Kí ló dé tí UK ń pààrọ̀ Olóòtú ìjọba léraléra?

Akojọpọ aworan awọn ti wọn ti jẹ olootu ijọba UK lati ọdun mẹwaa sẹyin. Lati apa osi si ọtun: David Cameron, Theresa May, Boris Johnson, Liz Truss, Rishi Sunak and Keir Starmer

Oríṣun àwòrán, Getty Images

    • Author, Rob Watson
    • Role, UK political correspondent, BBC World Service
  • Published
  • Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Sir Keir Starmer ni Olootu ijọba kẹfa to maa kọwe fipo silẹ tabi tawọn oludibo maa mu ni tipa lati fi ipo rẹ silẹ laaarin ọdun mẹwaa.

Ni eto oṣelu ilẹ Gẹẹsi, ohun to n ṣẹlẹ yii kii ri bẹẹ tẹlẹ. Lati igba ti wọn ti da ipo olootu ijọba silẹ ni Senturi kejidinlogun, o kere tan, olootu ijọba kan maa n lo to odun marun-un lori ipo ṣugbọn ti adinku ti ba eyi lati bii ọdun mẹwaa sẹyin.

Ki lo fa ayipada yii? O ni idi kan pataki ti ayipada yii fi n waye fun awọn Olootu ijọba mẹfa ti wọn fi ipo wọn silẹ laaarin ọdun mẹwaa yii.

David Cameron kọwe fipo silẹ lọdun 2016 nitori o pe fun ki boya ki UK ṣi wa ni ẹgbẹ iṣọkan ilẹ Yuroopu amọ to fidi rẹmi.

Theresa May naa jẹ ẹni to fori ṣọta Brexit bi wọn ṣe kọ awọn aba rẹ to gbe kalẹ lori ibaṣepọ laaarin UK ati EU ko to di pe wọn ko gba aba rẹ wọle.

Wọn le Boris Johnson kuro lori ipo nitori iwa rẹ tawọn aṣofin ẹgbẹ Conservative bii tirẹ naa sọ pe ko wulo fun ipo to wa bii ti tẹlẹ mọ.

Liz Truss kuro nipo naa nitori bi awọn eeyan ṣe gba awọn aba rẹ lori isuna fun gige owo ori, gẹgẹ bi awọn oludokoowo ṣe sọ, gige owo ori naa ko pe wọn rara.

Rishi Sunak ni ọmọ ẹgbẹ oṣelu Conservative to kuro lori ipo naa kẹyin bi wọn ṣe fi ibo gbe kuro pe iṣejọba ẹgbẹ oṣelu Conservative fun ọdun mẹrinla tis u awọn araalu.

Fun Keir Starmer to ṣẹṣẹ kọwe fipo silẹ, o kuro lori ipo nitori ko ri atilẹyin awọn aṣofin akẹgbẹ rẹ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party mọ.

Awọn aṣofin naa gbagbọ pe Starmer ko gbajumọ mọ ati pe o maa jẹ idunkoko si ẹgbẹ oṣelu wọn.

Amọ pẹlu gbogbo awọn okunfa to fa ijakulẹ awọn olootu ijọba yii, o dabi pe awọn nnkan mii n lọ lagbo oṣelu UK eyi to mu ki oṣelu naa le diẹ, to si n mu ki awọn oludibo ma nii aforiji, ti wọn si n pin yẹlẹyẹlẹ.

Aisi idunnu

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Awọn iwadii n fi han pe awọn oludibo n ri bi eni pe awọn oloṣelu ko ni imọ kikun nipa nnkan mẹta to n fa aisi idunnu fun wọn.

Ohun akọkọ ni bi awọn ohun amayederun to n mu igbe aye rọrun wọn ṣe duro soju kan. Eyi ni a le tọpinpin si laasigbo eto isuna to waye lọdun 2008.

Fun idi eyi, ti a ba n wo idi ti UK ṣe ni olootu ijọba mẹfa lati ọdun 2016, o yẹ lati wo o lati ọdun 2008 naa.

Bakan naa ni adinku ko i tii ba igbe aye irọrun to bayii lati igba ogun Napoleonic Wars ni ibẹrẹ Ṣenturi kọkandinlogun.

Nigba ti awọn eeyan ba n daamu lori owo nina, ti wọn si n rii bii pe ijọba ko mu ileri rẹ ṣẹ pe saa to n bọ maa da ju ti atẹyinwa lọ, ko ni yani lẹnu ti nnkan ko ba lọ deedee.

Ohun keji ni pe awọn eeyan gbagbọ pe nnkan ko le deedee ni UK mọ paapaa ni awọn ẹka to jẹ ti ijọba bii eto irinna, idajọ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

A le sọ pe esi bi eto ọrọ aje orilẹ ede naa ko ṣe gbera to ni, eyi to n mu ki igbe aye maa lọlẹ fun awọn eeyan.

Airajaja eto ọrọ aje yii ti dena awọn ijọba to ti wa lori ipo lati ri owo dokoowo sawọn ohun amayedẹrun bo ṣe ye biieto ẹkọ ati ilera.

Awọn oṣiṣẹ ilera wa ni ile iwosan

Oríṣun àwòrán, PA Media

Ohun kẹta ni pe ọpọ lo gbagbọ pe ko si ifẹnuko ni orilẹ ede naa ti wọn si gbagbọ pe orilẹ ede naa ti pin.

Awọn kan maa n di ẹbi eyi ru bi ẹnu ko ṣe ṣọkan lori ilana tawọn ajoji to n wọ orilẹ ede UK lati fi ṣe ibugbe lati bii ọdun mẹwaa.

Ọpọ awọn oludibo gbagbọ pe awọn olootu ijọba to ti wa nipo ko ni imo nipa ohun to n bi wọn ninu lori ayipada to ti ba UK.

UK gẹgẹ bi awọn orilẹ ede Yuroopu mii ṣi n lakaka lati se akojọ awọn orilẹ ede to kun fun ọpọ ẹya, ati aṣa.

Awọn nnkan mii naa n yipada, kii ṣe UK nikan lo ti n ṣẹlẹ, kii si ṣe pe awọn eeyan n binu lori awọn igbese kankan kọ, wọn ko fara pamọ lati fi han mọ.

Boya ayelujara wa lara awọn ohun to fa eyi tabi bẹẹkọ, awọn eeyan n fi ẹdun ọkan wọn han sawọn oloṣelu to fi mọ awọn olootu ijọba ni ọna ti eeyan ko le r oni ọdun diẹ sẹyin.

Ṣe UK ti ṣoro bayii lati ṣejọba le lori?

Awọn oluwọde n ti awọn ọlọpaa lasiko iwọde kan

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ṣe a le sọ pe UK ti ṣoro lati ṣejọba le lori? Ṣe a le sọ pe idi niyi ti UK ṣe maa ni olootu ijọba keje laaarin ọdun mẹwaa?

Ọpọ awọn oloṣelu ni ko ni ronu lọ sibe yẹn. Wọn ni bi o tile jẹ pe iṣejọba ti lagbara si, kii ṣe ohun ti ko ṣeeṣe.

Amọ bi ijakulẹ ṣe tib a awọn olootu ijọba mẹfa lati gbe yọ UK ninu ajaga ti wọn ti ko si lati igba laasigbo eto isuna 2008 ati Brexit 2016, awọn eeyan n kọminu lori ohun ti ẹni to ba gbapo olootu ijọba maa le ṣe to ba depo naa.