Ọmọdé mẹ́ta wà nínú àwọn èèyàn mẹ́fà tí afurasí gún lọ́bẹ pa ní China
Eeyan mẹfa to fi mọ awọn ọmọde mẹta kan wa ninu awọn ti afurasi kan gun lọbẹ pa ni ile ẹkọ jẹleosinmi kan ni agbegbe Guangdong ni China.
Ọlọpaa sọ pe awọn ti mu afurasi arakunrin ẹni ọdun marundinlọgbọn kan ni ilu Lianjiang.
Ninu awọn to padanu ẹmi wọn ninu iṣẹlẹ yi la ti ri awọn obimeji ati olukọ kan gẹgẹ bi ileeṣẹ iroyin AFP ti ṣe jabọ.
Eeyan kan naa farapa ninu iṣẹlẹ ọhun.
Ni ọjọ Aje ni a gbọ pe iṣẹlẹ yi waye ni nkan bi ago mẹjọ ku ogun iṣẹju eleyi to ṣe deede ago mejila oru ku ogun iṣẹju ni onka GMT.
O ṣẹlẹ nigba ti awọn obi n ja awọn ọmọ wn sile ẹkọ.
Awọn ọlọpaa mu arakunrin ni nkan bi ago mẹjọ ti wọn si sọ pe iṣẹlẹ ikọlu ni ohun to ṣẹlẹ yi.
Oniṣowo kan to ni ṣọọbu lagbegbe naa sọ pe awọn ọlọpaa ti gbegi dina agbegbe naa.
Niṣe lawọn araalu gbarata bi fọnran fidio iṣẹlẹ naa ṣe bẹrẹ si ni ran kaakiri loju opo ayelujara.
Wọn ko faaye gba gbigbe ibọn kaakiri ni China.
Eleyi mu ki ọpọ iṣẹlẹ ikọlu si araẹni ma waye nipa gigun awọn eeyan lọbẹ lẹnu ọdun meloo kan sẹyin ni China.
Koda a gbọ pe eeyan kan da kẹmika lati fi da ọgbẹ sara awọn akẹkọọ aadọta to wa ninu kilaasi wọn.
BBC ti ṣe iwadii to ṣafihan iṣẹlẹ igunilọbẹ mẹtadinlogun ni awọn ile ẹkọ to fi mọ fasiti lati ọdun 2010.
Mẹwaa ninu awọn iṣẹlẹ yi waye laarin ọdun 2018 ati 2023.