Nǹkan kan tí mo mọ̀ ni pé bí orin tí mo bá kọ bá bùkún fún mi, yóò bùkún fún gbogbo èèyàn tó bá gbọ́ ọ - Bisi Manuel

Nǹkan kan tí mo mọ̀ ni pé bí orin tí mo bá kọ bá bùkún fún mi, yóò bùkún fún gbogbo èèyàn tó bá gbọ́ ọ - Bisi Manuel
Published

"Nnkan kan ni mo mọ nipa awọn orin ti mo ba kọ, bi orin mi ba ti bukun mi, mo mọ pe yoo jẹ ibukun fun ọpọ eeyan pẹlu."

Eyi ni ọrọ ti gbajumọ akọrin ẹmi, Bisi Manuel sọ ṣaaju ọr rẹ ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba.

O ṣalaye pe ifẹ oun si ede Yoruba pẹlu n han ninu bi orin ti oun ba fi ede naa kọrin ṣe maa n fa ọkan oun si Ọlọrun.

Bakan naa lo ṣalaye pe oun ni igbagbọ pe nigba ti yoo ba fi di ọdun diẹ si asiko yii, awọn orilẹede miran ti ko gbọ ede Yoruba yoo bẹrẹ si ni ni ifẹ si gbigbọ orin Yoruba pẹlu.