Ìdàrúdàpọ̀ gba ọ̀pọ̀ ìlú ní Osun, èèyàn kan ku, ọ̀pọ̀ farapa bí APC àti Accord ṣe gbéná wojú ara wọn

Diẹ lara awọn to farapa ninu ikọlu  awọn janduku to walye ni ipinlẹ Osun, wn n fi oju ọgbẹ wọn han

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Lakọlakọ ni iro ibọn n ro niluu Osogbo ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Osun atawon agbegbe mi-in nipinlẹ naa lanaa ode yii, ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan-an oṣu Kẹfa ọdun 2026.

Eyi ri bẹẹ latari ija to bẹ silẹ laaarin awọn alatilẹyin ẹgbẹ oṣelu APC ati Accord, eyi to pada mu ẹmi eeyan kan lọ, ti ọpọ eeyan si farapa.

Awọn agbegbe bii Ile Ife, Owode, Aisu, Olaiya ati Oke-Fia ni rogbodiyan naa tun kan, eyi to mu araalu maa sa asala fun ẹmi wọn.

Bakan naa ni rogbodiyan naa tun waye nilu Ile Ife ati Ede.

Ọkan lara awọn eeyan to farapa fi oju ọgbẹ rẹ han

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ki lo ṣẹlẹ gan-an?

Iwadii fi han pe awọn alatilẹyin oludije fun ipo gomina ipinlẹ Osun ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Bola Oyebamiji, (AMBO) lo ṣeto iwọde kan lati fi atilẹyin wọn han si oloṣelu naa.

Wọn ṣeto iwọde naa bii ipolongo ibo ni imurasilẹ de ibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii.

Agbegbe Mayfair, niluu Ile Ife ni wọn ti bẹrẹ irin naa ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ. Abimbola Ajilesoro, aṣofin to n ṣoju Ife Central/Ife East/Ife North/Ife South l'Abuja lo si ko wọn sodi.

Nigba ti wọn de agbegbe Sabo ni iwọde wọn naa di nnkan mi-in, rogbodiyan bẹ silẹ.

Rogbodiyan ọhun bi a ṣe gbọ, bẹrẹ nigba ti awọn to n wọde bẹrẹ si i fa iwe alẹsode to n kede ẹgbẹ oṣelu keji ti wọn ri nibẹ ya.

Iroyin sọ pe iwe to n kede ipolongo ibo fun Gomina Ademola Adeleke ninu ẹgbẹ Accord ni awọn alatilẹyin APC naa n fa ya ni Sabo, ilu Ile Ife.

Eyi lo bi rogbodiyan naa, nigba ti awọn alatilẹyin ẹgbẹ Accord naa da a pada, to si di ija igboro.

Ọkan lara awọn eeyan to farapa fi oju ọgbẹ rẹ han

Oríṣun àwòrán, Screenshot

"Awọn nnkan ija oloro ni wọn lo, awọn ọmọ ita APC ati ti Accord ni wọn koju ara wọn"

O ṣoju mi koro kan ti ko darukọ rẹ, ṣalaye pe ibọn, ada atawọn nnkan ija oloro miran ni wọn bẹrẹ si I lo funra wọn, eyi to pada mu ibọn ba ẹnikan, ti awọn eeyan miran si farapa.

"Awọn ọmọ ita to n ṣiṣẹ fun APC ati Accord ni wọn doju kọ ara wọn.

"Wọn ba ọkada ọkan lara awọn ọmọ ita yẹn gan-an jẹ, wọn n yinbọn funra wọn bẹẹ ni wọn ṣa ara wọn ladaa."

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, lasiko ti rogbodiyan naa n lọ lọwọ n'Ile Ife, awọn kan tun bẹrẹ tiwọn ni Osogbo.

Awọn agbegbe bii Aisu, Owode-Ede, Aregbesola,Olaiya, Old Garage ati Oke Fia naa ko si fararọ l'Osogbo.

Bi iro ibọn ṣe n ro to n balẹ si ara awọn ọkọ̀ ero, bẹẹ lo ba awọn eeyan mi-in naa.

Ọlọja kan ni aṣita ibọn kọkọ ba ni Owode-Ede bii iroyin ṣe wi, ẹsẹkẹsẹ ni ẹni naa si dagbere faye.

Bakan naa ni ibọn ba baba agba kan ti wọn si sare gbe e lọ sile iwosan ijọba ipinlẹ Osun.

Lagbegbe Aregbesola, l'Osogbo, ibọn ba awakọ, bẹẹ ni fidio ṣafihan ikeji ti wọn ṣa ladaa ni ẹba ẹti.

Ọkan lara awọn eeyan to farapa fi oju ọgbẹ rẹ han

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Gomina Adeleke ṣabẹwo sile iwosan l'Osogbo, Ede, o rọ Tinubu atawọn olori ẹka aabo lati kilọ fun awọn eeyan wọn

Lẹyin iṣẹlẹ yii, Gomina Ademola Adeleke ti ipinlẹ Osun, ṣabẹwo si awọn eeyan to farapa ninu rogbodiyan naa.

Adeleke de UNIOSUN Teaching Hospital, l'Osogbo ati ile iwosan ijọba ipinlẹ Osun to wa l'Ede.

Ninu atẹjade ti Gomina Adeleke fi sita lori ọrọ yii lo ti ni:

"Awọn janduku oloṣelu Ambo ṣeto ikọlu apapọ si awọn olugbe Ile Ife, Ede ati Osogbo lonii.

"Lẹyin aburu ti wọn ṣe n'Ile Ife, awọn onikọlu naa kọri si Akoda, Owode, Olaiya, Old Garage, Okefia atawọn apa ibomi-in l'Osogbo.

"Awọn to ṣe ikọlu naa gbe ọkọ mẹẹẹdogun (15) ti wọn kọ AMBO si pẹlu fọto rẹ, wọn n wọde kiri lai jẹ pe ọlọpaa da wọn lẹkun.

"Awọn janduku meji ti wọn n pe ni Aleba ati Asiri lo lewaju awọn alatako yii.

"Nibi to si buru de, ileeṣẹ ọlọpaa Osun ko ti i wi nnkan kan lati da wọn lẹkun tabi mu awọn alatako naa."

Ọkan lara awọn eeyan to farapa fi oju ọgbẹ rẹ han

Oríṣun àwòrán, Screenshot

"Aarẹ Tinubu, Ribadu àti ẹyin ileesẹ alaabo, ẹ gba wa lọwọ rukeruke yii, ẹ wa da alaafia pada si ipinlẹ Osun"

Gomina Adeleke ṣapejuwe ikọlu naa bii eyi to buru jai, ti ko si idi kankan fun un lati waye, bi ko ṣe pe awọn eeyan naa kan ya oniwahala ni.

"Mo koro oju si ipa idarudapọ ti minisita to n ri si sisọ omi okun di owo, Gboyega Oyetola ati oludije dupo gomina Osun ninu APC, Bola Oyebamiji,ko ninu ọrọ yii.

"Itẹnulojumọlẹ yii ti n de ibi ti a ko le mu mọra mọ.

"Lati bii oṣu meloo kan ni mo ti n ni kawọn eeyan mi maa ṣe suuru, ti mo n rọ wọn pẹlu bi wọn ṣe n kọlu wa to."

Gomina Adeleke waa pe Aarẹ Bola Tinubu, Nuhu Ribadu to jẹ Oludamoran pataki lori eto aabo ni Naijiria, ọga agba ọlọpaa Naijiria, awọn DSS atawọn ẹṣọ alaabo yoku lati dide si ọrọ yii.

O ni wọn nilo lati dide ki rogbodiyan oṣelu ma baa gba ipinlẹ Osun karikari.

Bakan naa lo pe Gboyega Oyetola ati Bola Oyebamiji lati pe awọn eeyan wọn si iwa ọmọluabi.

Adeleke kilọ pe bi won ba tẹsiwaju bayii, o le da ipinlẹ Osun ru.

APC naa fesi: "Awọn alatilẹyin Adeleke lo doju kọ wa"

Ninu idahun rẹ si ọrọ yii, APC Osun sọ pe awọn ọmọ ita oloṣelu to faramọ Gomina Adeleke Ademola lo kọlu awọn.

Ninu atẹjade ti olori ikede ati iroyin fun igbimọ ipolongo ẹgbẹ naa, Remi Omowaiye, fi sita lo ti ṣalaye pe wọn ba mọto ẹgbẹ awọn jẹ ni Owode-Ede.

"Ọpọlọpọ awọn alatilẹyin AMBO ni wọn farapa gidi ninu ikọlu naa, bẹẹ ni wọn ba awọn dukia olowo iyebiye ẹgbẹ wa jẹ.

"Ki lo de to fi gbọdọ di ọran bi awọn oludibo ba fẹran oludije kan?

"Ki lo de ti gomina yoo maa fi ọna kan tabi ikeji kọju ija si awọn eeyan rẹ nitori pe wọn ko faramọ ẹgbẹ oṣelu to n ṣe?

"Iroyin sọ pe wọn ri awọn bọọsi ti wọn ya aworan Gomina Adeleke si, to kun fun awọn eeyan ti ọwọ wọn ko mọ, ti wọn n ṣafihan awon nnkan ija oloro ti wọn tun n yinbọn."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade ti APC fi da Adeleke lohun wi.

Ileesẹ ọlọpaa mu eeyan mẹta lori ikọlu oloselu naa

Ileeṣẹ ọlọpaa Osun ti sọ pe iwadii ti bẹrẹ lori iṣẹlẹ naa.

Alukoro ọlọpaa Osun, Abiodun Ojelabi, ṣalaye pe iṣẹlẹ naa ti de etigbọọ awọn.

O ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ lori rẹ, ọwọ si ti ba eeyan mẹta ti wọn n ko nnkan ija atawọn nnkan mi-in fawọn oloṣelu.

Awọn eeyan mẹta ti ọlọpaa Osun kede pe awọn mu naa ni Adekola Olayinka Abdulazeez; ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn,Omolara Ezekiel; ẹni ọdun mejidinlọgbọn ati Babatunde Azeez, ẹni ọdun mẹtalelọgbọn.

Afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun ni wọn pe wọn.

Awọn nnkan ti wọn ri gba lọwọ wọn bi wọn ṣe kede ni: Ibọn ilewọ oyinbọ mẹta,ọta ibọn ti wọn ko ti i yin, ibọn kan, awọn ọta ibọn meji mi-in ti wọn ko ti i yin, ada mẹrin ati aake mẹta.