You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ìjọba àpapọ̀ sọ̀kò ọ̀rọ̀ padà sí Emir Sanusi, bó ṣe ní òun kò ní ran Tinubu lọ́wọ́ láti wá ojútùú sọ́rọ̀ aje
Emir ti ilu Kano, Muhammadu Sanusi II ti kede pe oun ko setan lati ran ijọba orilẹede Naijiria lọwọ lọna lati le wa ojutuu si kudiẹkudiẹ to de ba ọrọ aje.
Sanusi sọ eyi niluu Eko níbi ayẹyẹ Fawehinmism, nibi to ti bu ẹnu atẹlu ìṣejọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu ati ọna ti ijọba n lo lati koju kudiẹkudiẹ eto ọrọ aje.
Emir ni oun gbe igbesẹ yii nítori inu oun ko dun si bi ijọba ṣe n se awọn araalu, eyi to ni ko tẹ oun lọrun.
"Ṣe ki ma parọ, mo duro siwaju yin lonii pe gbogbo ohun nnkan yii ni ko yẹ ko waye, bi o se n lọ ati ọna lati bọ ninu rẹ, mi o setan lati sọ ohunkóhun.
"Mo ti pinnu lati ma sọ ọrọ tabi salaye nípa ọrọ aje, ti mo ba sọ ọrọ, yoo se iranlọwọ fun ijọba, ti mi o si fẹ ṣe iranlọwọ fun ijọba."
Ìjọba Tinubu ko nilo iranlọwọ Sanusi - ijọba apapọ
Ijọba apapọ orilẹede Naijiria ti wa fesi fun Emir Kano, Muhammadu Sanusi II lẹyin to ni oun ó setan lati ran ijọba orilẹede Naijiria lọwọ.
Ìjọba apapọ labẹ isakoso Aarẹ Bola Ahmed Tinubu jẹ ko di mímọ pe, oun ko fi igba kan beere iranlọwọ lọwọ Emir Sanusi.
Eyi lo wa ninu atẹjade ti minisita fun iroyin ati idanilẹkọ, Mohammed Idris buwọlu lati fesi pada fun Emir Kano, Muhammadu Sanusi II.
"A ko nilo ibuwọlu Sanusi lori ìṣejọba wa.
"Ọrọ ti Emir Muhammadu Sanusi II sọ nípa ìṣejọba Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori ọrọ aje ni ko boju mu paapaa lori ipinnu rẹ lati ma ran ijọba orilẹede Naijiria lọwọ.
"Ni akọkọ, a mọ pe gbogbo ọmọ Naijiria lo ni anfani lati sọ ohun ti wọn ro sita sugbọn ohun iyalẹnu ni eyi jẹ pe ọrọ bayii n jade lẹnu olori ilu, to si n wi eyi jade nitori oun to ro lọkan ara rẹ.
"Asiko ti Naijiria wa ni a nilo lati gbe awọn akọ igbesẹ ti yoo gbe ogun tí iwa ibajẹ.
"Ayipada ti n de ba wa, ko rọrun sugbọn ọjọ ọlá dara."