Ka nípa ohun tó fa ìjà tí àwọn ẹyà Hausa fí n béèrè ilẹ̀ bàbá wọn lọ́wọ́ ìjọba Sudan

Oríṣun àwòrán, AFP
Awọn ẹya Hausa kan ti n beere pe ki ijọba ni orilẹede Sudan ri awọn gẹgẹ bi ẹni to ni awọn ilẹ to wa ni agbegbe Blue Nile .
Eyi ko ṣẹyin ija to bẹ silẹ laarin wọn lati opin ọsẹ laarin ati awọn ẹya Berta to kọḳo wa ni agbegbe naa.
O ti le ni ọgọrun eniyan ti ẹmi rẹ ti lọ si iṣẹlẹ naa, ti wọn si ti le ẹgbẹgbẹrun awọn ẹya Hausa naa kuro ni ilẹ wọn.
Iṣẹlẹ yii ti fa gbọnmi si omi o to, ti ọpọ eniyan si faraya pẹlu ifẹhọnuhan kaakiri Sudan fun ihuwasi yii.
O kere tan eniyan mẹjọ miran ni awọn ọlọpaa ti ṣekupa ninu ikọlu naa lasiko ifẹhọnuhan.
Bawo ni awọn Hausa ṣe de Sudan?
Iha ẹkun Iwọ oorun ilẹ Afrika ni awọn ẹya Hausa yii ti wa, ti wọn si tẹdo si orilẹede Sudan lati ẹgbẹgbẹrun ọdun sẹyin.
A gbọ pe pupọ awọn Hausa wọnyii maa n duro sinmi si ilẹ yi lasiko ti wọn baa n n rinrinajo lọ sẹ Hajj ni Makkah.
Iwadii fihan pe awọn amunisin Ilẹ Gẹẹsi ti wọn ko kogun ja ọpọlọpọ ẹya Hausa lo mu ki wọn sa kuro ni ilẹ wọn lẹyin ti ikọ oogun awọn akonilẹru naa bori Sultan ti Sokoto ni ọdun 1903.
Kilo fa ija lasiko yii?
Ọrọ ilẹ lo fa ija laarin awọn Hausa ati awọn ẹya miran ni agbegbe Blue Nile ni Sudan.
Ni igba ikonilẹru ni awọn akonilẹru lati Ilẹ Gẹẹsi da oko to tobi julọ lagbaye nigba naa si agbegbe Blue Nile ati While Nile, ti wọn pe orukọ rẹ ni Gezira project ni ọdun 1911, to si jẹ awọn ẹru ni wọn n lo lati fi ṣe iṣẹ gbingbin owu fun awọn ile iṣẹ nla nla ni Ilẹ Gẹẹsi.
Lẹyin ti wọn fofin de kikoni lẹru nigba naa ni wọn fun awọn Hausa to le ni ẹgbẹrun mẹta ni anfaani lati duro si ibẹ, ki wọn si maa gbe agbegbe ọhun.
Amọ lati ibeere ni awọn to ni ilẹ naa ti fi aidunnu wọn han si bi wọn ṣe fun awọn Hausa ni ilẹ ni agbegbe naa lati jogun.
Lati igba naa lọhun ni wọn ti n beere fun ẹtọ lati jẹ ọmọ ilẹ Sudan ni gbogbo ọna, amọ wọn ko gba fun wọn.
Ifẹhọnuhan le ṣe ipalara fun dida ijọba tiwantiwa pada ni Sudan
Ni Oṣu to kọja ni gomina tuntun jẹ ni agbegbe Blue Nile naa to si fun awọn Hausa ọhun ni aaye lati yan Emir tiwọn ni ipinlẹ naa, eleyii ti ko dun mọ awọn ara ibilẹ naa ninu.
Olori ijọba ibilẹ nibẹ, iyẹn Berta ni ki awọn Hausa naa ma ni Emir amọ Sheriff, eleyii ti ko dun mọ wọn ninu.
Bakan naa ni awọn araalu wa n beere fun ki wọn gba ipo lọwọ awọn Hausa naa gẹgẹ bi ọmọ onilu, eleyii to fa ifẹhọnuhan.
Ibẹru wa pe ti wọn ko ba dẹkun ifẹhọnuhan naa ijọba Ologun le lo eleyii lati maṣe gba iṣejọba tiwantiwa laaye ṣaaju idibo ni ọdun to n bọ.
























