Ìjàmbá ọkọ̀ ojú'rin pa èèyàn 288,bíi 850 farapa

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ko din ni eeyan 288 to ti ku bayoi, ti 850 si farapa ninu ijamba ọkọ ojú'rin kan to waye nipinlẹ Odisha, ni orílẹ̀-èdè India.
Ọkọ̀ ojú'rin kan to ko èrò ni igbagbọ wa pe o yẹ̀ kuro ni oju ọna rẹ, ko to di wi pe ọkọ ojú'rin miran to n kọja lọ ni òdì-kejì kọlu u, lalẹ́ ọjọ Ẹti.
Ijamba yii ni ti ọkọ ojú'rin to tii buru ju ni India, lati bi ọgọrun ọdun.
Àwọn aláṣẹ sọ pe o ṣeéṣe ki awọn to kú pọ̀ si.
Akọwe ijọba ipinlẹ Odisha, Pradeep Jena sọ pe igba ọkọ ambulansi ni wọn ti ko lọ sibi iṣẹlẹ naa.
Bakan naa lo sọ pe dokita to le ni ọgọrun-un ni wọn tun ti ko lọ síbẹ̀.
Àwọn aláṣẹ ileeṣẹ ọkọ reluwe ni India sọ pe ọkọ ojú'rin Coromandel Express ati Howrah Superfast Express lo kagbako ninu ijamba naa.
India wa lara awọn orile-ede ti eto irinna ojú'rin rẹ tobi julọ ni agbaye, ijamba reluwe si jẹ nnkan to wọ́pọ̀ níbẹ̀.
Ọdun 1981 ni ijamba oko ojú'rin to tíì buru julọ ni India waye.
Iji lile kan lo ti ọkọ ojú'rin kan kuro ni oju ọna rẹ ni ipinlẹ Bihar. Ko din ni eeyan 800 to ku.













