Ṣé lóòótọ́ ni Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Osun ń hùwà kò kàn mí sí rògbòdìyàn òṣèlú àti ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ náà? Ohun tí a mọ̀ rèé

Agbarijọpọ awọn ọdọ ati awọn akẹkọọ ile ẹkọ gíga gbogbo to wa ni ipinlẹ Osun parapọ̀ ṣe ifẹhonuhan lori ọrọ eto aabo to mẹhẹ ati rogbodiyan oṣelu to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ naa.
Wọn ni iwọde naa tun da lori ẹsun ti wọn fi kan kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Osun, Ibrahin Gotan, pe kọ kọbi ara si ọrọ eto aabo ati ọrọ awọn janduku oloṣelu ti wọn n yinbon kaakiri ipinlẹ Osun.
Ti ẹ ko ba gbagbe pe, lọsẹ to kọja ni awọn janduku awọn oloselu n yinbon kaakiri ilu Owode-Ede ati Osogbo ti eleyii si mu ki ọpọlọpọ eeyan ko fara pa ninu ikọlu naa.
Fọnran kan to ti gba ori ayelujara pa bayii ṣafihan bi Ọba Jimoh Olanipekun Ataoja ti ilu Osogbo ṣe pariwo sita pe awọn agbenipa ṣe ikọlu si aafin oun ti wọn si yin ìbọn lakọ lakọ.
Kabiyesi ni titi di akoko yii, Ọga agba ọlọpaa ipinlẹ Osun ko ti i ri ẹnikankan mu ninu gbogbo awọn n to ṣiṣẹ laabi naa.
Eleyii lo mu ki awọn ọdọ ati awọn agbalagba ilu Osogbo dide lati ṣe iwọde lọjọ Aje.
Ninu ọrọ rẹ, Wale Balogun to jẹ ọkan lara awọn oluwọde naa, ni ohun ti o ṣẹlẹ ni orilẹ-ede Naijiria lọwọ lọwọ bayii gba amojuto ni kiakia, kii si ṣe ohun ti eeyan le mọ wo niran rara.
Balogun ni bi Ọga Ọlọpaa ipinlẹ Osun, Ibrahim Gotan, ṣe dakẹ si gbogbo rogbodiyan n to ṣẹlẹ ni ipinlẹ Osun lasiko yii ku diẹ kaato.
O wa rọ ọga agba ọlọpaa Naijiria wi pe ko gbe Ibrahim Gotan lọ si ipinlẹ miran ''latari bi o ṣe kọ eti ikun si gbogbo rogbodiyan n to lọ ni ipinlẹ Osun bayii.''
Olowu Emmanuel, ọkan lara awọn ọdọ naa tun salaye siwaju pe, araalu nilo eto aabo fun ẹmi ati dukia paapaa awọn akẹkọọ lati ile ẹkọ alakọbẹrẹ to fi de eyi to ga julọ.
Emmanuel fikun ọrọ rẹ pe ''bi ọpọ ẹmi awọn eeyan ipinlẹ Osun ṣe n ṣofo ni gbogbo igba lori ija oṣelu n jẹ ki ẹru ko mọ ba awọn ọdọ ati awọn akẹkọọ.
O wa rọ ijọba apapọ ati Ọga Ọlọpaa patapata ni orileede Naijiria lati da si ọrọ awọn janduku n to da omi alaafia ipinlẹ Ọsun ru.
Irọ nla ni gbogbo ẹsun ti wọn fi kan mi - Ọga ọlọpaa Osun
Ẹwẹ, Ọga Ọlọpaa ipinlẹ Oṣun, Ibrahim Gotan ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu gbogbo ẹsun ti ẹgbẹ oṣelu Accord ati awọn ọdọ to ṣe ìwọ́de fi kan oun rara.
Gotan ni oun n ṣiṣẹ oun takuntakun lai fi igba kan bọkan ninu rara, ati pe ọpọ awọn afurasi janduku ati ajinigbe lọwọ ọlọpaa ti tẹ ti wọn si wa nui atimọle bayii.
''Irọ to jinna si otitọ ni gbogbo ohun ti gomina Ademola Adeleke ati awọn ọdọ sọ pe mo n gbe lẹyin ẹgbẹ oṣelu kan.
Ko si ẹgbẹ oṣelu kankan t imo n ṣegbe lẹyin rẹ, mo n siṣe mi lati jẹ ki alaafia jọba ni ipinlẹ Osun,'' Kọmiṣọna ọlọpaa ipinlẹ Osun lo sọ bẹẹ.
Ọga Ọlọpaa naa wa rọ gbogbo awọn oloselu lati kọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ lakoko ti eto idibo ti n sun mọ ile bayii.
O tun kilọ pe ko gbọdọ si awọn ti yoo maa lo awọn janduku lati da omi alaafia ipinlẹ Ọsun ru.
Gotan wa fi gbogbo awọn olugbe ipinlẹ ọsun lọkan balẹ pe eto aabo ko ni mẹhẹ ati pe gbogbo awọn ti o n da ilu ru ni awọn yoo fi pampẹ ofin gbe.

























