Orí kó arìnrìnàjò 17 yọ nínú ìjàmbá ọkọ̀ l'Osun

Published

Ileeṣẹ to n risi irinna FRSC nipinlẹ Osun ni ori ko arinrin ajo metadinlogun yọ ninu ijamba ọkọ to waye ni opopona Ilesa si Ipetu lọjọ Eti.

Ọga agba fun ileesẹ ọhun nipinlẹ Osun, Paul Okpe lo kede isẹlẹ naa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ rẹ, Agnes Ogungbemi, fi ransẹ si awọn akọroyin lọjọ Ẹti niluu Osogbo.

Okpe ni ijamba naa waye ni ago mọkanla ni agbegbe ọmọ Ijesa lẹyin ti ọkọ ayọkẹlẹ elero meji kọlu arawọn.

“A gba ipe pe ijamba ọkọ waye ni isẹju diẹ kọja ago mọkanla ni opopona Ilesa si Ipetu.

“ Ọkọ ayọkẹlẹ Nissan alawọ iwe pẹlu nọmba idanimọ FG 154 K20 kọlu ọkọ ayọkẹlẹ Vannet Nissan funfun pẹlu nọmba idanimọ KSF 143 DE.

“Ijamba naa ni agbara sugbọn a tete yọọ awọn eeyan kuro loju popo lati ma fa sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ.”

O ni ọkunrin meji mejila ati obinrin kan lo wa ninu awọn ọkọ naa, ti mẹta si farapa.

“Ọkunrin meji ati obinrin kan farapa, ti a si ti gbe wọn lọ si ile wosann Wesley Guild ni Ilesa fun itọju  ni ẹsẹkẹsẹ.

“Isẹlẹ ijamba naa waye nitori ere asapajude awọn awakọ naa."

Okpe ni FRSC ko ni dẹkun lati fi iya jẹ awọn awakọ to ba kọ lati tẹle ofin irina loju awọn opopona nipinlẹ Osun.