Oluwo fi ohùn ránṣẹ́ sí Baba Ifayemi Elebuibon àtàwọn babaláwo pé ó yẹ kí wọ́n lè kojú ajínigbé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti fo oko ọrọ ranṣẹ si awọn babalawo nilẹ Yoruba latari ijinigbe to ti di tọrọkọbọ.

Nigba to n sọrọ ninu aafin rẹ, Oluwo ni bo tilẹ jẹ pe oun ko gbagbọ ninu oogun ilẹ Yoruba, asiko ti to fun awọn oloogun ati babalawo ilẹ Yoruba lati fi agbara wọn koju igbesunmọmi.

Oluwo lo sọ ọrọ naa lẹyin ti awọn olukọ ati akẹkọọ ti awọn agbesunmọmi ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo ti lo oṣu oṣu kan lakata wọn.

Ori ade naa sọ pe oun ti ṣetan lati ṣe atilẹyin owo fun awọn oloogun nilẹ Yoruba ki wọn wọ inu igbo naa lọ lati doola awọn ọmọ naa.

"Baba Yemi Elebuibon atawọn babalawo gbọdọ dide"

Oluwo sọ pe gbogbo awọn alfaa, pasitọ abi babalawo ti wọn sọ pe agbara wa lọwọ wọn ko nilo lati maa woju ijọba ki wọn to tan iṣoro naa.

O ni "Iwọ babalawo ti o loogun, paapaa awọn babalawo ti wọn ma n ni awọn loogun owo, awọn yoo sọ oke di ilẹ, awọn yoo ṣẹ epe.

"Gbogbo nnkan ti ẹ ni ẹ n ṣe, o ti delẹ bayii o, awọn ọmọ wa ni wọn wa ninu igbo Esinele, ni Ogbomoso, ni ijọba ibilẹ Oriire.

"Ti ẹ ko ba lowo lati ṣe nnkan, ẹ wa ba mi, mo maa gbe owo fun yin.

"Paapaa baba Ifayemi Elebuibon, Araba awo, gbogbo ẹyin Araba patapata.

"O ṣe jẹ wipe awa ọmọ Yoruba nikan ni ẹ oo ma halẹ mọ, ogun lo de yii o."

Ọba Oluwo sọ pe o yẹ ki gbogbo awọn babalawo le ṣi'gun lọ sinu igbo naa pẹlu afẹẹri lati lọ doola awọn ọmọ ati olukọ to wa lakata ajinigbe silẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn babalawo naa ko nifẹ ọmọ Naijiria ti wọn ba kọ lati ṣe bẹẹ.

O sọ pe "Ki baba Ifayemi Elebuibon, ati gbogbo awọn babalawo, oniṣegun, adahunṣe, ki gbogbo wọn ki ẹ dide.

"Awọn ọba ti wọn ni awọn ni oogun ati gbogbo ẹ, isinyii lo yẹ ki ẹ wa ninu yara yin ki ẹ paṣẹ."

Oluwo ni ti awọn babalawo ba kọ lati ṣe bẹẹ, oun ko gbọdọ pe babalawo kankan n halẹ mọ ẹnikankan mọ nilẹ Yoruba.

O pari ọrọ rẹ pe oju ti gbogbo awọn olori ẹlẹsin ti wọn ko ba le lo agbara wọn lati tu awọn eeyan silẹ.