Elebuibon fún Oluwo lésì, ní àwọn ọba ni kò ṣe ojúṣe wọn mọ́ tí ètò ààbò fi mẹ́hẹ

Ifayemi Elebuibon n wo ọọkan , o mu irọkẹ ifa dani

Oríṣun àwòrán, Others

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Araba ilu Osogbo, Ifayemi Elebuibon ti fesi si ọrọ ti Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi fi ranṣẹ si I atawọn Babalawo mii nilẹ Yoruba.

Baba Elebuibon ni ohun ti Oluwo n beere fun ko pọju amọ ọna to n gbegba ni ko tọna rara.

Ṣaaju ni Oluwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti fi oko ọrọ ranṣẹ si awọn babalawo nilẹ Yoruba latari ijinigbe to ti di tọrọkọbọ.

Oluwo ni bi o tilẹ jẹ pe oun ko gbagbọ ninu oogun ilẹ Yoruba, asiko ti to fun awọn oloogun ati babalawo ilẹ Yoruba lati fi agbara wọn koju igbeṣumọmi.

Oluwo sọ pe gbogbo awọn alfaa, pasitọ abi babalawo ti wọn sọ pe agbara wa lọwọ wọn ko nilo lati maa woju ijọba ki wọn to tan iṣoro naa.

Amọ agba Babalawo naa ti wa fesi bayii, to si ni ọtọ ni awọn to yẹ ki Oluwo doju ọrọ rẹ kọ.

Elebuibon ni iṣẹ Babalawo kọ ni lati lọ soju ogun, pe ohun ti Babalawo wa fun ni lati maa ṣe iwure fun awọn to b awa loju ogun.

O ni oun to ba mu Babalawo lọ soju ogun, a jẹ pe o fẹ lọ ṣeranwọ fun ẹnikan loju ogun naa tabi boya Ifa lo dari rẹ lati lọ.

"Awọn to maa n jagun ni Eesa, Akọgun, Balogun, babalawo kii bawọn jagun, o ni ojuṣe tirẹ.

"Gbogbo igba ni awọn Babalawo n sure, ṣe etutu ni ọjọ marun-un marun-un ki ilu le dara."

Araba naa ni ọwọ awọn Ọba alaye ilu kọọkan ni iṣẹ wa si ju bayii lati le ri daju pe aabo to peye w ani ilu kọọkan wọn.

O ni ọpọ awọn ọba alaye ni ko mọ ibi ti "ogun o jalu" wọn wa to si jẹ pe o yẹ ki wọn maa bọ lati le dena irufẹ awọn iwa ko tọ ni ilu wọn.

O fi kun pe awọn ọba nilo lati mojuto awọn ojubọ naa lati le ma jẹ ẹ ki ogun wọ ilu wọn.

"Ọpọ awọn Ọba lo n gbe nigbekun nisin-in nitori awọn nnkan alalẹ ni wọn fi ọlaju ati ẹsin ko danu.

"Gbogbo nnkan alalẹ lo yẹ ka mojuto, ka maa pe wọn, ka maa ṣe ohun ti wọn ba fẹ, yoo si maa da aabo bo wa."

Oluwo fi ohùn ránṣẹ́ sí Baba Ifayemi Elebuibon àtàwọn babaláwo pé ó yẹ kí wọ́n lè kojú ajínigbé

Oluwo ilu Iwo lori itẹ rẹ

Oríṣun àwòrán, Oluwo ilu Iwo

Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi ti fo oko ọrọ ranṣẹ si awọn babalawo nilẹ Yoruba latari ijinigbe to ti di tọrọkọbọ.

Nigba to n sọrọ ninu aafin rẹ, Oluwo ni bo tilẹ jẹ pe oun ko gbagbọ ninu oogun ilẹ Yoruba, asiko ti to fun awọn oloogun ati babalawo ilẹ Yoruba lati fi agbara wọn koju igbesunmọmi.

Oluwo lo sọ ọrọ naa lẹyin ti awọn olukọ ati akẹkọọ ti awọn agbesunmọmi ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire, nipinlẹ Oyo ti lo oṣu oṣu kan lakata wọn.

Ori ade naa sọ pe oun ti ṣetan lati ṣe atilẹyin owo fun awọn oloogun nilẹ Yoruba ki wọn wọ inu igbo naa lọ lati doola awọn ọmọ naa.

"Baba Yemi Elebuibon atawọn babalawo gbọdọ dide"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Oluwo sọ pe gbogbo awọn alfaa, pasitọ abi babalawo ti wọn sọ pe agbara wa lọwọ wọn ko nilo lati maa woju ijọba ki wọn to tan iṣoro naa.

O ni "Iwọ babalawo ti o loogun, paapaa awọn babalawo ti wọn ma n ni awọn loogun owo, awọn yoo sọ oke di ilẹ, awọn yoo ṣẹ epe.

"Gbogbo nnkan ti ẹ ni ẹ n ṣe, o ti delẹ bayii o, awọn ọmọ wa ni wọn wa ninu igbo Esinele, ni Ogbomoso, ni ijọba ibilẹ Oriire.

"Ti ẹ ko ba lowo lati ṣe nnkan, ẹ wa ba mi, mo maa gbe owo fun yin.

"Paapaa baba Ifayemi Elebuibon, Araba awo, gbogbo ẹyin Araba patapata.

"O ṣe jẹ wipe awa ọmọ Yoruba nikan ni ẹ oo ma halẹ mọ, ogun lo de yii o."

Ọba Oluwo sọ pe o yẹ ki gbogbo awọn babalawo le ṣi'gun lọ sinu igbo naa pẹlu afẹẹri lati lọ doola awọn ọmọ ati olukọ to wa lakata ajinigbe silẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn babalawo naa ko nifẹ ọmọ Naijiria ti wọn ba kọ lati ṣe bẹẹ.

O sọ pe "Ki baba Ifayemi Elebuibon, ati gbogbo awọn babalawo, oniṣegun, adahunṣe, ki gbogbo wọn ki ẹ dide.

"Awọn ọba ti wọn ni awọn ni oogun ati gbogbo ẹ, isinyii lo yẹ ki ẹ wa ninu yara yin ki ẹ paṣẹ."

Oluwo ni ti awọn babalawo ba kọ lati ṣe bẹẹ, oun ko gbọdọ pe babalawo kankan n halẹ mọ ẹnikankan mọ nilẹ Yoruba.

O pari ọrọ rẹ pe oju ti gbogbo awọn olori ẹlẹsin ti wọn ko ba le lo agbara wọn lati tu awọn eeyan silẹ.