Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ademola Adeleke, olùdíje sípò gómìnà ẹ́gbẹ́ òṣèlú Accord l'Osun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Bi eto idibo gomina ipinlẹ Osun ṣe n sunmọ etile, ti eto ipolongo yoo si wa si opin lọsẹ yii, bẹẹ ni BBC Yoruba ko dẹkun lati maa mu iroyin ọlọkan-o-jọkan nipa eto idibo gomina naa wa fun un yin lati maa mọ bi nnkan ṣe n lọ.

Ọjọ Abamẹta ọsẹ yii tii ṣe ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 ni eto idibo gomina ipinlẹ Osun yoo waye, ti gbogbo agbaye si ti n woye bi eto idibo naa yoo ṣe lọ.

Lara awọn igbesẹ BBC Yoruba ni lati mu ẹkunrẹrẹ nipa oludije kọọkan sipo gomina wa fun gbogbo awọn to n fẹ mọ bi nnkan ṣe n lọ.

Lonii, Gomina ipinlẹ naa, Sẹnetọ Ademola Adeleke, ẹni toun naa jẹ ọkan lara awọn oludije, to fi fẹẹ pada sipo naa fun igbakeji labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Accord la mu diẹ lara itan igbesi aye rẹ wa fun un yin.

Ọjọ́ ìbí

Ọjọ kẹtala, oṣu Karun-un, ọdun 1960 ni wọn bi Ademola Nurudeen Jackson Adeleke sinu idile gbajugbaja agba oloṣelu nni, Sẹnetọ Raji Ayoola Adeleke ati iya rẹ, Nnenna Esther Adeleke siluu Ede nipinlẹ Osun.

Ọmọ ilu Ede ni baba rẹ, nigba ti mama rẹ jẹ ọmọ agbegbe Akwete nijọoba ibilẹ Ila-Oorun Ukwa, ipinlẹ Abia.

Eto Ẹkọ

Ile-ẹkọ alakọbẹrẹ Methodist to wa ni Surulere nipinlẹ Eko ni Adeleke ti bẹrẹ eto ẹkọ rẹ, ṣugbọn nigba to ya, lo pada si ipinlẹ Oyo atijọ, nibi to ti tẹsiwaju nile-ẹkọ alakọbẹrẹ Nawair-Ud-Deen to wa niluu Ikire.

Lẹyin eyi ni Adeleke tẹsiwaju nile-ẹkọ girama ti Seventh Day Adventist to wa niluu Ede, iyẹn nipinlẹ Oyo atijọ. Ibẹ lo tun ti tẹsiwaju ile-ẹkọ girama ni 'Ede Muslim Grammar School', Ede, ibẹ lo si ti pari ẹkọ girama rẹ.

Gbara ti Adeleke ti pari ni girama, lo ti lọ silẹ Amẹrika lati tẹsiwaju ẹkọ rẹ, nibi ti awọn ẹgbọn rẹ wa, ti wọn n kẹkọọ.

Fasiti Jacksonville State to wa niluu Alabama ni Adeleke lọ nilẹ Amẹrika, nibi to ti kẹkọọ nipa ẹkọ nipa eto oṣelu.

Ọdun 2021 ni Adeleke tun pada sile-ẹkọ Atlanta Metropolitan State College nilẹ Amẹrika, to si kẹkọọgboye nipa ọrọ ofin ti 'Idajọ Ọdaran' (Criminal Justice).

Iṣẹ́ òòjọ́ àti Okòòwò

Ogbontarigi ni Adeleke nidi okoowo ati alabojuto. O ṣiṣẹ gẹgẹ bi alakoso agba nileeṣẹ Guinness Nigeria Plc laaarin ọdun 1992 si 1999.

Adeleke ni alakoso ileeṣẹ Pacific Holdings Limited laaarin ọdun 2001 si 2016. Ṣaaju ko too darapọ mọ ileeṣẹ yii, lo ti ṣiṣẹ pẹlu Quicksilver Courier Company niluu Atlanta, Georgia, nilẹ Amẹrika, iyẹn laaarin ọdun 1985 si 1989.

Bakan naa lo tun ṣiṣẹ pẹlu Origin International LLC, niluu Atlanta, Georgia, US, to si jẹ gẹgẹ bi igbakeji aarẹ ileeṣẹ ọhun laaarin ọdun 1990 si 1994.

Òṣèlú

Ọdun 2001 ni Ademola Adeleke darapọ mọ oṣelu pẹlu ẹgbọn rẹ, Sẹnetọ Isiaka Adeleke to doloogbe ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2017.

Lẹyin iku ẹgbọn rẹ, Isiaka, Ademola Adeleke gbe apoti lati du ipo sẹnetọ to ṣoju ẹkun Iwọ-Oorun Osun, to si jawe olubori lọdun 2017 labẹ asia ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party.

Inu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress ni Adeleke wa tẹlẹ, ko to lọ darapọ mọ PDP ninu oṣu Kẹrin, ọdun 2017 naa.

Lẹyin naa, Ademola Adeleke gbe apoti ipo gomina, to si wọle idibo abẹle lọjọ kẹtalelogun, oṣu Keje, ọdun 2018, lẹyin to bori akẹgbẹ rẹ, Akin Ogunbiyi pẹlu ibo meje.

Inu oṣu Kejila, ọdun 2025 ni Adeleke darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu Accord, nibi to gba jade lati du ipo gomina fun saa keji.

Ipò Gómìnà

Sẹnetọ Adeleke ko deedee di gomina ipinlẹ Osun lojiji. Inu ẹgbẹ oṣelu PDP ni Adeleke wa to fi du ipo gomina lọdun 2018.

Oun pẹlu awọn agba oloṣelu bii Alaaji Gboyega Oyetola lẹgbẹ oṣelu APC ati Iyiola Omisore ninu ẹgbẹ SDP ni wọn jọ du ipo gomina lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan, ọdun 2018.

Ajọ eleto idibo INEC pada kede pe idibo naa ko tii kẹsẹ jare, ati pe wọn yoo tun ibo di lawọn agbegbe kan, iyẹn lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kẹsan, ọdun 2018.

Lẹyin atundi ibo naa ni ajọ INEC kede Oyetola gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ibo naa, ṣugbọn ti Adeleke pada tako o nile-ẹjọ to si fẹsun kan pe iditẹ ni ọrọ eto idibo ọhun.

Lọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2019 ni ile-ẹjọ Tribunal to n gbọ ẹjọ idibo kede Adeleke gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ninu idibo naa, ṣugbọn ṣa, lọjọ Karun-un, oṣu Keje, ọdun 2019 nile-ẹjọ agba ilẹ Naijiria tun kede Oyetola gẹgẹ bi ẹni to jawe olubori ibo gomina, ọdun 2018.

Sẹnetọ Adeleke labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP pada du ipo naa lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun 2022, to si jawe olubori, nigba to fi ẹyin gomina to wa nipo nigba naa, Gboyega Oyetola gbolẹ pẹlu ibo 402,979 si 375,077.

Ijọba ibilẹ mẹtadinlogun bii Olorunda, Ede South, Orolu, Osogbo, Odo Otin, Ifelodun, Boluwaduro, Atakumosa, ati Ila ni Adeleke ti bori idibo ọhun.

Ìwé-Ẹ̀rí

Lasiko ti Ademola Adeleke du ipo gomina, ni wọn fẹsun kan an pe o lo ayederu iwe-ẹri ti idanwọ WAEC ati ti ile-ẹkọ girama.

Ile-ẹjọ giga tiluu Osogbo ni wọn gbe Adeleke lọ, nibi ti wọn ti fẹsun kan an wi pe ayederu lo fi silẹ fun INEC. Wọn ni ogunjọ, oṣu Keje, ọdun 1988 lo wa lori iwe ẹri ile-ẹkọ Ede Muslim Grammar School ti Adeleke fi silẹ, ti wọn ti sọ pe wọn ko tii da ipinlẹ Osun silẹ lọdun naa.

Bakan naa ni wọn sọ pe eto idanwo ti Adeleke loun ṣe lọdun 1981 ni wọn ko tii bẹrẹ, ati pe ọga ile-ẹkọ to buwọ lu iwe ẹri Adeleke lọdun 1988 naa lo tun buwọ lu ti ọdun 2018.

Agbẹjọro Adeleke lo pada tako ẹsun naa wi pe ko lẹsẹ nilẹ, ati pe ki ile-ẹjọ da ọjọ oun nu, ti ile-ẹjọ si pada ṣe bẹẹ wi pe wọn ko le fidi rẹ mulẹ.