You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Coronavirus in Nigeria: A ti rań ọgọ́ta dókítà sí pápákọ̀ òfúrufú láti ṣàyẹ̀wò àwọn tó ń wọlé - Ìjọba Eko, kwara
Awọn ijọba ipinlẹ Iwọ oorun guusu Naijiria ti sọ pe gbogbo eto lo ti wa nilẹ ki arun Coronavirus ma ba tan kalẹ ju boṣeyẹ lọ.
Kọmiṣọna fun ọrọ to n lọ nipinlẹ nipinlẹ Eko, Gbenga Omotoso sọ fun BBC pe pe ijọba ipinlẹ Eko ti mura silẹ lati koju arun naa ko to di pe arun ọhun de Naijiria.
Ni kete ti ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si eto ilera fi lede pe arun naa ti tan de ipinlẹ Eko ni ijọba ipinlẹ naa pe apero awọn oniroyin lati sọ ibi ọrọ de duro lori arun naa.
Omotoso sọ pe ki awọn eeyan ipinlẹ Eko ma bẹru lori arun naa nitori ijọba ko sun lati ri pe arun ọhun ko di tọrọ kọbọ.
O ni ipinlẹ Eko ti ran awọn dokita ọgọta si papakọ ofurufu Eko fun ayẹwo gbogbo awọn eeyan to n wọle sorilẹ-ede Naijiria.
Ni ti Kwara, kọmiṣọna eto ilera nipinlẹ ọhun, Raji Razak sọ fun BBC Yoruba pe ijọba ti ta gbogbo awọn eleto ilera ipinle naa ti n ṣamojuto gbogbo ibode to wọ ipinlẹ ọhun.
O ni "Gbogbo ọna abawọle si ipinlẹ Kwara ni ijọba ti ran awọn eleto ilera si kin wọn lee ma ṣayẹwo gbogbo awọn eeyan to ba n wọle lati ibẹ."
O tẹsiwaju pe ijọba tun ti fiwe ranṣẹ si ileeṣẹ to n ri si eto ẹkọ lati da awọn ileewe lẹkọ nipa ṣiṣe itọju ara ẹni, bii fifọ ọwọ pẹlu ọṣẹ, lilo igbọnwọ lati bo ẹnu bi eeyan ba fẹ wukọ, ati bẹbẹ lọ.
Raji sọ pe ipìnlẹ Kwara ti ni awọn ibudo ti wọn lee ko awọn eeyan to ba n ṣaarẹ si fun itọju ni imurasilẹ fun arun naa nipinlẹ ọhun.
Ni kuktukutu owurọ ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Keji ọdun 2020 ni iroyin jade pe arun Coronavirus ti tan de ilu Eko, leyi ti wọn ni ọmọ orilẹ-ede Italy kan lo mu wa.