Sẹ́nétọ̀ Osun wọ gàù lẹ́yìn tó ní kí àwọn alátìlẹyìn òun máa pa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Accord lọ́jọ́ ìbò

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti ke Sẹnetọ Francis Fadahunsi to n ṣoju ẹkun ila oorun Osun nile igbimọ aṣofin ko yọju si agọ wọn lẹyin to ni ki awọn alatilẹyin oun pa awọn ọmọ ẹgbẹ Accord lọjọ idibo gomina ti yoo waye lopin ọsẹ yii.

Fadahunsi lo sọ ọrọ naa lasiko to n ba awọn ololufẹ rẹ sọrọ niluu Ilesha.

Nibẹ lo ti sọ pe awọn gẹgẹ bi ẹgbẹ oṣelu APC ko fẹ gburo ẹgbẹ oṣelu Accord lagbege awọn mọ.

Bo ṣe n ta ohun ti awọ ofeefee ti ẹgbẹ oṣelu Accord n lo naa lo n fẹsun kan awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa pe awọn lo n gbẹmi awọn eeyan kaakiri ipinlẹ Osun nitori oṣelu.

O ni "A ti de, ati wa sọ fun yin, titi di ọjọ ibo ti a ba ri wọn, pipa ni o. Awa o le maa wo."

Peter Obi, Adeleke, atawọn araalu mii bu ẹnuatẹ lu ọrọ naa

Lẹyin ti fidio naa gba ori ayelujara kan lọpọ awọn oloṣelu ni Naijiria bẹrẹ si n bu ẹnu atẹ lu ọrọ ti agba oloṣelu naa sọ, ti wọn si ke pe ileeṣẹ ọlọpaa lati fi ṣikun ofin gbe.

Ademola Adeleke

Lara wọn ni Ademole Adeleke to ke si ọlọpaa pe ki wọn mu ọkunrin ọhun lai fi akoko ṣofo.

Adeleke, lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ọrọ naa da bii pe o ti n kọja oṣelu bayii, o si yẹ ki Aarẹ Bola Tinubu da si.

O ni "Ọrọ yii ti kọja oṣelu o, o ti di ọrọ idunkokomọni ti Aarẹ, lati ọọfisi olubadamọran pataki si lori eto abo gbọdọ da si.

"A fi akoko yii ke si ọlọpaa ati DSS ki wọn mu sẹnetọ Fadahunsi fun ọrọ ifẹmiṣofo to sọ si awọn eeyan ipinlẹ Osun.

Peter Obi

Nigba to n sọrọ loju opo Facebook rẹ, oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu ADC, Peter Obi koro oju si ọrọ sẹnetọ naa.

Obi sọ pe Fadahunsi to jẹ aṣofin yẹ ko jẹ apẹrẹ rere faraalu, ko si yẹ ko jẹ iru rẹ ni yoo dunkoko mọ araalu lasiko ti eto idibo sunmọle.

Gomina Anambra tẹlẹ naa wa rọ sẹnetọ ọhun ko ko ọrọ aburu naa jẹ ko si tọrọ aforijin lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Osun.

Ọlọpaa pe sẹnetọ Fadahunsi ko wa wi tẹnu rẹ lagọ wọn

Wayi o, ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti ke si sẹnetọ ọhun lati wa wi tẹnu rẹ lori ọrọ to sọ pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC maa pa awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Accord.

Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, Abiodun Ojelabi lo fidi iroyin naa mulẹ fun BBC ninu ifọrọwerọ kan.

O ni ootọ ni pe kọmiṣọna to n ri si eto idibo naa ti ke si, o si gbọdọ wa wi tẹnu rẹ lori ẹsun "ẹ maa poa wọn" ti wọn fi kan an.

Mi o sọ pe ki wọn lọ gbẹmi awọn eeyan; Fadahunsi ṣalaye ohun to sọ

Lẹyin ti ọpọ ọmọ Naijiria bu ẹnu atẹ lu ọrọ ọkunrin naa lo pada ṣalaye itumọ ohun to sọ.

Ninu atẹjade kan fo ti lede, o ni owe loun fi ọrọ naa pa, ati pe oun kii ṣe oni jagidijagan.

Atẹjade naa sọ pe sẹnetọr ọhun ko sọ pe ki awọn ọmọ ẹgbẹ APC ṣekupa awọn alatilẹyin Accord, amọ nnkan to sọ ni pe ki wọn fi "ibo pa wọn."

Lẹyin naa lo rọ awọn eeyan ki wọn ma ṣi oun gbọ ki wọn ma si ṣi ọrọ ti oun sọ tumọ lọna ati mọọmọ da wahala silẹ nipinlẹ Osun.