naa bayii.
O ni ki wọn maa ba karakata ati igbe aye wọn lọ lai si ibẹru nitori iwadii fi han wọn ko si ninu ewu tabi pe ado oloro mii ṣi w ani agbegbe wọn.
Kọmiṣanna naa tun ṣalaye pe ado oloro to dun gbamu naa ni awọn ti mu eyi to ṣẹku nidii rẹ lati lọ ṣe ayẹwo rẹ daadaa, ki wọn si le ṣawari bo ṣe de ibẹ ati lati fidi ti awọn to ṣiṣẹ naa ati idi ti wọn fi ṣe mulẹ.


























