You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọ Mímọ́ CCC bẹ̀rẹ̀ ìwádìí ẹ̀sùn táwọn èèyàn fi kan Olùṣọ́ ọ̀rẹ́kùnrin Tope Osoba lóri ohun tó ṣokùnfà ikú rẹ̀
Ijọ mimọ CCC ti bẹrẹ iwadii lori nnkan to ṣokunfa iku to gbajumọ oṣere tiata, Temitope Osoba.
Ijọ CCC gbe iwadii yii dide latari awuyewuye to n lọ lori ayelujara wi pe o ṣee ṣe ki ọrẹkunrin rẹ, Ọgbẹni Itunu Onadeko, to jẹ Oluṣọ ijọ CCC to wa ni Bogije, ni Ibeju-Lekki niluu Eko mọ nipa iku rẹ.
Ijọ naa sọ pe awọn ẹsun tawọn eeyan fi kan Onadeko lori iku Tope n kọ awọn lominu tori o ti ta ẹrẹ ba orukọ ijọ mimọ CCC.
Lọjọ kẹrin oṣu Kẹjọ yii ni gbajumọ oṣere naa jade laye, ṣugbọn lọjọ keji iku rẹ ti i ṣe ọjo karun un oṣu yii ni ọpọ eeyan gbọ iroyin iku Tope.
Arun jẹjẹrẹ ọyan eyi ti o beere iranwọ owo fun lọdun 2024 ni ọpọ ro tẹlẹ wi pe o ṣekupa Tope.
Amọ, nnkan ti ẹbi rẹ n sọ nipa ilera rẹ, oogun lilo ati iporuuru ọkan lasiko iku rẹ ti jẹ ki ọpọ maa beere nnkan to le ṣokunfa iku oṣere naa gan an.
Ijọ CCC ko ṣai kẹdun pẹlu ẹbi Tope, amọ, inu wọn tun bajẹ nitori bi orukọ ijọ naa ti di nnkan ti ọpọ eeyan n sọ nipa rẹ lọna ti ko tọ.
''Inu wa bajẹ wi pe Tope jade laye nigba ti ko ti i dagba, a si kẹdun pẹlu ẹbi rẹ.
Ṣugbọn awuyewuye to n lọ lori Ọnadeko nipa iku Tope jẹ nnkan to n kọ wa lominu tori o n tabuku orukọ ijọ CCC.
A fẹ sọ fun gbogbo eeyan wi pe ijọ to gbagbọ ninu Bibeli ni ijọ CCC, ẹmi lo si maa n dari eto ijọsin wa.
Ko si aye fun ibọriṣa, idan, ẹgbẹ okunkun tabi ogun ṣiṣe ninu ijọ wa,'' Ijọ CCC ṣalaye ninu atẹjade to fi sita.
Ẹbí Tope Osoba ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi sún ètò ìsìnkú rẹ̀ tó yẹ kó wáyé lónìí síwájú di ọjọ́ míì ọjọ́ ire
Oni Ọjọbọ, ọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni awọn ẹbi gbajumọ oṣere nni, Tope Osoba to jade laye ti kede pe awọn yoo sin oku rẹ tẹlẹ, amọ wọn ti ni isinku naa ko ni i waye lonii mọ.
Ana Ọjọru ni awọn ẹbi Oloogbe fi ikede tuntun naa sita pe awọn ti sun ọjọ isinku Tope siwaju.
Wọn ni awọn yoo maa kede asiko isinku tuntun lawọn oju opo to yẹ ti asiko ba to.
Tẹ o ba gbagbe, lara eto ti wọn la kalẹ fun isinku Tope Osoba to jade laye lẹni ogoji ọdun ni Aṣalẹ awọn oṣere to waye ninu ọgba tẹlifiṣan ipinlẹ Eko lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii, ati eto titan abẹla.
Bi awọn eeyan to ti ro pe awọn yoo peju si Iperu Remo nipinlẹ Ogun l'Ọjọbọ lati sinku Tope ṣe n gbaradi ni awọn ẹbi rẹ kede loju opo Instagram rẹ l'Ọjọru pe :
" Pẹlu ibanujẹ to jinlẹ, ẹbi Osoba n fi eyi sọ fun ẹyin ọrẹ, alajọṣiṣẹ, ololufẹ atẹyin afẹnifẹre, pe a ti sun eto isinku siwaju titi digba ta o tun maa pada fi to yin leti.
"Lẹyin ayẹyẹ titan abẹla ati aṣalẹ awọn oṣere to waye lati ṣẹyẹ fun Tope, ẹbi ti pinnu lati sun isinku siwaju, ka le raye ṣeto si i, ka si le fi ẹnu ko sibi kan."
Atẹjade naa ti ẹbi Osoba ati Awonuga buwọlu, tẹsiwaju pe awọn yoo kede ọjọ isinku tuntun lawọn oju opo to ba yẹ bi asiko ba to.
Wọn rọ awọn eeyan to ti n ba iṣẹlẹ naa bọ bo ṣe n lọ lati ṣe suuru titi tawọn yoo fi yanju awọn ọrọ to wa nilẹ.
Ki ni ẹbi kede ṣaaju?
Ẹ o ranti pe ile ijọsin Saint James Anglican Church to wa ni Iperu Remo, nipinlẹ Ogun ni awọn ẹbi kọkọ kede pe eto isinku yoo ti bẹrẹ fun Tope Osoba.
Itẹ oku Iperu Remo, nipinlẹ Ogun kan naa ni wọn si ni kawọn eeyan peju si fun isinku l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtala oṣu Kẹjọ 2026.
Aago mẹwaa owurọ si mọkanla ni wọn fi eto naa si, ki wọn too sun un siwaju bayii lai ti i sọ pato igba ti yoo tun pada waye.
Tẹ o ba gbagbe, latigba ti iroyin iku Tope ti gbode l'Ọjọru ọsẹ to kọja ni awuyewuye ti n tẹle iku naa, paapaa bi wọn ṣe n naka aleebu si Oluṣọ Itunu Onadeko ti Tope n fẹ nigba aye rẹ pe o mọ nipa iku naa.
Bakan naa si ni ai ba awọn ẹbi rẹ ṣe fun igba pipẹ tun jẹ ọrọ kan ti ọpọ eeyan n gba bii ẹni gba igba ọti nipa iku Oloogbe Tope Osoba.
Wó kókó méjìlá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Temitope Osoba, òṣèré tíátà tó jáde láyé
Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajugbaja oṣerebinrin nni, Temitope Kofoworola Osoba ti jade laye lẹni ogoji ọdun, sibẹ, ọpọ awọn akẹgbẹ ati ololufẹ rẹ ṣi n ṣedaro rẹ.
Ọpọlọpọ adojukọ ni oloogbe naa koju lati kekere rẹ, titi to fi dagba, to fi mọ nidi iṣẹ tiata to yan laayo.
Lara awọn adojukọ ojiji ti oṣerebinrin naa koju ni ti aisan jẹjẹrẹ ọmu to kọluu lọsan gangan.
Gbara ti Temitope Osoba ti ṣakiyesi koko to so si ẹgbẹ ọmu rẹ, lo ti gba ile iwosan lọ.
Sugbọn awọn oniṣegun oyinbo sọ pe ko sewu loko longẹ, lai mọ pe ewu nla ni longẹ funra rẹ.
Obinrin naa pada ṣiṣẹ abẹ lati yọ koko naa to jẹ jẹjẹrẹ ọmu kuro, to si gba oniruuru iwosan, ko to di pe o pada sidi iṣẹ tiata rẹ.
Temitope Osoba ko ipa takuntakun nidi iṣẹ tiata, eyi to jẹ ko maa wa loju iworan gbogbo awọn olulufẹ ere tiata ni gbogbo igba, ko to di pe o ki aye pe o digboṣe lọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.
Ni bayii, ẹ wa wo awọn ohun mejila pataki nipa igbe aye Temitope Osoba.
Ilu to ti wa
Ọmọ bibi ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Temitope Osoba
Ọjọ ibi rẹ
Ọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 1985 ni wọn bi oloogbe naa niluu Abẹokuta, nibẹ si lo ti bẹrẹ sii nifẹ si iṣẹ tiata, lati kekere.
Bo ṣe jade sita
Temitope Osoba tan mọ gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Olusegun Osoba, nitori pe inu idile kan naa ni Segun Osoba ati baba Temitope ti jọ jade.
Temitope ko duro lati maa lo orukọ naa fi gbe ara rẹ, ṣugbọn o jade sita, o si ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe oun ni orukọ toun, fun igbelarugẹ orukọ idile Osoba.
Eto ẹkọ rẹ
Ẹkọ imọ nipa okoowo (Business Education) ni Osoba ni, ni fasiti Olabisi Onabanjo to wa niluu Ago-Iwoye, ipinlẹ Ogun.
Imọ ẹkọ naa lo fi kun iṣẹ rẹ to yan laayo, eyi tii ṣe tiata, fun igbelarugẹ gbigbe ere jade, ati kikopa ninu ere.
Ṣaaju iṣẹ tiata
Temitope ko ṣa deede bẹrẹ iṣẹ tiata lojiji, tipẹtipẹ ko too bẹrẹ sii farahan ninu awọn ere agbelewo, lo ti n ṣiṣẹ alajota, to si tun n jo ninu awọn awo orin loriṣiriṣi.
Nigba to ṣiṣẹ alajota titi, lo ri anfaani lati wọnu iṣẹ tiata, to si ẹrẹ lẹkunrẹrẹ ni nnkan bi ọdun 2005. Gbara to wọle, lo ti bẹrẹ sii lokiki, to jẹ ki wọn maa lo o kaakiri.
Awọn iṣẹ fiimu agbelewo to ti kopa
Ọpọ ere agbelewo ti ko lonka ni Osoba kopa ninu rẹ nigba to wa laye, lara rẹ si ni Gucci Girls ti ọdun 2012, Accident to jade lọdun 2013, ati Ifedolapo to jade lọdun 2015, ati awọn miran ti a ko le mẹnuba tan.
Bi Osoba ṣe n kopa inu ere gẹgẹ bii jagidijagan, bẹẹ lo n kopa alawada ati iyaale ile, to fi mọ awọn miran.
Bo ṣe kofiri aisan jẹjẹrẹ ọmu
Ọdun 2024 ni Osoba ṣakiyesi koko kan lẹgbẹ ọmu rẹ. Kaka ko pa ẹnu rẹ mọ, ko si maa woran, niṣe lo.
O ṣeni laanu pe kaka ki awọn oniṣegun oyinbo fun un ni amoran, nipa bi yoo ṣe tete tọju ara rẹ, ko si ṣiṣẹ abẹ, niṣe ni wọn sọ pe ko si nnkan nibẹ.
Diẹdiẹ ni jẹjẹrẹ naa n dagba, ko to tun sare pada lọ, leyi to jẹ ko pada ṣiṣẹ abẹ.
Lasiko ti iṣẹ abẹ naa n lọ lọwọ, Osoba ṣe fọnran sita lati fi gba awọn obinrin lamọran nipa itọju ara ẹni, to si fi ara rẹ ṣe apẹẹrẹ.
Awọn eeyan dide iranlọwọ
Ọpọ awọn ololufẹ ati ọrẹ rẹ ni wọn dide iranlọwọ fun un nigba to jade lati ṣalaye nipa iṣoro to n koju.
Lẹyin to pada ṣiṣẹ abẹ tan, ti wọn si gbe jẹjẹrẹ naa jade, awọn dokita sọ fun un pe o gbọdọ lo oogun fun ọdun kan, ti ko si gbọdọ loyun, depodepo wi pe yoo bimọ.
Eyi lo jẹ ko jade lati bẹbẹ fun iranlọwọ awọn araalu, paapaa awọn ololufẹ rẹ lori oogun ti awọn dokita ni ko maa lo loore-koore.
Si iyalẹnu, awọn ẹlẹyinju aanu dide kaakiri Naijiria ati lagbaye, ko to tun pada sidi iṣẹ tiata rẹ.
O pari iṣẹ abẹ
Lẹyin ọpọlọpọ ayẹwo ti Osoba ṣe lẹyin iṣẹ abẹ, awọn dokita sọ fun un pe jẹjẹrẹ naa ko tii tan kaakiri ara rẹ.
Eyi lo si ṣalaye lori ayelujara fun awọn ololufẹ rẹ, nibi to ti n dupẹ.
Bi ara rẹ ṣe pada bọ sipo, lo n jẹ iyalẹnu nla fun ọpọ awọn ololufẹ rẹ, ti wọn si n wo o gẹgẹ bi awokọṣe nipa awọn ti ori ko yọ lọwọ aisan jẹjẹrẹ.
Temitope pada soko ere
Lẹyin ti gbogbo wahala ati iṣoro naa d'opin, Temitope Osoba pada sidi iṣẹ tiata lọdun 2025 to yan laayo.
Kaka ko jẹ ki irẹwẹsi ọkan ba oun, nipa awọn ohun to ṣẹṣẹ la kọja, obinrin naa wo o pe ohun to tọ ni lati pada soju iworan gbogbo awọn ololufẹ oun.
O ṣapejuwe ara rẹ fun gbogbo eeyan gẹgẹ bi akikanju, to si loun ṣetan lati fi awọn alakoja ati iriri oun kọ awọn eeyan lẹkọọ kaakiri agbaye.
Ipolongo aisan jẹjẹrẹ ọmu
Temitope Osoba di ohun to ja geere fun ipolongo aisan jẹjẹrẹ ọmu fawọn obinrin.
Lẹyin to ti gbadun, ti ara rẹ ya, o bẹrẹ sii ṣe ipolongo fun awọn obinrin lati maa ṣayẹwo ara, paapaa ọmu wọn loore-koore, lati le tete kofiri aisan naa lara, ko too pẹ ju.
Bi ko ṣe fi ọrọ sabẹ ahọn sọ fawọn eeyan, lo fa a ti gbogbo bi awọn obinrin ṣe n bo ẹnu lati sọrọ jade, paapaa lagboole amuludun.
Iku Temitope
Bi iroyin Temitope Osoba ṣe jade sigboro aye lọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 to dakẹ, lẹni ogoji ọdun, lo ti jẹ kayeefi fun awọn eeyan, paapaa awọn to sunmọ ọn.
Bi awọn kan ṣe n gbera ṣanlẹ, lawọn miran n wa ẹkun mu, pẹlu bi iku naa ṣe ba wọn lọkan jẹ to.
Gbajugbaja oṣere kan ti wọn n pe ni Alesh Sanni lo kọkọ gbe iroyin naa jade sori ikanni ayelujara, leyi to ṣe ọpọ ni kayeefi.
Latigba naa lawọn akẹgbẹ rẹ ti bẹrẹ sii gbe e kaakiri, ti wọn si n ṣedaro iku rẹ.
Ipa to fi lelẹ
Yatọ si idi iṣẹ tiata, ipa rere ni Temitope Osoba fi lelẹ.
Awọn ipa to fi lelẹ yii ni ko le jẹ ki awọn eeyan tete gbagbe rẹ, paapaa loju iworan.
Osoba fi awọn igbe aye rẹ to ṣokunkun lati tan imọlẹ fun awọn obinrin bii tiẹ, to si fun awọn obinrin to n koju ipenija aisan jẹjẹrẹ ni ireti ọjọ iwaju rere.
O fun ọpọ obinrin ni igboya lati koju iṣoro aisan jẹjẹrẹ nigbakugba to ba wọle de.