You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ọ̀pọ̀ èèyàn di àwátì lẹ́yìn tí ọkọ̀ ojú omi ńlá kọlù afárá l’Amẹrika
Akojọpọ awọn iṣẹlẹ kaakiri agbaye
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Olumide Owaduge and Olubusola Afolayan
Ọkùnrin tó ṣá ìyàwó rẹ̀ nítorí ẹ̀sùn yíyan àlè gbé ‘snipper’ mu ní Edo
Agbẹ kan, Friday Omosigho, ti gbẹmi ara rẹ nipinlẹ Edo lẹyin to ṣa iyawo rẹ pa lori ẹsun yiyan ale.
Iroyin ni ilu Ehiozevbaru, ni ijọba ibilẹ Uhunmwode ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, oloogbe naa ti kọkọ fẹsun yiyan ale kan iyawo rẹ, Mercy Omosigho, to si fi ọrọ naa to awọn agbagba ilu leti lati da si ọrọ ọhun.
Ẹnikan ti ọrọ naa ṣoju rẹ sọ pe “Lẹyin ti awọn agbagba da si ọrọ naa tan lo lọ ṣa iyawo rẹ lada ninu oko, to si fi silẹ ninu agbara ẹjọ rẹ.”
“Lẹyin naa lo sọ fun aburo rẹ pe oun ti pa iyawo oun pa, ko to lọ gbe majele ‘snipper’ jẹ.”
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Edo, Chidi Nwabuzor, to fidi iroyin na mulẹ sọ pe o ṣeeṣe ko jẹ pe snipper ni oloogbe naa gbe mu nitootọ.
O fi kun pe awọn ọlọpaa ti gbe oku ọkunrin ọhun lọ sile igbokupamọsi.
Ẹwẹ, o ni iyawo oloogbe naa ko ku, awọn si ti gbe lọ sile iwosan nibi to ti n gba itọju lọwọ, iwadii si ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.
Wọ́n dábẹ́ fún Fatmata tán ló kú lọ́jọ́ kejì- Olólùfẹ́ Fatmata
Súnkẹrẹ-fàkẹrẹ àti òjò àrọ̀rọ̀dá ni kò tíì jẹ́ ká parí ojú ọ̀nà márosẹ̀ Eko sí Ibadan – Ìjọba àpapọ̀
Ijọba apapọ ti da ojo arọrọda ati sunkẹre-fakẹrẹ lẹbi fun ikuna rẹ lati pari iṣẹ oju ọna marosẹ Eko si Ibadan ni ipari oṣu to kọja.
Ọga agba ileeṣẹ to n ri si atunṣe oju popo, Federal High Ways, ni guusu iwọ oorun Naijiria, Ademola Kuti, lo fi ọrọ naa lede ninu ifọrọwerọ kan pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels.
Lẹyin ti ijọba ti kọkọ kuna lati pari iṣẹ atunṣe oju ọna marosẹ naa lopin ọdun to kọja, minisita fun ọrọ iṣẹ ati ile gbigbe, Raji Fashola tun da ipari oṣu Kẹrin ọdun yii lati pari iṣẹ naa.
Ademola Kuti ni “Lootọ ni a sọ pe a maa pari iṣẹ naa nipari oṣu Kẹrin amọ a kuna nitori awọn idi kan.”
“Lara awọn idi naa ni ojo arọrọda ati sunkẹre-fakẹrẹ ọkọ to n waye ni gbogbo igba loju ọna naa.”
O wa ṣeleri pe ijọba yoo yanju iṣẹ naa laipẹ, bo tilẹ jẹ pe ko sọ ni pato akoko ti wọn yoo pari rẹ.
O ni “Bi a ṣe n wọ inu oṣu Karun un lọ yii, igbagbọ wa pe ojo yoo rọ lọpọlọpọ eyii ti yoo mu ki iṣẹ naa ṣoro, amọ a fẹ fi da awọn eeyan wa loju pe a wa ni ikalẹ lati yanju iṣẹ ọhun.”
“Koda, a ti ṣi ọna OPIC si Kara Bridge ati Long Bridge, iṣẹ to ku sibẹ ko ju kilomita kan pere, a ti si ṣetan lati yanju rẹ laipẹ.”
Ìjọba Egypt ti ṣílẹ̀kùn ibodè rẹ̀ fún àwọn ọmọ Naijiria tí ogun lé kúrò ní Sudan
Ijọba apapọ ti sọ pe ijọba Egypt ti ṣilẹkun ibode rẹ fun awọn ọmọ Naijiria ti ogun le kuro ni Sudan.
Ajọ to n ri si ọrọ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okeere, NIDCOM, lo sọ bẹẹ ninu atẹjade kan loju opo Twitter rẹ lẹyin wakati mẹfa to kọkọ sọ pe awọn eeyan naa ṣi ha si ẹnubode orilẹ-ede ọhun.
O fi kun pe nibayii ti awọn eeyan naa ti wọ Egypt, wọn yoo bẹrẹ si n ko wọn lati ibẹ pada wale si Naijiria.
“Atẹjade naa ni, pẹlu iranlọwọ Aarẹ Buhari, ijọba Egypt ti ṣilẹkun ibode rẹ fun awọn ọmọ Naijiria lati gba ibẹ kọja.”
O fi kun pe ọkọ ofurufu ileeṣẹ ọmọ ogun NAF C 130 ti wa nikalẹ ni papakọ ofurufu Aswan lati ko awọn eeyan ọhun wale.
Wo oríṣiríṣi ìgbádun ibálòpọ̀ láwọn orílẹ̀èdè mìíràn
Ìjọba Cuba wọ́gilé àyájọ́ òṣíṣẹ́ nítorí ọ̀wọ́ngógó epo bẹntirò, Ìdì réè tí Ìjọba Cuba ṣe wọ́gilé àyájọ́ òṣíṣẹ́
Ayajọ oṣiṣẹ to yẹ ko waye ni orileede Cuba ni ijọba ti wọgile tori ọwọngogo epo bẹntiroo to n ba raalu finra.
Ayajọ yi jẹ ọjọ kan pato tawọn oṣiṣẹ ijọba a maa ṣe orisi eto ni paapa ikorajọ si ojude Revolution Square eleyi to wa ni olu ilu ilẹ naa Havana.
Ijọba a maa pese awọn ọkọ ti wọn yoo fi gbe awọn oṣiṣẹ ẹka ijọba lorisi ṣugbọn ọwọngogo epo bẹntiroo gbegidina iru nkanbayi lọdun yi.
A gbọ pe aarẹ Miguel Diaz-Canel lo wọgile ajọdun ayajọ naa.
Ko si ọjọ miran ti orileede yi fi n gboṣuba kaare fawọn ajijagbara ilẹ naa to da bi ọjọ yi ninu oṣu Kaarun.
Iwọgile ayajọ yi lorileede Cuba ṣafihan bi nkan ko ṣe rọgbọ lorileede yi.
Lọpọ ibi lawọn awakọ ti n to sile epo toun ti pe ko si eto irina to munadoko eleyi ti wọn yoo fi gbe ọpọ awọn dokita,olukọ ati awọn agbẹ.
Ofin ijiya ti orileede Amẹrika gbe lori ijọba ilẹ naa da kun aito awọn ohun amayederun ni orileede Cuba.
O ti to nkan bi ọgọta ọdun bayii ti Amẹrika ti gbe ijiya lori Cuba.
Irọ́ ni pé a máa kó owó naira tuntun kúrò nílẹ̀ – CBN
Banki apapọ Naijiria, CBN, ti sọ pe irọ ni iroyin to n lọ nigboro pe oun yoo ko owo nairan tuntun kuro nilẹ.
Agbẹnusọ banki ọhun,Isa AbduMumimas lo fi ọrọ naa lede ninu atẹjade kan niluu Abuja.
Atẹjade naa ni “Iroyin ẹlẹjẹ kan to n lọ nigboro ti to wa leti pe a fẹ ko owo ₦1000, ₦500 ati ₦200 tuntun kuro nilẹ.”
“A fẹ ko ye gbogbo muutumuwa pe irọ ni iroyin naa, ati pe awọn to fẹ lati da ipaya sọkan awọn araalu lo n pin irufẹ iroyin bẹẹ kiri.”
“A fẹ ki awọn araalu mọ pe owo naira aatijọ ati tuntun naa lraalu awọn ṣi le maa na papọ bo tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ijọba to n tẹ owo tuntun naa ti n ko jiṣẹ fun CBN.”
“Lai ṣe aniani, awọn araalu le maa na owo ati ati owo tuntu lọ titi di ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023 yii ti a o ko owo naira atijọ naa kuro nilẹ patapata.”
Ti ẹ ko ba gbagbe, ọdun to kọja ni CBN tẹ owo tuntun sita to si kede pe owo naira atijọ ko ni ṣe itẹwọgba mọ to si kọ lati ko owo tuntun sita.
Eyii to mu inira ba ọpọ ọmọ Naijiria, koda ẹmi awọn eeyan kan lọ si.
Bí a ṣe ná $1.2m tí a fi yá bọ́ọ̀sì tó kó àwọn ọmọ Naijiria kúrò ní Sudan rèé – Ijọba apapọ
Ijọba apapọ ti tu pẹrẹpẹrẹ bo ṣe na $1.2 miliọnu owo ilẹ Amẹrika to fi ya awọn bọọsi to fi ko awọn ọmọ Naijiria kuro ni Sudan lọ si Egypt.
Alaga igbimọ to n ri si bi wọn ṣe ko awọn eeyan naa kuro ni Sudan, Nasir Sani-Gwarzo lo ṣalaye ọrọ ọhun lẹyin ipade bonkẹlẹ kan to waye niluu Abuja.
O ṣalaye pe ẹgbẹrun lọna ọgbọn dọla lawọn san lati gba bọọsi kọọkan to ko awọn eeyan naa, ati pe ogoji bọọsi lawọn gba.
Sani-Gwarzo sọ siwaju si pe idiwọ ti awọn eeyan naa ri lẹnubode Egypt ko ṣẹyin bi banki apapọ, CBN, ko ṣe tete fi owo naa ranṣẹ ati bi ijọba Egypt ṣe kọ jalẹ pe awọn eeyan ọhun gbọdọ ni iwe irinna ki wọn to le wọn orilẹ-ede wọn.
Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn to ni bọọsi naa kọ sọ pe awọn ko ni bẹrẹ iṣẹ ayafi ti wọn ba kọkọ gba owo iṣẹ, ati pe o ṣoro lati fi owo ranṣẹ si Sudan lai lo alarena.
O fi kun pe gbogbo bi igbesẹ naa ṣe lọ lawọn fi to ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS atawọn ileeṣẹ alabo mii ti ọrọ naa kan leti.
Igbẹsi yii lo n waye lẹyin ti awọn araalu n tabuku ijọba Naijiria owo naa latari bi ọpọ eeyan ṣe gbagbọ pe owo ti ijọba kede pọ ju iye owo to na lori eto naa lọ.
Èèyàn mẹ́rìndínlógún jóná gúrúgúrú nínú ìjàmbá ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Osun
Ko din ni eeyan mẹrindinlogun to ti jona kọja mimọ bayii latari ijamba ọkọ kan to waye lagbegbe Odeomu, nipinlẹ Osun.
Iwaju ile epo Mat Oil ni ọkọ akero bọọsi Maxda kan to ni nọmba APP834XT ati ọkọ ayọkẹlẹ Lexus to ni nọmba LSR304HW ti fori sọ ara wọn.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ loju popo, FRSC nipinlẹ Osun, arabinrin Agnes Ogungbemi, to fidi ijamba naa mulẹ sọ pe lara awọn eeyan naa jona guruguru.
O sọ siwaju si pe wọn ti ko awọn to farapa lọ sile iwosan Ise-Oluwa to wa niluu naa fun itọju.
Lara awọn ti ijamba naa kan ni agbalagba mọkanla ati ọmọ wẹwẹ marun un.
Iwadii fi han pe ere asapajude lo ṣokunfa ijamba ọkọ ọhun.
Wọn ti wa ko oku awọn to jade laye lọ sile igbokupsamọsi to wa nile iwosan fasiti Ladoke Akintola to wa niluu Osogbo.
Ẹwẹ, ọga agba FRSC, Dauda Ali Biu, ti ke si awọn araalu lati ṣọra fun kiko awọn ohun to le bu gbamu bii gaasi sinu ọkọ wọn.
Lónìí ni súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ojú ọ̀nà márosẹ̀ Lagos-Ibadan yóò dópin – Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun
Gomina ipinlẹ Ogun, Dapo Abiodun ti sọ pe oni ni sunkẹrẹ-fakẹrẹ yoo dopin loju ọna marosẹ Eko si Ibadan.
Abiodun ni awọn agbaṣẹṣe to n ṣe iṣẹ atunṣe ọna ọhun lagbagbe Kara ti fi da oun loju pe iṣẹ wọn yoo pari lonii, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2023, ti ọna naa yoo si di ṣiṣi fun awọn eeyan lati maa gba.
Gomina Abiodun lasiko to ṣabẹwo sibẹ sọ pe inira ti awọn araalu n dojukọ en kọ oun lominu, inira awọn araalu yoo si dopin laipẹ.
O ni “Mo duro nibẹ lọjọ Ẹti, mo si sọ fun awọn agbaṣẹṣe agbegbe Kara loju ọna naa pe inira ti awọn eeyan n la kọja nibẹ ti pọ ju.”
“Inu mi dun pe wọn fi da mi loju pe iṣẹ agbegbe Kara to n da sunkẹrẹ-fakẹrẹ silẹ ni opopona ọhun yoo pari, o pẹ ju, lọjọ Isinmi, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹrin ti a wa yii.”
Gomina Abiodun ni ọkan oun balẹ pe ileri ti awọn agbaṣẹṣe naa ṣe fun oun ko ni yẹ, awọn araalu yo si bẹrẹ si n gbadun opopona naa laipẹ.
O wa rọ awọn araalu to n gba opopona ọhun lati ṣe suuru nitori irọrun yoo de ba wọn laipẹ jọjọ.
Ọdun 2013 ni Aarẹ ana, Goodluck Jonathan ṣe ifilọlẹ atunṣe opopona marose Eko si Ibadan naa, to si gbe iṣẹ rẹ fun ileeṣẹ Julius Berger ni owo ti iye rẹ to ₦167 biliọnu.
Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ tọkọ-taya tó jí ara wọn gbé ní ìpínlẹ̀ Eko láti gba ₦3m lọ́wọ́ àwọn mọ̀lébí wọn
Ọwọ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti tẹ tọkọ-taya kan ti wọn ji ara wọn gbe lọna ati gba owo ti iye rẹ to miliọnu marun un naira lọwọ awọn mọlẹbi wọn.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin lo fidi iroyin naa mulẹ fun ileeṣẹ iroyin ijọba apapọ, News Agency of Nigeria.
Hundeyin sọ pe ọwọ tẹ tọkọ-taya ọhun lẹyin ti ọkan lara awọn mọlẹbi wọn sọ fun ọlọpaa pe wọn ti ji awọn eeyan naa gbe.
O ni awọn mejeji ti jẹwọ lagọ ọlọpaa pe lootọ lawọn ji ara awọn gbe lọna ati ko owọ ti iye rẹ miliọnu mẹta naira jọ lati fi ra ile awọn to wa lagbegbe Badagry pada.
Alukoro ọlọpaa naa sọ siwaju si pe “Ọkunrin naa lo mu aba ọhun wa fun iyawo rẹ, ko si sẹ lasiko to de agọ ọlọpaa.”
“O ni oun mọọmọ ṣe bẹẹ ni lọna ati ra ile awọn to wa ni Badagry pada pẹlu miliọnu mẹta naira.”
“Ọkunrin naa sọ pe oun mọọmọ ji ara oun gbe lọna ati le gba owo lọwọ awọn ibatan oun to wa loke okun, ti wọn si jẹ ọlọla.”
“Afurasi naa ni ti awọn mọlẹbi oun ba gbọ pe wọn ti ji oun ati iyawo oun gbe, awọn mọlẹbi oun yoo ba awọn ajinigbe naa dunadura, wọn yoo si fi owo ranṣẹ.”
Hundeyin pari ọrọ rẹ pe awọn mejeji ṣi wa ni ile wọn ti wọn ni awọn fẹ ra pada naa lasiko ti ọlọpaa ṣabẹwo sibẹ ni Badagry, koda awọn mejeji, atawọn ọmọ wọn ni wọn ba ninu ile ọhun.
Lára àwọn ogún rere tí Ààrẹ Buhari yóò fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ Naijiria ni ètò ìlera tó péye – Lai Mohammed
Minisita fun iroyin ati aṣa, Lai Mohammed, ti sọ pe lara awọn ogun rere ti Aarẹ Muhammadu Buhari yoo fi silẹ fun awọn ọmọ Naijiria ni eto ilera to peye.
Lai Muhammed lo sọ ọrọ yii lasiko ti wọn n ṣi ile iwosan onibusun ọgọrin kan niluu Oro, ni ijọba ibilẹ Irepodun, nipinlẹ Kwara.
Ile iwosn naa ni ọọfisi olubadamọran pataki si Aarẹ lori eto idagbasoke, SDG, ṣe onigbọwọ rẹ.
Eto yii lo waye nibi ayẹyẹ “Oro Day” to waye niluu naa, nibi ti wọn ti n ko owo ti iye rẹ to ẹẹdẹgbẹta miliọnu naira jọ fun idagbasoke egbegbe ọhun.
Yatọ si ile iwosan yii, wọn tun kọ ile iwosan toni ogoji ibusun mii siluu Igbaja, eyii to waye lati ipasẹ minisita ọhun, ati ọọfisi SDG.
Lai Muhammed sọ pe ijọba Aarẹ Buhari ko fi eto ilera awọn araalu jafara lo ṣe fọwọsi akanṣẹ iṣẹ ọhun.
O ni oniruru aṣeyọri lo ti waye lẹka eto ilera Naijiri lasiko iṣejọba Buhari, lara rẹ ni bi ajọ WHO ṣe kede pe arun polio ti di ohun itan ni Naijiria.
Ìjọba lù wá ní jìbìtì, gba ilẹ̀ wa - Àwọn olùgbé ìlú Ibadan figbe ta
‘’Ìdí nìyíí tí a fi sún ètò ìkànìyàn oͅdun 2023 sí iwájú’’
'Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló máa ń bú mi pé mo fẹ́ ẹni tó ní ìpèníjà ara àmọ́ ohun tó mú mi fẹ́ ọkọ mi nìyí'
Irọ́ ni gbogbo ohun tí ìyàwó mi ń sọ nípa mi - Dókítà tó ń jẹ́jọ́ ìfipábánilopọ̀ sọ fún ilé ẹjọ́
Ẹ wo bí Mr Success ṣe ń dáhùn ìbéèrè lédè Yorùbá
Àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé gbọdọ́ gbẹ́sẹ̀lé ìwé ìrìnnà Buhari àti mọ̀lẹ́bí rẹ̀ lẹ́yìn May 29 – PDP
Ẹgbẹ oṣelu PDP ti ke si awọn orilẹ-ede agbaye lati gbẹsẹle iwe irinna Aarẹ Muhammadu Buhari atawọn ẹbirẹ ki wọn ma le rinrinajo lọ ilẹ okeere mọ lẹyin saa rẹ loṣu to n bọ.
Ọrọ naa jade lasiko ti PDP n fesi si ọrọ kan ti Buhari sọ pe ọgbọn agbọnju lo jẹ ki awọn ẹgbẹ alatako lulẹ ninu ibo Aarẹ to waye lọdun yii.
Agbẹnusọ PDP, Debo Ologunagba sọ ni ọọfisi ẹgbẹ ọhun pe o ṣe pataki lati fofin irinna de Buhari nitori oun funra rẹ lo sọ pe ajọ European Union gbọdọ da seria fun ẹnikẹni to ba di eto iṣejọba awara lọwọ, to si tun faye gba magiomago ibo.
PDP ni awọn orilẹ-ede agbaye naa ko gbọdọ gba Buhari laaye lati ṣabẹwo silẹ wọn nitori bo ṣe ko ẹrẹ ba iṣejọba awara ni Naijiria.
Ẹgbẹ naa sọ si siwaju si pe ọrọ ti Buhari nipa awọn ẹgbẹ alatako naa ko tọ, nitori irufẹ ọrọ bẹẹ le ṣakoba fun irẹpọ to wa laarin awọn ọmọ Naijiria.
Ologunagba sọ siwaju si pe ọrọ naa tun le ṣakoba fun igbẹjọ awọn to ti pe ẹjọ tako esi ibo Aarẹ to waye loṣu Keji ọdun yii, Buhari si gbọdọ jẹ iya to tọ fun ọrọ ọhun.
Gẹgẹ̣ bii ohun to sọ, ọpọ eeyan lo fẹnuko pe eto idibo Aarẹ ọdun yii lo buru julọ ninu gbogbo idibo to ti n waye ni Naijiria.
O pari ọrọ rẹ pe Aarẹ Buhari ti ṣẹ niwọn igba ti e to idibo to buru jai naa ti le waye labẹ iṣakoso rẹ.
Ọmọ ọdún méjìdínlógún dèrò àgọ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Oyo lórí ẹ̀sùn pé ó ṣekúpa bàbá rẹ̀
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti fi ṣikun ofin mu ọkunrin ẹni ọdun mejidinlogun kan, Taofeek Adeagbo, lori ẹsun pe o lu baba rẹ pa.
Ọlọpaa tun mu iya afurasi naa pe o kọ lati sọrọ soke lẹyin ti ọdọkunrin naa lu baba rẹ pa.
Nigba to n fi oju awọn afurasi ọhun atawọn mii lede niluu Ibadan, alukoro ileẹṣẹ naa, Adewale Osifeso sọ pe ilu Tede, ni ijọba ibilẹ Atisbo ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Osifeso sọ fun awọn akọroyin pe iwadii ọlọpaa fi han pe ṣe ni afurasi ọhun la irin mọ baba rẹ lori, ti oloogbe naa si gba ibẹ ku.
O ni “Afurasi naa jẹwọ pe iya oun Adeagbo Rashidat mọ pe oun ti lu baba oun pa, amọ o yan lati ṣe ọrọ naa ni oku oru, ṣugbọn a ti fi pamper ofin mu Rashidat naa pẹlu.”
Nigba ti Rashidat ba awọn akọroyin sọrọ, o ni ṣe loun dede ji laarọ ọjọ ti iṣẹlẹ naa waye, ti oun si ba oku ọkọ oun nilẹ to ti dagbere faye.