You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Ọlọ́pàá tó ń tọrọ owó lọ́wọ́ arìn ìrìnàjo wọ gàù
Àwọn agbébọn kọlu àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ẹ̀kọ́ gíga, wọ́n jí ọ̀pọ̀ gbé lọ
NJC gba iṣẹ́ lọ́wọ́ adájọ́ ìpínlẹ̀ Osun, kọ ẹ̀bẹ̀ Adeleke láti yọ adájọ́ àgbà Adepele Ojo nípò
Àṣìta àdó olóró míràn tún ti wáyé, ẹ̀mí márùn ún ló lọ síi
Eeyan marun un lo ti jade laye bayii lẹyin ti ado oloro kọlu ọkọ to n gbe alaisan ni Ethiopia.
Eeyan mẹta ati olori ile iwosan abẹlẹ naa farapa yanayana ninu ikọlu naa to waye ni agbegbe Wogel Tena ni apa ariwa Amhara.
Ikọlu naa waye lọsẹ to kọja sugbọn wọn fi di rẹ mulẹ lọjọru, ọjọ keje oṣu kejila ọdun 2023 nitori ofin kikede ọrọ ti awọn alasẹ gbe kalẹ lorilẹede ọhun.
Awakọ alaisan, akọle wa lara eeyan mẹta to padanu ẹmi wọn.
Ileeṣẹ ologun ijọba apapọ ni wọn n lo ọkọ ofurufu yii lati gbe ogun ti awọn janduku lẹyin ti wahala bẹ silẹ ninu oṣu kẹrin to si n peleke si lati igba naa.
Loṣu to kọja, Ajọ UN n kominu lori bi ado oloro ọhun se n sekupa awọn araalu ni agbegbe Amhara .
UN ni ọpọ eeyan lo padanu ẹmi wọn nibi ikọlu to waye ni agbala ile ẹkọ ati ibudo ọkọ.
Wáá gbọ́ ohun tí àwọn èèkàn ìlú n sọ nípa àdó olóró tó pa ọ̀pọ̀ ní Tundun Biri
Frank Kokori, èèkàn láàrín àwọn tó jà fún ìdápadà ìjọba alágbádá ní Nàìjíríà jáde láyé
Nàìjíríà fẹ́ ta bàlúù ààrẹ
'Orí ló kó èmi àti ìyàwó mi yọ, àwa náà ìbá kú nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó gbẹ̀mí àwọn ọba mẹ́ta l'Ogbomoso'
Ìyá ju ọmọ oṣù mẹ́jọ sínú òkun
Ọwọ awọn ọlọpaa lorilẹede Kenya ti tẹ arabinrin kan ti wọn fi ẹsun kan pe o ju ọmọ rẹ, ọmọ oṣu mẹjọ si inu okun lọjọ Aiku.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣe oju wọn sọ pe arabinrin naa ju ọmọde jojolo naa sinu okun lati ori ọkọ oju omi kan to fẹ gunlẹ si ebute ilu Mombassa.
Fọran fidio kan to ṣe afihan bi awọn omuwẹ ṣe kan lu omi lati doola ẹmi ọmọde jojolo naa wa lori ayelujara, eleyi to mu ki awọn eeyan orilẹede naa o maa fi ẹhonu ati ibinu wọn han si obinrin naa.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ mohunmaworan aladani kan nibẹ K24 ati Citizen TV ṣe sọ, “Wọn gbe ọmọdebinrin naa lọ si ibudo awọn ajọ alagbelebu pupa, Red Cross ni ibi to ti gba itọju ti wọn si da a silẹ. Amọṣa wọn wọn gbe iya rẹ lọ si agọ ọlọpaa fun ifọrọwanilẹnuwo.”
ajọ alagbelebu pupa, Red Cross ti kọkọ sọ pe ọmọde jojolo naa ti wa lalafia o si wa ni ibudo idoola ẹmi wọn
Ko tii si ẹni lee sọ ẹsun ti ọlọpaa yoo fi kan arabinrin naa bayii
Amẹ́ríkà ṣetán àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ìjọba ológun Niger, aṣojú rẹ̀ fí ìwé ẹ̀rí ṣọwọ́
Iroyin to n tẹwa lọwọ sọ pe aṣoju orileede America si Niger ti ko awọn iwe ẹri rẹ yọju si ileeṣẹ ilẹ okere ni Niamey.
Laarin oṣu Kẹjọ ni Kathleen FitzGibbon de si Niger lẹyin ti awọn aditẹgbajọba ologun yẹ aga nidi aarẹ Mohamed Bazoum.
Gẹgẹ bi ileeṣẹ amohunmaworan ilẹ Niger-Tele Sahel ṣe sọ,o to oṣu mẹrin sẹyin to ti de sẹnu iṣẹ.
Minisita ilẹ okere Niger Bakary Yaou Sangare sọ pe igbesẹ yi tọka si itẹwọgba ijọba Niger lọdọ America.
‘’A n ṣeto lati ri pe gbogbo awọn alabaṣe wa gbogbo lo pada ti wọn si ni igbagbọ ninu ijọba ologun to n dari ilẹ wa’’
Orileede America ni awọn ibudo ologun meji kan nilẹ ọhun ti awọn ọmọ ogun rẹ to sunmọ ẹgbẹrun kan wa nibẹ.
Ibudo yi a maa ṣe idanilẹkọ fawọn ọmọ ogun Niger lori ọna ati koju awọn agbesunmọmi.
Washington fopin si ibaṣepọ pẹlu Niger lẹyin ti awọn ologun gbajọba ṣugbọn o ti yi ipinnu rẹ yi pada tipẹ.
Ko daju iru iha ti orileede France yoo kọ si iṣẹlẹ yi.
Awọn ologun to gbajọba ti ṣaaju le aṣoju France latari bi ko ṣe foju ree wo ijọba ologun to wa lori alefa bayii.
Ọlọ́pàá wa'kọ̀ pa akẹ́kọ̀ọ́ kan l'Ogun, akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́ta míì farapa
Ọlọ́pàá yìnbọn pa Salisu níbi tó ti ń wọ́de ní Kano, kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá bá ní kí wọ́n tìí sí gbaga
Koko lara mi le lẹ́yìn tí mo parí Wash-a-thon, ohun tó gbé mi lọ sílé ìwòsàn rèé – Subair Enitan
Mama Kuto rèé, ìyá àgbà awakọ̀èrò tí àìsàn ìyá rẹ̀ sọ̀ di ọmọ gáréèjì
Àwọn obìnrin lẹ́gbẹ́ òṣèlú NNPP fẹ̀hónú hàn nítorí gómìnà Kano tí kóòtù yọ nípò
A máa kàńpá fún INEC láti máa fi èsì ìbò sórí ayélujára - Ilé aṣòfin àgbà
Ìgbìmọ̀ tó ń rí sí ètò ìdìbò nílé aṣòfin àgbà Nàìjíríà ti ní àwọn máa gbé òfin kalẹ̀ láti pọ́n ní dandan fún àjọ tó ń rí sí ètò Nàìjíríà, INEC láti máa fi èsì ìbò sórí ayélujára lásìkò ìbò.
Alága ìgbìmọ̀ náà, Aṣòfin Sharafadeen Alli ló sọ̀rọ̀ náà lásìkò tó ń bá Iléeṣẹ́ ìròyìn Channels TV sọ̀rọ̀ lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun.
Alli ní òfin tó wà nílẹ̀ báyìí kò ṣe é ní dandan fún INEC láti máa fi èsì ìbò sórí ayélujára àmọ́ tí àwọn ti ń gbèrò láti yí òfin náà padà.
Ó ní ọ̀kan lára ètò tí ìgbìmọ̀ àwọn fẹ́ gbájúmọ́ nìyí tó fi mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ tó jọ mọ́ ètò ìdìbò mìíràn.
Ó fi kun pé àwọn tún ń mójútó láti ri pé gbogbo ẹ̀sùn tó máa ń wáyé ṣáájú ètò ìdìbò ni ilé ẹjọ́ yanjú kí ètò ìdìbò gangan tó wáyé.
Aṣòfin náà ni èyí máa mú àdínkù bá bí àwọn awuyewuye tó yẹ kó ti parí ṣáájú ètò ìdìbò ṣe máa ń wólẹ̀.
Bákan náà ló fi kun pé àwọn tún ń gbèrò láti rí pé gbogbo ẹ̀hónú tó ń wáyé lẹ́yìn ìdìbò ni ilé ẹjọ́ parí ṣáájú kí wọ́n tó búra wọlé fún ẹni tí ìlú bá yàn.
Ó ní èyí máa mú àdínkù bá bí ètò ìdìbò ṣe máa ń wáyé ní àwọn ìpínlẹ̀ kan lẹ́yìn ètò ìdìbò gbogbogbo.
Ó tẹ̀síwájú pé àwọn ohun èlò ẹ̀rọ̀ INEC ni àwọn tún ń gbèrò láti ṣe àmójútó rẹ̀ nítorí ohun ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún àwọn pé IReV kò ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ lásìkò ìbò tó kọjá.
Alli ni àwọn máa mójútó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí kí àsìkò ìbò mìíràn tó gbéra sọ.
Bàtà mi ẹsẹ̀ kan làwọn ìkà lò láti mú kí ẹsẹ̀ mi méjèèjì rọ - Grace Garuba
Láìnání ìdájọ́ ilé ẹjọ́, Gómìnà Adeleke yọ adájọ́ àgbà ìpínlẹ̀ Osun nípò
Ilé dàwó ní Eko, gbẹ̀mí ìyá àgbàlagbà kan
Ìyá àgbàlagbà kan pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ lẹ́yìn tí ilé kan dàwó ní òwúrọ̀ ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrìndínlógún oṣù Kọkànlá ọdún 2023 ní òpópónà Oloto, agbègbè Oyingbo ní ìpínlẹ̀ Eko.
Àjọ tó ń rí sí ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní Eko, Lagos State Emergency Management, LASEMA nínú àtẹ̀jáde kan ní ilé tó dàwó ló ṣokùnfà ìkú ìyá náà.
LASEMA ní kò sí ẹlòmíràn tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún.
Wọ́n ṣàlàyé pé irin tí wọ́n fi di ilé náà mú ló ṣàdédé wó lulẹ̀ ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ kú ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀dógún lọ́jọ́bọ̀ tó sì fa kí ilé náà dàwó.
LASEMA ní ilé náà ti gbó tí wọn kò sì ṣe àmójútó rẹ̀ mọ́.
Wọ́n ní àwọn ti kàn sí àjọ tó ń mójútó ọ̀rọ̀ ilé ní ìpínlẹ̀ Eko ìyẹn Lagos State Building Control Agency (LABSCA).
Bákan náà ni wọ́n fi kun pé àwọn ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ láti fi mọ̀ bóyá àwọn ènìyàn kò há sínú ilé náà.