N kò le fẹ́ ọkùnrin tó lówó, n kò sì le bá ọkùnrin jìyà tàbí ṣe ìyàwó kejì àbí ìkẹta - Eyiyemi Afolayan

N kò le fẹ́ ọkùnrin tó lówó, n kò sì le bá ọkùnrin jìyà tàbí ṣe ìyàwó kejì àbí ìkẹta - Eyiyemi Afolayan
Published

Lara awọn gbajumọ osere tiata to jẹ ọdọ to sẹsẹ n dide lẹ lẹnu isẹ naa ni Eyiyemi Afolayan.

Omidan naa jẹ ọmọ gbajumọ osere tiata, Kunle Afolayan, to si ti kopa ninu awọn sinima ti baba rẹ maa n gbe jade.

A si le sọ pe inu ẹjẹ Eyiyemi ni ere tiata wa nitori baba to bi baba rẹ gan, Adeyemi Afolaya, ti a tun mọ si Ade Love jẹ gbajumọ osere nigba aye rẹ.

Ko tan sibẹ awọn ẹgbọn ati aburo baba rẹ naa, bii Moji Afolayan, Gabriel Afolayan ati Aremu Afolayan gan jẹ gbajugbaja osere nilẹ Yoruba.

BBC News Yoruba wa ba Eyiyemi Afolayan sọrọ nipa igbe aye rẹ, awọn obi rẹ ati nipa isẹ tiata, to si sọ ero rẹ.

"Jijẹ gbajumọ osere maa n mu ki eeyan sọrase amọ emi kii dibọn lati wu ẹnikẹni lori nipa iwa mi, ohun to ba wu mi, ni maa se"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, Eyiyemi Afolayan salaye awọn ipa ti jijẹ gbajumọ osere n ko lori igbesi aye rẹ.

"Jijẹ gbajumọ osere ni awọn anfaani to n fun mi tori ti mo ba lọ sibi kan, awọn eeyan to fẹran isẹ mi maa n ki mi daadaa, eyi si maa n wu mi lori.

Ipenija to wa nidi jijẹ gbajumọ osere ni pe eeyan ni lati sọra nipa awọn nnkan to ba n se boya lori ayelujara ni tabi nita gbangba.

Idi ni pe ohun ti eeyan ba sọ lori ayelujara ni wọn le fun ni itumọ miran.

Fun apẹrẹ, ti mo ba wọ ọkada nisinyi, tabi wọ mọto ero, wọn le ni sebi o lowo lọwọ, sebi gbajumọ osere ni, ki lo n se ninu ọkọ ero?

Nitori eyi, jijẹ gbajumọ osere kii jẹ kawọn osere se bo se wu wọn tori a ni orukọ ati ipo ti a fẹ daabo bo.

Amọ emi ni temi o, maa se ohun ti mo fẹ se, emi kii tiraka lati dibọn fun ẹnikẹni nipa iwa mi."

"Bi baba mi se nifẹ lati fẹ iyawo pupọ ko ta mi lara rara, ẹbi wa yoo fi gbooro si ni, a si dijọ tọ awọn ọmọ to ba bi ni"

Bakan naa ni Eyiyemi Afolayan tun sọrọ nipa ero rẹ si igbeyawo iya ati baba rẹ to ti fori sanpọn.

"Lootọ ni baba mi sọ pe oun maa fẹ iyawo pupọ, amọ eyi ko ta mi lara rara tori agbalagba ni, o si mọ ohun to fẹ fun ara rẹ.

Awa ọmọ ti wọn bi naa ti dagba, ti a si maa gbe igbe aye to wu wa, ti a si ni idile tiwa naa.

Nitori naa, ti baba mi ba ni oun fẹ fẹ iywao meji si mẹta, ko si wahala, ẹbi wa n gbooro si ni.

A maa dijọ tọ awọn ọmọ ti wọn ba bi ni, awọn ni wọn mọ idi ti wọn se sọ bẹẹ amọ eyi ko ni jẹ ki wọn da wa, eyi kii se isoro mi.

Pe mama mi ati baba mi ko gbe papọ bii tọkọtaya ko fi bẹẹ nipa lori awa ọmọ wọn tori inu ile ti wọn ti n fi ifẹ lo la dagba si.

Agbalagba si lawọn mejeeji, bi wọn ba ni awọn ko se papọ mọ, awọn ni wọn ri ara wọn, ti wọn si ni awọn fẹ maa fẹra wọn, ki wọn to bi wa.

Awọn naa si tun ni wọn ri ara wọn, ti wọn ni awọn ko fẹ se mọ, kii se pe baba mi maa n sọ nnkan buruku nipa iya mi fun mi.

Tabi pe iya mi n sọ nnkan buruku nipa baba mi si mi, ẹbi kan soso si ni wa lai naani pe awọn mejjeji ko gbe papọ."

"Abolanle ni mi, wọn bi mi sinu ọla ni, ọkọ ti mo ba fẹ gbọdọ ni nnkan to n se funra rẹ tori emi ko le maa bọ ọkunrin"

Eyiyemi Afolayan, ninu ọrọ rẹ fidi rẹ mulẹ pe oun ko le ba se iyawo keji tabi ikẹta fun ọkunrin kankan.

"N ko le se iyawo keji tabi ikẹta fun ọkunrin kankan, kii se pe mo n jowu ni amọ ile olorogun maa n fa wahala to pọ.

Emi ko le ba ọkunrin pilẹ ọrọ nitori pe awọn ọkunrin maa n ya alaimoore lẹẹkọkan.

Amọ ti mo ba fẹ ọkunrin ti ko lowo lọwọ tabi ti ko ni ọla, o maa duro ti mi, a si jẹ olotitọ si mi, o si maa gbaju mọ emi nikan.

Kii se pe o nifẹ mi lo se n maa duro ti mi amọ tori pe ko ni owo yẹn lati maa se sina kiri sugbọn to ba ti ni owo yẹn, sina maa bẹrẹ."

Gbajumọ osere tiata naa wa kesi awọn akẹẹgbẹ rẹ lagbo tiata lati maa pe fun ere sise nitori ko si ipa ti oun ko le ko ninu ere tiaata.

"Abolanle ni mi, wọn bi mi sinu ọla ni, ọkọ ti mo ba fẹ gbọdọ ni nnkan to n se funra rẹ tori emi ko le maa bọ ọkunrin amọ mo le seranwọ ati atilẹyin fun.

Mo fẹ ki awọn alakoso sinima mọ anfaani mi ninu isẹ wọn, ki wọn si maa lo mi ninu sinima wọn.

Ki wọn mase lero pe tori pe baba mi jẹ Kunle Afolayan, eyi yoo jẹ anfaani nla fun mi, rara o.

Emi funra mi ni ẹbun ere tiata, mo si le ko eyikeyi ipa ninu ere tiata."