Kò dín ní 7,000 èèyàn tó ha ́sí ẹnubodè Egypt lẹ́yìn tí ogun lé wọn kúrò ní Sudan – Ìjọba àpapọ̀
Ijọba Naijiria ti sọ pe ko din ni ẹgbẹrun meje eeyan to ti ha si ẹnubode orilẹ-ede Egypt bayii lẹyin ti ogun le wọn lati Sudan.
Alaga ajọ to n ri si ọrọ ọmọ Naijiria nilẹokeere, NIDCOM, Abike Dabiri-Erewa lo fi ọrọ naa lede.
O ni awọn eeyan naa, ti ọpọ ọmọ Naijiria wa lara wọn ni wọn ha si ẹnubode Egypt, ti wọn ko si ri aye lati wọn ilẹ naa.
Ninu atẹjade kan ti alukoro NIDCOM, Gabriel Odu, fi lede, o ni ipo ti awọn eeyan naa wa n kọ ijọba Naijiria lominu.
Atẹjade naa ni “Dabiri-Erewa sọ pe o le ni ẹgbẹrun meje eeyan, ti awọn ọmọ Naijiria walara wọn, ti wọn ko gba laaye lati rekọja wọ orilẹ-ede Egypt lẹnubode ilẹ naa lati igba ti wọn ti wọn ti de ibẹ lati alẹ ana.”
Ọọfisi ijọba Naijiria ni Egypt ti n ṣiṣẹ takuntakun lati ri pe awọn eeyan ọhun rekọja si Egypt amọ ijọba Egypt n sọ pe awọn to ba fẹ wọ ilẹ awọn gbọdọ ni iwe irina lọwọ.
“O ti wa rọ ijọba Egypt lati fun awọn eeyan naa lanfani lati gba ilẹ rẹ kọja ki wọn le pada si orilẹ-ede wọn lai si idiwọ kankan.”
Iṣẹlẹ yii lo n waye lẹyin ti minisita ọrọ ilẹ okeere, Geoffrey Onyeama, kede pe ijọba Naijiria ti ya ọkọ akero ogoji ni owo iye rẹ to $1.2m lati fi ko awọn ọmọ Naijiria to ha si Sudan kuro nibẹ lọ si Egypt ki wọn le pada wale.