You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Oyinlola ṣàtìlẹ́yìn fún Oyebamiji nínú ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Accord ní ó ti padà sínú èébì rẹ̀
Ni bayii to ku ọjọ perete ki eto idibo sipo gomina ipinlẹ Osun waye, gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Olagunsoye Oyinlola, ti jawọ kuro lẹyin oludije ninu ẹgbẹ oṣelu Allied Peoples Movement, APM, Adewale Adebayo, lati ṣatilẹyin fun Bola Oyebamiji ti ẹgbẹ oṣelu APC.
Oyinlola to jẹ korikosun gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde ti kọkọ sọ pe Adebayo loun wa lẹyin rẹ nitori ẹgbẹ oṣelu DPD ati Accord ko ni le taputu ninu idibo ọhun.
Nigba to n sọrọ nibi eto kan nile rẹ to wa lagbegbe Okuku, nibi ti akọwe ijọba lasiko rẹ lori oye, Fatai Akinbade ati igbakeji PDP lẹkun iwọ oorun tẹlẹ, Tajudeen Oladipo wa, awọn mẹtẹta sọ pe sọ pe oludije naa lawọn dibo fun.
Oyinlola sọ pe igun ẹgbẹ PDP ti Turaki n dari rẹ ni ajọṣepọ pẹlu APM, o fi kun pe ajọṣepọ naa n waye ni ipinlẹ Osun.
Lẹyin naa lo gbe asia ẹgbẹ oṣelu APM le Adebayo lọwọ lati fi han pe oun ni wọn wa lẹyin rẹ.
Wayi o, lẹyin ọjọ diẹ to gbe igbẹsẹ yii lo tun yi ohun pada lati ṣatilẹyin fun oludije ninu ẹgbẹ oṣelu APC.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ lọjọ Aiku, Oyinlola ni oun gbe igbesẹ naa fun anfani awọn eeyan ipinlẹ Osun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, inu ẹgbẹ oṣelu PDP ni oun atawọn ẹmẹwa oun ṣi wa amọ idagbasoke ipinlẹ Osun ṣe pataki ju ifẹ inu ẹgbẹ lọ.
Lori eredi to fi to sẹyin Oyebamiji bayii, o ni eredi igbesẹ naa ko ṣeyin pe gomina Ademola Adeleke kọ lati ko awọn eeyan mọra ninu ijọba rẹ.
Lẹyin naa lo rọ oludije naa pe ko ko awọn eeyan mọra ko ma si ṣe idẹyẹsi ẹnikẹni gẹgẹ bii gomina ki gbogbo ọmọ ipinlẹ Osun si le pe ni tiwọn.
Oyinlola ti pada sinu eebi rẹ – Accord fi ohun ranṣẹ
Nigba to n sọrọ lori igbesẹ Oyinlola naa, ẹgbẹ oṣelu Accord ipinlẹ Osun ti fi oko ọrọ ranṣẹ si.
Gẹgẹ bi Accord sẹ sọ, Oyinlola kan pada sinu eebi rẹ lasan ni, ati pe ko ni ipa kankan ti igbesẹ rẹ yoo ko ninu esi idibo naa.
Accord sọ pe Oyinlola ṣiṣẹ tako Adeleke ninu eto idibo to waye lọdun 2018 ati ọdun 2022, nitori naa, ko ni tu irun kankan lara awọn to ba tun ṣiṣẹ tako Adeleke ninu eto idibo ọdun yii.
Ẹgbẹ naa sọ siwaju si pe Oyinlola atawọn ẹmẹwa rẹ ko lẹnu ni ijọba ibilẹ wọn lati da ibo Adeleke ru.
Wọn pari ọrọ naa pẹlu arọwa si awọn eeyan ipinlẹ Osun pe ki wọn ma sọ ireti wọn ni ninu Adeleke, ki wọn si jade witiwiti lati dibo fun un.