Nítorí ìjà ilẹ̀ àti ìdigunjalè, èèyàn mẹ́wàá bọ́ sọ́wọ́ ọlọ́pàá l'Ondo

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Afurasi ti ko din ni mẹwaa ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti mu si ahamọ bayii lori ẹsun jija si ilẹ ati idigunjale laaarin Eko ati Ondo.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Felix Ohagwu, ṣalaye pe meje ninu awọn mẹwaa naa ni awọn mu latari rogbodiyan ija ilẹ kan to ṣẹlẹ ni Kajola, niluu Akure, nigba ti awọn mẹta jẹ afurasi adigunjale.

Ọlọpaa gba ibọn atawọn nnkan ija oloro miran lọwọ ikọ mejeeji

Ni itẹsiwaju alaye kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo, o ni ibọn atawọn nnkan ija oloro miran ni awọn gba lọwọ awọn eeyan naa lasiko ti rogbodiyan ọhun waye .

"Ija ilẹ ti wọn fi da rogbodiyan silẹ naa waye lọjọ Abamẹta, ọjọ kejidinlogun oṣu Keje ọdun 2026, ni nnkan bii aago mẹsan-aabọ aarọ, lori ilẹ oko kan to wa ni Adegbiji, nitosi Kajola.

"Iwadii fi han pe ija naa kan Akinsulu Titus ati Ajani Abiodun ti wọn jọ jẹ ọmọ Ayetoro, nitosi Kajola, ti wọn si jọ n fa ọrọ ilẹ kan nile ẹjọ giga to wa ni Ore."

Kọmiṣanna ọlọpaa Ondo lo ṣalaye bẹẹ.

O fi kun un pe ikọ mejeeji ko awọn ti yoo ba wọn da wahala silẹ lọ sori ilẹ ọhun, titi kan awọn ọlọkada igboro ti wọn bẹ lọwẹ lati fa wahala.

Ohagwu sọ pe awọn mẹta kan wa ninu awọn to wa fa wahala naa ti wọn ni ṣọja ni wọn, amọ wọn ti sa lọ bayii.

"Pe wọn ba awọn ire oko bii igi ọpẹ atawọn igi to n so eso to ṣee ta ko dowo ni wọn kọkọ jọ n ba ara wọn ja si, ko too di rogbodiyan, ti awọn mejeeji farapa, ti aṣọ wọn tun ya."

Nipa awọn nnkan ija ti wọn gba lọwọ awọn onija naa, Ohagwu sọ pe apo alawọ ofeefe kan lawọn kọkọ gba, ninu rẹ ni ibọn ṣakabula wa, ada meji ati apo mi-in ti wọn ko awọn nnkan to jọ oogun abẹnugọngọ si.

Ohagwu sọ pe ike kan ti wọn kọ asiidi si lara, ti kinni kan bii omi wa ninu rẹ tun wa lara ohun ti ọlọpaa gba lọwọ awọn eeyan naa.

Awọn ti wọn mu fun idigunjale

Lori ẹsun idigunjale laarin ipinlẹ Eko ati Ondo, Kọmiṣanna ṣalaye pe ọwọ ba Promise Daniel, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (34); Ifeanyi Umahi, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn (29) ati Adaramoye Abayomi, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37).

"Ọjọ Satide, ọjọ kejidinlogun oṣu Keje ọdun 2026 ni ọwọ ba wọn lẹyin itọpinpin ọlọpaa."

Ohagwu sọ pe ọwọ ba wọn lẹyin tawọn tọpinpin wọn tawọn si ri i pe wọn mọ nipa idigunjale kan ti ifisun waye nipa rẹ lọjọ kẹrinla oṣu Kẹfa ọdun 2026.

O ni agọ ọlọpaa Iju, Ita-Ogbolu, nijọba ibilẹ Ariwa Akure ni wọn mu ifisun naa lọ.

"Ikọ agbofinro nawọ gan wọn lasiko ti wọn n rin irin ajo ninu ọkọ ayọkẹlẹ Mercedes-Benz ML 350 SUV, alawọ eeru."

Nigba ti wọn yẹ inu ọkọ naa wo bi ọlọpaa ṣe wi, wọn ba ibọn AK-47 kan, ibọn kan to ni ọta ibọn mejidinlogun ti wọn ko ti i yin, ibọn ilewọ oyinbo kan to ni ọta ibọn mẹrin, aake UTC ati irinṣẹ kan ti wọn fi maa n ge irin.

"Iwadii fi han pe awọn afurasi yii jẹ ikọ adigunjale ti ọlọpaa Ondo ti n wa tipẹ, fun ẹsun ole jija kaakiri Ondo.

Kọmiṣanna fi kun un pe awọn afurasi adigunjale naa jẹwọ nigba tawọn n fi ọrọ wa wọn lẹnu wo, eyi to n ran awọn oluwadii lọwọ lati mu awọn yoku wọn to ti na papa bora bo ṣe sọ.