Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika

Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan

  1. Ìjọba Naijiria wọ́gilé àwọn 'App' ayáni lówó kan

  2. Ààrùn Anthrax kò tíì ran ẹnikẹ́ni ní Naijiria àyàfi àwọn ẹran ọ̀sìn

    Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC, ti sọ pe aarun Anthrax to ti ran awọn ẹran ọsin kan ni Naijiria, ko ti ran eniyan kankan.

    Ileeṣẹ agbohunsafẹfẹ NTA sọ ninu iroyin kan to gbe jade pe olori ajọ NCDC, Dokita Nasir Ahmed, sọ pe ajọ naa ṣi n ṣe amojuto, to si n fimu finlẹ paapaa ni agbegbe Suleja, ipinlẹ Niger, nibi ti aarun naa ti kọkọ bẹrẹ ni Naijiria.

    Bakan naa lo sọ pe ijọba, nipasẹ ileeṣẹ eto ilera n ṣe eto ilanilọyẹ lori awọn apẹẹrẹ ti aarun naa ma n fi han, ati bi eniyan ṣe le dena kiko o.

    Ṣaaju ni ijọba kede pe oun ti ra abẹrẹ ajẹsara lati fi tọju awọn ẹran ọsin niluu suleja.

    Awọn ẹran ọsin ati awọn ẹranko miran to n gbe ninu igbo ma n ko aarun naa ti wọn ba mu omi tabi jẹ koriko to ni kokoro aarun naa.

    Awọn ẹranko to ma n ṣaba mu ni agutan, maalu, ewurẹ ati igala.

    Awọn onimọ iṣegun oyinbo sọ pe eniyan le ko aarun naa nigba ti wọn ba ni ifarakanra pẹlu ẹranko to ni i, tabi fi ọwọ kan ohunkohun to wa lati ara ẹranko bẹẹ.

    Ijọba fi ikilọ sita nigba ti aarun naa bu jade ni Naijiria pe, ki awọn eeyan ṣọra fun jijẹ ẹya ara ẹran ti aisan ba n ṣe.

    • Wo ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa àrùn Anthrax to ṣẹ̀ṣẹ̀ wọ Nàìjíríà
    • Àìsàn Diphteria tún pa ènìyàn mẹ́wàá ní Kaduna, ohun tí a mọ̀ rèé
  3. Ikú dóró! Sunday Igboho pàdánù ìyá rẹ̀

  4. Àjọ ọmọlẹ́yìn Kristi, CAN sọ̀rọ̀ sókè lórí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntiró tó gbòde kan

    Aworan

    Ajọ ọmọlẹyin Kristi ni Naijiria, CAN ti fi ẹhọnu wọn han si ọwọngogo epo bẹntiro to gbode ni Naijiria.

    Ninu atẹjade ti ajọ naa fi lede ni wọn ti ni ijiya to kọja afẹnusọ ni awọn ọmọ Naijiria n fi arar ọ ni asiko yii.

    Ajọ naa wa kesi ijọba apapọ lati tete wa wọrọkọ fi se ada lori iṣẹlẹ ọwọngogo to gbode kan yii.

    Aarẹ ẹgbẹ CAN, Archbishop Daniel Okoh ni bio tilẹ jẹpe o ti to asiko ki wọn yọ owo iranwọ epo lati mu ki orilẹde Naijiria tẹsiwaju, o ni o yẹ ki wọn se e ni ọna ti ko ni nira jọjọ fun awọn ọmọ Naijiria.

    ‘’Nitori ọwọngogo yii ni a se sọrọ soke, ti a si fi ẹhọnu wa han si ohun to n waye ni awujọ wa.

    ''Iya ati iṣẹ ti gbode kan, ti nkan ko si rọrun fun awọn araalu mọ.''

    ''Nitori naa a n fi asiko yii kesi awọn adari lorilẹede Naijiria ki wọn wa ọna abayọ si ipenija ti awọn eniyan n koju wọnyii.''

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    ''Asiko ti awọn araalu si n wa ọna atijẹ ati mu lẹyin ti owo ounjẹ lọ si oke si N540, ti eyi si fa ki owo eto irinna, ounjẹ, ati awọn ọja gbe pẹẹli soke kaakiri ''

    ''Eyi mu ki igbeaye nira fun awọn araalu, ti wọn ko tii bọ nibẹ, ti ọwọngogo miran tun gun ori epo, to fi da N617.''

    ''Eleyii mu ki alafo to wa laarin awọn ọlọla ati talaka gun si ju bi o se uẹ lọ, ti awọn araalu ko si ri owo fi se nkan rere mọ tabi ki wọn tilẹ jẹun.''

    ''IIsoro yii pọju fun awọn ọmọ Naijiria ti wọn ko tilẹ ria je jẹun tẹlẹ, ki wọn to wa dakun iṣoro wọn.''

    Bakan naa ni CAN wa gba ijọba ni imọran lati gbe eto ọrọ aje Naijiria gba ibomiran lọ, ki iya ati iṣẹ yii le dopin laipẹ fun awọn araalu.

    Wọn ni ki iranwọ ti ijọba fẹ se fun awọn araalu ju owo perese ti wọn fẹ fun wọn lọ, amọ ki wọn pese eto irinna fun wọn kaakiri ipinlẹ de ipinlẹ, eleyii ti yoo mu aye rọrun fun awọn araalu.

  5. ‘’ Ìjìyà tó lágbára jùlọ ní ayé ló tọ́sí ẹni tó bá sọ̀rọ̀ lòdì sí Qur’an,’’

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Reuters

    Olori ẹsin Islam, Ayatollah Ali Khamenei ti sọ pe ẹnikẹni to ba sọrọ lodi si Quran gbọdọ foju wina ijiya to lagbara julọ lagbaye.

    Eyi ko ṣẹyin ifẹhọnuhan tako ẹsin Islam ati Quran to waye ni orilẹede Sweden, to fi mọ Denmark naa.

    Awọn to fẹhọnuhan naa ni iroyin gbe pe o ṣeese ki wọn tẹ Quran mọlẹ, tabi ki wọn sọrọ tako rẹ lasiko ifẹhọnuhan naa.

    Ayatollah ni idahun si iṣẹlẹ yii bu ẹnu atẹ lu iru igbesẹ bẹẹ, to si ni awọn to n hu iru iwa bẹẹ ko dara to.

    Bakan naa lo kesi ijọba orilẹede Sweden lati fi panpẹ ọba mu awọn to hu iru iwa bẹẹ, to si ni ki wọn yonda wọn fun awọn orilẹede ti wọn n se ẹsin Musulumi lati se idajọ wọn.

    O ni gbogbo awọn onimọ nipa Islam lo ti buwọlu pe ẹnikẹni to ba sọrọ tako Qur’an naa yẹ fun ijiya to gajulọ ni aye.

    To si ni ohun to tọ ni ki ijọba Sweden jọwọ awọn afẹhọnuhan naa nitori ọdaran ni wọn, ki wọn si fi wọn jofin.

    Ẹwẹ, awọn onimọ Islam ti kede pe ki wọn pa ọmọbinrin kan ti wọn ni o sọ ọrọ odi si Prophet Muhammed SAW.

  6. Wo ohun to ṣẹ̀lẹ̀ lẹ́yìn tí Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ṣe ikọlu sí ibùba IPOB

    Aworan nkan ija ti ọmọ ogun Naijiria gba lọwọ IPOB

    Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

    Ileeṣẹ ologun ni Naijiria sọ pe awọn ti ri ọkan ninu awọn ọmọ ikọ agbesunmọmi IPOB mu bẹẹ si ni awọn ri nkan ija oloro gba lọwọ awọn ọdaran yii.

    Ninu atẹjade kan ti ileeṣẹ naa fi soju opo Twitter wọn ni wọn ti kede ọrọ yi.

    Onyema Nwachukwu to jẹ ọga ẹka ibaraẹnisọrọ ileeṣẹ naa sọ pe ṣaaju lawọn ti kọkọ ṣe ikọlu si ibuba awọn ikọ yi lowurọ ọjọ Abamẹta ninu igbo kijikiji kan ni ilu Asaba.

    O ni nigba tawọn tọ awọn to salọ ninu awọn agbesunmọmi yi lọwọ tẹ ọkan ninu wọn tawọn si gba nkan ija ni ibọn AK47 marun un,ibọn ṣakabula mẹrin, ọta ibọn ati alupupu to fi mọ foonu tawọn ikọ yi n lo,

    Aworan awọn nkan tawọn ologun lawọn ri gba ree gẹgẹ bi wọn ṣe fi han loju opo Twitter wọn.

    Aworan ọmọ ogun Naijiria

    Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

    Aworan nkan ija ti ileeṣẹ ologun gba lọwọ awọn ọmọ ikọ IPOB

    Oríṣun àwòrán, @HQNigerianArmy

  7. Iṣẹ́ bọ lọ́wọ́ Ọgá àgbà, igbákejì àjọ tó n mójútó ìpèsè àti lílò òògùn

    Afihan paali oogun ikọ to ṣeku pa awọn ọmọde ni The Gambia

    Oríṣun àwòrán, WHO

    Àkọlé àwòrán, Aworan oogun to ṣeku pa awọn ọmọde ni The Gambia

    Ijọba orileede Gambai ti fọwọ osi juwe ile fun ọga agba ajọ to n mojuto ipese oogun nilẹ naa ati igbakeji rẹ.

    Igbesẹ yi ko ṣẹyin abọ igbimọ iwadii ti ijọba gbe kalẹ to ṣafihan pe ajọ naa ko forukọ ileeṣẹ apoogun ilẹ India kan ni ibamu pẹlu ofin ilẹ ọhun.

    Ileeṣẹ yi ni wọn lo lọwọ si iku awọn ọmọde aadọrin to lo oogun ikọ ayederun ileeṣẹ naa,

    Markieu Janneh Kaira ati Foumata Jah Sowe ni ọga agba ati igbakeji ajọ to n mojuto ipeese ati lilo oogun lorileede The Gambia.

    Wọn lawọn mejeeji ko ṣe iṣẹ wọn bo ṣe yẹ koda wọn ti fa awọn mejeeji le ọlọpaa lọwọ fẹkunrẹrẹ iwadii.

    Igbimọ iwadii ti ijọba gbe kalẹ tun sọ pe ileeṣẹ to pọn oogun naa ni India lọwọ ninu iku awọn ọmọde to lo orisi oogun mẹrin ti ileeṣẹ yi pọn gẹgẹ bi ajọ ilera lagbaye WHO ti ṣe sọ.

    Bakan naa ni ijọba gba iwe aṣẹ lọwọ ileeṣẹ 'Atlantic Pharmacy Company Limited' to ṣe atọna fun ileeṣẹ apoogun taa n wi yi.

    Ṣugbọn ileeṣẹ apoogun 'Maiden Pharmaceuticals', to pọn awọn oogun to ṣokunfa iku awọn ọmọde yi sọ pe ko si ootọ ninu ọrọ pe oogun awn ṣekupa awọn ọmọde yi.

    Wọn ni esi ayẹwo tawọn alaṣẹ orileede India gbejade fihan pe ko si nkankan to ṣe oogun tawọn pọn.

    Titi di asiko yi, kosi ẹni le sọ pato aawọ ti iṣẹlẹ yi lu da silẹ laarin ijọba The Gambia, ileeṣẹ to ṣatọna Maiden Pharmaceuticlas ati ileeṣẹ to n mojuto pipọn oogun wọnyi.

  8. Olubadan ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn Alaagba, yí ìpinnu rẹ̀ padà

  9. Ẹ kéde mi bí ẹni tó jáwé olúborí ìbò Ààrẹ - Atiku sọ fún ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò

    Atiku Abubakar

    Oríṣun àwòrán, FACEBOOK

    Olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lẹ́gbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, nínú ètò ìdìbò tó kọjá, Alhaji Atiku Abubakar ti rọ ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò láti kéde òun gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí ètò ìdìbò náà.

    Atiku Abubakar ní àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò Nàìjíríà, INEC gbà wí pé ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún ni òun ti gbégbá orókè níbi ètò ìdìbò náà.

    Atiku sọ̀rọ̀ yìí ní ọjọ́ Ẹtì nínú ọ̀rọ̀ àsọkẹ́yìn èyí tí òun àti ẹgbẹ́ òṣèlú rẹ̀ gbé kalẹ̀ fún ìgbìmọ̀ tó ń gbọ́ ẹ̀hónú ìbò náà láti fi tako ìjáwe olúborí Tinubu.

    Nínú ọ̀rọ̀ náà èyí tí agbẹjọ́rò rẹ̀, Chris Uche ní INEC kò sọ wí pé àwọn ṣe àṣìṣe bí wọ́n ṣe ti ṣaájú sọ wí pé òun jáwé olúborí ní ìpínlẹ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n títí tí ìgbẹ́jọ́ náà fi parí.

    INEC nínú èsì sí ẹjọ́ tí Atiku pè ní ìpínlẹ̀ mọ́kànlélógún ni Atiku tí jáwé olúborí.

    Àwọn Ìpínlẹ̀ tí INEC kà kalẹ̀ pé Atiku tí jáwé olúborí ni Adamawa, Akkwa Ibom, Bauchi, Bayelsa, Borno, Delta, Ekiti, Gombe, Jigawa, Kaduna, Katsina, Kebbi, Kogi, Kwara, Nasarawa, Niger, Osun, Sokoto, Taraba, Yobe àti Zamfara.

    Ó ní láti ìgbà náà títí tí ìgbẹ́jọ́ náà fi parí kò sí ìgbà tí INEC fi yí ọ̀rọ̀ náà padà.

    Ó ní èyí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun ni ẹni tó yẹ kí wọ́n kéde gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ nítorí náà kí Adájọ́ gbé ipò náà fún òun.

  10. Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ ènìyàn mẹ́rin lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ní kí àwọn obìnrin méjì rìn ní ìhòhò

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Ileeṣẹ ọlọpaa ni orilẹede Inidia ni ọwọ awọn ti tẹ ọkunrin mẹrin kan lori ẹsun pe wọn ni ki obinrin rin ni ihoho ni gbangba ni agbegbe ariwa orilẹede naa.

    Agbegbe naa lo ti n koju ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ, ti eniyan 120 si ti ba iṣẹlẹ naa lọ.

    Awọn mẹrin ti ọwọ tẹ naa ni wọn ri ninu fidio to ja ranyin ni osu karun un nibi ti awọn araalu ti n rin obinrin meji naa ni ihoho.

    Ileeṣẹ ọlọpaa loju opo Twitter wọn ni awọn mẹrin to wa ni idi iṣẹlẹ naa ni ọwọ awọn ti tẹ.

    Awọn obinrin naa ni fidio ṣafihan ti wọn n rin ni ihoho, ti awọn araalu si n fi wọn ṣe yẹyẹ.

    Agbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye ni kosi ẹrọ ayelujara nitori ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ to waye nibẹ.

    Ijọba ton ṣe akoso agbegbe naa, Bharatiya Janata Party, BJP ni ileeṣẹ ọlọpaa gbe igbeṣẹ naa lẹyin ti fidio ọhun jade si ori ẹrọ ayelujara.

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Others

    Wọn fikun un pe iwadii lẹkunrẹrẹ lai yọ ẹnikẹni kuro n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa

    Bakan naa ni wọn ṣeleri pè awọn to hu iru iwa bẹẹ yoo fi oju wina ofin.

    Ti wọn si ni o ṣeeṣẹ ki ijiya to tọsi wọn gba ọna iku lọ.

    Ifẹhọnuhan naa lo bẹ silẹ lasiko ti ija waye ni Manipur, nitori awọn araalu ti ko ri iṣẹ ijọba ati awọn anfaani miran.

    Awọn afẹhọnuhan naa ṣekọlu si ile ijọsin ati awọn ile miran ni agbegbe naa, ti ẹgbẹgbẹrun eniyan si na papa bora ni agbegbe naa.

  11. Wọ́n fi ẹ̀sùn kan àwọn ọkùnrin tó na obìnrin yìí dojú ikú tí wọ́n tún ju òkú rẹ̀ s' ódò adágún ilé ìtura

  12. Ọkọ, ìyàwó, ọmọ méjì àti èèyàn méjì míì kú lẹ́yìn tí wọ́n kó sílé tuntun

  13. Davido pín ₦237m fáwọn ọmọ aláìníìyá yíká Nàìjíríà

  14. Adebutu takú pé ẹbu ìwé ẹ̀rí WAEC ni Abiodun ń lò, WAEC kọ̀ láti fi ẹ̀dà ìwé ẹ̀rí ránṣẹ́ sí ‘Tribunal’ l‘Ogun

  15. Irọ́ ni pé wọ́n fẹ́ fi orò lé àwọn àjòjì kúrò ní Eko - Ìjọba

    Asia ipinle Eko

    Oríṣun àwòrán, LASG

    Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti ní kí àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ náà má tẹ́tí sí ìròyìn kan tó gba orí ayélujára pé orò fẹ́ jáde ní àwọn agbègbè kan.

    Ṣáájú ni ìròyìn ti gba orí ayélujára pé orò fẹ́ jáde ní àwọn àdúgbò kan lọ́jọ́bọ̀, ogúnjọ́ àti ọjọ́ Ẹtì ọjọ́ Kọkànlélógún oṣù Keje láàárín aago méjìlá sí aago márùn-ún àbọ̀ ìdájí àwọn ọjọ́ náà.

    Lára àwọn àdúgbò tí wọ́n ní orò náà ti máa wáyé ni Ikate,Ijora-Badiya, Amuwo-Odofin, Ojota, Ikorodu àti Somolu-Bariga àti agbègbè rẹ̀.

    Bákan náà ni wọ́n tún dárúkọ Igbobi-Sabe, Ojodu-Isheri, Isolo-Okota-Ilasamaja, Ejigbo-Idimu, Isheri-Ijegun, Ikotun-Igando, Iba, Lawanson-Itire àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

    Ohun tí wọ́n kọ sórí ìròyìn náà ni pé kí àwọn obìnrin àti àwọn tí kìí bá ṣe ọmọ Eko ó fi ara pamọ́ láwọn àsìkò tí orò fi fẹ́ jáde náà pé ọmọ onílùú fẹ́ ṣe orò.

    Ẹ̀wẹ̀, agbenusọ gómìnà ìpínlẹ̀ Eko, Gboyega Akosile nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn PUNCH sọ̀rọ̀ lọ́jọ́bọ̀ ní Alausa, Ikeja ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.

    Akosile rọ àwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Eko láti máa bá iṣẹ́ oòjọ́ wọn lọ pé kò sí nǹkan tó jọ pé orò kankan fẹ́ wáyé.

    Ó ní kò sí nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ rárá àti pé kìí ṣe ohun tó yẹ kí ìjọba tilẹ̀ máa dá sí ni.

  16. Wo ọ̀nà mẹ́sàn-án tí ìjọba ìpínlẹ̀ àti àpapọ̀ yóò fi mú àdínkù bá ìyà aráàlú torí ọ̀wọ́n owó epo

  17. Ènìyàn méjì farapa níbi ìjàm̀bá ọkọ̀ òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan

    Lagos-Ibadan expressway

    Oríṣun àwòrán, @drizzie99

    Kò dín ní ènìyàn mẹ́jọ tí orí kó yọ lọ́wọ́ ikú nígbà tí ìjàm̀bá ọkọ̀ kan wáyé ní òpópónà márosẹ̀ Eko sí Ibadan lọ́jọ́rú.

    Ìròyìn ní ọkọ̀ ńlá kan tó kó àwọn màálù ló lọ kọlu àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ mẹ́ta mìíràn.

    Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn ṣe fìdí rẹ̀ múlẹ̀, ènìyàn méjì farapa níbi ìjàm̀bá ọ̀hún.

    Ní agbègbè Sagamu Interchange ni ọkọ̀ ńlá náà pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì lọ kọlu ọkọ̀ Toyota Hiace méjì, Toyota SUV kan àti ọkọ̀ ńlá kan mìíràn.

    Ẹni tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ Azeez Olayiwola gẹ́gẹ́ bí ìwé ìròyìn PUNCH ṣe sọ ní awakọ̀ ọkọ̀ ńlá náà kò iwájú láti mọ̀ wí pé súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ wà ní iwájú rẹ̀ tó sì ń sáré bọ̀.

    Olayiwola ní ìgbà tí awakọ̀ náà máa fi súnmọ́ àwọn ọkọ̀ náà kò ríbi mú àdínkù bá eré tó ń sá, tó sì lọ kọlu àwọn ọkọ̀ tó wà níwájú rẹ̀.

    Nígbà tó ń fìdí ìjàm̀bá náà múlẹ̀, Ọ̀gá àgbà àjọ tó ń mójútó ojú pópó (FRSC) tí ìpínlẹ̀ Ogun, Ahmed Umar ní àwọn méjì tó farapa níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti ń gba ìtọ́jú ní ilé ìwòsàn.

    Ó ní ènìyàn mẹ́jọ ló wà nínú àwọn ọkọ̀ tí ìjàm̀bá náà kàn àmọ́ àwọn méjì ló farapa tí wọ́n sì ti wà ní ilé ìwòsàn fún ìtọ́jú.

  18. Irọ́ ni o, mi ò pé Tinubu lórí ìgbẹ́jọ́ ẹ̀hónú ìbò to ń wáyé ní Abuja - Adájọ́ àgbà, Ariwoola

    Bola Tinubu

    Oríṣun àwòrán, Bola Tinubu

    Ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ìyẹn Supreme court tí jiyàn àhesọ ọ̀rọ̀ tó gba ìgboro pé Adájọ́ àgbà Nàìjíríà, Olukayode Ariwoola bá Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu sọ̀rọ̀ lórí ìgbẹ́jọ́ ètò ìdìbò sípò Ààrẹ.

    Ariwoola ní òun kò tún ní àjọsọ kankan pẹ̀lú Ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ́ ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́, DSS, Yusuf Bichi.

    Adájọ́ àgbà náà ní ilé ẹjọ́ kò ní èròńgbà láti ṣègbè lẹ́yìn ẹnikẹ́ni kò bá à jẹ́ Tinubu, olùdíje ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar tàbí olùdíje lẹ́gbẹ́ òṣèlú Labour Party, Peter Obi.

    Nínú àtẹ̀jáde kan tí adarí ètò ìròyìn ilé ẹjọ́ náà, Dókítà Festus Akande fi léde lọ́jọ́rú ní kò sí òótọ́ nínú ìròyìn tí àwọn kan ń gbé kiri lórí ayélujára.

    Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa ṣe àtìlẹyìn fún ẹ̀ka ètò ìdájọ́ kí wọ́n lè máa ṣe ojúṣe wọn bó ṣe yẹ.

    Ó ṣàlàyé pé àwọn ará ìlú ti ń bá ẹjọ́ tó ń wáyé lórí awuyewuye lórí ètò ìdìbò sípò Ààrẹ lọ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé nítorí náà kò yẹ kí wọ́n fààyè àhesọ ọ̀rọ̀ tí kò ní so èso rere lórí ejò náà.

    Ó fi kun pé tí àwọn ìròyìn ẹlẹ́jẹ̀ bá ti ń tàn kalẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, orílẹ̀ èdè kò ní tẹ̀síwájú àti pé ìdásílẹ̀ àwọn ilé ẹjọ́ wáyé láti jà fún ará ìlú ni.

    Ariwoola ní bíbọ̀wọ̀ fún òfin àti tí tẹ̀lé àlàkalẹ̀ ìwé òfin Nàìjíríà nínú gbogbo àwọn ẹjọ́ ni òun to máa ń jẹ àwọn lógún ní gbogbo ìgbà.

    Bákan náà ló fi àwọn ènìyàn lọ́kàn balẹ̀ pé ìdájọ́ òdodo ló máa wáyé nínú gbogbo àwọn ẹjọ́ tó ń lọ ní àwọn ilé ẹjọ́ káàkiri Nàìjíríà.

  19. Gomina Adeleke yan àwọn Kọmísọ́nà rẹ̀, ohun náà náwọ́ gan ipò kọ́misọ́nà kan fún ara rẹ̀

  20. Ìjọba tí àwọn iléẹ̀kọ́ pa nítorí ìfẹ̀họ́núhàn tó gbòde kan ní Kenya

    Aworan

    Oríṣun àwòrán, Getty Images

    Ijọba orilẹede Kenya ti ti awọn ileẹkọ to wa ni olu ilu meji ni orilẹede naa pa.

    Eyi ko ṣẹyin ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ to ti le ni ọjọ mẹta bayii to bẹ silẹ nibẹ.

    Laiko ifẹhọnuhan naa ni awọn afẹhọnuhan n ṣekọlu si awọn ọlọpaa, ti awọn naa si n fin tajutaju si awọn eniyan.

    Lara awọn agbegbe ti wọn ti fin tajutaju ni agbegbe Mombasa to fi mọ Nairobi, pẹlu ẹsun pe ijọba kọ lati mu ayedẹru fun awọn araalu ti ọwọngogo si gbode kan.

    ọpọlọpọ ile itaja naa lo wa ni titi pa nitori ibẹru pe awọn afẹhọnuhan naa le sékọlu si awọn ile itaja, ki awọn si ji awọn ẹru gbe lọ.

    Ni ọṣẹ to kọja, eniyan mẹrinla lo ku ninu ifẹhọnuhan, ti ọlọpaa si pa eniyan mẹra ninu wọn.

    Ajọ ajafẹtọ ọmọ eniyan ti bu ẹnu atẹ lu igbese awọn ọlọpaa nipa bi wọn ṣe n lo iwa ipa pẹlu awọn afẹhọnuhan.

    O kere tan awọn ọmọ ileẹkọ aadọta ni wọn gbe digba digba lọ si ileewosan lẹyin ti wọn fin tajutaju si ileẹkọ wọn ni ilu Nairobi.

    Ẹgbẹ awọn alatako lo pe fun ifẹhọnuhan ọlọgọọrọ lori bi ijọba ṣe ṣe afikun un owo ori lati bi osu kan ti eyi si ti fa inira fun awọn araalu, labẹ isẹjọba Aarẹ William Ruto.

    Ninu ọrọ wọn, ileeṣẹ ọlọpaa ni ifẹhọnuhan naa fẹ da omi alaafia orilẹede naa ru ni, ti awọn si gbọdọ ri pe iru rẹ ko ṣẹlẹ,

    Ni awọn ilu bii Nairobi ati Nakuru, awọn afẹhọnuhan naa di awọn oju ọna pa, ti wọn si n ju okuta lu awọn ọlọpaa.

    Bakan naa ni agbegbe Migori ni awọn afẹhọnuhan ti koju ọlọpaa, ti ọpọlọpọ si farapa lasiko ti wọn koju ara wọn.