Femi Falana: Ẹ yé fojú ẹ̀sín wo àwọn aláwo, gbogbo ènìyàn ló lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wù ú lábẹ́ òfin - Femi Falana

Published

Ogbontarigi Amofin lorileede Naijiria, Amofin Fẹmi Falana ti jẹ ko di mimọ pe gbogbo eeyan lo lẹtọọ lati ṣe ẹsin to ba wuu labẹ ofin, paapaa awọn Onifa to fi mọ Babalawo.

Oni, ọjọ Abamẹta, Satide tii ṣe ọjọ kẹsan-an, oṣu kẹrin, ọdun 2022 ni Amofin Falana sọrọ yii niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, nibi ifilọlẹ ẹgbẹ Ijọ awọn Onifa niluu Ẹgba, nibi ti gbogbo awọn Babalawo kaakiri ilu Abẹokuta ti peju-pesẹ.

Amofin Falana sọ pe ninu abala kejidinlogoji iwe ofin Naijiria, o wa nibẹ wi pe onikaluku lo lẹtọọ labẹ ofin lati ṣe oniruuru ẹsin to ba wuu lai si idiwọ kankan nibẹ.

Bakan naa lo tun bu ẹnu atẹ lu bi ile ẹjọ kan nipinlẹ Kano ṣe ju ọmọ ọkunrin kan, Mubarak Bala sẹwọn ọdun mẹrinlelogun nitori ainigbagbọ Ọlọrun, to si ni ko yẹ ki iru nnkan bẹẹ maa ṣẹlẹ.

O wa gba gbogbo awọn Babalawo lamọran lati dide ji giri, ki wọn si wa gbogbo ọn ati wọn yoo fi tun orukọ wọn t'awọn eeyan buruku ti bajẹ nipa oogun owo ṣiṣe, to si ni titẹ ipa mọ iṣẹ nikan ni oogun owo to daju, kii ṣe nipa pipaayan lati fi ṣoogun owo.

Nibi eto yii ni wọn ti fun gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ naa ni iwe ẹri ati kaadi idanimọ gẹgẹ bi ojulowo ọmọ ẹgbẹ, ti wọn si tun yan igbimọ ẹlẹni meje, iyẹn Task Force ti yoo ṣawari awọn to jẹ ayederu Babalawo, ati igbimọ ẹlẹni mejilelogun, Disciplinary Committee, lati fi iya to tọ jẹ awọn oniwa ibajẹ labẹ ofin.

Ninu ọrọ Amofin Fẹmi Falana, o sọ pe "Ẹgbẹ yin lẹtọọ labẹ ofin, ẹyin ọmọ ẹgbẹ, gbogbo yin lẹ lẹtọọ labẹ ofin lati pejọ ṣe Ifa n'ipinlẹ Ogun ati ni gbogbo Naijiria. Bi awọn Kritẹẹni ṣe wa, lawọn Musulumi naa wa, awọn Babalawo naa wa. Gbogbo yin lẹ lẹtọọ labẹ ofin lati ṣe nnkan ti ẹ fẹẹ ṣe, lati ṣe ipade, lati d'Ifa f'awọn to ba n wa.

Ẹ tete tun orukọ ti awọn ọbayejẹ ti fẹ bajẹ ṣe

"Ọpọlọpọ lo wa n'ijọba, to jẹ pe ẹsin mẹtẹẹta ni wọn n ṣe. Awọn to wa n'ijọba ni wọn n gba agbara kaakiri, wọn n lọ sile Babalawo. Ẹsin ti a n ṣe ko ni ki a ma beere aabo, ti a ko ba ti fi pa ọmọ ẹnikankan. Maa bẹ yin, iṣẹ wa lọwọ yin. Awọn Babalawo ti gba orukọ, mi o ni sọ pe orukọ buruku.

"Bi ẹ ba mu awọn danadana, ajinigbe tabi ajinigbe, ti ẹ mu wọn de ile ẹjọ tabi lọdọ awọn ọlọpaa, ti ẹ wa ri onde tabi ifunpa lara wọn, wọn a sọ pe Babalawo lo ṣe e fun wọn ki ọwọ ọlọpaa ma ba a tẹ wọn. Awọn gbọmọgbọmọ tun n lo o lati fi ṣoogun owo, bi ẹ ba beere lọwọ awọn naa, wọn a sọ pe awọn ni Babalawo.

"Awọn kan a tiẹ tun ran awọn miran lati lọ paayan wa lati fi ṣoogun ki wọn ma ba a mu wọn. Babalawo naa ni wọn tun maa darukọ. Fun idi eyi, ẹ ni iṣẹ pupọ lati ṣe. Iṣẹ ti ẹ si maa ṣe fun ara yin ati fun ilu ni pe ẹgbẹ yin kii ṣe ẹgbẹ apaayan, kii ṣe ẹgbẹ awọn to n ṣe oogun owo. Ẹni to ba n tan ara rẹ jẹ lonii, to sọ pe o digba ti oun ba gba ẹjẹ eeyan ko to lowo, ẹni to yẹ ki wọn fi si ahamọ ni o, ko si foju ba ile-ẹjọ.

"Ẹ ma jẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ yin ṣe oogun f'awọn danadana, adigunjale, ajinigbe atawọn to n fẹ ṣe oogun owo, ko si ọna nibẹ. Iṣẹ ọwọ wa nikan lo le fun wa lowo. To ba jẹ pe oogun wa, ko sẹni ti yoo ṣiṣẹ o. Ọpọlọpọ ninu awọn to n ṣoogun owo, aṣọ pupa, aṣọ idọti ni wọn n wọ kaakiri. To ba jẹ pe lotitọ ni oogun owo wa, ki lo de ti wọn ko ṣee funra wọn. Ẹ ma jẹ ka maa tan ara wa mọ.

"Nitori naa, maa fẹ ki awọn ọmọ ẹgbẹ yin bẹrẹ iṣẹ gidigidi, ki orukọ yin ba a le dara. Igba yẹn ni ijọba ati awọn araalu maa fẹ bọwọ fun un yin. Inu mi dun nigba ti mo rii yin lonii wi pe ẹ wọ aṣọ gidi. Ẹ ma jẹ kawọn eeyan maa sọ pe awọn ti ko rikanṣekan ni wọn ṣiṣẹ Babalawo. Lati oni lọ, fun ẹyin ẹgbẹ Babalawo, ẹ jade sita lati sọ pe ẹgbẹ ti ẹ n ṣe ree. Bi ẹ ba ti n tẹle ofin nilẹ yii, ko si ibẹru kankan fun un yin.

"Labẹ ofin, ọmọ orileede Naijiria lẹtọọ lati sin Ọlọrun tabi Olodumare tabi Ifa. Laipẹ yii, wọn ju ẹnikan sẹwọn ọdun mẹrinlelogun nitori to sọ pe oun ko gba Ọlọrun gbọ, ko si iyẹn labẹ ofin, ko si ohun teeyan ko le ṣe labẹ ofin Naijiria. Abala kejidinlogoji sọ pe ọmọ Naijiria lẹtọọ lati ṣe ẹsin to ba wuu. Eyi to ṣẹlẹ ni Kano yẹn o ba ofin mu. O tun wa ninu iwe ofin Naijiria wi pe ijọba ko gbọdọ fọwọ si ẹsin kankan. Gbogbo wa la lẹtọọ lati sin Ọlọrun, yala Jesu, Anọbi tabi Ifa to ba wu wa labẹ ofin.

"Nitori naa, bi ijọba ba ṣe nnkan fun Kritẹẹni tabi Musulumi, wọn gbọdọ ṣee fun ẹyin naa, kii ṣe Naijiria nikan ni wọn ti n ṣe Babalawo. Nigba ti mo kọkọ lọ si Cuba, Ifa ni wọn n da nibẹ. Gbogbo awọn oriṣa to ti ku ni Naijiri ko ku ni Cuba ati Brazil. Nibẹ ni mo ti mọ pe Ifa maa n sọrọ, ti awọn eeyan si n gbagbọ. Gbogbo awọn Oriṣa yii ni wọn ṣe ere fun. Bi wọn ba n ṣe Oro ni Brazil, gbogbo ilu lo maa jade.

"Iṣẹ pọ lọwọ, iṣẹ ti mo si n fun un yin lonii ni pe ki ẹ lọ bẹrẹ bi ẹ ṣe maa tun orukọ yin ṣe, awọn eeyan buburu ti ba orukọ ẹgbẹ yin jẹ. Iṣẹ keji si ni pe, ẹ ni lati mọ pe kii ṣe Naijiria nikan ni wọn ti n ṣe ẹgbẹ yin, fun idi eyi, ẹ ni lati mọ ohun to n ṣẹlẹ lẹyin odi, iyẹn gbogbo awọn ibi ti wọn ti n da Ifa."

O yẹ ki ẹ maa fi iya jẹ àwọn to ba tako ofin iṣẹ yin - Ileeṣẹ Ọlọpaa ipinlẹ Ogun

Ki eeyan to le jẹ Babalawo, mo ro pe o gbọdọ kọ iṣẹ yẹn nibi kan, eeyan ko le ji lọjọ kan, ko sọ pe Babalawo loun, nitori pe eeyan ko le deede ji lọjọ kan lati sọ pe ọlọpaa loun, lai gba ile-ẹkọ ọlọpaa kankan kọja, aṣiri rẹ yoo tu nibi imura rẹ, ti a si maa n fi ọwọ ofin mu iru wọn. Iya to ba si yẹ ko jẹ iru ẹni bẹẹ ni ile-ẹjọ mmaa fi jẹ ẹ.

Bi awa ba le maa mu awọn to jẹ ayederu ọlọpaa, ko si ohun to da awọn Babalawo duro lati maa fi ọwọ ofin mu awọn to jẹ ayederu laaarin wọn. Ẹ pe ẹni to ba pe ara rẹ ni Babalawo lati beere ibi to ti kọ iṣẹ tiẹ, ati Babalawo to kọ ọ niṣẹ.

Awọn ayederu yii ni wọn n ba iṣẹ ti ẹ n ṣe jẹ fun un yin. Wọn mọ pe awọn ko lorukọ, ṣugbọn wọn n wa ọn alati ba orukọ olorukọ jẹ lasan ni. Laipẹ yii la ri awọn ọmọ keekeeke ti wọn lawọn fẹẹ ṣoogun owo, wọn lawọn rii lori ẹrọ ayelujara ti fesibuuku ni, a ṣe iwadii, a si ba bẹẹ lotitọ.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ti gbe kinni naa kuro lori fesibuuku, sibẹ bi aja wọn ba pe ogun ọdun laye, ẹran ogun ni gbogbo wọn nitori pe ọwọ yoo tẹ wọn. Iru awọn wọnyi ni wọn n ba iṣẹ Babalawo jẹ. Eeyan kan le fi gbogbo ẹnu sọ pe oun n bọ lati ọdọ Aafa oun ni, ki ẹlomiran sọ pe oun n bọ lati ọdọ Pasitọ oun ni, ẹ ko le ri eeyan ko sọ pe oun n bọ lati ọdọ Babalawo oun ni. Idi ni pe wọn ti n fi oju eeyan buruku wo gbogbo awọn to jẹ Babalawo ni, ko si yẹ ko ri bẹẹ.

Nitori ọlaju ati igbalode la ṣe da ẹgbẹ silẹ

Oludasilẹ ẹgbẹ naa, Oloye Ifadimeji Jegbe Biobaku nigba to n sọ idi to fi da ẹgbẹ naa silẹ labẹ ofin sọ pe "Ẹsin Ifa jẹ ẹsin to ti wa lati ọjọ to ti pẹ, ki wọn to o mu awọn ẹsin miran wa. Awọn to tẹ ilu Ẹgba do ti pese ara wọn silẹ nipa imọ lẹka ohun gbogbo.

"Awọn ti a ba iṣẹ yii lọwọ wọn ko ronu lati fi ẹgbẹ naa lelẹ labẹ ofin lọdọ ijọba nigba naa. Ṣugbọn awọn ọlaju to n ṣẹlẹ lakoko yii jẹ ka ronu nipa ọn ati ijọba le fi tẹwọ gba wa.

"Ọdun 2019 la fi orukọ yii silẹ labẹ ofin nipasẹ ẹni to jẹ Oluwo Onifa Ẹgba lonii, Oloye Ifagbeminiyi Atanda Baoku."

O wa rawọ ẹbẹ si gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa lati ṣiṣẹ takuntakun gbe orukọ ẹgbẹ naa larugẹ, ki ijọba le fun wọn ni ọlude ti wọn n beere fun lati ọjọ pipẹ.

Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ; Olubara tilu Ibara, Ọba Jacob Ọmọlade; Alawọ Erin ilu Ẹgba, Oloye Nurudeen Ọlalẹyẹ to jẹ aṣoju awọn Babalawo lọdọ ijọba ipinlẹ Ogun atawọn agba oloye lo wa nibi eto yii.

Awọn ọga agba ileeṣẹ eleto aabo So Safe, Sifu Difẹnsi, PCRC, Amọtẹkun ati aṣoju ijọba ipinlẹ Ogun lọrọ eto aabo ko gbẹyin nibi eto naa.